ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 5 ojú ìwé 18-ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 5
  • Nóà Kan Áàkì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nóà Kan Áàkì
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nóà Kan Ọkọ̀ Áàkì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Nígbà Ìkún Omi, Àwọn Wo Ló Tẹ́tí sí Ọlọ́run? Àwọn Wo Ni Kò Tẹ́tí sí I?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 5 ojú ìwé 18-ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 5
Nóà àti ìdílé rẹ̀ kan ọkọ̀ áàkì

Ẹ̀KỌ́5

Nóà Kan Áàkì

Nígbà tó yá, àwọn èèyàn pọ̀ gan-an láyé. Àmọ́ ìwà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ń hù ò dáa rárá. Kódà, àwọn áńgẹ́lì kan bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú. Wọ́n fi ọ̀run sílẹ̀ wá sí ayé. Ṣé o mọ ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ ṣe bí àwa èèyàn, kí wọ́n sì fẹ́ ìyàwó.

Àwọn áńgẹ́lì yẹn fún àwọn ìyàwó wọn lóyún, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin. Nígbà táwọn ọmọ yẹn dàgbà, wọ́n lágbára gan-an, wọ́n sì máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Wọ́n tún máa ń ṣèkà fáwọn èèyàn. Inú Jèhófà ò dùn sí ìwà búburú yẹn. Torí náà, Jèhófà pinnu pé òun máa fi omi tó pọ̀ gan-an pa àwọn èèyàn náà run.

Nóà àti ìdílé rẹ̀ kan ọkọ̀ áàkì, wọ́n sì ṣètò oúnjẹ

Àmọ́, ọkùnrin kan wà tí kò bá wọn lọ́wọ́ sí ìwà búburú. Nóà lorúkọ ẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Òun àti ìyàwó ẹ̀ bí ọmọkùnrin mẹ́ta, orúkọ àwọn ọmọ náà ni, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyàwó kan. Jèhófà sọ fún Nóà pé kó kan áàkì kan kí òun àti ìdílé ẹ̀ lè wà nínú ẹ̀ nígbà tí òjò ńlá náà bá ń rọ̀. Áàkì náà dà bí àpótí tó tóbi gan-an, àmọ́ tó lè dúró sórí omi. Jèhófà tún sọ fún Nóà pé kó kó àwọn ẹranko sínú áàkì náà, káwọn ẹranko náà má bàa kú sínú òjò ńlá tó máa rọ̀ yẹn.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Jèhófà bá Nóà sọ̀rọ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kan áàkì náà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta (50) ọdún tí Nóà àti ìdílé ẹ̀ fi kan áàkì yẹn. Bí Jèhófà ṣe ní kí wọ́n ṣe é náà ni wọ́n ṣe é. Yàtọ̀ síyẹn, Nóà tún máa ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa òjò ńlá tó fẹ́ rọ̀ yẹn. Àmọ́, wọn ò gbọ́rọ̀ sí Nóà lẹ́nu.

Nígbà tó yá, Ọlọ́run ní kí wọ́n wọnú áàkì náà. Ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Orí tó kàn máa ṣàlàyé.

“Bí àwọn ọjọ́ Nóà ṣe rí gẹ́lẹ́ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín.”​—Mátíù 24:37

Ìbéèrè: Kí ló fà á tí Jèhófà fi sọ pé òun máa fi omi pa ayé rẹ́? Kí ni Jèhófà sọ fún Nóà pé kó ṣe?

Jẹ́nẹ́sísì 6:1-22; Mátíù 24:37-41; 2 Pétérù 2:5; Júùdù 6

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́