ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ll apá 6 ojú ìwé 14-15
  • Kí Ni Ìkún Omi Náà Kọ́ Wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ìkún Omi Náà Kọ́ Wa?
  • Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apa 2
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
  • Ìkìlọ̀ Láti Inú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Àtijọ́
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Nígbà Ìkún Omi, Àwọn Wo Ló Tẹ́tí sí Ọlọ́run? Àwọn Wo Ni Kò Tẹ́tí sí I?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ohun Tó Mú Kí Nóà Rójú Rere Ọlọ́run—Ìdí Tó Fi Kàn Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
ll apá 6 ojú ìwé 14-15

APÁ 6

Kí Ni Ìkún Omi Náà Kọ́ Wa?

Ọlọ́run pa àwọn èèyàn burúkú yẹn run, àmọ́ ó dá Nóà àti ìdílé rẹ̀ sí. Jẹ́nẹ́sísì 7:11, 12, 23

Áàkì náà léfòó lójú omi, àwọn èèyàn burúkú mumi yó, àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ sì bọ́ àwọ̀ èèyàn tí wọ́n gbé wọ̀ sílẹ̀

Ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì òru ni òjò fi rọ̀, omi sì bo gbogbo ayé. Gbogbo àwọn èèyàn burúkú ló kú.

Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà bọ́ ara èèyàn sílẹ̀, wọ́n sì di ẹ̀mí èṣù.

Nóà, ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹranko jáde nínú áàkì, òṣùmàrè sì yọ lójú ọ̀run

Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ áàkì ò kú nígbà ìkún omi yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ kú nígbà tó yá, Ọlọ́run máa jí wọn dìde, wọ́n á sì wà láàyè títí láé.

Ọlọ́run ṣì tún máa pa àwọn ẹni burúkú run, á sì dá àwọn ẹni rere sí. Mátíù 24:​37-39

Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń fi oríṣiríṣi nǹkan ṣi àwọn lọ́nà

Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù kò tíì dáwọ́ dúró láti máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà.

Nígbà ayé Nóà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò tẹ̀ lé ìtọ́ni tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, ohun kan náà sì ni ọ̀pọ̀ ń ṣe lóde òní. Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn èèyàn burúkú run.​—2 Pétérù 2:​5, 6.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi Bíbélì wàásù fún ẹnì kan; ọkùnrin kan ń ka Bíbélì

Àwọn kan wà tó dà bíi Nóà. Wọ́n ń tẹ́tí sí Ọlọ́run, wọ́n sì ń ṣe ohun tó sọ; àwọn èèyàn náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

  • Yan ọ̀nà tó lọ sí ìyè.​—Mátíù 7:13, 14.

  • Àwọn ẹni burúkú máa pa run; àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ máa gbádùn àlàáfíà.​—Sáàmù 37:​10, 11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́