Gbígbẹ́jọ́ “Aládàámọ̀” Kan Àti Pípa á
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ
NÍ APÁ kan iyàrá ilé ẹjọ́ amúnifòyà náà, ni tábìlì kẹ̀ǹkẹ̀ tí ó ga sókè kan wà fún àwọn adájọ́. Ìjókòó alága tí ó wà láàárín ni wọ́n fi aṣọ ìbòrí dúdú kan, tí àgbélébùú onípákó, tí gbogbo iyàrá ilé ẹjọ́ kọjú sí, wà lórí rẹ̀, bò. Akóló olùjẹ́jọ́ wà níwájú rẹ̀.
Bí a ti sábà máa ń ṣàpèjúwe àwọn ilé ẹjọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ti Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ti Kátólíìkì nìyí. Ẹ̀sùn ajániláyà tí a fi kan àwọn olùjẹ́jọ́ aláìní olùgbèjà náà ni “àdámọ̀,” ọ̀rọ̀ tí ń múni rántí ìdálóró àti ìpani nípa sísunni lórí òpó. Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ (láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe Látìn náà, inquiro, “láti ṣèwádìí nǹkan”) jẹ́ àkànṣe ilé ẹjọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì gbé kalẹ̀ láti fòpin sí àdámọ̀, ìyẹn ni, àwọn ìrònú tàbí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí kò bá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Roman Kátólíìkì ti gbogbogbòò.
Ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ Kátólíìkì sọ pé, wọ́n gbé e kalẹ̀ ní ìpele-ìpele. Póòpù Lucius Kẹta gbé Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ náà kalẹ̀ ní Àpérò Verona ní 1184, àwọn póòpù míràn sì sọ ìṣètò àti àwọn ìlànà rẹ̀ di pípé—bí a bá lè lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ṣàpèjúwe ìgbékalẹ̀ bíbanilẹ́rù náà. Ní ọ̀rúndún kẹtàlá, Póòpù Gregory Kẹsàn-án gbé àwọn ilé ẹjọ́ aṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ kalẹ̀ ní apá ibi púpọ̀ ní Europe.
Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ tí a kò sọ ohun rere nípa rẹ̀ ní Sípéènì ni a gbé kalẹ̀ ní 1478, pẹ̀lú òfin póòpù kan tí Póòpù Sixtus Kẹrin gbé jáde tí àwọn ọba aláṣẹ náà, Ferdinand àti Isabella, tí ń ṣàkóso béèrè fún. A gbé e kalẹ̀ láti gbógun ti àwọn Marrano, àwọn Júù tí wọ́n fi ẹ̀tàn yí pa dà sí ìsìn Kátólíìkì láti jà bọ́ lọ́wọ́ inúnibíni; àwọn Morisco, àwọn Mùsùlùmí tí wọ́n fi ẹ̀tàn yí pa dà sí ìsìn Kátólíìkì nítorí ìdí kan náà; àti àwọn aládàámọ̀ ará Sípéènì. Nítorí ìtara ìgbawèrèmẹ́sìn rẹ̀, ẹni àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ olórí nínú ìwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ ní Sípéènì, Tomás de Torquemada, ajẹ́jẹ̀ẹ́-ànìkàngbé tí ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Dominic, wá di àmì àfihàn bíburú jù lọ nípa Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ náà.
Ní 1542, Póòpù Paul Kẹta gbé Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ti Róòmù, tí ó ní agbára lórí Kátólíìkì ní gbogbogbòò, kalẹ̀. Ó ṣàgbékalẹ̀ ilé ẹjọ́ gbogbogbòò kan tí ó ní àwọn kádínà mẹ́fà nínú, tí a ń pè ní Ìjọ Mímọ́ Róòmù àti Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ Ti Gbogbogbòò, ẹ̀ka ṣọ́ọ̀ṣì kan tí ó di “ìjọba ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ó fi ìbẹ̀rù kún gbogbo Róòmù.” (Dizionario Enciclopedico Italiano) Ìfìyà ikú jẹ àwọn aládàámọ̀ kó ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bá àwọn ilẹ̀ tí ẹgbẹ́ alákòóso Kátólíìkì ti ń ṣàkóso ní kíkún.
