Àwọn Cathar Kristian Ajẹ́rìíkú Ha Ni Wọ́n Bí?
“ẸPA gbogbo wọn; Ọlọrun yóò mọ àwọn Tirẹ̀.” Ní ọjọ́ ìgbà ẹ̀rùn ti 1209 yẹn, a pá àwọn olùgbé Béziers, ní gúúsù France nípakúpa. Arnold Amalric ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé náà, tí a yàn sípò gẹ́gẹ́ bí aṣojú póòpù ní ipò-orí àwọn ajagun ìsìn Katoliki, kò fi àánú hàn rárá. Nígbà tí àwọn alájùmọ̀ṣepọ̀ rẹ̀ béèrè bí àwọn yóò ṣe dá àwọn Katoliki mọ̀ yàtọ̀ sí àwọn aládàámọ̀, ìròyìn sọ pé ìdáhùn tí ó burú jáì tí a fà yọ lókè ni ó fún wọn. Àwọn òpìtàn Katoliki bu omi là á wí pé: “Ẹ má bìkítà. Mo gbàgbọ́ pé àwọn díẹ̀ ni a óò yí lọ́kàn padà.” Ohun yòówù kí ó jẹ́ ìdáhùn rẹ̀ gan-an, ìyọrísí rẹ̀ ni ìpalápalù ó kéré tán 20,000 ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé láti ọwọ́ nǹkan bí 300,000 àwọn ajagun ìsìn, tí àwọn bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki ṣáájú wọn.
Kí ni ó fa ìpakúpa yìí? Ó wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Ìsìn Àwọn Ará Albi tí Póòpù Innocent III ti gbé dìde lòdì sí àwọn tí a fẹnu lásán pé ní aládàámọ̀ ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Languedoc, àárín gbùngbùn gúúsù France. Kí ó tó parí ní nǹkan bí 20 ọdún lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe kí ó tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn—àwọn Cathar, àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo, àti kódà ọ̀pọ̀lọpọ̀ Katoliki pàápàá—tí wọ́n ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Àìfohùnṣọ̀kan Ìsìn Europe ti Sànmánì Agbedeméjì
Ìdàgbàsókè yíyá kánkán ti ìṣòwò ní ọ̀rúndún kọkànlá C.E. mú ìyípadà ńláǹlà wá nínú ìgbékalẹ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ọrọ̀-ajé ti Europe ti sànmánì agbedeméjì. Àwọn ìlú ṣẹ́yọ láti pèsè ibùgbé fún àwọn oníṣòwò àti òǹtàjà tí ń pọ̀ sí i. Èyí pèsè àyè fún àwọn èrò tuntun. Àìfohùnṣọ̀kan ìsìn ta gbòǹgbò ní Languedoc, níbi tí ìráragba-nǹkan-sí lọ́nà tí ó pẹtẹrí àti ọ̀làjú gíga ti gbilẹ̀ ju ibikíbi mìíràn lọ ní Europe. Ìlú-ńlá Toulouse ní Languedoc ni ìlú-ńlá tí ó lọ́rọ̀ ṣe ìkẹta ní Europe. Ó jẹ́ ayé kan nínú èyí tí àwọn akọrinkéwì ti ṣàṣeyọrí, tí díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ orin àti ewì wọn sọ̀rọ̀ lórí àwọn kòkó ẹ̀kọ́ ìṣèlú àti ti ìsìn.
Ní ṣíṣàpèjúwe ipò ìsìn ní ọ̀rúndún kọkànlá àti ìkejìlá, ìwé náà Revue d’histoire et de philosophie religieuses sọ pé: “Ní ọ̀rúndún 12, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀rúndún tí ó ṣáájú, ìwàhíhù àwùjọ àlùfáà, ọlá wọn, ìwà àbòsí wọn nítorí owó, àti ìwà pálapàla wọn, ń bá a nìṣó ní dídi ohun tí a ń gbé ìbéèrè dìde sí, ṣùgbọ́n ní pàtàkì ọrọ̀ àti agbára wọn, ìlẹ̀dí-àpò-pọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ayé, àti ìwà ìpá-kúbẹ́kúbẹ́-ṣẹrú wọn ní a ṣe lámèyítọ́ rẹ̀.”
