Sísálọ Àwọn Alátùn-únṣe Kí Wọ́n Lè Lómìnira
“Lọ́lá Ọba àti Ayaba. . . . A lo àǹfààní yìí láti Kéde Pé, gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tí ń bẹ nílẹ̀ Faransé tí ó bá wá Ààbò wá sábẹ́ Ìjọba Wa, tí wọ́n sì fúnra wọn Wá síhìn-ín, yóò rí Ààbò Ọba . . . A Óò Sì tún Sa gbogbo Ipá Wa ní gbogbo Ọ̀nà láti Tì wọ́n Lẹ́yìn, láti Ràn wọ́n Lọ́wọ́ àti láti Tọ́jú wọn . . . kí ìgbésí ayé wọn àti wíwà wọn lábẹ́ Àkóso yìí lè dẹ̀ wọ́n lọ́rùn, kí ó sì tù wọ́n lára.”
BÍ ÌKÉDE tí William àti Mary, ọba àti ayaba England, ṣe ní ọdún 1689 ti kà nìyẹn. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tí ń bẹ nílẹ̀ Faransé, tàbí àwọn Alátùn-únṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wọ́n sì, ṣe ní láti wá ìsádi àti ààbò lọ sẹ́yìn òde ilẹ̀ Faransé? Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwa tí ń gbé lóde òní nífẹ̀ẹ́ sí mímọ ohun tí ó fa sábàbí sísá tí wọ́n sá kúrò nílẹ̀ Faransé ní bí 300 ọdún sẹ́yìn?
Ogun àti ìjà ẹ̀sìn kò jẹ́ kí Yúróòpù ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún rímú mí rárá. Rògbòdìyàn yìí kò yọ ilẹ̀ Faransé sílẹ̀, nítorí Ogun Ẹ̀sìn tí ó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì (1562-1598). Ṣùgbọ́n, ní ọdún 1598, Ọba Henry Kẹrin ti ilẹ̀ Faransé fọwọ́ sí òfin ìfàyègbẹ̀sìn mìíràn, Òfin Nantes, tí ó fún àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Alátùn-únṣe lómìnira ẹ̀sìn díẹ̀. Irú fífàyègbẹ̀sìn méjì báyìí lábẹ́ òfin kò ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn Yúróòpù. Fún sáà kan, ó fi òpin sí rúkèrúdò ẹ̀sìn tí ó ti ń bá ilẹ̀ Faransé ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún fínra fún ohun tó lé ní 30 ọdún.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ète wọn ni pé kí Òfin Nantes “wà pẹ́ títí, kí ó mà sì ṣeé yí padà,” ní ọdún 1685, Òfin Fontainebleau fagi lé e. Lẹ́yìn èyí, ọlọ́gbọ́n èrò orí, ará ilẹ̀ Faransé náà, Voltaire, ṣàpèjúwe ìfagilé yìí gẹ́gẹ́ bí “ọ̀ràn ìbànújẹ́ jù lọ tí ó tí ì dé bá ilẹ̀ Faransé.” Láàárín àkókò díẹ̀, àbájáde rẹ̀ ni pé nǹkan bí 200,000 àwọn Alátùn-únṣe sá lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn. Ṣùgbọ́n, díẹ̀ lásán nìyẹn lára àwọn àbájáde rẹ̀. Kí tilẹ̀ ní ìdí tí wọ́n fi fagi lé òfin àkọ́kọ́ tí ó fàyè gbẹ̀sìn mìíràn?
Ìbẹ̀rẹ̀ Ni Wọ́n Ti Ta Kò Ó
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí 90 ọdún ni Òfin Nantes fi wà lẹ́nu iṣẹ́, òpìtàn kan sọ pé “kó tó di pé a pa á pátápátá ní ọdún 1685 pàápàá ni ó ti ń kú lọ.” Lóòótọ́, a kò gbé òfin náà karí ìpìlẹ̀ tí ó lágbára. Láti ìbẹ̀rẹ̀, ó ti dá kún ohun tí a ti ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ìjà orogún” láàárín àwọn àlùfáà Kátólíìkì àti ẹ̀sìn tí wọ́n pè ní “R.P.R.” (Ẹ̀sìn Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì) Láti ìgbà tí a ti gbé Òfin Nantes kalẹ̀ ní ọdún 1598 títí di nǹkan bí ọdún 1630, ìjiyàn ìta gbangba láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì àti Kátólíìkì àti nínú àwọn ìwé ẹ̀sìn ni ó máa ń fa àtakò tí a ń ṣe sí i. Àmọ́ ṣá o, àìfàyègbẹ̀sìn pín sí onírúurú ọ̀nà.