Ìgbẹ́jọ́ àti Ayẹyẹ Ìmúdàájọ́ṣẹ [Auto-da-fé]
Ìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn olùṣèwádìí láti gbogun ti àdámọ̀ dá àwọn tí a fẹ̀sùn àdámọ̀ kan lóró láti lè fipá mú wọn ṣe ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ pé, aládàámọ̀ ni àwọn. Nínú ìsapá láti dín ẹ̀bi Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ náà kù, àwọn abẹnugan nínú Kátólíìkì ti kọ̀wé pé, ní àkókò náà, ìdánilóró wọ́pọ̀ ní àwọn ilé ẹjọ́ ìlú pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n, ìyẹn ha dá irú ìwà bẹ́ẹ̀, láti ọwọ́ àwọn òjíṣẹ́ tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ aṣojú Kristi, láre bí? Kò ha yẹ kí wọ́n ti fi ìyọ́nú tí Kristi fi hàn sí àwọn ọ̀tá rẹ̀ hàn bí? Láti fi ojú àìṣègbè wo èyí, a lè ronú lórí ìbéèrè rírọrùn kan: Kristi Jésù yóò ha dá àwọn tí àwọn ẹ̀kọ́ wọn yàtọ̀ sí tirẹ̀ lóró bí? Jésù wí pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, láti máa ṣe rere sí àwọn wọnnì tí ń kórìíra yín.”—Lúùkù 6:27.
Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ náà kò fún ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà ní ẹ̀rí ìdánilójú ìdájọ́ òdodo èyíkéyìí. Bí àṣà, olùṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ náà ní agbára tí kò láàlà. “Ìfura, ìfẹ̀sùnkanni, kódà àgbọ́sọ pàápàá, ti tó fún olùṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ láti pàṣẹ fún ẹnì kan láti fara hàn níwájú rẹ̀.” (Enciclopedia Cattolica) Italo Mereu, òpìtàn nípa òfin, fìdí ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹgbẹ́ alákòóso Kátólíìkì fúnra rẹ̀ ló pilẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ ìdájọ́ ìṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀, tí wọ́n sì ń ṣàmúlò rẹ̀, ní kíkọ ètò ìgbékalẹ̀ ìfẹ̀sùnkanni ìgbàanì tí àwọn ará Róòmù gbé kalẹ̀ sílẹ̀. Òfin Róòmù béèrè pé kí olùfisùn fi ẹ̀rí ìfẹ̀sùnkanni rẹ̀ hàn. Bí iyè méjì èyíkéyìí bá wà, ó sàn jù láti dáni sílẹ̀ pátápátá ju láti wà nínú ewu dídẹ́bi ìfìyàjẹni fún ẹnì kan tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀. Ẹgbẹ́ alákòóso Kátólíìkì fi èrò pé ìfurasíni ti fini hàn bí ẹlẹ́bi rọ́pò ìlànà bíbófinmu yìí, olùjẹ́jọ́ ni ó sì ní láti fi àìmọwọ́mẹsẹ̀ rẹ̀ hàn. Wọn forúkọ bo àwọn ẹlẹ́rìí agbẹjọ́rò ìjọba (àwọn amúròyìnwá) láṣìírí, bí agbẹjọ́rò olùjẹ́jọ́ kan bá sì wà, ó dojú kọ ewu ojútì àti ti pípàdánù ipò rẹ̀ bí àbájáde ìgbẹjọ́rò fún ẹni tí a ronú pé ó jẹ́ aládàámọ̀ náà bá yọrí sí rere. Ní àbájáde rẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Enciclopedia Cattolica gbà pé, “ẹni tí a fẹ̀sùn kàn kò lólùgbèjà ní gidi. Gbogbo ohun tí agbẹjọ́rò náà lè ṣe ni pé kí ó gba ẹni tí ó jẹ̀bi náà nímọ̀ràn láti ṣe ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀!”
