ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/22 ojú ìwé 4-9
  • Àwọn Ogun Ìsìn Ní Ilẹ̀ Faransé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ogun Ìsìn Ní Ilẹ̀ Faransé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtàn Àtẹ̀yìnwá
  • Ìtẹ̀rì Yíyòkú-Òǹrorò
  • Ìgbésẹ̀ Tí Ó Ṣáájú Ogun
  • Àwọn Ogun Mẹ́ta Àkọ́kọ́
  • Ìpakúpa Lọ́jọ́ Ìrántí Batolómíù “Mímọ́”
  • Àwọn Ogun Ìsìn Ń Bá A Lọ
  • Èso Tí Ogun So
  • Sísálọ Àwọn Alátùn-únṣe Kí Wọ́n Lè Lómìnira
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Wọ́n Ti Gbà Báyìí Pé Àwọn Ò Gba Ẹ̀sìn Míì Láyè
    Jí!—2000
  • Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo—Látorí Jíjẹ́ Aládàámọ̀ Dórí Jíjẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìpàdé Àlàáfíà Westphalia—Ló Yí Ìgbà Padà Nílẹ̀ Yúróòpù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 4/22 ojú ìwé 4-9

Àwọn Ogun Ìsìn Ní Ilẹ̀ Faransé

NÍ SUNDAY, March 1, 1562, aláṣẹ ti Guise àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin Charles, kádínà ti Lorraine—àwọn aṣáájú méjì nínú ìsìn Kátólíìkì ilẹ̀ Faransé—ń lọ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ wọn tí wọ́n dìhámọ́ra síhà Vassy, abúlé kan tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Paris. Wọ́n pinnu láti yà ní ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní Vassy láti ṣe ìsìn Máàsì.

Lójijì, wọ́n gbọ́ ìró orin ìsìn. Orin náà wá láti ọ̀dọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n pé jọ sínú abà kan láti jọ́sìn. Àwọn sójà wọn fipá wọlé. Láàárín ìdàrúdàpọ̀ tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n bú ara wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jùkò lu ara wọn. Àwọn sójà náà ṣíná ìbọn yíyìn, wọ́n sì pa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì, wọ́n sì pa àwọn ọgọ́rọ̀ọ̀rún mìíràn lára.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló fa ìpakúpa yìí? Báwo ni àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì náà ṣe hùwà pa dà?

Ìtàn Àtẹ̀yìnwá

Láàárín apá ìdajì àkọ́kọ́ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ilẹ̀ Faransé láásìkí, kò sì kún àkúnya. Ipò ètò ọrọ̀ ajé àti ti ìwàdéédéé iye àwọn olùgbé ilẹ̀ náà ni àwọn ìsapá láti ṣe irú ìsìn Kátólíìkì tí ó túbọ̀ jẹ̀ ti ẹ̀mí àti ti arákùnrin ń bá rìn. Àwọn ènìyàn fẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan tí kò lọ́rọ̀ púpọ̀, tí ó sì túbọ̀ jẹ́ mímọ́. Àwọn kan lára àwọn mẹ́ńbà àwùjọ àlùfáà àti àwọn ọ̀mọ̀wé afẹ́dàáfẹ́re fi dandan béèrè fún àtúnṣe ìsìn láti gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn àlùfáà onípò gíga àti àìtóótun àwọn àlùfáà kéékèèké ń hù. Mẹ́ńbà àwùjọ àlùfáà kan tí ó sakun fún ìsọdọ̀tun ni bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì náà, Guillaume Briçonnet.