Àwọn Oníwàásù Arìnrìn-Àjò Kiri
Kódà Póòpù Innocent III pàápàá mọ̀ pé ìwà ìbàjẹ́ tí ó wọ́pọ̀ láàárín ṣọ́ọ̀ṣì náà ni ó fa kí àwọn olùyapa láìfohùnṣọ̀kan, àwọn oníwàásù arìnrìn-àjò kiri ní Europe, ní pàtàkì ní gúúsù France àti àríwá Itali máa pọ̀ sí i. Èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn wọ̀nyí jẹ́ yálà àwọn Cathar tàbí àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo. Ó bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn àlùfáà fún ṣíṣàìkọ́ àwọn ènìyàn, ní sísọ pé: “Awọn ọmọ ń fẹ́ búrẹ́dì tí ẹ̀yin kò fẹ́ láti pín fún wọn.” Síbẹ̀, dípò gbígbé ẹ̀kọ́ Bibeli lárugẹ fún àwọn ènìyàn, Innocent sọ pé “Ìwé Mímọ́ Ọlọrun jinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, débi pé kì í ṣe kìkì àwọn kò-mọ̀-kan àti púrúǹtù ni kò tóótun láti lóye rẹ̀, ṣùgbọ́n kódà àwọn amòyemèrò àti ọ̀mọ̀wé pàápàá kò tóótun.” A fòfin de kí gbogbo wọn má ṣe ka Bibeli àyàfi àwùjọ àlùfáà tí ó sì jẹ́ ní èdè Latin nìkan nígbà náà.
Láti lè dá ìwàásù ìrìnrìn-àjò kiri tí àwọn olùyapa láìfohùn ṣọ̀kan ń ṣe lọ́wọ́ kọ́, póòpù fọwọ́ sí ìdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ Oníwàásù Arìnrìn-Àjò Kiri, tàbí àwọn Ọmọlẹ́yìn Dominic. Ní ìyàtọ̀ gédégédé sí ipò-ọ̀rọ̀ àwùjọ àlùfáà Katoliki, àwọn arìnrìn-àjò kiri wọ̀nyí níláti jẹ́ oníwàásù arìnrìn-àjò tí a fàṣẹ fún láti gbèjà ìlànà tí gbogbo Katoliki tẹ́wọ́ gbà lòdì sí “àwọn aládàámọ̀” ní gúúsù France. Póòpù náà tún rán àwọn aṣojú póòpù láti jíròrò pẹ̀lú àwọn Cathar kí wọ́n sì gbìyànjú láti mú wọn padà wá sínú agbo Katoliki. Níwọ̀n bí àwọn ìsapá wọ̀nyí ti já kulẹ̀, tí a sì pa ọ̀kan lára àwọn aṣojú rẹ̀, tí a lérò pé ó jẹ́ láti ọwọ́ aládàámọ̀ kan, Innocent III pàṣẹ jíja Ogun Ìsìn ti Àwọn Ará Albi ní 1209. Albi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí àwọn Cathar pọ̀ sí jù lọ ní pàtàkì, nítorí ìdí èyí àwọn òpìtàn ṣọ́ọ̀ṣì tọ́ka sí àwọn Cathar gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Albi (Albigeois, ní èdè French) wọ́n sì lo ọ̀rọ̀ náà láti fi pe gbogbo “àwọn aládàámọ̀” tí ń bẹ ní ẹkùn náà, títí kan àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo. (Wo àpótí nísàlẹ̀.)
Àwọn Wo Ni Àwọn Cathar?
Ọ̀rọ̀ náà “cathar” wá láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà ka·tha·rosʹ, tí ó túmọ̀ sí “mímọ́ gaara.” Láti ọ̀rúndún kọkànlá sí ìkẹrìnlá, ìsìn Cathar tàn kálẹ̀ ní pàtàkì ní Lombardy, àríwá Itali, àti ní Languedoc. Èrò ìgbàgbọ́ àwọn Cathar jẹ́ àpapọ̀ ojú ìwòye ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ abaraméjì ti Ìlà-Oòrùn àti ti Ìmọ̀-Awo, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àwọn oníṣòwò láti ilẹ̀ òkèèrè àti míṣọ́nnárì ni wọ́n mú un wọlé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion túmọ̀ ojú ìwòye ẹ̀dà ènìyàn jẹ́ abara méjì tí àwọn Cathar ní gẹ́gẹ́ bí èrò ìgbàgbọ́ nínú “ìlànà méjì: ọ̀kan tí ó dára, tí ń ṣàkóso gbogbo ohun tẹ̀mí, èkejì tí ó burú, tí ó jẹ́ okùnfà fún ayé ti ara, títí kan ara ènìyàn.” Àwọn Cathar gbàgbọ́ pé Satani ni ó dá ayé ti ara, èyí tí a ti dá lẹ́bi sí ìparun láìṣeé yí padà. Ìrètí wọn ni láti ja àjàbọ́ kúrò nínú ibi, ayé ti ara.