Ìgbẹ́jọ́ náà parí sórí ayẹyẹ ìmúdàájọ́ṣẹ [auto-da-fé], gbólóhùn ọ̀rọ̀ èdè Potogí kan tí ó túmọ̀ sí “ìṣe ìgbàgbọ́.” Kí ni ó jẹ́? Àwọn àwòrán ìgbà láéláé fi hàn pé àwọn olùjẹ́jọ́ tí kò rìnnà kore, tí wọ́n fẹ̀sùn àdámọ̀ kàn wá di òjìyà àfiṣèranwò bíbanilẹ́rù kan. Ìwé atúmọ̀ èdè Dizionario Ecclesiastico túmọ̀ auto-da-fé bí “ìṣe ìlàjà níta gbangba tí àwọn aládàámọ̀, tí a ti dájọ́ ikú fún, tí wọ́n ronú pìwà dà, ṣe” lẹ́yìn kíka ẹ̀rí ẹ̀bi wọn.
Ẹ̀rí ẹ̀bi náà àti ìfìyà ikú jẹ àwọn aládàámọ̀ ni a sún síwájú kí wọ́n baà lè kó àwọn bíi mélòó kan pọ̀ fún ìwòran ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mejì láàárín ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. A ń kó ìtọ́wọ̀ọ́rìn àwọn aládàámọ̀ kan tí ó gùn kọjá níwájú àwọn òǹwòran, tí wọ́n ń kópa nínú ìdàpọ̀ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ àti ìfanimọ́ra amúnibanújẹ́. Àwọn tí a ti fi ẹ̀rí ẹ̀bi wọn hàn náà ni a mú gun orí pèpéle kan láàárín gbàgede ńlá kan, a óò sì ka ìdájọ́ wọn sókè ketekete. Àwọn tí wọ́n bọ́hùn, ìyẹn ni pé, tí wọ́n kọ àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ aládàámọ̀ sílẹ̀, ni a óò dá sílẹ̀ kúrò nínú kádàrá ìyọniníjọ, a óò sì ṣèdájọ́ onírúurú ìjìyà fún wọn títí kan ẹ̀wọ̀n gbére. Àwọn tí wọ́n kò bọ́hùn, àmọ́ tí wọ́n wá ṣe ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ fún àlùfáà kan níkẹyìn, ni a óò fà lé àwọn aláṣẹ ìlú lọ́wọ́ láti yí wọn lọ́rùn pa, yẹgi fún wọn, tàbí bẹ́ wọn lórí, tí wọn óò wá sun òkú wọ́n lẹ́yìn náà. Àwọn tí wọn kò ronú pìwà dà ni a óò sun lóòyẹ̀. Ìpani náà yóò wáyé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn ìran ìtagbangba mìíràn.
Ìgbòkègbodò Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ní Róòmù náà jẹ́ èyí tí a ṣe lọ́nà gíga jù lọ. Kódà lónìí, wọn kò jẹ́ kí àwọn ọ̀mọ̀wé yẹ àwọn ibi àkójọ ìsọfúnni rẹ̀ wò. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwádìí àfisùúrùṣe ti mú díẹ̀ lára àwọn àkọsílẹ̀ ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ Róòmù wá sójú táyé. Kí ni wọ́n fi hàn?
Gbígbẹ́jọ́ Bíṣọ́ọ̀bù Kan
Pietro Carnesecchi, tí a bí ní ìlú ńlá Florence ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, tẹ̀ síwájú lọ́nà yíyá kánkán nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ fún ṣọ́ọ̀ṣì ní àgbàlá Póòpù Clement Keje, tí ó yàn án sípò gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé òun fúnra rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìsìn Carnesecchi dópin láìròtẹ́lẹ̀ nígbà tí póòpù kú. Lẹ́yìn náà, ó wá dí ojúlùmọ̀ àwùjọ àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti ti àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ pé, bíi tirẹ̀, wọ́n tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ díẹ̀ tí Àwọn Alátùn-únṣe Pùròtẹ́sítáǹtì fi ń kọ́ni. Ní àbájáde rẹ̀, wọ́n gbẹ́jọ́ lẹ́nu rẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta. Níwọ̀n bí wọ́n ti dájọ́ ikú fún un, wọ́n bẹ́ ẹ lórí, wọ́n sì sun òkú rẹ̀.
