ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ll apá 5 ojú ìwé 12-13
  • Nígbà Ìkún Omi, Àwọn Wo Ló Tẹ́tí sí Ọlọ́run? Àwọn Wo Ni Kò Tẹ́tí sí I?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Ìkún Omi, Àwọn Wo Ló Tẹ́tí sí Ọlọ́run? Àwọn Wo Ni Kò Tẹ́tí sí I?
  • Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nóà Kan Áàkì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Apa 5
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
  • Nóà Kan Ọkọ̀ Áàkì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
ll apá 5 ojú ìwé 12-13

APÁ 5

Nígbà Ìkún Omi, Àwọn Wo Ló Tẹ́tí sí Ọlọ́run? Àwọn Wo Ni Kò Tẹ́tí sí I?

Ìwà burúkú ni àwọn èèyàn tó pọ̀ jù nígbà ayé Nóà ń hù. Jẹ́nẹ́sísì 6:5

Àwọn áńgẹ́lì burúkú tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ wá fẹ́ àwọn obìnrin

Ádámù àti Éfà bí àwọn ọmọ, àwọn èèyàn sì wá pọ̀ ní ayé. Nígbà tó yá, àwọn áńgẹ́lì kan dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.

Wọ́n wá sí ayé, wọ́n sì gbé àwọ̀ ọkùnrin wọ̀ kí wọ́n lè gbé àwọn obìnrin níyàwó. Àwọn obìnrin yìí bí àwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ òmìrán, wọ́n lágbára gan-an, wọ́n sì ya ẹhànnà.

Obìnrin kan gbé ọmọ dání, ọmọ kan fẹ́ gbá a ní ẹ̀ṣẹ́; àwọn Néfílímù ń hùwà ipá, àwọn ni ọmọ táwọn áńgẹ́lì burúkú bí

Àwọn èèyàn tó ń hùwà ibi wá pọ̀ ní ayé. Bíbélì sọ pé: “Ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, . . . kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.”

Nóà tẹ́tí sí Ọlọ́run, ó sì kan ọkọ̀ áàkì. Jẹ́nẹ́sísì 6:​13, 14, 18, 19, 22

Nóà tẹ́tí sí Ọlọ́run

Èèyàn rere ni Nóà. Jèhófà sọ fún Nóà pé òun máa fi ìkún omi pa àwọn èèyàn burúkú run.

Nóà àti ìdílé rẹ̀ ń kan ọkọ̀ áàkì

Ọlọ́run tún sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ ojú omi ńlá kan, tí Bíbélì pè ní áàkì, kí ó sì kó ìdílé rẹ̀ àti àwọn ẹranko lóríṣiríṣi sínú ọkọ̀ náà.

Nóà ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa Ìkún Omi tó ń bọ̀, àmọ́ wọ́n ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́

Nóà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa Ìkún Omi tó ń bọ̀, àmọ́ wọn ò tẹ́tí sí i. Àwọn kan fi Nóà ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn míì sì kórìíra rẹ̀.

Nóà àti ìdílé rẹ̀ ń kó àwọn ẹranko lọ sínú áàkì

Nígbà tí Nóà parí ọkọ̀ áàkì náà, ó kó àwọn ẹranko sínú rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́