ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ll apá 3 ojú ìwé 8-9
  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?
  • Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Kan Wà Nípò Tó Ga Ju Tiwa Lọ
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ìdí Tí Wọ́n Fi Pàdánù Ibùgbé Wọn
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tí Wọ́n Tẹ́tí sí Sátánì?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Apa 3
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
Àwọn Míì
Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
ll apá 3 ojú ìwé 8-9

APÁ 3

Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?

Àìmọye nǹkan rere ni Jèhófà fún Ádámù àti Éfà. Jẹ́nẹ́sísì 1:28

Lẹ́yìn tí Jèhófà dá Éfà, ó fà á lé Ádámù lọ́wọ́

Jèhófà dá Éfà tó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fà á lé Ádámù lọ́wọ́ pé kó fi ṣe aya.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:​21, 22.

Nígbà tí Jèhófà dá wọn, ó fún wọn ní ọpọlọ pípé àti ara pípé, wọn ò ní àbùkù kankan rárá.

Ádámù àti Éfà ń wo ọgbà wọn tó rẹwà

Ọgbà Édẹ́nì ni ilé wọn, ọgbà tó lẹ́wà gan-an ni. Odò, àwọn igi eléso àti àwọn ẹranko wà níbẹ̀.

Jèhófà máa ń bá wọn sọ̀rọ̀; ó máa ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Tí wọ́n bá tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n á wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ èso ọ̀kan lára àwọn igi tó wà nínú ọgbà náà. Jẹ́nẹ́sísì 2:​16, 17

Igi tó wà nínú ọgbà náà tí Jèhófà sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso rẹ̀

Jèhófà fi igi eléso kan tó wà nínú ọgbà náà han Ádámù àti Éfà, ó wá sọ fún wọn pé tí wọ́n bá jẹ èso rẹ̀, wọ́n máa kú.

Sátánì Èṣù, áńgẹ́lì burúkú náà, ń lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀

Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Sátánì Èṣù ni áńgẹ́lì búburú yẹn.

Sátánì ò fẹ́ kí Ádámù àti Éfà gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Nítorí náà, ó lo ejò kan láti sọ fún Éfà pé tó bá jẹ èso igi náà, kò ní kú, ṣe ló máa dà bí Ọlọ́run. Ó dájú pé irọ́ ni Sátánì pa.​—Jẹ́nẹ́sísì 3:​1-5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́