Àwọn abẹnugan ṣàlàyé àhámọ́ tí Carnesecchi wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n bí ẹni tí ó wà bí aláìsí. Kí ó baà lè bọ́hùn, wọ́n dá a lóró, wọ́n sì febi pa á. Ní September 21, 1567, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ kádínà ní Róòmù ni wọ́n wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣe ayẹyẹ ìmúdàájọ́ṣẹ rẹ̀ tí ó le koko. Wọ́n ka ìdájọ́ tí a ṣe fún Carnesecchi fún un lórí pèpéle náà níwájú àwọn èrò. Ó parí pẹ̀lú ọ̀nà ìgbàṣe kan tí ó jẹ́ bí àṣà àti àdúrà sí àwọn mẹ́ńbà ilé ẹjọ́ ìlú, tí a óò fa aládàámọ̀ náà lé lọ́wọ́ láìpẹ́, láti ‘jẹ́ kí ìdájọ́ ìyà rẹ̀ mọ níwọ̀n, kí wọ́n má sì dájọ́ ikú fún un, kí wọ́n má sì jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù jù.’ Èyí kì í ha ṣe àṣejù àgàbàgebè bí? Àwọn olùṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ náà fẹ́ láti mú àdámọ̀ kúrò, àmọ́, nígbà kan náà, wọ́n ń díbọ́n láti béèrè pé kí àwọn aláṣẹ ṣàánú, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ojú ayé, wọ́n sì ń ti ẹrù ẹ̀bí ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lórí ara wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka ìdájọ́ Carnesecchi, wọ́n fún un ní aṣọ sanbenito kan láti wọ̀—aṣọ ọ̀fọ̀ aláwọ̀ ìyeyè tí wọ́n ya àwọn àgbélébùú pupa sí, ní ti àwọn tí wọ́n ronú pìwà dà tàbí dúdú tí ó ní àwọn ọwọ́ iná àti àwọn èṣù lára, ní ti àwọn tí wọn kò ronú pìwà dà. Wọn mú ìdájọ́ náà ṣẹ ní ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà.
Èé ṣe tí wọ́n fẹ̀sùn àdámọ̀ kan akọ̀wé póòpù tẹ́lẹ̀ rí yìí? Àkọsílẹ̀ bí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ṣe lọ, tí a ṣàwárí lópin ọ̀rúndún tó kọjá, fi hàn pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn 34 tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí ó pè níjà. Lára wọn ni ẹ̀kọ́ nípa pọ́gátórì, ẹ̀jẹ́ ànìkàngbé àwọn àlùfáà àti àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé, ìyípadàdi-gidi àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ ara Olúwa, ìgbọ́wọ́léni, ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀, kíka àwọn oúnjẹ léèwọ̀, ìsanpadà owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti gbígbàdúrà sí “àwọn ẹni mímọ́.” Ẹ̀sùn kẹjọ ń ru ọkàn sókè láti gbọ́ ní pàtàkì. (Wo àpótí, ojú ìwé 21.) Nípa dídájọ́ ikú fún àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba kìkì “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a sọ nínú Ìwé Mímọ́” gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún èrò ìgbàgbọ́, Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ náà fi hàn kedere pé, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kò ka Bíbélì Mímọ́ sí orísun ìmísí kan ṣoṣo náà. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà ni wọn kò gbé karí Ìwé Mímọ́, àmọ́ lórí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ṣọ́ọ̀ṣì.