Àwọn Cathar pín sí apá méjì, àwọn ẹni pípé àti àwọn onígbàgbọ́. Àwọn ẹni pípé ni a gbà sínú ẹgbẹ́ nípa ààtò batisí nípa tẹ̀mí, tí a ń pè ní consolamentum. Èyí ni a ń ṣe nípa ìgbọ́wọ́lénilórí, lẹ́yìn àyẹ̀wò káṣìmáawòó ọlọ́dún kan. Ààtò náà ni a rò pé yóò jẹ́ fún dídá ẹni tí ń bẹ lábẹ́ àyẹ̀wò káṣìmáawòó náà nídè kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Satani, kí a sọ ọ́ di mímọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, kí a sì fún un ní ẹ̀mí mímọ́. Èyí yọrí sí orúkọ tí a fún wọn náà “àwọn ẹni pípé,” tí a lò fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú tí wọ́n kéré ní ìfiwéra tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ fún àwọn onígbàgbọ́. Àwọn ẹni pípé máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ ìtakété, wíwà ní mímọ́, àti ipò òṣì. Bí ó bá ti gbéyàwó tàbí lọ́kọ, ẹni pípé kan níláti fi ìyàwó tàbí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n bí àwọn Cathar ti gbàgbọ́ pé ìbálòpọ̀ takọtabo ni ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Àwọn onígbàgbọ́ ni àwọn kọ̀ọ̀kan tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ àwọn Cathar, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò gbé ìgbésí ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́. Nípa kíkúnlẹ̀ ní bíbọlá fún àwọn ẹni pípé lọ́nà aláàtò ìsìn tí a ń pè ní melioramentum, onígbàgbọ́ náà ń tọrọ ìdáríjì àti ìbùkún. Láti lè jẹ́ kí wọ́n gbé ìgbésí-ayé bí ti gbogbo ènìyàn, àwọn onígbàgbọ́ ń wọnú àdéhùn convenenza pẹ̀lú àwọn ẹni pípé, tàbí ìfohùnṣọ̀kan, ní ṣíṣétò ìbatisí tẹ̀mí nígbà tí wọ́n bá wà lójú ikú, tàbí consolamentum.
Ìṣarasíhùwà sí Bibeli
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Cathar máa ń ṣàyọlò Bibeli gan-an, lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n kà á sí orísun òwe àti àlọ́. Wọ́n gbà pé apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù. Wọ́n lo àwọn apá kan Ìwé Mímọ́ Lédè Griki, irú bí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó fi ìyàtọ̀ ara àti ẹ̀mí hàn, láti ṣètìlẹyìn fún ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn ojú ìwòye pé ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ abara méjì. Nínú Àdúrà Oluwa, wọ́n gbàdúrà fún “búrẹ́dì wa tí ń tẹ́ni lọ́rùn dọ́ba” (tí ó túmọ̀ sí “búrẹ́dì nípa tẹ̀mí”) dípò “búrẹ́dì wa fún ọjọ́ òní,” lójú wọn búrẹ́dì nípa ti ara jẹ́ ohun búburú tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn Cathar ta ko Bibeli ní tààràtà. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n gbàgbọ́ nínú àìlèkú ọkàn àti àtúnwáyé. (Fiwé Oniwasu 9:5, 10; Esekieli 18:4, 20.) Wọ́n tún gbé èrò-ìgbàgbọ́ wọn karí àwọn ẹsẹ ìwé apocrypha. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn Cathar ni ó túmọ̀ apá kan Ìwé Mímọ́ sí èdè ìbílẹ̀, dé ìwọ̀n àyè kan, wọ́n sọ Bibeli di ìwé tí ó gbajúmọ̀ sí i ní Sànmánì Agbedeméjì.