Lẹ́yìn ogun tí ìjọba ilẹ̀ Faransé bá àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì jà láàárín ọdún 1621 sí 1629, ó gbìyànjú láti gbé onírúurú ìgbésẹ̀ ìfipámúni láti mú kí wọn wọnú agbo ẹ̀sìn Kátólíìkì. Lábẹ́ ìṣàkóso Louis Kẹrìnlá, “Ọba Oòrùn,” ìfòòró náà tún légbá kan. Ìlànà inúnibíni rẹ̀ ni ó yọrí sí fífagi lé Òfin Nantes.
Ìkálọ́wọ́kò Pátápátá
Gẹ́gẹ́ bí apá kan ìkálọ́wọ́kò pátápátá náà, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ a gba àwọn ẹ̀tọ́ ti gbogbo gbòò tí àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ní lọ́wọ́ wọn. Ní ọdún 1657 sí 1685, a ṣe nǹkan bí 300 òfin, tó jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, àwùjọ àlùfáà ni ó dábàá rẹ̀, ní ìlòdì sí àwọn Alátùn-únṣe. Àwọn òfin wọnnì nípa lórí gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. Fún àpẹẹrẹ, a ka lílọ́wọ́ nínú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe, bí iṣẹ́ dókítà, amòfin, àní agbẹ̀bí pàápàá, léèwọ̀ fún àwọn Alátún-únṣe. Ní ti isẹ́ agbẹ̀bí, òpìtàn kan sọ pé: “Báwo ni a ṣe lè gbé ìwàláàyè ẹni lé aládàámọ̀ lọ́wọ́, ẹni tí góńgó rẹ̀ jẹ́ láti pa ètò tí ó wà nílẹ̀ run?”
Wọ́n túbọ̀ mú ìnilára náà le sí i ní ọdún 1677. Alátùn-únṣe èyíkéyìí tí a bá gbá mú, tí ń gbìyànjú láti yí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan lọ́kàn padà yóò san ẹgbẹ̀rún kan pọ́n-ùn owó ilẹ̀ Faransé gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn. Wọ́n lo owó tí ìjọba rí nínú owó orí gègèrè láti yí àwọn Alátùn-únṣe lọ́kàn padà. Ní ọdún 1675, àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì gbé mílíọ̀nù 4.5 pọ́n-ùn ti ilẹ̀ Faransé fún Ọba Louis Kẹrìnlá, wọ́n sọ pé: “Wàyí o, máa fi ìwà ìmoore rẹ̀ hàn nípa lílo ọlá àṣẹ rẹ láti pa àwọn aládàámọ̀ run pátápátá.” Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ti “fífowó ra” àwọn ọmọlẹ́yìn tuntun yìí yọrí sí nǹkan bí 10,000 tí ó di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì láàárín ọdún mẹ́ta.
Ní ọdún 1663, a kéde pé dídi ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tàpá sófin. Ìkálọ́wọ́kò tún wà nípa ibi tí àwọn Alátùn-únṣe lè gbé. Ọ̀kan nínú àwọn ìgbésẹ̀ lílégbá kan tí wọ́n gbé ni pé àwọn ọmọ ọdún méje lè di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì bí àwọn òbí wọn pàápàá kò bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Wọ́n fipá mú àwọn òbí tí í ṣe ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì láti sanwó ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọ wọn ń kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit tàbí àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì mìíràn.
Irinṣẹ́ mìíràn tí wọ́n lò láti tẹ àwọn Alátùn-únṣe rì ni àjọ ìmùlẹ̀ Compagnie du Saint-Sacrement (Ẹgbẹ́ Sákírámẹ́ǹtì Mímọ́). Ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan tí òpìtàn Janine Garrisson sọ pé ó jẹ́ “ìsokọ́ra rẹpẹtẹ” tí ó gba gbogbo ilẹ̀ Faransé pátá. Níwọ̀n bí kò ti sí apá ibi tí kò dé láwùjọ, owó àti ìsọfúnni àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kò wọ́n ọn. Garrisson ṣàlàyé pé ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ: “Láti orí ìfipámúni dé ìfòfindeni, ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí títí dorí ìfibú, àjọ Compagnie lo gbogbo ọ̀nà tí ó mọ̀ láti káàárẹ̀ bá àwùjọ Pùròtẹ́sítáǹtì.” Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Alátùn-únṣe kò kúrò ní ilẹ̀ Faransé lákòókò inúnibíni yìí. Òpìtàn Garrisson kọ̀wé pé: “Ó ṣòro láti mọ ìdí tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì kò fi kúrò ní sàkání Ìjọba náà bí ìkórìíra náà ti ń pọ̀ sí i.” Àmọ́, nígbà tí ó yá, ó pọndandan pé kí wọ́n sá lọ nítorí òmìnira.