Pípa Ọ̀dọ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kan
Ìtàn ìgbésí ayé kúkúrú tí ó sì ń ru ìmọ̀lára sókè ti Pomponio Algieri, tí wọ́n bí nítòsí Naples ní 1531, ni a kò mọ̀ dáradára, àmọ́ ó wá láti inú ìgbà tí ó kọjá tí kò ṣe kedere náà, ọpẹ́ ni fún àwọn ìwádìí ìtàn aláápọn tí àwọn ọ̀mọ̀wé bíi mélòó kan ṣe. Nípa kíkàn sí àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní onírúurú ibi ní Europe nígbà tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní Yunifásítì Padua, wọ́n fi ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí a pè ní àdámọ̀ àti ti Alátùn-únṣe Pùròtẹ́sítáǹtì han Algieri. Ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ru sókè.
Ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́ pé Bíbélì nìkan ṣoṣo ni ó ní ìmísí, ní àbájáde rẹ̀, ó pa díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì tì, àwọn bí ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀, ìgbọ́wọ́léni, pọ́gátórì, ìyípadàdi-gidi àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ ara Olúwa, àti ìgbẹnusọ “àwọn ẹni mímọ́” fúnni, àti ẹ̀kọ́ pé póòpù ni aṣojú Kristi.
Ilé Ẹjọ́ Aṣèwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ní Padua fàṣẹ mú Algieri, ó sì gbẹ́jọ́ lẹ́nu rẹ̀. Ó wí fún àwọn olùṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ rẹ̀ pé: “Mo ń fínnúfíndọ̀ pa dà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, bóyá sí ikú mi pàápàá bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run nìyẹn. Nípasẹ̀ ògo Ọlọ́run, òun yóò túbọ̀ máa la olúkúlùkù lóye síwájú sí i. Èmi yóò gba ìdálóró kọ̀ọ̀kan tọ̀yàyàtọ̀yàyà nítorí pé Kristi, Olùtùnú pípé fún àwọn ọkàn tí a ń pọ́n lójú, tí ń là mí lóye, tí ó sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ mi, lè mú gbogbo òkùnkùn kúrò.” Lẹ́yìn náà, Ilé Ẹjọ́ Aṣèwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ní Róòmù náà gba ìránpadà ọ̀daràn sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ fún ìjẹ́jọ́, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un.
Ẹni ọdún 25 ni Algieri nígbà tí ó kú. Lọ́jọ́ tí wọ́n pa á ní Róòmù, ó kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ tàbí láti gba Ara Olúwa. Ohun èlò tí wọ́n fi pa á tilẹ̀ burú jáì ju èyí tí wọ́n máa ń lò lọ. Wọn kò fi igi tí a dì jọ sun un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìkòkò irin ńlá kan tí ó kún fún àwọn ohun tí ó lè tètè gbiná—epo, ọ̀dà, àti oje igi—ni wọ́n gbé sórí pèpéle náà níbi tí àwọn èrò ti lè rí i dáradára. Wọ́n de ọ̀dọ́kùnrin náà, wọ́n sì sọ ọ sínú ìkòkò irin ńlá náà, wọ́n sì ṣáná sí àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. Wọ́n sun ún díẹ̀díẹ̀ lóòyẹ̀.
Orísun Ẹ̀bi Wíwúwo Mìíràn
Carnesecchi, Algieri, àti àwọn mìíràn tí Ilé Ẹjọ́ Aṣèwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ pa ní òye tí kò pé nípa Ìwé Mímọ́. Òye ṣì máa wá di “púpọ̀ yanturu” ní “àkókò òpin” ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n fẹ́ láti kú fún ìwọ̀nba “ìmọ̀ tòótọ́” tí wọ́n ti jèrè láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Dáníẹ́lì 12:4.
Kódà àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì, títí kan àwọn kan lára àwọn Alátùn-únṣe wọn, mú àwọn oníyapa kúrò nípa sísun wọ́n lórí òpó tàbí kí wọ́n pa àwọn Kátólíìkì nípa gbígba ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìlú. Fún àpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Calvin ń fẹ́ pé kí wọ́n máa bẹ́ àwọn aládàámọ̀ lórí, ó jẹ́ kí wọ́n sun Michael Servetus lóòyẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ aládàámọ̀ tí ó ṣòdì sí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan.
