Ǹjẹ́ Kì Í Ṣe Pé Apá Ò Fẹ́ Ká Ìwà Ibi Mọ́?
Ọmọdékùnrin kan rí nǹkan kan nílẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ mú un. Ohun tó ń bú gbàù ni, bó ṣe di afọ́jú àti aláàbọ̀ ara títí ayé rẹ̀ nìyẹn. Obìnrin kan gbé ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sọ nù, abẹ́ pàǹtí tí wọ́n ń dà sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ló jù ú sí. Òṣìṣẹ́ kan tí wọ́n dá dúró lẹ́nu iṣẹ́ padà lọ síbi iṣẹ́ náà, ó yìnbọn pa gbogbo àwọn tó rí, lẹ́yìn náà ló para rẹ̀. Ẹnì kan táwọn èèyàn kà sí ọmọlúwàbí èèyàn ń bá àwọn ọmọ kéékèèké tí wọn ò mọ nǹkan kan lò pọ̀.
Ó BANI nínú jẹ́ pé irú àwọn ìròyìn ìwà ibi báyìí ti wá pọ̀ gan-an lásìkò yìí. Èyí tó tiẹ̀ tún bani nínú jẹ́ jù ni pé, àwọn ìròyìn wọ̀nyí sábà máa ń kéré gan-an lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìròyìn bíi pípa odindi ẹ̀yà run àti ìròyìn àwọn apániláyà. Ọ̀rọ̀ olóòtú tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn kan lọ́dún 1995 sọ pé: “Tá a bá wo gbogbo láabi tó ti ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún [ogún], a lè pè é ní ọ̀rúndún Sátánì. Kò tíì sírú ọ̀rúndún bẹ́ẹ̀ táwọn èèyàn ní ọgbọ́n burúkú, tó sì ń wù wọ́n gan-an láti pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn nítorí ọ̀ràn kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀sìn, àti ipò táwọn èèyàn wà láwùjọ.”
Bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn tún ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́, wọ́n ń sọ ayé dẹlẹ́gbin, wọ́n ń lo gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ inú ayé nílòkulò, wọ́n ń pa àwọn ẹranko nípakúpa, débi pé àwọn ẹ̀yà ẹranko kan ti fẹ́rẹ̀ẹ́ run tán. Ǹjẹ́ aráyé lè borí gbogbo ìwà ibi yìí kí wọ́n sì mú kí ayé tún padà di ibi tó dára láti gbé, tí ọkàn èèyàn á sì tún balẹ̀? Àbí ńṣe ni gbígbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ yóò wulẹ̀ dà bí ìgbà téèyàn ń da omi sẹ́yìn igbá? Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé lórí ọ̀ràn ìwà ibi sọ pé: “Ó wù mí gan-an láti yí bí nǹkan ṣe ń lọ láyé padà, kí n mú kí ayé túbọ̀ dára sí i. Àmọ́, ó hàn gbangba pé ayé kò dára sí i.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ìwọ náà nìyẹn.
A lè fi bí ayé ṣe ń lọ báyìí wé ọkọ̀ òkun kan tó kọrí sínú òkun kan tó ń ru gùdù, tí ìgbì òkun náà ń le sí i, tó sì ń léwu sí i lójoojúmọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó fẹ́ láti kọrí síbi eléwu yẹn, síbẹ̀ pàbó ni gbogbo ìsapá láti kọrí síbòmíràn ń já sí. Ńṣe ni ọkọ̀ òkun ọ̀hún kàn ń lọ tààràtà sínú ìjì líle náà láìṣeé dá dúró.
A lè sọ pé jíjẹ́ tí ẹ̀dá èèyàn jẹ́ aláìpé wà lára ohun tó fa bí ipò nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i yìí. (Róòmù 3:23) Síbẹ̀, bí ìwà ibi ṣe pọ̀ tó, bó ṣe gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ tó, tí kò sì dáwọ́ dúró, lágbára kọjá ohun tá a kàn lè sọ pé èrò ibi ọkàn èèyàn nìkan ló ń fà á. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹnì kan tá ò lè rí àmọ́ tó lágbára tó sì jẹ́ ẹni ibi ló ń darí aráyé? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta lẹni náà, báwo la sì ṣe lè gba ara wa lọ́wọ́ rẹ̀. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
© Heldur Netocny/Àwọn fọ́tò Panos