Pípadà sí Ẹsẹ Àárọ̀
Àdéhùn Àlàáfíà ti Nymegen (1678) àti Àdéhùn Ìdáwọ́ọ̀jà-dúró ti Ratisbon (1684) gba Ọba Louis Kẹrìnlá lọ́wọ́ ogun ilẹ̀ òkèèrè. Ní February 1685, ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan jọba ní òdì kejì àwọn erékùṣù Channel ní England. Louis Kẹrìnlá lè lo àǹfààní ipò tuntun yìí. Ní ọdún mélòó kan ṣáájú, àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì ní ilẹ̀ Faransé gbé Òfin Mẹ́rin ti Gaul jáde, èyí tí ó dín agbára póòpù kù. Nígbà náà lọ́hùn-ún, Póòpù Innocent Kọkànlá “wo Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Faransé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tí ó dà bí èyí tí ń dá ìyapa sílẹ̀.” Nítorí náà, nípa fífagi lé Òfin Nantes, Louis Kẹrìnlá lè tún orúkọ rẹ̀ tí a ti bà jẹ́ ṣe, kí ó sì padà mú kí àárín òun pẹ̀lú póòpù gún.
Ọwọ́ tí ọba fẹ́ fi mú àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì wá túbọ̀ ṣe kedere. Ó hàn gbangba pé wọn kò fẹ́ gba ojú bọ̀rọ̀ (ìyíléròpadà àti òfin). Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, lílo àwọn afipámúni-yẹ́sìnpadàa láìpẹ́ yìí wá kẹ́sẹ járí. Nítorí náà ní ọdún 1685, Louis Kẹrìnlá fọwọ́ sí Òfin ti Fontainebleau, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fagi lé Òfin Nantes. Inúnibíni oníwà ipá tí ó bá fífagi lé òfin náà rìn mú kí ipò tí àwọn Alátùn-únṣe wà lẹ́yìn fífagi lé Òfin ti Nantes burú ju ipò ti wọ́n wà ṣáájú kí a tó fagi lé e. Kí ni wọn yóò wá ṣe báyìí o?
Ṣé Kí Wọ́n Sá Pa Mọ́ Ni, Àbí Kí Wọ́n Jà, Àbí Kí Wọ́n Sá Lọ?
Àwọn alátùn-únṣe kan yàn láti máa jọ́sìn ní bòókẹ́lẹ́. Nígbà tí a ba ibi ìpàdé wọn jẹ́, tí a sì fòfin de ìjọsìn wọn ní gbangba, wọ́n yíjú sí ‘Ṣọ́ọ̀ṣì Aṣálẹ̀,’ tàbí ìjọsìn abẹ́lẹ̀. Wọ́n ṣe èyí láìka òtítọ́ náà sí pé àwọn tí ń ṣe irú ìpàdé bẹ́ẹ̀ ń fara wọn wewu gbígba ìdájọ́ ikú, gẹ́gẹ́ bí òfin tí a gbé kalẹ̀ ní July 1686. Àwọn Alátùn-únṣe kan sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n ronú pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ yóò ṣeé ṣe láti padà sínú ẹ̀sìn wọn. Irú àwọn tí ó yí padà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì afaraṣe-máfọkànṣe, tí àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò kọ́ àpẹẹrẹ wọn.