Òkodoro òtítọ́ náà pé, ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ìfìyà ikú jẹ àwọn aládàámọ̀ wọ́pọ̀ láàárín àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì kò dá àwọn ìwà wọ̀nyẹn láre. Àmọ́ àwọn ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn tún ṣì jẹ̀bi lọ́nà wíwúwo—fún sísọ pé Ìwé Mímọ́ dá wọn láre fún àwọn ìpànìyàn náà àti lẹ́yìn náà fún dídíbọ́n pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló pàṣẹ irú ìwà bẹ́ẹ̀. Èyí kò ha kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run bí? Àwọn ọ̀mọ̀wé bíi mélòó kan jẹ́rìí pé, Augustine, olókìkí “Fadáa Ṣọ́ọ̀ṣì” Kátólíìkì náà, ni ẹni tí ó kọ́kọ́ ṣètìlẹ́yìn fún ìlànà ìfagbáramúni “onísìn,” ìyẹn ni, lílo ipá láti ṣẹ́gun àdámọ̀. Nínú ìgbìyànjú láti lo Bíbélì láti dá àṣà náà láre, ó tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ inú òwe àkàwé Jésù tí ó wá nínú Lúùkù 14:16-24 pé: “Ṣe é ní ọ̀ranyàn fún wọn láti wọlé.” Ó ṣe kedere pé, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí Augustine lọ́ sódì, tọ́ka sí aájò àlejò ọlọ́làwọ́, kì í ṣe ìfagbáramúni ti òǹrorò.
Ó yẹ fún àfiyèsí pé, kódà nígbà tí Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ náà ń lọ lọ́wọ́, àwọn alátìlẹ́yìn ìráragbaǹkan ní ti ìsìn jiyàn lòdì sí ṣíṣe inúnibíni sí àwọn aládàámọ̀, ní títọ́ka sí òwe àkàwé àlìkámà àti èpò. (Mátíù 13:24-30, 36-43) Ọ̀kan lára wọn ni Desiderius Erasmus, láti Rotterdam, tí ó wí pé, Ọlọ́run, Ẹni tí ó ni pápá náà, fẹ́ kí a fàyè gba àwọn aládàámọ̀, àwọn èpò náà. Ní ọwọ́ kejì, Martin Luther gbé ìwà ipá dìde sí àwọn tálákà oníyapa, wọ́n sì pa iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 100,000.
Nígbà tí a ti rí ẹ̀bi wíwúwo ti ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù tí ó dá kún ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àwọn tí a pè ní aládàámọ̀ náà, kí ló yẹ kí ó sún wa láti ṣe? Dájúdájú, ó yẹ kí a fẹ́ láti wá ìmọ̀ tòótọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù wí pé, àmì ìdánimọ̀ Kristẹni tòótọ́ kan yóò jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò—ìfẹ́ tí ó dájú pé kì yóò fi àyè gba ìwà ipá.—Mátíù 22:37-40; Jòhánù 13:34, 35; 17:3.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
Díẹ̀ Lára Àwọn Ẹ̀sùn Tí Wọ́n Dá Carnesecchi Lẹ́bi Rẹ̀
8. “[O tẹnu mọ́ ọn] pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo tí a sọ nínú Ìwé Mímọ́ ni ó yẹ kí a gbà gbọ́.”
12. “[O gbà gbọ́] pé, ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba ara Olúwa kò sí ní de jure Divino [ìbámu pẹ̀lú òfin àtọ̀runwá], pé, Kristi kọ́ ló gbé e kalẹ̀, pé Ìwé Mímọ́ kò sì jẹ́rìí sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni irú ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí kò pọn dandan yàtọ̀ sí èyí tí a jẹ́wọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run fúnra rẹ̀.”
15. “O ṣiyè méjì nípa pọ́gátórì.”
16. “O ka ìwé Maccabees, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú gbígbàdúrà fún àwọn òkú, sí èyí tí ìjójúlówó rẹ̀ kò dájú.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck