Òmìnira Ìsìn—Ìbùkún ni Tàbí Ègún
Ó gba iṣẹ́ ńláǹlà kí èrò nípa òmìnira ìsìn tó wáyé nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ó jẹ́ ìwàyá ìjà pẹ̀lú èrò tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ẹ̀tanú, àti àìfún ẹ̀sìn lómìnira. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí ló ti ṣòfò sórí rẹ̀ nínú àwọn ogun ìsìn. Kí ni ìtàn tí ń bani nínú jẹ́ yìí fi kọ́ wa?
ROBIN Lane Fox kọ ọ́ sínú ìwé rẹ̀ Pagans and Christians pé: “Ohun kan tí ń bá a lọ ni inúnibíni jẹ́ nínú ìtàn Kristẹni.” A pe àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní ẹ̀ya ìsìn, a sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń yọ ìlú lẹ́nu. (Ìṣe 16:20, 21; 24:5, 14; 28:22) Ní àbáyọrí rẹ̀, àwọn kan jìyà ìdálóró, àwọn ẹranko ẹhànnà sì pa wọ́n ní àwọn gbọ̀ngàn eré ìjàkadì ní Róòmù. Lójú irú inúnibíni bíburújáì bẹ́ẹ̀, àwọn kan, bí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Tertullian (wo àwòrán lójú ewé kẹjọ), jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún òmìnira ìsìn. Ní ọdún 212 Sànmánì Tiwa, ó kọ̀wé pé: “Ó jẹ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí ó ṣe pàtàkì, ẹ̀tọ́ àbímọ́ni, pé ìjọsìn olúkúlùkù gbọ́dọ̀ dá lórí ohun tó bá gbà gbọ́.”
Ní ọdún 313 Sànmánì Tiwa, inúnibíni tí ilẹ̀ Róòmù ń ṣe sí àwọn Kristẹni wá sópin lábẹ́ ìṣàkóso Constantine, pẹ̀lú Òfin Milan, tí ó fàyè òmìnira ìsìn gba àwọn Kristẹni àti kèfèrí. Fífìdí “ìsìn Kristẹni” múlẹ̀ lábẹ́ òfin ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù fòpin sí inúnibíni náà. Ṣùgbọ́n ní nǹkan bí ọdún 340 Sànmánì Tiwa, òǹkọ̀wé kan tó pe ara rẹ̀ ní Kristẹni ní kí a ṣenúnibíni sí àwọn kèfèrí. Níkẹyìn, ní ọdún 392 Sànmánì Tiwa, nípasẹ̀ Òfin Constantinople, Ọba Theodosius Kìíní fòfin de ìsìn àwọn kèfèrí, òmìnira ìsìn sì forí ṣánpọ́n láìtọ́jọ́. Níwọ̀n bí “ìsìn Kristẹni” ti Róòmù ti jẹ́ ìsìn Orílẹ̀-èdè, Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba dáwọ́ lé ìgbétáásì inúnibíni fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, èyí tó dé òtéńté rẹ̀ nígbà Ogun Ìsìn tó gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn láàárín ọ̀rúndún kọkànlá sí ìkẹtàlá àti nígbà ìwà òǹrorò ti àwọn Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kejìlá. Wọ́n ka àwọn tí wọ́n gbójú gbóyà gbé ìbéèrè dìde sí ìgbàgbọ́ gbogbo gbòò tí a gbé kalẹ̀, ìnìkàndarí ìgbàgbọ́ ìsìn, sí aládàámọ̀, wọ́n sì wá wọn kàn ní sáà tí a ń fòòró àwọn elérò mìíràn. Kí ló wà lẹ́yìn irú àwọn ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀?