Ìjọba gbìyànjú láti sọ yíyí ẹ̀sìn padà di ohun pàtàkì. Láti lè ríṣẹ́, àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ẹ̀sìn wọn padà gbọ́dọ̀ fi ìwé ẹ̀rí wọn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì hàn, tí àlùfáà àgbègbè wọn, tí ń kíyè sí àwọn tí ń wá sí ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́dọ̀ fọwọ́ sí. Bí a kò bá batisí àwọn ọmọ kí a sì tọ́ wọn dàgbà gẹ́gẹ́ bí Kátólíìkì, a lè gbà wọ́n lọ́wọ́ òbí wọn. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ gbọ́dọ̀ gbé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì lárugẹ. Wọ́n sapá láti mú àwọn ìwé tí ń gbé ẹ̀sìn Kátólíìkì lárugẹ jáde fún “àwọn ènìyàn Ìwé náà [Bíbélì],” gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ìjọba tẹ ìwé tí ó lé ní mílíọ̀nù kan jáde, ó sì kó wọn lọ sí àwọn àgbègbè tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti yí ẹ̀sìn wọn padà. Àwọn ìgbésẹ̀ náà le débi pé bí ẹnì kan tí ara rẹ̀ kò dá bá kọ ààtò ìkẹyìn ti ẹ̀sìn Kátólíìkì, tí ara rẹ̀ sì wá yá lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọn ó jù ú sẹ́wọ̀n gbére tàbí kí ó di ẹrú nínú ọkọ̀ òkun alájẹ̀ títí ayé. Tí onítọ̀hún bá sì wá kú, orí ààtàn ni wọn ó ju òkú rẹ̀ sí, wọn ó sì gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo dúkìá rẹ̀.
Àwọn Alátùn-únṣe kan di ajìjàgbara. Ní ẹkùn Cévennes, tí a mọ̀ fún ìtara ìsìn rẹ̀, àwọn ọmọ ogun Alátùn-únṣe tí a ń pè ní Camisards dìtẹ̀ ní ọdún 1702. Ní dídáhùnpadà sí bíba tí àwọn Camisards ń ba ní ibùba, tí wọ́n sì ń jagun lóru, àwọn ọmọ ogun ìjọba dáná sun àwọn abúlé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun ìdákúrekú tí àwọn Alátùn-únṣe ń jà bá a lọ fún sáà kan, nígbà tí ó di ọdún 1710, agbára àwọn ọmọ ogun Ọba Louis ti run àwọn Camisards.
Ohun mìíràn tí àwọn Alátùn-únṣe ṣe ni pé, wọ́n sá lọ sí ilẹ̀ Faransé. A pe sísá tí wọ́n sá jáde yìí ní ojúlówó ìjádelọ. Nígbà tí wọn yóò fi sá lọ, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Alátùn-únṣe ti di òtòṣì, nítorí pé ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé ohun ìní wọn, tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sì ti gba apá kan ọrọ̀ wọn. Nítorí náà kò rọrùn láti sá lọ. Ìjọba ilẹ̀ Faransé dáhùn padà kíámọ́sá sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ àwọn ọ̀nà tí ó gba inú ìlú jáde, wọ́n sì ń yẹ inú àwọn ọkọ̀ òkun wò. Àwọn jàgùdà ojú omi dá àwọn ọkọ̀ òkun tí ń fi ilẹ̀ Faransé sílẹ̀ lọ́nà, nítorí wọn yóò rí owó rẹpẹtẹ gbà bí wọ́n bá rí àwọn tí ń sá lọ gbá mú. Àwọn Alátùn-únṣe tí a gbá mú pé wọ́n ń sá lọ jẹ baba ńlá ìyà. Láti mú kí ọ̀ràn náà burú sí i, àwọn amí tí ń bá àwùjọ ṣiṣẹ́ gbìyànjú láti rí orúkọ àwọn tí ń wéwèé láti sá lọ àti ọ̀nà tí wọ́n fẹ́ gbà. Kíkọ̀wé mọ́ni, yíyíwèé, àti ìfọgbọ́nmúni wá di ohun tí ó gbalégbòde.
Ìsádi Tí A fi Tayọ̀tayọ̀ Tẹ́wọ́ Gbà
Sísá tí àwọn Alátùn-únṣe sá kúrò ní ilẹ̀ Faransé àti bí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sá lọ sí ṣe gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ ni a pè ní Ìsádi. Àwọn Alátùn-únṣe sá lọ sí Holland, Switzerland, Germany, àti England. Lẹ́yìn náà, àwọn kan sá lọ sí Scandinavia, America, Ireland, West Indies, Gúúsù Áfíríkà, àti Rọ́ṣíà.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù ṣòfin tí ó fún àwọn Alátùn-únṣe níṣìírí láti máa sá bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn. Lára ohun amóríwú tí wọ́n nawọ́ rẹ̀ sí wọn ní sísọ wọ́n di ọmọ onílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, yíyọ̀ǹda pé kí wọ́n má san owó orí, àti jíjẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ oníṣòwò láìsan kọ́bọ̀. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Elisabeth Labrousse ti sọ, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Alátùn-únṣe jẹ́ “ọ̀dọ́mọkùnrin . . . alákíkanjú, alágbára tí wọ́n ní ìwà ọmọlúwàbí títayọ.” Nípa báyìí, ilẹ̀ Faransé, ní òtéńté agbára rẹ̀, pàdánù àwọn òṣìṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ọwọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, “dúkìá, aásìkí, àti ọgbọ́n” ti lọ sókè òkun. Àwọn kókó tí ó tan mọ́ ti ẹ̀sìn àti ti ìṣèlú tún kó ipa kan nínú fífún àwọn Alátùn-únṣe ní ìsádi. Ṣùgbọ́n kí wá ní àbájáde onígbà pípẹ́ ti jíjáde lọ yìí?