Ní àgbègbè tí Briçonnet ń ṣàkóso ní Meaux, ó rọ gbogbo ènìyàn láti máa ka Ìwé Mímọ́. Ó tilẹ̀ fowó ṣètìlẹ́yìn fún ìtumọ̀ tuntun kan ti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sí èdè Faransé. Kò pẹ́ tí Yunifásítì Ẹ̀kọ́ Ìsìn ní Sorbonne, Paris, tí ń ṣe kòkárí ipò jíjẹ́ ti gbogbogbòò ti Kátólíìkì bínú sí i, tí wọ́n sì dá àwọn ìsapá rẹ̀ dúró. Ṣùgbọ́n bíṣọ́ọ̀bù náà ní ìdáàbòbò láti ọ̀dọ̀ Francis Kíní, ọba ilẹ̀ Faransé láti 1515 sí 1547. Lákòókò yẹn, ọba fọwọ́ sí ṣíṣàtúnṣe.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Francis Kíní fàyè gba ìṣelámèyítọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà kìkì dé àyè tí kò ní máa wu ìwàlétòlétò ìlú àti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè léwu. Ní 1534, àwọn aláṣejù Pùròtẹ́sítáǹtì lẹ àwọn ìwé àlẹ̀-fiṣèsọfúnni tí ó fẹ̀sùn kan ìsìn Máàsì Kátólíìkì gẹ́gẹ́ bí ìbọ̀rìṣà, ó tilẹ̀ kan ìwé àlẹ̀-fiṣèsọfúnni sára ilẹ̀kùn iyàrá ọba. Gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí rẹ̀, Francis Kíní yí èrò rẹ̀ pa dà, ó sì ṣèfilọ́lẹ̀ ìgbétásì ìtẹ̀rì rírorò kan.

Ìtẹ̀rì Yíyòkú-Òǹrorò

Kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sun àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì lórí òpó. Ọ̀pọ̀ àwọn afẹ́dàáfẹ́re, àwọn abánidárò wọn, àti àwọn ọmọlẹ́yìn onísìn Pùròtẹ́sítáǹtì tuntun náà sá kúrò ní orílẹ̀-èdè náà. Àwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé, wọ́n sì ń darí àwọn olùkọ́, àwọn òǹṣèwé, àti àwọn olùtẹ̀wé.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo jìyà apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú ìṣòdìsíni àfàṣẹsí náà. Wọ́n jẹ́ àwùjọ kíkéré jọjọ ti àwọn ènìyàn tí èrò wọn dá lórí Bíbélì, tí ń gbé inú àwọn abúlé tí ó tòṣì ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Wọ́n sun àwọn kan lórí òpó, wọn pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún ní ìpakúpa, wọ́n sì fọ́ nǹkan bí 20 lára àwọn abúlé wọn túútúú.—Wo àpótí ojú ìwé 6.

Nígbà tí àjọ àwọn bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì kan rí àìní fún àtúnṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà, wọ́n pàdé ní December 1545, ní Trent, Ítálì. Gẹ́gẹ́ bí ìdìpọ̀ kẹta ìwé náà, The Cambridge Modern History, ṣe sọ, nígbà tí àpérò náà parí ní 1563, “àbáyọrí àpapọ̀” tí ó ní “jẹ́ láti fún àwọn tí wọ́n ti pinnu láti fa ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò lókun.”

Ìgbésẹ̀ Tí Ó Ṣáájú Ogun

Nítorí pé ó ti sú wọn láti máa dúró de àwọn ìyípadà, púpọ̀ lára àwọn mẹ́ńbà ìgbòkègbodò alátùn-únṣe nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fara mọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ní nǹkan bí 1560, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tọ̀kùlú ọmọ ilẹ̀ Faransé àti àwọn alátìlẹ́yìn wọn dara pọ̀ mọ́ àwọn Alátùn-únṣe, bí a ti ń pe àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ẹnu àwọn Alátùn-únṣe náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀rọ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ìpàdé ìtagbangba wọn jẹ́ orísun ìmúnibínú àti ìdojúùjà-kọni. Fún àpẹẹrẹ, ní 1558, ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn kóra jọ ní Paris fún ọjọ́ mẹ́rin léraléra láti kọ sáàmù.

Gbogbo èyí bí àwọn alágbára aṣáájú ìsìn nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti àwọn ènìyàn gbáàtúù Kátólíìkì nínú. Nípasẹ̀ ìsúnniṣe láti ọ̀dọ̀ Kádínà Charles ti Lorraine, Ọba Henry Kejì, tí ó gbapò bàbá rẹ̀, Francis Kíní, polongo Àṣẹ Écouen, ní June 1559. Ète rẹ̀ tí a fi dáni lójú jẹ́ láti pa “ọmọlẹ́yìn Luther olórúkọ burúkú aláìjámọ́-ǹkan” náà run. Èyí ṣamọ̀nà sí ìgbétásì ìkópayà bá àwọn Alátùn-únṣe ní Paris.

Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà ni Henry Kejì kú nítorí ọgbẹ́ tí ó fara gbà níbi ìdíje kan. Ọmọkùnrin rẹ̀, Ọba Francis Kejì, tí ìdílé Guise rọ̀ láti gbégbèésẹ̀, tún sọ àṣẹ tí ó gbé ìdájọ́ ikú kalẹ̀ fún àwọn tí wọ́n bá ranrí mọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì dọ̀tun. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Francis Kejì kú, ìyá rẹ̀, Catherine de Médicis, sì ṣàkóso nípò àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, Charles Kẹsàn-án. Ìlànà ìlàjà tí Catherine gbé kalẹ̀ kò dùn mọ́ àwọn Guise, tí wọ́n ti pinnu láti pa àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì run, nínú.

Ní 1561, Catherine ṣètò àpérò kan ní Poissy, nítòsí Paris, níbi tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì ti pàdé. Nínú àṣẹ tí a gbé jáde ní January 1562, Catherine fún àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ní òmìnira láti pé jọ fún ìjọsìn lẹ́yìn òde àwọn ìlú ńlá. Inú bí àwọn Kátólíìkì gan-an! Èyí ṣínà sílẹ̀ fún ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lóṣù méjì sí àkókò náà—pípa àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n wà nínú abà ní abúlé Vassy nípakúpa, bí a ṣe ṣàpèjúwe níbẹ̀rẹ̀.

Àwọn Ogun Mẹ́ta Àkọ́kọ́

Ìpakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní Vassy tanná ran àkọ́kọ́ lára àwọn ogun ìsìn mẹ́jọ tẹ̀lératẹ̀léra tí ó ri ilẹ̀ Faransé sínú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ pípa tọ̀túntòsì wọn láti 1562 títí di àárín àwọn ọdún 1590. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀ràn ìṣèlú àti ti àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn kún un pẹ̀lú, ìsìn ni lájorí okùnfà ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà.

Lẹ́yìn Ogun Dreux ní December 1562, tí ó mú 6,000 ẹ̀mí lọ, ogun ìsìn àkọ́kọ́ yẹn wá sópin. Àdéhùn Àlàáfíà Amboise, tí wọ́n fọwọ́ sí ní March 1563, fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú Alátùn-únṣe ní òmìnira tí ó láàlà láti jọ́sìn ní àwọn ibì kan.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ẹ̀rù ìdìtẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Kátólíìkì jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè tí ń ba àwọn Alátùn-únṣe ló mú kí ogun kejì náà bẹ́ sílẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀.” Lákòókò náà, ó wọ́pọ̀ kí àwọn adájọ́ tí wọ́n jẹ́ Kátólíìkì máa dájọ́ yíyẹgi fún àwọn aráàlú kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ Alátùn-únṣe. Ní 1567, ìgbìyànjú Alátùn-unṣe kan láti jí Ọba Charles Kẹsàn-án àti ìyá rẹ̀, Catherine, gbé, tanná ran ogun kejì.

Lẹ́yìn sísọ nípa ogun kan tí ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ ti ṣàn gan-an ní St.-Denis, lẹ́yìn odi Paris, òpìtàn Will àti Ariel Durant kọ̀wé pé: “Ilẹ̀ Faransé tún ṣe kàyéfì lẹ́ẹ̀kan sí i pé irú ìsìn wo lèyí tí ń sún àwọn ènìyàn sí irú ìpànìyàn nípakúpa bẹ́ẹ̀.” Láìpẹ́ sí ìgbà náà, ní March 1568, Àdéhùn Àlàáfíà Longjumeau gba àwọn Alátùn-únṣe ní àyè tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tí wọ́n ti gbádùn tẹ́lẹ̀ lábẹ́ Àdéhùn Àlàáfíà Amboise.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, inú àwọn Kátólíìkì ru, wọ́n sì kọ̀ láti ṣe àwọn ohun àfilélẹ̀ fún àlàáfíà náà. Nípa bẹ́ẹ̀, ní September 1568, ogun ìsìn kẹta bẹ́ sílẹ̀. Àdéhùn àlàáfíà kan tí ó wáyé lẹ́yìn náà fún àwọn Alátùn-únṣe ní ìyọ̀ǹda tí ó tilẹ̀ pọ̀ díẹ̀. Wọ́n jọ̀wọ́ àwọn ìlú olódi, títí kan La Rochelle, fún wọn. Bákan náà, wọ́n yan aṣáájú pàtàkì kan nínú Pùròtẹ́sítáǹtì, Ọ̀gágun Ojú Omi de Coligny, sípò nínú ìgbìmọ̀ ọba. Lẹ́ẹ̀kan sí i, inú àwọn Kátólíìkì tún ru.