Wọn Kì í Ṣe Kristian
Àwọn ẹni pípé ka ara wọn sí ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbapò àwọn aposteli àti, lójú ìwòye èyí, wọ́n pe ara wọn ní “Kristian,” ní títẹnumọ́ èyí nípa fífi “tòótọ́” tàbí “rere” kún un. Bí ó ti wù kí ó rí, dájúdájú ọ̀pọ̀ èrò-ìgbàgbọ́ àwọn Cathar ṣàjèjì sí ìsìn Kristian. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Cathar gba Jesu gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọrun, wọ́n kọ wíwá rẹ̀ nínú ẹran-ara àti ẹbọ ìranipadà rẹ̀. Ní ṣíṣi bí Bibeli ṣe dẹ́bi fún ẹran-ara àti ayé lóye, wọ́n gbà pé gbogbo ohun tí a lè fojú rí wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù. Nítorí náà wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé kìkì ara tẹ̀mí nìkan ní Jesu ti lè ní àti pé nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé ó wulẹ̀ fara hàn pé òun ní ẹran-ara ni. Bíi ti àwọn apẹ̀yìndà ọ̀rúndún kìíní, àwọn Cathar jẹ́ “awọn ẹni tí kò jẹ́wọ́ Jesu Kristi pé ó wá ninu ẹran-ara.”—2 Johannu 7.
Nínú ìwé rẹ̀ Medieval Heresy, M. D. Lambert kọ̀wé pé ìsìn Cathar “fi ìṣẹ́ra-ẹní-níṣẹ̀ẹ́ lápàpàǹdodo rọ́pò ìlànà ìwàhíhù Kristian, . . . ó yọ ìràpadà kúrò nípa kíkọ̀ láti gba agbára tí ń gbani là [ikú Kristi] gbọ́.” Ó gbà pé “ìbátan tímọ́tímọ́ tòótọ́ ti àwọn ẹni pípé ní í ṣe pẹ̀lú àwọn olùkọ́ni ní ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ ti Ìlà-Oòrùn, àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti ìsìn Buddha àti ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti Musulumi ti China tàbí India, àwọn ògbógi ti iṣẹ́-awo Orpheus, tàbí àwọn olùkọ́ni ní Ìmọ̀-Awo.” Nínú èrò-ìgbàgbọ́ àwọn Cathar, ìgbàlà kò sinmi lé ẹbọ ìràpadà Jesu Kristi, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ lórí consolamentum, tàbí batisí sínú ẹ̀mí mímọ́. Lójú àwọn tí a ti sọ di mímọ́, ikú yóò dá wọn sílẹ̀ kúrò nínú ohun tí ó ṣeé fojú rí.
Ogun Ìsìn Aláìmọ́
Àwọn gbáàtúù ènìyàn, tí ìfidandangbọ̀n lọ́ni lọ́wọ́ gbà àti ìbàjẹ́ bàlùmọ̀ àwùjọ àlùfáà tí ó gbalé-gbòde ti kó àárẹ̀ bá, ni ọ̀nà ìgbésí-ayé àwọn Cathar fà mọ́ra. Àwọn ẹni pípé fi Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki àti ìṣàkóso nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀ hàn bí “sinagọgu Satani” àti “ìyá awọn aṣẹ́wó” ti Ìṣípayá 3:9 àti 17:5. Ìsìn Cathar ń gbilẹ̀ ó sì ń gbapò ṣọ́ọ̀ṣì ní gúúsù France. Ìhùwàpadà Póòpù Innocent III ni láti gbé ohun tí a fẹnu lásán pè ní Ogun Ìsìn Àwọn Ará Albi dìde kí ó sì ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀, ogun ìsìn àkọ́kọ́ tí a ṣètò láàárín Kristẹndọm lòdì sí àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ Kristian.
Nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà àti àwọn aṣojú, póòpù náà halẹ̀ mọ́ àwọn ọba Katoliki, àwọn ọlọ́lá, àwọn mọ́gàjí, àti àwọn ajagungboyè ti Europe. Ó ṣèlérí ìmúkúrò ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrọ̀ ti Languedoc fún gbogbo ẹni tí ó ba lè jà láti mú àdámọ̀ kúrò “nípasẹ̀ ọ̀nà èyíkéyìí.” Wọ́n kò kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Onírúurú àwọn ọmọ ogun ajagun ìsìn láti àríwá France, Flanders, àti Germany kọrí sí ìhà gúúsù ní Àfonífojì Rhône, tí àwọn bíṣọ́ọ̀bù Katoliki àti àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé sì ṣáájú wọn.