Fífagi lé Òfin Nantes àti gbígbé inúnibíni dìde ru ìbínú àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé sókè. Àǹfààní èrò títako ìlànà ìjọba ilẹ̀ Faransé ni William ti Orange lò tí ó fi di alákòóso ilẹ̀ Netherland. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ òṣìṣẹ́ àwọn Alátùn-únṣe, ó tún di ọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní rírọ́pò James Kejì tí í ṣe ẹlẹ́sìn Kátólíìkì. Òpìtàn Philippe Joutard ṣàlàyé pé: “Ìlànà tí Louis Kẹrìnlá gbé kalẹ̀ nípa àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì jẹ́ ọ̀kan lára ìdí pàtàkì tí a fi gbàjọba lọ́wọ́ James Kejì [tí a sì] fi dá ìmùlẹ̀ Augsburg sílẹ̀. . . . Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ [wọ̀nyí] sàmì sí àkókò ìyípadà pàtàkì nínú ìtàn Yúróòpù, èyí tí ó yọrí sí gbígborí tí ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gborí lọ́wọ́ ìjọba ilẹ̀ Faransé.”
Àwọn Alátùn-únṣe kó ipa pàtàkì ní ti àṣà ìbílẹ̀ ní Yúróòpù. Wọ́n lo òmìnira wọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà láti mú àwọn ìwé tí ó ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnṣe ìmọ̀ ọ̀ràn nípa Ìlàlọ́yẹ̀ àti èrò ìfàyègbẹ̀sìn mìíràn jáde. Fún àpẹẹrẹ, láti lè gbé èrò ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lárugẹ, Pùròtẹ́sítáǹtì kan tí ó jẹ́ ara ilẹ̀ Faransé, túmọ̀ ìwé tí ọlọ́gbọ́n èrò orí, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, John Locke kọ. Àwọn òǹkọ̀wé mìíràn tí ó jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì òmìnira ẹ̀rí-ọkàn. Èrò náà dìde pé ìgbọràn sí àwọn alákòóso ní ààlà, a sì lè pa á tì bí wọ́n bá ba àdéhùn tí ó wà láàárín àwọn àti àwọn aráàlú jẹ́. Nípa báyìí, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Charles Read ti ṣàlàyé, fífagi lé Òfin Nantes jẹ́ “ọ̀kan lára kókó tí ó hàn kedere pé ó fa Ìyípadà Tegbòtigaga ti Ilẹ̀ Faransé.”
Èyí Ha Kọ́ Wọn Lọ́gbọ́n Bí?
Nígbà tí a fún Marquis de Vauban, olùdámọ̀ràn ọ̀ràn ológun fún Ọba Louis Kẹrìnlá, ní àbájáde inúnibíni náà àti iye àwọn ènìyàn pàtàkì tí wọ́n ti pàdánù sí àwọn ilẹ̀ mìíràn, ó rọ ọba náà láti padà fi ìdí Òfin Nantes múlẹ̀, ó wí pé: “Ọlọ́run nìkan ni ó lè yíni lọ́kàn padà.” Nítorí náà, èé ṣe tí Ìjọba ilẹ̀ Faransé kò fi kẹ́kọ̀ọ́ nínú èyí, kí ó sì yí ìpinnu rẹ̀ padà? Dájúdájú ìdí kan ni pé ẹ̀rù ń ba ọba náà pé pípadà fìdí òfin náà múlẹ̀ yóò dín agbára orílẹ̀-èdè náà kù. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣàǹfààní jù láti kúkú fàyè gba ìmúsọjí ẹ̀sìn Kátólíìkì àti àìfàyègbẹ̀sìn mìíràn ti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ti ilẹ̀ Faransé.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yí fífagi lé òfin náà ká ti mú kí àwọn kan béèrè pé, “Ẹ̀sìn mélòó ni ó tọ́ kí àwùjọ kan fàyè gbà?” Ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn ti sọ, kò ṣeé ṣe láti gbé ìtàn àwọn Alátùn-únṣe yẹ̀ wò láìronú nípa “bí agbára ṣe ń gunni gàràgàrà àti bí a ti ṣe ṣì í lò.” Nínú àwọn àwùjọ tí ẹ̀yà àti ẹ̀sìn ọlọ́kan-ò-jọ̀kan ti ń pọ̀ sí i lónìí, sísá tí àwọn Alátùn-únṣe sá lọ nítorí òmìnira jẹ́ ìránnilétí gbọnmọ-gbọnmọ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá jẹ́ kí ẹ̀mí òṣèlú tí ṣọ́ọ̀ṣì súnná sí borí ire àwọn ènìyàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpótí lójú ìwé 28.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìfipámúni-Yẹ́sìnpadà