Ìdí tí wọ́n ṣe fàyè gba àìfún ẹ̀sìn lómìnira ni pé ìṣọ̀kan ìsìn ló jẹ́ ìpìlẹ̀ lílágbára jù lọ tí Orílẹ̀-èdè náà ní àti pé àwọn àìfohùnṣọ̀kan tó wà nínú ìsìn ń yọ ìlú lẹ́nu. Ní England, ní ọdún 1602, ọ̀kan lára àwọn mínísítà Elizabeth Ọbabìnrin England sọ pé: “Ẹ̀mí Orílẹ̀-èdè kò dè tó bá fi lè gba ẹ̀sìn méjì láyè.” Ní gidi, ó túbọ̀ rọrùn láti fòfin de àwọn oníyapa ìsìn ju láti wádìí bóyá wọ́n jẹ́ ìyọnu fún Orílẹ̀-èdè tàbí fún ìsìn tí wọ́n dá sílẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia sọ pé: “Àwọn aláṣẹ ayé àti àwọn aláṣẹ ìsìn kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàárín àdámọ̀ tó léwu àti èyí tí kò léwu.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nǹkan kò ní pẹ́ yí padà.
Fífún Ẹ̀sìn Lómìnira Dé Pẹ̀lú Ìroragógó
Rúkèrúdò tí àwọn onísìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ẹgbẹ́ oníyapa kan tí ó kọ̀ láti kógbá sílé, dá sílẹ̀ ló fa ìyípadà wá ní Yúróòpù. Pẹ̀lú ìyárakánkán tí ó yani lẹ́nu, Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe Pùròtẹ́sítáǹtì pín ilẹ̀ Yúróòpù ní ti ọ̀ràn ìsìn, wọ́n sì gbé èrò nípa òmìnira ẹ̀rí-ọkàn jáde. Fún àpẹẹrẹ, gbajúmọ̀ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe náà, Martin Luther, dá èrò rẹ̀ láre ní 1521, nípa sísọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń darí ẹ̀rí-ọkàn mi.” Ìpínyà tún tanná ran Ogun Ọlọ́gbọ̀n Ọdún náà (1618 sí 1648), ọ̀wọ́ àwọn ogun bíburújáì tí ó fọ́ Yúróòpù túútúú.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun ń jà lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn wá mọ̀ pé ìforígbárí kì í mú ìtẹ̀síwájú wá. Nípa bẹ́ẹ̀, onírúurú òfin, bí Òfin Nantes ní ilẹ̀ Faransé (1598), gbìyànjú láti fìdí àlàáfíà múlẹ̀ ní Yúróòpù tí ogun ti sọ di ìdàkudà, àmọ́ pàbó ló já sí. Inú àwọn òfin wọ̀nyí ni èrò fífún ẹ̀sìn lómìnira tí a ń pariwo lóde òní ti bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá díẹ̀díẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, “fífún ẹ̀sìn lómìnira” ní ìtumọ̀ òdì. Olókìkí ọ̀mọ̀wé náà, Erasmus, kọ̀wé ní 1530 pé: “Bí a bá ní láti fàyè gba àwọn ẹ̀ya ìsìn mìíràn lábẹ́ àwọn ipò kan . . . , kò sí iyè méjì pé nǹkan ibi ni yóò jẹ́—nǹkan ibi gbáà—àmọ́ kò ní burú tó ogun.” Nítorí èrò òdì yìí, àwọn kan bí ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Paul de Foix, ní 1561, yàn láti sọ̀rọ̀ nípa “òmìnira ìsìn” dípò “fífún ẹ̀sìn lómìnira.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí àkókò ti ń lọ, a wá rí i pé a kò ka fífún ẹ̀sìn lómìnira sí aburú mọ́ bí kò ṣe ohun tí ń dáàbò bo òmìnira. A kò tún kà á sí fífaramọ́ àìlera bí kò ṣe ẹ̀rí ìdánilójú. Nígbà tí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí mọyì pé oríṣiríṣi èrò àti ẹ̀tọ́ jẹ́ ìpìlẹ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ òde òní, ìtara òdì dínkù lọ́ràn-anyàn.
Lópin ọ̀rúndún kejìdínlógún, a wá so fífún ẹ̀sìn lómìnira pọ̀ mọ́ òmìnira àti èrò jíjẹ́ ọgbọọgba. A gbé èyí jáde bíi òfin àti ìpolongo, bí Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ènìyàn àti ti Ará Ìlú (1789) tí ó lókìkí ní ilẹ̀ Faransé, tàbí Òfin Ẹ̀tọ́ (1791), ní United States. Bí àwọn ìwé wọ̀nyí ṣe wá ń nípa lórí ríronú fàlàlà láìsídìíwọ́ láti ọ̀rúndún kọkàndínlógún lọ, fífún ẹ̀sìn lómìnira àti òmìnira wá di ohun tí a kò tún kà sí ègún mọ́ bí kò ṣe ìbùkún láti ìgbà náà.