Ìpakúpa Lọ́jọ́ Ìrántí Batolómíù “Mímọ́”

Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, ní August 22, 1572, Coligny la ìkọlù ìyọ́kẹ́lẹ́pani-lójijì kan já ní Paris, tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó ń rìn lọ sí ilé rẹ̀ láti Ààfin Louvre. Bí inú ti bí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì gan-an, wọ́n halẹ̀ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ líle koko láti gbẹ̀san fúnra wọn bí a kò bá tètè ṣèdájọ́ òdodo. Níbi àpérò àdáṣe kan, ọ̀dọ́mọdé Ọba Charles Kẹsàn-án, ìyá rẹ̀ Catherine de Médicis, àti àwọn ọmọ aládé bíi mélòó kan pinnu láti pa Coligny. Láti yẹra fún ìforóyáró èyíkéyìí, wọ́n tún pàṣẹ pípa gbogbo àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n wá sí Paris fún ìgbéyàwó Henry ti Navarre, tí ó jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì, àti Margaret ti Valois, tí ó jẹ́ ọmọbìnrin Catherine.

Ní alẹ́ August 24, agogo ṣọ́ọ̀ṣì Saint-Germain-l’Auxerrois, ní ìdojúkọ Louvre, ṣe àmì ìsọfúnni láti bẹ̀rẹ̀ ìpakúpa náà. Aláṣẹ ti Guise àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ já wọ ilé tí Coligny ń sùn. Ibẹ̀ ni wọ́n pa Coligny sí, wọ́n sì jù ú gba ojú fèrèsé, wọ́n sì kun òkú rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Aláṣẹ tí ó jẹ́ Kátólíìkì náà tan ọ̀rọ̀ náà kálẹ̀ pé: “Ẹ pa gbogbo wọn. Àṣẹ ọba ni.”

Láti August 24 sí 29, àwọn ìran ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ba àwọn òpópónà Paris jẹ́. Àwọn kan sọ pé, odò Seine ń ṣàn fún ẹ̀jẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Alátùn-únṣe tí wọ́n ṣekú pa. Ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ ṣàn ní àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú. Àwọn ìfojúdíwọ̀n iye àwọn tó kú wà láti 10,000 sí 100,000; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ fohùn ṣọ̀kan lórí iye kan, ó kéré tán 30,000.

Òpìtàn kan ròyìn pé: “Òkodoro òtítọ́ kan, tí ó jẹ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ gan-an bí ìpakúpa náà fúnra rẹ̀ ti jẹ́, ni ìdùnnú tí ó ru sókè.” Nígbà tí Póòpù Gregory Kẹtàlá gbọ́ nípa ìpànìyàn náà, ó pàṣẹ ètò ìsìn ìdúpẹ́ kan, ó sì fi ìkíni ìbániyọ̀ rẹ̀ ránṣẹ́ sí Catherine de Médicis. Ó tún pàṣẹ ṣíṣe àmì ẹ̀yẹ àkànṣe kan láti fi ṣèrántí pípa àwọn Alátùn-únṣe, ó sì fàṣẹ sí títẹ àwòrán ìpakúpa náà, tí ó ní àwọn ọ̀rọ̀ náà nínú pé: “Póòpù fọwọ́ sí pípa Coligny.”