Ìparun Béziers ni ó sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ogun ìjagunmólú tí ó pa Languedoc run nínú iná tí ń sọ kẹ̀ù àti alagbalúgbú ẹ̀jẹ̀. Albi, Carcassonne, Castres, Foix, Narbonne, Termes, àti Toulouse ṣubú sọ́wọ́ àwọn ajagun ìsìn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ. Ní ibi ìsádi àwọn Cathar bíi Cassès, Minerve, àti Lavaur, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ẹni pípé ni a dáná sun lórí òpó igi. Gẹ́gẹ́ bí ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé òpìtàn Pierre des Vaux-de-Cernay ti sọ, àwọn ajagun ìsìn náà ‘dáná sun àwọn ẹni pípé láàyè, tí inú wọn sì ń dùn.’ Ní 1229, lẹ́yìn ìjà àti ìparundahoro 20 ọdún, Languedoc wá sábẹ́ Ìjọba France. Ṣùgbọ́n ìpakúpa náà kò tí ì parí.
Ìwádìí Láti Gbógun ti Àdámọ̀ Súnná sí Ìṣẹ̀lẹ̀ Apanirun
Ní 1231, Póòpù Gregory IX gbé Ìwádìí Láti Gbógun ti Àdámọ̀ lòdì sí ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki kalẹ̀ láti fún ìtakàn-ǹ-gbọ̀n ohun-ìjà ní ìṣírí.a Ètò ìgbékalẹ̀ ìwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ ni a kọ́kọ́ gbé karí ìfibú àti ìkánilọ́wọ́kò aláìbófinmu àti lẹ́yìn náà, a gbé e karí ìdálóró oníṣìsẹ́ntẹ̀lé. Ète rẹ̀ ni láti kásẹ̀ ohun tí idà kò lè parun. Àwọn adájọ́ Ìwádìí Láti Gbógun ti Àdámọ̀—ní pàtàkì àwọn Ọmọlẹ́yìn Dominic àti àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti àwọn Ọmọlẹ́yìn Francis—wà lábẹ́ póòpù nìkan. Ikú nípa dídáná sunni ni ìjìyà tí a fàṣẹ sí fún àdámọ̀. Ìgbawèrèmẹ́sìn àti ìwà òkú-òǹrorò àwọn olùṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ìdìtẹ̀ fi wáyé ní Albi àti Toulouse, àti ní àwọn ibòmíràn. Ní Avignonet, gbogbo àwọn mẹ́ḿbà ìgbìmọ̀ Ìwádìí Láti Gbógun ti Àdámọ̀ ni a pa nípakúpa.
Ní 1244 yíyọ̀ǹda òkè ìsádi ti Montségur, ibi ìsádi ìkẹyìn fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹni pípé, jẹ́ ìró agogo ikú fún ìsìn Cathar. Nǹkan bí 200 ọkùnrin àti obìnrin parẹ́ nínú ìdánásunni papọ̀ lórí òpó igi. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, Ìwádìí Láti Gbógun ti Àdámọ̀ ti ṣàwárí àwọn Cathar tí ó ṣẹ́kù. Ìròyìn sọ fúnni pé 1330 ni a dáná sun Cathar kan tí ó ṣẹ́kù ní Languedoc. Ìwé náà Medieval Heresy ṣàlàyé pé: “Ìṣubú ìsìn Cathar jẹ́ olórí àṣeparí títayọ jù lọ tí Ìwádìí Láti Gbógun ti Àdámọ̀ ṣe.”
