ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ll apá 4 ojú ìwé 10-11
  • Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tí Wọ́n Tẹ́tí sí Sátánì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tí Wọ́n Tẹ́tí sí Sátánì?
  • Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Apa 4
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
  • Ibo Làwọn Òkú Wà?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ibo Là Ń Lọ Tá A Bá Kú?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
ll apá 4 ojú ìwé 10-11

APÁ 4

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tí Wọ́n Tẹ́tí sí Sátánì?

Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì kú. Jẹ́nẹ́sísì 3:​6, 23

Éfà jẹ èso tí Ọlọ́run ní kí wọ́n má jẹ, ó sì fún Ádámù lára rẹ̀

Éfà tẹ́tí sí ejò yìí, ó sì jẹ èso igi náà. Lẹ́yìn náà, ó fún Ádámù lára rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.

Ádámù àti Éfà kúrò nínú ọgbà tó rẹwà tí wọ́n ń gbé

Ohun tí wọ́n ṣe yìí ò dáa rárá, ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ọlọ́run lé wọn jáde nínú Párádísè tí wọ́n ń gbé.

Ádámù àti Éfà darúgbó, wọ́n sì kú

Nǹkan wá nira fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn. Wọ́n darúgbó, wọ́n sì kú. Wọn ò lọ sí ibi tí àwọn ẹ̀mí ń gbé o; ṣe ni wọ́n ṣaláìsí.

Àwọn tó ti kú dà bí erùpẹ̀ lásán. Jẹ́nẹ́sísì 3:19

Àwọn èèyàn láti oríṣiríṣi ẹ̀yà tí wọ́n gbé ayé ní ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Ìdí tí àwa èèyàn fi ń kú ni pé àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà ni gbogbo wa. Àwọn òkú ò lè ríran, wọn ò lè gbọ́ràn, wọn ò sì lè ṣe nǹkan kan.​—Oníwàásù 9:​5, 10.

Ọmọbìnrin kan kú, ìdílé rẹ̀ sì ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀

Jèhófà ò fẹ́ kí àwa èèyàn máa kú. Láìpẹ́, ó máa jí àwọn tó ti kú dìde. Tí wọ́n bá tẹ́tí sí i, wọ́n á wà láàyè títí láé.

  • Kí nìdí tí a fi ń kú?​—Róòmù 5:12.

  • Kò ní sí ikú mọ́.​—1 Kọ́ríńtì 15:26.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́