ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 2/1 ojú ìwé 3-4
  • Kí Ni Òmìnira Ìsìn Túmọ̀ Sí fún Ọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Òmìnira Ìsìn Túmọ̀ Sí fún Ọ?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òmìnira Ìsìn Ńkọ́?
  • Irú Òmìnira Mìíràn Ní Ti Ìsìn
  • Ẹ Maṣe Tàsé Ète Ominira Tí Ọlọrun Fi Funni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Awọn Eniyan Olominira Ṣugbọn Ti Wọn Yoo Jíhìn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run Tí Ń Fúnni Ní Òmìnira
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ẹ Kaabọ Si Awọn Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olufẹ Ominira”!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 2/1 ojú ìwé 3-4

Kí Ni Òmìnira Ìsìn Túmọ̀ Sí fún Ọ?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ka òmìnira ìsìn sí ẹ̀tọ́ pàtàkì ní United States, ìwà ipá púpọ̀ láti ọwọ́ àwọn ènìyànkénìyàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba orílẹ̀-èdè náà kan ní àwọn ọdún 1940

ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ ti jà fún un. Àwọn kan tilẹ̀ ti kú nítorí rẹ̀. Ní tòótọ́, ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun ìní tí ó ṣeyebíye jù lọ fún aráyé. Kí ni ohun náà? Òmìnira ni! Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, túmọ̀ òmìnira gẹ́gẹ́ bí “agbára láti ṣe àwọn yíyàn, kí a sì mú wọn ṣẹ.” Ó ń bá a nìṣó pé: “Kí a fi ojú òfin wò ó, àwọn ènìyàn wà ní òmìnira bí ẹgbẹ́ àwùjọ kò bá gbé ààlà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, tí kò pọn dandan, tí kò sì bá ọgbọ́n mu kà wọ́n lórí. Ẹgbẹ́ àwùjọ tún gbọ́dọ̀ dáàbò bo àwọn ẹ̀tọ́ wọn—ìyẹn ni, òmìnira wọn pàtàkì, ọlá àṣẹ wọn, àti àǹfààní wọn.”

Èròǹgbà náà dún bí ohun tí ó rọrùn. Ṣùgbọ́n, ní ṣíṣe é, ó dà bí ẹni pé kò fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn láti fohùn ṣọ̀kan lórí ibi tí ó yẹ kí ààlà òmìnira dé gan-an. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan gbà gbọ́ pé ìjọba gbọ́dọ̀ ṣe àwọn òfin láti dáàbò bo òmìnira àwọn ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn yóò jiyàn pé àwọn òfin wọ̀nyí ni ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ náà gan-an tí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ní láti bọ́ kúrò nínú rẹ̀! Ní kedere, òmìnira túmọ̀ sí ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Òmìnira Ìsìn Ńkọ́?

Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé òmìnira ìsìn, tí a túmọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀tọ́ láti gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn tí ẹnì kan bá yàn, kí ó sì máa ṣe ẹ̀sìn tí ó wù ú,” ni òmìnira tí ó máa ń fa awuyewuye gbígbóná janjan jù lọ. Ní ìbámu pẹ̀lú Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé Láti Ọwọ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, “olúkúlùkù ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ìsìn.” Èyí ní nínú ẹ̀tọ́ ẹni “láti yí ìsìn tàbí ìgbàgbọ́ rẹ̀ pa dà,” pẹ̀lú òmìnira “láti fi ìsìn tàbí ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn nínú kíkọ́ni, nínú ìṣe, nínú ìjọsìn àti nínú ayẹyẹ.”—Ìsọ̀rí 18.

Dájúdájú, a óò retí pé kí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí tí ó bá ń fi tinútinú bójú tó àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ fọwọ́ sí irú òmìnira bẹ́ẹ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé, èyí kì í fìgbà gbogbo wáyé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, wí pé: “Ìsìn ń nípa lórí ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ jù lọ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní. Àwọn ìjọba kan ní àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìsìn kan, wọ́n sì ka àwọn mẹ́ńbà ìsìn yòó kù sí ewu fún ọlá àṣẹ ìṣèlú. Ìjọba kan tún lè ka ìsìn sí ewu fún ìṣèlú nítorí pé ìsìn lè fi ìtúúbá fún Ọlọ́run ṣíwájú ìgbọ́ràn sí orílẹ̀-èdè.”

Nítorí àwọn ìdí wọ̀nyí, àwọn ìjọba kan gbé ìkálọ́wọ́kò karí ìsìn ṣíṣe. Àwọn díẹ̀ kò fàyè gba ṣíṣe ìsìn èyíkéyìí rárá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ pé àwọn ń ṣalágbàwí òmìnira ìjọsìn, àwọn mìíràn ń ṣòfíntótó gbogbo ìgbòkègbodò àwọn ìsìn títí dé orí bíńtín.

Fún àpẹẹrẹ, gbé ipò tí ó gbilẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún ní Mexico yẹ̀ wò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin mú òmìnira ìsìn dáni lójú, ó sọ pé: “Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí a ń lò fún ìjọsìn ní gbangba jẹ́ ohun ìní Orílẹ̀-èdè, tí Ìjọba Àpapọ̀ ń ṣojú fún, òun ni yóò sì lè pinnu èwo ni a lè máa bá nìṣó láti lò bẹ́ẹ̀.” Ní 1991, a ṣàtúnṣe Òfin yẹn láti fòpin sí ìkálọ́wọ́kò yí. Síbẹ̀síbẹ̀, àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé ohun tí a túmọ̀ òmìnira ìsìn sí lè yàtọ̀ ní onírúurú ilẹ̀.

Irú Òmìnira Mìíràn Ní Ti Ìsìn

Òmìnira ìsìn ha wà ní ilẹ̀ tí o ń gbé bí? Bí ó bá wà, báwo ni a ṣe túmọ̀ rẹ̀? O ha lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí o bá yàn bí, tàbí a ha fi agbára mú ọ láti di mẹ́ńbà ìsìn Orílẹ̀-èdè bí? A ha fàyè gbà ọ́ láti ka àwọn ìwé ìsìn, kí o sì pín wọn kiri, tàbí ìjọba ha gbẹ́sẹ̀ lé irú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ bí? O ha lè sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ẹ̀sìn rẹ, tàbí a ha ka èyí sí títẹ ẹ̀tọ́ wọn ní ti ìsìn lójú bí?

Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí sinmi lórí ibi tí o ń gbé. Bí ó ti wù kí ó rí, ó dùn mọ́ni pé irú òmìnira kan wà ní ti ìsìn, tí kò sinmi rárá lórí àgbègbè kan. Nígbà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 32 Sànmánì Tiwa, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:31, 32.

Kí ni Jésù ní lọ́kàn tí ó fi sọ gbólóhùn yí? Àwọn Júù tí ń tẹ́tí sí i ń yán hànhàn fún òmìnira kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù. Ṣùgbọ́n kì í ṣe òmìnira kúrò lábẹ́ ìnilára ìṣèlú ni Jésù ń jíròrò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń ṣèlérí ohun kan tí ó sàn jù fíìfíì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́