Ó dájú pé àwọn Cathar kì í ṣe Kristian tòótọ́. Ṣùgbọ́n lámèyítọ́ tí wọ́n ṣe nípa Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki ha mú wọn yẹ fún pípa run pátápátá láti ọwọ́ àwọn tí a fẹnu lásán pè ní Kristian bí? Àwọn Katoliki tí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn tí wọ́n sì pa wọ́n tàbùkù sí Ọlọrun àti Kristi, wọ́n sì fi ìsìn Kristian tòótọ́ hàn lọ́nà òdì bí wọ́n ṣe ń dá ẹgbẹẹgbàarùn ún àwọn olùyapa láìfohùnṣọ̀kan lóró tí wọ́n sì ń dúḿbú wọn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé síwájú sí i lórí Ìwádìí Láti Gbógun ti Àdámọ̀ sànmánì agbedeméjì, wo “Ìwádìí Bíbanilẹ́rù Láti Gbógun ti Àdámọ̀” nínú Jí! ti April 22, 1986 (Gẹ̀ẹ́sì), tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, ojú-ìwé 20 sí 23.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
ÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN WALDO
Bí ọ̀rúndún kejìlá C.E. ṣe ń parí lọ, Pierre Valdès, tàbí Peter Waldo, ọlọ́rọ̀ oníṣòwò ní Lyons, ṣe onígbọ̀wọ́ ìtumọ̀ àkọ́kọ́ fún apá kan Bibeli sí onírúurú èdè ìbílẹ̀ ti àwọn ará Provençal, èdè ìbílẹ̀ tí àwọn ará gúúsù àti ìlà-oòrùn gúúsù France ń sọ. Katoliki olóòótọ́ ọkàn kan ni, ó fi iṣẹ́-ajé rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún wíwàásù Ìhìnrere. Nítorí ìwà ìbàjẹ́ àwùjọ àlùfáà tí ó kò wọn nírìíra, ọ̀pọ̀ àwọn Katoliki mìíràn tẹ̀ lé e wọ́n sì di oníwàásù arìnrìn-àjò kiri.
Kó pẹ́ púpọ̀ tí Waldo fi bá ìkóguntini pàdé láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àlùfáà àdúgbò, tí wọ́n yí póòpù lọ́kàn padà láti fòfin de ìjẹ́rìí rẹ̀ ní gbangba. Èsì tí a gbọ́ pé ó sọ ní pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun dípò àwọn ènìyàn.” (Fiwé Ìṣe 5:29.) Nítorí ìtẹpẹlẹmọ́ rẹ̀, a yọ Waldo lẹ́gbẹ́. Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tí a ń pè ní àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo, tàbí Àwọn Òtòṣì Ẹ̀dá ti Lyons, fi tìtara-tìtara tiraka láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ní wíwàásù ní méjì-méjì nínú ilé àwọn ènìyàn. Èyí yọrí sí ìtànkálẹ̀ yíyá kánkán ẹ̀kọ́ wọn jákèjádò gúúsù, ìlà-oòrùn, àti àwọn apá àríwá France, bákan náà sì ni àríwá Itali.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n ṣalágbàwí ìpadà sí àwọn èrò-ìgbàgbọ́ àti àṣà àwọn Kristian ìjímìjí. Wọ́n pe àwọn ẹ̀kọ́ bíi pọ́gátórì, àdúrà fún àwọn òkú, ìjọsìn Maria, àdúrà sí “àwọn ẹni mímọ́,” ìjúbà àgbélébùú, ìdásílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, Ìdàpọ̀, àti ṣíṣe batisí ìkókó níjà.*
Ẹ̀kọ́ àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo yàtọ̀ gédégédé sí ẹ̀kọ́ tí kò bá ìgbàgbọ́ Kristian mú ti ojú ìwòye ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ abara méjì tí ó jẹ́ ti àwọn Cathar, àwọn tí wọ́n sábà máa ń ṣì wọ́n mú fún lọ́pọ̀ ìgbà. Ìṣìmú yìí ní pàtàkì jẹ́ nítorí àwọn alátakò gbígbóná janjan onísìn Katoliki tí wọ́n mọ̀ọ́mọ́ gbìdánwò láti so ìwàásù àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ará Albi, tàbí àwọn Cathar.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo, wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Awọn Waldenses—Awọn Aladamọ̀ tabi Awọn Ti Nwá Otitọ Kiri?” nínú Ilé-Ìsọ́nà ti February 1, 1982, ojú-ìwé 27 sí 30.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin ni ó kú sí Ṣọ́ọ̀ṣì St. Mary Magdalene ní Béziers, níbi tí àwọn ajagun ìsìn ti pa 20,000 ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé nípakúpa