A gbọ́ pé, lẹ́yìn ìpakúpa náà, Charles Kẹsàn-án ń rí àwọn òjìyà náà nínú ìran, ó sì ń ké gbàjarè sí ẹni tí ń tọ́jú rẹ̀ pé: “Ẹ wo bí ìmọ̀ràn tí mo gbà ti burú tó! Ìwọ Ọlọ́run mi, dárí jì mí!” Ó kú ní 1574 ní ẹni ọdún 23, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin, Henry Kẹta, sì gbapò rẹ̀.

Àwọn Ogun Ìsìn Ń Bá A Lọ

Láàárín àkókò kan náà, àwọn aṣáájú ìsìn Kátólíìkì sún àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ lòdì sí àwọn Alátùn-únṣe. Ní Toulouse, àwọn mẹ́ńbà àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì gba àwọn ọmọlẹ́yìn wọn níyànjú pé: “Ẹ pa gbogbo wọn, ẹ kó ìkógun; àwa ni bàbá yín. A óò dáàbò bò yín.” Nípasẹ̀ ìtẹ̀rì oníwà ipá, ọba, àwọn ìgbìmọ̀ aṣòfin, àwọn gómìnà, àti àwọn ọ̀gágun fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, àwọn gbáàtúù Kátólíìkì sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Alátùn-únṣe jà pa dà. Láàárín oṣù méjì lẹ́yìn ìpakúpa Lọ́jọ́ Ìrántí Batolómíù “Mímọ́” náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ogun ìsìn ìkẹrin. Níbi tí wọ́n ti pọ̀ ju àwọn Kátólíìkì lọ, wọn ba àwọn ère, àgbélébùú, àti àwọn pẹpẹ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì jẹ́, wọ́n tilẹ̀ pànìyàn pàápàá. John Calvin, aṣáájú ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ilẹ̀ Faransé, nínú ìwé ìléwọ́ kékeré rẹ̀ náà, Declaration to Maintain the True Faith, polongo pé: “Ọlọ́run kò fẹ́ kí a dá àwọn ìlú tàbí àwọn ènìyàn sí.”

Àwọn ogun ìsìn mẹ́rin mìíràn jà tẹ̀ lé e. Ìkarùn-ún wá sópin ní 1576, nígbà tí Ọba Henry Kẹta sì fọwọ́ sí àdéhùn àlàáfíà tí ó fún àwọn Alátùn-únṣe ní òmìnira ìjọsìn kíkún níbi gbogbo ní ilẹ̀ Faransé. Paris, ìlú ńlá Kátólíìkì ìgbàlódé náà wá ṣọ̀tẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn, wọ́n sì lé Henry Kẹta, tí wọ́n kà sí ẹni tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Alátùn-únṣe ti pọ̀ jù, dà nù. Àwọn Kátólíìkì gbé ìjọba alátakò kan kalẹ̀, Àjọ Mímọ́ Kátólíìkì, tí Henry ti Guise ṣe aṣíwájú rẹ̀.

Níkẹyìn, ogun kẹjọ, tàbí Ogun Àwọn Henry Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, rí i tí Henry Kẹta (Kátólíìkì) kó wọnú àjọṣe pẹ̀lú ẹni tí yóò gba ipò rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, Henry ti Navarre (Pùròtẹ́sítáǹtì), ní ìdojúùjàkọ Henry ti Guise (Kátólíìkì). Henry Kẹta rọ́nà yọ́ kẹ́lẹ́ pa Henry ti Guise lójijì, àmọ́, ní August 1589, ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan tí ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Dominic yọ́ kẹ́lẹ́ pa Henry Kẹta fúnra rẹ̀ lójijì. Nípa bẹ́ẹ̀, Henry ti Navarre, tí wọ́n ti dá sí láìpa ní ọdún 17 ṣáájú, nígbà ìpakúpa Lọ́jọ́ Ìrántí Batolómíù “Mímọ́,” wá di Ọba Henry Kẹrin.

Níwọ̀n bí Henry Kẹrin ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Alátùn-únṣe, Paris kọ̀ láti wà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Àjọ Mímọ́ Kátólíìkì ṣètò àtakò tí ó mú ìdìhámọ́ra dání sí i jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Henry borí nínú ìjà ogun bíi mélòó kan, àmọ́, nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sípéènì kan dé láti ran àwọn Kátólíìkì lọ́wọ́, ó pinnu níkẹyìn láti kọ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì sílẹ̀, ó sì tẹ́wọ́ gba ìsìn Kátólíìkì. Nígbà tí wọ́n dé e ládé ní February 27, 1594, Henry wọ Paris, níbi tí àwọn ènìyàn, tí àwọn ogun náà ti tán lókun pátápátá, kókìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Nítorí èyí, àwọn Ogun Ìsìn ní ilẹ̀ Faransé dópin lẹ́yìn ohun tí ó lé ní 30 ọdún tí àwọn Kátólíkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì fi ń pa ara wọn lóòrèkóòrè. Ní April 13, 1598, Henry Kẹrin gbé Àṣẹ ti Nantes ọlọ́rọ̀ ìtàn jáde, èyí tí ó fàyè òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti ìjọsìn gba àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì. Gẹ́gẹ́ bí póòpù ti sọ, àṣẹ náà ni “ohun tí ó burú jù lọ tí a lè finú wòye, nítorí pé ó fàyè òmìnira ẹ̀rí ọkàn gba olúkúlùkù ènìyàn, tí ó jẹ́ ohun tí ó burú jáì lágbàáyé.”

Jákèjádò ilẹ̀ Faransé, àwọn Kátólíìkì ronú pé àṣẹ náà jẹ́ àìtẹ̀lé àdéhùn tí Henry ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ wọn. Ṣọ́ọ̀ṣì náà kò sinmi ìgbòkègbodò títí di, ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀rúndún kan lẹ́yìn náà, nígbà tí Louis Kẹrìnlá yí Àṣẹ ti Nantes náà pa dà, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe inúnibíni tí ó túbọ̀ le koko sí àwọn Alátùn-únṣe.

Èso Tí Ogun So

Nígbà tí ó di òpin ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, aásìkí tí ilẹ̀ Faransé ní ti pòórá. Ìdajì ilẹ̀ ọba náà ni wọ́n ti sàga ti, kó ní ìkógun, rà pa dà, tàbí sọ di ahoro. Àwọn sójà ń béèrè ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, tí ó ṣamọ̀nà sí ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ènìyàn gbáàtúù. Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ìlú, tí a ṣekú pa ọ̀pọ̀ lára wọn nípa ìdájọ́ ikú, ìpakúpa, ìlélọnílùú, àti ìsẹ́ni, ni iye wọn dín kù wọ ọ̀rúndún kẹtàdínlógún.

Lọ́nà tí ó hàn gbangba, àwọn Kátólíìkì ti borí nínú Àwọn Ogun Ìsìn ní ilẹ̀ Faransé. Àmọ́, Ọlọ́run ha bù kún ìjagunmólú wọn bí? Dájúdájú, kò rí bẹ́ẹ̀. Bí gbogbo ìpànìyàn lórúkọ Ọlọ́run yìí ti kó àárẹ̀ bá àwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé, ọ̀pọ̀ lára wọn di aláìnífẹ̀ẹ́-sí-ìsìn. Àwọn ni aṣáájú nínú ohun tí a ti pè ní ìdarí èrò orí ìṣòdìsí-ìsìn-Kristẹni ní ọ̀rúndún kejìdínlógún.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“Ọlọ́run kò fẹ́ kí a dá àwọn ìlú tàbí àwọn ènìyàn sí.” Ni ohun tí àṣáájú ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ilẹ̀ Faransé polongo

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo Kò Juwọ́ Sílẹ̀—Kí Ni Ìyọrísí Rẹ̀?

PIERRE VALDES, tàbí Peter Waldo, jẹ́ oníṣòwò tí ó lọ́rọ̀ ní ọ̀rúndún kejìlá ní ilẹ̀ Faransé. Lákòókò yí tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn ènìyàn sínú òkùnkùn nípa Bíbélì, Waldo fowó ṣètìlẹ́yìn fún ìtumọ̀ Àwọn Ìhìn Rere àti àwọn ìwé mìíràn nínú Bíbélì sí èdè tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé. Ó wá fi iṣẹ́ okòwò rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbájú mọ́ wíwàásù Ìhìn Rere náà. Kò pẹ́ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn dara pọ̀ mọ́ ọn, nígbà tí ó sì di 1184, Póòpù Lucius Kẹta yọ òun àti àwọn olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀ níjọ.

Bí àkókò ti ń lọ, àwùjọ àwọn oníwàásù tí èrò wọn dá lórí Bíbélì wọ̀nyí di ẹni tí a mọ̀ sí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo. Wọ́n ṣalágbàwí pípadà sórí àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà ìsìn Kristẹni ní ìjímìjí. Wọ́n kọ àwọn àṣà àti èrò ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ Kátólíìkì sílẹ̀, títí kan ìsanpadà owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àdúrà fún àwọn òkú, pọ́gátórì, ìjọsìn Màríà, àdúrà sí “àwọn ẹni mímọ́,” ìrìbọmi ọmọ-ọwọ́, jíjúbà àgbélébùú, àti ìgbàgbọ́ ìyípadàdi-gidi àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ ara Olúwa. Ní àbáyọrí rẹ̀, ìgbà gbogbo ni Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo máa ń jìyà púpọ̀ lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Òpìtàn Will Durant ṣàlàyé ipò náà nígbà tí Ọba Francis Kìíní kéde ìwọ́de kan lòdì sí àwọn tí kì í ṣe Kátólíìkì pé:

“Kádínà de Tournon, nígbà tí ó ń fẹ̀sùn kan Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo pé wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ láti dojú ìjọba dé, rọ Ọba tí ń ṣàìsàn, tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ náà láti fọwọ́ sí àṣẹ kan (January 1, 1545) pé kí a pa gbogbo Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo tí wọ́n jẹ̀bi àdámọ̀. . . . Láàárín ọ̀sẹ̀ kan (April 12 sí 18) wọ́n sun àwọn abúlé mélòó kan níná; nínú ọ̀kan lára wọn, àwọn 800 ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé ni wọ́n pa; láàárín oṣù méjì, àwọn 3,000 ni wọ́n pa, wọ́n pa abúlé méjìlélógún run, wọ́n rán àwọn 700 ọkùnrin lọ sínú àwọn ọkọ̀ òkun ológun. Iná tí a dá sí àbáwọlé hòrò kan, pa àwọn obìnrin 25 tí jìnnìjìnnì bò, tí wọ́n ń wá ìsádi nínú hòrò náà.”

Nípa irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọlọ́rọ̀ ìtàn bẹ́ẹ̀, Durant sọ pé: “Àwọn inúnibíni wọ̀nyí ló mú kí ìṣàkóso Francis forí ṣánpọ́n lọ́nà kíkàmàmà.” Àmọ́, kí ní ìyọrísí rẹ̀ lórí àwọn tí wọ́n ṣàkíyèsí ìdúróṣinṣin Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo lákòókò inúnibíni tí ọba fàṣẹ sí náà? Durant kọ̀wé pé: “Ìgboyà tí àwọn ajẹ́rìíkú náà ní fi iyì àti ògo fún ohun tí wọ́n jà fún; ó gbọ́dọ̀ ti wú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òǹwòran lórí, kí ó sì dà wọ́n láàmú, àwọn tó jẹ́ pé, láìsí àwọn ìṣekúpani gbígbàfiyèsí wọ̀nyí, wọ́n lè má ṣe wàhálà láti yí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti jogún pa dà.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìpakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní Vassy tanná ran àwọn ogun ìsìn

[Credit Line]

Bibliothèque Nationale, Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìpakúpa Lọ́jọ́ Ìrántí Batolómíù “Mímọ́,” nínú èyí tí àwọn Kátólíìkì ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì

[Credit Line]

Fọ́tò Musée cantonal des Beaux-Arts, Lausanne

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì pa àwọn Kátólíìkì wọ́n sì ba ohun ìní ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ (lókè àti nísàlẹ̀)

[Àwọn Credit Line]

Bibliothèque Nationale, Paris

Bibliothèque Nationale, Paris

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́