ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 2/1 ojú ìwé 2-4
  • Ire Ní Ìdojú-ìjà Kọ Ibi—Ijakadi Àtọjọ́mọ́jọ́ Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ire Ní Ìdojú-ìjà Kọ Ibi—Ijakadi Àtọjọ́mọ́jọ́ Kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ire Yoo Ha Bori Ibi Lae Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Kí Ló Máa Ń Mú Ká Hùwà Rere Tàbí Búburú?
    Jí!—2010
  • Bí Ire Ṣe Máa Borí Ibi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Ẹ Má Ṣe Fi Ibi San Ibi Fún Ẹnì Kankan”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 2/1 ojú ìwé 2-4

Ire Ní Ìdojú-ìjà Kọ Ibi—Ijakadi Àtọjọ́mọ́jọ́ Kan

NINU aworan sinima awọn ọdún-àná, “àgbà akin” ni o sábà maa ń ṣẹgun awọn agbara ibi. Ṣugbọn otitọ kò tíì fi ìgbà kan rọrùn tobẹẹ rí. Ni ọpọ ìgbà ninu ayé gidi, ibi dabi eyi tí ń mókè.

Awọn irohin ti ń kópayàbáni nipa awọn ìwà ibi jẹ́ irohin ti a ń gbọ́ ni alaalẹ́. Ni ariwa United States, ọkunrin kan lati Milwaukee pa eniyan 11 ó sì kó òkú ara wọn ti a ti bajẹ yánnayànna sinu ẹ̀rọ-amú-nǹkan-dì-gbagidi rẹ̀. Lọ́hùn-ún ní guusu, ajeji kan ya wọnu ilé-oúnjẹ kan ni Texas ó sì bẹrẹ sii yinbọn laidawọduro fun iṣẹju mẹwaa, ni sísọ awọn eniyan 23 dòkú, ti ó ní oun funraarẹ ninu. Alatako alainitẹẹlọrun kan ni Korea ti iná bọ Gbọngan Ijọba awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó sì pa awọn olujọsin 14.

Kìí wulẹ ṣe pe awọn ìbújáde ibi wọnyi wà nikan ni ṣugbọn ibi ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ miiran ti ó nipa lori ayé wà pẹlu—ìpalápalù. A ṣírò rẹ̀ pe million kan awọn ará Armenia, million mẹfa awọn Ju, ati eyi ti ó ju million kan awọn ará Cambodia ni a ti parun ninu ìpalápatán ti ẹ̀yà tabi ti oṣelu ni kìkì ọrundun yii nikanṣoṣo. Ìwẹ̀mọ́ tonitoni ẹ̀yà, ìran, ati ti orilẹ-ede ti a fẹnu lasan pe bẹẹ ti lu ọpọlọpọ bolẹ ni Yugoslavia tẹlẹri. Kò sí ẹni ti ó mọ iye million awọn eniyan alaimọwọ-mẹsẹ ti a ti daloro lọna ìkà yika-aye.

Ọ̀ràn ibanujẹ bi iru iwọnyi fipá mú wa lati dojukọ ibeere adanilaamu naa, Eeṣe ti awọn eniyan fi ń huwa lọna bẹẹ? A kò lè saa gbà pe awọn ìwà-ìkà òǹrorò wọnyi jẹ iṣẹ́-ọwọ́ awọn diẹ ti ọpọlọ wọn dàrú. Gbigbooro ibi ti a ń ṣe ni ọrundun wa lasan fi irú alaye bẹẹ hàn gẹgẹ bi eyi ti kìí ṣe otitọ.

Ìwà ibi kan ni a tumọ si ọ̀kan ti ó ṣaitọ niti iwarere. Ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan ti ẹnikan ti ó lè yàn laaarin ṣiṣe rere ati ṣiṣe ibi ń dá. Lọna kan ṣáá agbara ironu rẹ̀ lọna ti iwarere di eyi ti ó di wíwọ́ tí ibi sì lékè. Ṣugbọn eeṣe ati bawo ni eyi ṣe ń ṣẹlẹ?

Awọn àlàyé tí isin fun ibi ni kìí fi ìgbà gbogbo tẹnilọrun. Ọlọgbọn-imọ-ọran Katoliki Thomas Aquinas jẹwọ pe “ọpọ awọn ohun rere ni a o mú kuro bi Ọlọrun kò bá fi ààyè gba ibi kankan lati wà.” Ọpọ awọn ọlọgbọn-imọ-ọran Protẹstanti ni oju-iwoye ti ó ri bakan naa. Fun apẹẹrẹ, gẹgẹ bi a ṣe sọ ọ́ ninu The Encyclopædia Britannica, Gottfried Leibniz ka ibi si “ohun ti ó wulẹ jẹ́ ki ire hàn ketekete sii ninu ayé, eyi tí ó ń mú pọ̀ sii nipa ifiyatọwera.” Ni èdè miiran, ó gbagbọ pe a nilo ibi ki a baa lè mọriri ire. Iru ironu bẹẹ dabi sisọ fun alárùn jẹjẹrẹ kan pe àrùn rẹ̀ wulẹ jẹ kìkì ohun tí a nilo lati lè mú ki ẹlomiran kan nimọlara wiwalaaye ati wíwàlálàáfíà nitootọ.

Awọn èrò ibi gbọdọ wá lati ibikan. A ha nilati dọgbọn dẹ́bi fun Ọlọrun bi? Bibeli dahun pe: “Ki ẹnikẹni ti a dánwò maṣe wi pe, lati ọwọ́ Ọlọrun ni a ti dán mi wò: nitori a kò lè fi buburu dán Ọlọrun wò, oun naa kìí sìí dán ẹnikẹni wò.” Bi Ọlọrun kò bá nilati dahun fun un, ta ni yoo ṣe bẹẹ? Awọn ẹsẹ ti ó tẹle e yii fun wa ni idahun naa pe: “Ṣugbọn olukuluku ni a ń dánwò, nigba ti a bá ti ọwọ́ ifẹkufẹẹ araarẹ̀ fà á lọ ti a sì tàn án jẹ. Ǹjẹ́, ifẹkufẹẹ naa nigba ti ó bá loyun, a bí ẹ̀ṣẹ̀: ati ẹ̀ṣẹ̀ naa nigba ti ó bá sì dagba tán, a bí iku.” (Jakọbu 1:13-15) Nipa bayii ìwà buburu kan ni a ń bí nigba ti a bá mú ìfẹ́-ọkàn buburu kan dagba dipo ki a kọ̀ ọ́ silẹ. Bi o ti wu ki o ri, iyẹn kọ́ ni gbogbo ohun ti ó wémọ́ ọn.

Iwe Mimọ ṣalaye pe awọn ìfẹ́-ọkàn buburu ń dide nitori pe iran eniyan ni àléébù pataki kan—aipe ajogunbá. Aposteli Paulu kọwe pe: “Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ̀ ti ti ipa ọ̀dọ̀ eniyan kan wọ ayé, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ̀; bẹẹ ni iku sì kọja sori eniyan gbogbo, lati ọ̀dọ̀ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹ́ṣẹ̀.” (Romu 5:12) Nitori ẹ̀ṣẹ̀ ti a ti jogunba, imọtara-ẹni-nikan ni ó lè ṣeeṣe ki ó bori inurere ninu ironu wa, ìwà-ìkà sì lè jọba lori ìyọ́nú.

Niti tootọ, eyi ti ó pọ julọ ninu awọn eniyan mọ̀ laitilẹ jẹ pe a sọ fun wọn pe iru awọn ìwà-ìkà kan kò tọ̀nà. Ẹ̀rí-ọkàn wọn—tabi ‘ofin ti a kọ sinu ọkàn wọn’ gẹgẹ bi Paulu ṣe pè é—ń fà wọn sẹhin kuro ninu ìwà buburu. (Romu 2:15) Sibẹ, ayika oníkà kan lè tẹ iru awọn imọlara yẹn rì, ti ẹ̀rí-ọkàn kan sì lè di eyi ti kò ṣiṣẹ mọ́ bi a bá ṣàìkà á sí leralera.a—Fiwe 1 Timoteu 4:2.

Ǹjẹ́ aipe eniyan nikanṣoṣo ha lè ṣalaye ibi ti a wewee fun akoko wa bi? Opitan Jeffrey Burton Russell ṣakiyesi pe: “Otitọ ni pe ibi wà ninu ẹnikọọkan wa, ṣugbọn kíkó iye ibi rẹpẹtẹ ti awọn eniyan pupọ jọ paapaa kò lè ṣalaye Auschwitz . . . Ibi ní ipele ìwọ̀n yii dabi eyi ti ó yatọ lọna jíjẹ́ ojulowo ati lọna jíjẹ́ eyi ti o pọ̀ ní iye bakan naa.” Kìí ṣe ẹlomiran bikoṣe Jesu Kristi ni ó tọka orisun yiyatọ lọna jíjẹ́ ojulowo yii nipa ibi.

Laipẹ si ìgbà iku rẹ̀, Jesu ṣalaye pe awọn eniyan ti ń wewee lati pa oun kò gbegbeesẹ patapata lori ìgbèrò tiwọn funraawọn. Agbara kan tí kò ṣeefojuri ni o dari wọn. Jesu sọ fun wọn pe: “Ti Eṣu baba yin ni ẹyin íṣe, ifẹkufẹẹ baba yin ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apaniyan ni oun íṣe lati atetekọṣe, kò sì duro ni otitọ.” (Johannu 8:44) Eṣu, ẹni ti Jesu pe ni “alade ayé yii,” ní kedere ní ipa ti ó ṣe pataki kan lati kó ninu jíjẹ́ ki ibi gbèrú.—Johannu 16:11; 1 Johannu 5:19.

Ati aipe eniyan ati agbara-idari Satani ti yọrisi ijiya pupọ fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun. Kò sì sí àmì kankan pe ọwọ́ lilekoko wọn lara araye ń dẹ̀. Ibi yoo ha maa wà titilọ bi? Tabi awọn agbara ire yoo ha fa gbongbo ibi tu ni asẹhinwa-asẹhinbọ bi?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Awọn oluṣewadii lẹnu aipẹ yii ti rí ibatan kan ti ó wà laaarin ìwà-ipá pọ́ńbélé lori tẹlifiṣọn ati ìwà-ọ̀daràn awọn màjèṣí. Awọn adugbo nibi ti ìwà-ọ̀daràn ti gbode ati awọn ilé ti ó túká tun jẹ́ kókó abajọ pẹlu ninu ìwà àìbẹ́gbẹ́pé. Ni Germany ti Nazi ìgbékèéyíde elérò igbagbọ ẹ̀yà-ìran-tèmi-lọ̀gá aláìdabọ̀ sún awọn kan lati dáre fun—ati ki wọn tilẹ fogo fun—awọn ìwà ìkà-òǹrorò lodisi awọn Ju ati awọn ti ń sọ èdè Slavic.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Fọto U.S. Army

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọto U.S. Army

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́