Kó Ìpayà Bá Wọn
Àwọn kan wo àwọn afipámúni-yẹ́sìnpadà gẹ́gẹ́ bí “àwọn míṣọ́nnárì tí ó pegedé.” Ṣùgbọ́n, ohun tí ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn Alátùn-únṣe ni wọ́n jẹ́, àní nínú àwọn ọ̀ràn kan, tí wọ́n bá gbọ́ pé wọ́n ti dé, odindi abúlé kan yóò yí padà di Kátólíìkì lọ́gán. Ṣùgbọ́n àwọn wo ni àwọn afipámúni-yẹ́sìnpadà wọ̀nyí?
Àwọn afipámúni-yẹ́sìnpadà jẹ́ àwọn sójà tí ó dìhámọ́ra háháhá tí a fún láṣẹ láti máa gbé nínú ilé àwọn Alátùn-únṣe láti lè kó ìpayà bá àwọn alájọgbé wọn. Lílò wọ́n lọ́nà yìí ni a ń pè ní ìfipámúni-yẹ́sìnpadà. Láti lè mú kí hílàhílo tí wọ́n mú wá bá ọ̀pọ̀ ìdílé pọ̀ sí i, iye sójà tí wọ́n máa ń rán sínú ilé kan máa ń ju iye ẹnu tí ìdílé náà lè bọ́ lọ. A fún àwọn afipámúni-yẹ́sìnpadà láṣẹ láti ṣe ìdílé bí ọṣẹ ti ń ṣojú, kí wọ́n máà jẹ́ kí wọ́n róorun sùn, kí wọ́n sì ba dúkìá wọn jẹ́. Bí àwọn olùgbé ilé náà bá gbà láti kúrò nínú ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, àwọn afipámúni-yẹ́sìnpadà pẹ̀lú á fi ilé wọn sílẹ̀.
Wọ́n lo ìfipámúni-yẹ́sìnpadà láti mú kí ọ̀pọ̀ yí ẹ̀sìn wọn padà ní ọdún 1681 ní Poitou, Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Faransé, àgbègbè kan tí àwọn Alátùn-únṣe pọ̀ sí gan-an. Láàárín oṣù díẹ̀, 30,000 sí 35,000 ti yí ẹ̀sìn wọn padà. Wọ́n lo ọ̀nà kan náà ní ọdún 1685 ní àwọn àgbègbè mìíràn tí àwọn Alátùn-únṣe ń gbé. Láàárín oṣù díẹ̀, 300,000 sí 400,000 ti sẹ́ ẹ̀sìn wọn. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Jean Quéniart, ti sọ, ìkẹ́sẹjárí àwọn afipámúni-yẹ́sìnpadà “mú kí Fífagi Lé [Òfin Nantes nípa fífàyègbẹ̀sìn mìíràn] dí èyí tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, nítorí pé ó wá dà bí ohun tí ó ṣeé ṣe.”
[Credit Line]
© Cliché Bibliothèque Nationale de France, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìkéde yìí tí a ṣe ní ọdún 1689 fún àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì Ilẹ̀ Faransé tí ń wá ìdáǹdè kúrò lábẹ́ àwọn aninilára onísìn ní ìsádi
[Credit Line]
Nípasẹ̀ àṣẹ The Huguenot Library, Huguenot Society of Great Britain and Ireland, London
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Fífagi lé Òfin Nantes, 1685 (Ojú ìwé àkọ́kọ́ ìfagilé náà rèé)
[Credit Line]
Documents conservés au Centre Historique des Archives nationales à Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọ̀pọ̀ tẹ́ńpìlì ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ni a bà jẹ́
[Credit Line]
© Cliché Bibliothèque Nationale de France, Paris