Òmìnira Tó Láàlà
Bí òmìnira ṣe ṣeyebíyé tó yẹn, ó láàlà. Nítorí òmìnira púpọ̀ fún gbogbo ènìyàn, Ìjọba ṣe àwọn òfin tó pààlà sí àwọn òmìnira ara ẹni. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ òmìnira tí a ń jíròrò lé lórí báyìí ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Yúróòpù nìwọ̀nyí: Dé àyè wo ló yẹ kí òfin ìjọba nípa lórí bí ẹnì kan ṣe ń lo ìgbésí ayé ara rẹ̀? Báwo ló ṣe gbéṣẹ́ tó? Báwo ló ṣe kan òmìnira?
Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ti tẹnu mọ́ ìjíròrò lórí òmìnira tí a ní ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀. Ẹ̀sùn ìpaniléròdà, líluni ní jìbìtì owó, bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìwà ọ̀daràn bíburújáì mìíràn ni a ti hù sí àwùjọ àwọn onísìn kan, láìsí ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kankan lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ti tan àwọn ìròyìn tó ní í ṣe pẹ̀lú àwùjọ àwọn onísìn tí kò gbajúmọ̀ kálẹ̀. Àwọn orúkọ tí ń bani jẹ́ bí “ẹgbẹ́ òkùnkùn” tàbí “ẹ̀ya ìsìn” ti wà lára ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fàlàlà lójoojúmọ́. Pẹ̀lú ìdààmú tí ń wá láti inú èrò ará ìlú, àwọn ìjọba tilẹ̀ ti tẹ orúkọ àwọn tí a pè ní ẹgbẹ́ òkùnkùn tó léwu jáde.
Ilẹ̀ Faransé jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tó máa ń fi àṣà fífún ẹ̀sìn lómìnira àti yíya ìsìn àti Ìjọba sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ yangàn. Ó fi ìyangàn pòkìkí ara rẹ̀ bí ilẹ̀ “Òmìnira, Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba, Ẹgbẹ́ Arákùnrin.” Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé Freedom of Religion and Belief—A World Report ṣe sọ, wọ́n ti dábàá “ìgbétáásì ẹ̀kọ́ tí yóò ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ àwọn àjọ onísìn tuntun sílẹ̀ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́” ní orílẹ̀-èdè yẹn. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ ènìyàn rò pé irú ìgbésẹ̀ yìí lè fa ewu wá sórí òmìnira ìsìn. Lọ́nà wo?
Àwọn Ohun Tó Wu Òmìnira Ìsìn Léwu
Kìkì ìgbà tí Ìjọba bá bá gbogbo ẹgbẹ́ onísìn tí ó bọ̀wọ̀ fún òfin, tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i lò lọ́gbọọgba ni a tó ní òmìnira ìsìn ní tòótọ́. Èyí kì í rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí Ìjọba bá pinnu lọ́sàn-án kan òru kan nípa èyí tí kì í ṣe ìsìn lára àwọn ẹgbẹ́ onísìn tó wà, tí ó wá tipa bẹ́ẹ̀ fi àwọn àǹfààní tí Ìjọba ń fún àwọn ẹ̀sìn dù ú. Ìwé ìròyìn Time sọ ní ọdún 1997 pé: “Èrò ṣíṣeyebíye tí òmìnira ìsìn ní kì í ní láárí tí ìjọba bá pa ẹ̀tọ́ fífọwọ́ sí àwọn ìsìn mọ́ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìgbà tó ń fúnni ní ìwé àṣẹ ìwakọ̀.” Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kan ní ilẹ̀ Faransé sọ láìpẹ́ yìí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ “ń yọrí sí ètò ìjọba aṣetinú-ẹni yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀ọ́mọ̀.”
A tún ń wu àwọn òmìnira pàtàkì-pàtàkì léwu nígbà tí ẹgbẹ́ kan bá ń dá ṣàkóso àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde. Ó dunni pé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nìyí. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìgbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tó tọ̀nà ní ti ìsìn, àwọn àjọ tí ń gbógun ti ẹgbẹ́ òkùnkùn ti sọ ara wọn di agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́, adájọ́, àti ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, wọ́n sì ti gbìyànjú láti fagbára mú kí àwọn ará ìlú tẹ́wọ́ gba èrò ẹlẹ́tanú wọn nípasẹ̀ àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde. Ṣùgbọ́n, ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Le Monde, sọ pé ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn àjọ wọ̀nyí máa ń fi “ìwà ìyapa ìsìn kan náà tí wọ́n sọ pé àwọn ń gbógun tì hàn, wọ́n sì ń fa ara wọn sínú ewu ‘wíwá’ àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ ‘kiri.’” Ìwé ìròyìn náà béèrè pé: “Ǹjẹ́ àbààwọ́n tí a ń kó bá àwọn ẹgbẹ́ onísìn tí kò gbajúmọ̀ láwùjọ . . . kì í kó àwọn òmìnira pàtàkì-pàtàkì sínú ewu?” Martin Kriele tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé ìròyìn Zeitschrift für Religionspsychologie (Ìwé Ìròyìn fún Èrò Nípa Ìsìn), sọ pé: “Wíwá àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ kiri bí oníyapa túbọ̀ ru àníyàn sókè ju ti ọ̀pọ̀ jù lọ ‘àwọn tí a ń pè ní ẹ̀ya ìsìn àti ẹgbẹ́ àwọn afìṣemọ̀rònú.’ Kí a wulẹ̀ sọ ọ́ pé: Ó yẹ kí a fi àwọn aráàlú tí wọn kì í rú òfin sílẹ̀ lálàáfíà. Ó yẹ kí ìsìn àti àkópọ̀ èròǹgbà ètò òṣèlú àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ní òmìnira, kí ó sì wà lómìnira bẹ́ẹ̀, àti ní Germany.” Ẹ jẹ́ kí a gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.
A Pe “Àwọn Aráàlú Tí Wọ́n Jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ” ní Eléwu
Lérò àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ nínú ìwé ìròyìn ABC, tí ó gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Sípéènì, ẹgbẹ́ onísìn wo ni wọ́n sọ pé ó “léwu jù lọ lára gbogbo ẹ̀ya ìsìn”? Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìwé ìròyìn ABC ń sọ nípa wọn. Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀sùn tí a fi kàn wọ́n ní ìpìlẹ̀ jẹ́ èyí tí kò ní ojúsàájú, tí kò sì ní ẹ̀tanú? Ṣàkíyèsí àwọn ìkéde tí ó tẹ̀ lé e yìí tí ìwé mìíràn ṣe pé:
“Àwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ àwọn ènìyàn láti máa san owó orí wọn láìṣèrú, kí wọ́n má ṣe kópa nínú ogun tàbí ìmúrasílẹ̀ fún ogun, kí wọ́n má ṣe jalè àti, lápapọ̀, kí wọ́n gbé ìgbésí ayé tó jẹ́ pé bí àwọn ẹlòmíràn bá gbé irú rẹ̀, yóò jẹ́ kí ọ̀pá ìdiwọ̀n àjọṣepọ̀ gbogbo gbòò sunwọ̀n sí i.”—Sergio Albesano, ìwé ìròyìn Talento, November-December 1996.
“Lòdì sí àwọn ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ òdì tí a tàn kálẹ̀ ní àwọn àkókò kan, lójú tèmi, [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] kò dà bí ẹni tó jẹ́ ewu sí àwọn ètò tí Ìjọba gbé kalẹ̀. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ.”—Mẹ́ńbà ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kan ní Belgium.
“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni a mọ̀ sí olódodo jù lọ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira yìí.”—Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Germany náà, Sindelfinger Zeitung.
“A lè ka [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] sí ẹni tó ṣeé fi ṣàwòkọ́ṣe. Wọ́n máa ń san owó orí wọn dáadáa, wọ́n ń tọ́jú àwọn tí ń ṣàìsàn, wọ́n ń bá àìmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà jà.”—Ìwé ìròyìn San Francisco Examiner ní United States.
“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣàṣeyọrí gan-an ju àwọn ọmọ ìjọ mìíràn lọ nínú níní ìdè ìgbéyàwó tó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin.”—ìwé ìròyìn American Ethnologist.
“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn aráàlú tí ń ṣòdodo, tó sì jẹ́ aláápọn jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà.”—Ọ̀mọ̀wé Bryan Wilson, Yunifásítì Oxford.
“Àwọn tí ń ṣe ìsìn yẹn ti kó ipa pàtàkì nínú lílo òmìnira ẹ̀rí-ọkàn lọ́nà tí ó pọ̀ ní àwọn ẹ̀wádún tó ti kọjá.”—Nat Hentoff, Free Speech for Me—But Not for Thee.
“Wọ́n ti . . . lọ́wọ́ nínú dídáàbòbo díẹ̀ lára àwọn ohun tó ṣeyebíye jù lọ nínú ètò ìjọba tiwa-n-tiwa wa lọ́nà pàtó.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n C. S. Braden, These Also Believe.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn àyọlò òkè wọ̀nyí ṣe fi hàn, níbi gbogbo kárí ayé ni a ti mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ẹni tó ṣeé fi ṣàwòkọ́ṣe. Ní àfikún, a mọ̀ wọ́n mọ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn lọ́fẹ̀ẹ́ àti gbígbé ìwà ọmọlúwàbí nínú ìdílé lárugẹ. Àwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà wọn ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn lọ́wọ́, iṣẹ́ ìfẹ́dàáfẹ́re tí wọ́n ti ń ṣe láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún wá sì ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́wọ́, ní pàtàkì ní ilẹ̀ Áfíríkà.
Àǹfààní Tó Wà Nínú Àìṣègbè
Àwọn ènìyàn tí kò ní ìlànà, tí wọ́n ń fìyà jẹ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kún inú àwùjọ ẹ̀dá. Nítorí èyí, a ní ìdí pàtó láti wà lójúfò tó bá kan ọ̀ràn ẹ̀tọ́ ìsìn. Ṣùgbọ́n dáadáa wo ló wà nínú rẹ̀, báwo ló sì ṣe ti òmìnira ìsìn lẹ́yìn tó nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn kan bá gbẹ́kẹ̀ lé ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń rí i pé iye wọn ń dín kù tàbí èyí tí wọ́n gbà lọ́dọ̀ àwọn àjọ agbógunti ìyapa ìsìn tí àwọn ohun tí wọ́n ń gbé ṣe ń gbé ìbéèrè dìde dípò kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ àwọn ọ̀mọ̀ràn tí kì í ṣègbè? Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn tó pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní “ẹ̀ya ìsìn tó léwu jù lọ” jẹ́wọ́ pé, ọ̀rọ̀ tí òun lò náà wá láti ọ̀dọ̀ “àwọn ògbógi nínú Ìjọ [Kátólíìkì].” Ní àfikún, ìwé ìròyìn èdè Faransé kan sọ pé, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀ya ìsìn náà pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àjọ tí ń gbógun ti ìyapa ìsìn. Èyí ha dà bí ọ̀nà àìṣègbè tó dára jù lọ láti gba ìsọfúnni tí kò ṣègbè bí?
Àwọn ilé ẹjọ́ àgbáyé tí àwọn tó ṣe pàtàkì lára ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn jẹ lọ́kàn, bí àjọ UN, sọ pé, “ààlà ìyàtọ̀ tí a pa sáàárín ìsìn àti ẹ̀ya ìsìn kan jẹ́ àtọwọ́dá gan-an ju ohun tí a lè tẹ́wọ́ gbà lọ.” Ó dára nígbà náà, èé ṣe tí àwọn kan fi tẹra mọ́ lílo ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ òdì náà, “ẹ̀ya ìsìn”? Ó jẹ́ ẹ̀rí síwájú sí i pé òmìnira ìsìn wà nínú ewu. Ó dára, nígbà náà, báwo ni a ṣe lè dáàbò bo òmìnira ṣíṣeyebíye yìí?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn Olùgbèjà Òmìnira Ìsìn
A ń gbọ́ igbe ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ jíjágaara fún òmìnira ìsìn láti ọ̀dọ̀ àwọn tí a pa nínú ìforígbárí ìsìn ní Yúróòpù ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ yìí ṣì ní í ṣe pẹ̀lú ìjíròrò nípa òmìnira ìsìn.
Sébastien Chateillon (1515 sí 1563): “Ta ni aládàámọ̀? N kò rí ohunkóhun mìíràn àyàfi pé gbogbo àwọn tí kò bá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú èrò tiwa ni a kà sí aládàámọ̀. . . . Bí a bá kà ọ́ sí onígbàgbọ́ òdodo ní ìlú tàbí agbègbè yìí, tí o bá dé ìlú mìíràn, wọn óò kà ọ́ sí aládàámọ̀.” Olókìkí olùtumọ̀ Bíbélì èdè Faransé, tí ó tún jẹ́ alágbàwí fífún ẹ̀sìn lómìnira lójú méjèèjì náà, Chateillon, mẹ́nu kan ọ̀kan lára ohun pàtàkì nínú ìjíròrò lórí òmìnira ìsìn: Ta ni yóò sọ bí ẹnì kan bá jẹ́ aládàámọ̀?
Dirck Volckertszoon Coornhert (1522 sí 1590): “A kà pé nígbà kan rí . . . ní Jerúsálẹ́mù, Kristi alára àti lẹ́yìn náà ọ̀pọ̀ àwọn ajẹ́rìíkú ní Yúróòpù pàápàá . . . fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ wọn yọ [ìlú] lẹ́nu. . . . A ní láti ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà ‘yọ lẹ́nu’ yékéyéké, lọ́nà pípéye.” Coornhert ṣàlàyé pé kò yẹ kí a ka àìfohùnṣọ̀kan ìsìn sí ohun kan náà pẹ̀lú yíyọ ìlú lẹ́nu. Ó béèrè pé: Ṣé àwọn tí ń ṣègbọràn sí òfin, tí wọ́n sì kà á sí lójú méjèèjì ló ń yọ ìlú lẹ́nu?
Pierre de Belloy (1540 sí 1611): Ó jẹ́ “ìwà àìmọ̀kan láti gbà gbọ́ pé nítorí pé ìsìn pọ̀ ni rúkèrúdò fi wà, ló sì ṣe ń gbilẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè.” Belloy, amòfin ará Faransé kan kọ̀wé nígbà tí Àwọn Ogun Ìsìn ń lọ lọ́wọ́ (1562 sí 1598), pé ìṣọ̀kan Orílẹ̀-èdè kò sinmi lé bí ìsìn bá jẹ́ irú kan náà, àyàfi bí ìjọba bá ń fi ti ìyọnilẹ́nu àwọn onísìn ṣe.
Thomas Helwys (nǹkan bíi 1550 sí nǹkan bíi 1616): “Bí àwọn ènìyàn rẹ̀ [ti ọba] bá ṣe ìgbọràn àti òtítọ́ sí gbogbo òfin ènìyàn, kò sí ohun tí yóò tún béèrè lọ́wọ́ wọn mọ́.” Helwys, ọ̀kan lára àwọn tó dá Ìjọ Onítẹ̀bọmi ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀, kọ̀wé gbe yíya Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba sọ́tọ̀, ó sì rọ ọba láti fún gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì àti ẹ̀ya ìsìn ní òmìnira ìsìn, kí ó sì jẹ́ kí agbára ìṣàkóso tó ní lórí àwọn ènìyàn àti ohun ìní tó òun. Ìwé rẹ̀ tẹnu mọ́ ìbéèrè kan tí a ń gbé yẹ̀ wò lọ́wọ́: Dé àyè wo ló yẹ kí Ìjọba máa darí ọ̀ràn nípa ohun tẹ̀mí?
Òǹkọ̀wé kan tí kò kọrúkọ rẹ̀ (1564): “Láti lè mú òmìnira ẹ̀rí-ọkàn wọlé, kò tó láti máà jẹ́ kí ẹnì kan ṣe ìsìn kan tí kò fọwọ́ sí bí a kò bá gba èyí tó fọwọ́ sí láyè láti wà láìsídìíwọ́.”
[Àwọn àwòrán]
Tertullian
Chateillon
De Belloy
[Credit Line]
Gbogbo fọ́tò: © Cliché Bibliothèque Nationale de France, Paris