ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 4-8
  • Apilẹ̀ Àbùdá Ha Ní Ń Pinnu Àyànmọ́ Wa Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Apilẹ̀ Àbùdá Ha Ní Ń Pinnu Àyànmọ́ Wa Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìṣòótọ́ àti Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lò-Pọ̀ Ńkọ́?
  • Apilẹ̀ Àbùdá fún Ìmukúmu Ọtí àti Ìwà Ọ̀daràn
  • Ẹ̀bi Ta Ni—Ṣé Ẹ̀bi Rẹ Ni Àbí Ti Apilẹ̀ Àbùdá Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Kì í Ṣe Ẹ̀bi Mi”
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Oríṣiríṣi Ohun Ọ̀gbìn Ṣe Kókó fún Ìwàláàyè Èèyàn
    Jí!—2001
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 4-8

Apilẹ̀ Àbùdá Ha Ní Ń Pinnu Àyànmọ́ Wa Bí?

“A SÁBÀ máa ń ronú pé ìràwọ̀ ní ń pinnu kádàrá wa. Lọ́nà púpọ̀, a ti mọ̀ nísinsìnyí pé kádàrá wa sinmi lórí apilẹ̀ àbùdá wa.” Báyìí ni James Watson, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé náà, Exploding the Gene Myth, láti ọwọ́ Ruth Hubbard àti Elijah Wald, ṣe wí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kété lábẹ́ ọ̀rọ̀ Watson tí a fà yọ náà, a fa ọ̀rọ R. C. Lewontin, Steven Rose, àti Leon J. Kamin yọ, tí wọ́n sọ pé: “A kò lè ronú nípa ìhùwà pàtàkì èyíkéyìí nínú àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn tí ó wà nínú apilẹ̀ àbùda wa lọ́nà tí a kò fi ní lè mú un tọ́ nípasẹ̀ àwọn ipò àjọṣepọ̀.”

Èèpo ẹ̀yìn ìwé yẹn ṣàkópọ̀ díẹ̀ lára àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè pàtàkì náà, “Ìhùwà ẹ̀dá ènìyàn ha ní í ṣe pẹ̀lú apilẹ̀ àbùdá bí?” Ní èdè míràn, apilẹ̀ àbùdá tí ń gbé àwọn àmì ànímọ́ àti ìwà àjogúnbá tí a bí mọ́ni kiri nínú ara ló ha ń pinnu ìhùwà ẹ̀dá ènìyàn pátápátá bí? Ó ha yẹ kí a tẹ́wọ́ gba irú ìwà kan tí kò bójú mu látàrí pé ó ní í ṣe pẹ̀lú apilẹ̀ àbùdá bí? Ó ha yẹ kí a wo àwọn ọ̀daràn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìṣètò apilẹ̀ àbùdá ń jẹ níyà, kí ó baà lè gba ẹ̀bi tí kò tó nǹkan nítorí ìwà kan tí apilẹ̀ àbùdá àyànmọ́ni fà bí?

A kò lè sẹ́ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ṣe ọ̀pọ̀ àwọn àwárí tí ó ti ṣàǹfààní ní ọ̀rúndún yìí. Ọ̀kan lára àwọn àwárí yìí ni ásíìdì DNA fífani lọ́kàn mọ́ra, ohun tí a pè ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àpapọ̀ apilẹ̀ àbùdá wa. Ìsọfúnni tí ìṣètò apilẹ̀ abùdá ní nínú ti ru ọkàn ìfẹ́ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti àwọn ọ̀gbẹ̀rì pẹ̀lú sókè. Kí ni ìwádìí ní ẹ̀ka apilẹ̀ àbùdá ti ṣàwárí ní ti gidi? Báwo ni a ṣe lo àwọn ohun tí a ṣàwárí láti gbe àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìṣètòtẹ́lẹ̀ tàbí àyànmọ́ nídìí?

Àìṣòótọ́ àti Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lò-Pọ̀ Ńkọ́?

Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde The Australian ṣe sọ, àwọn ìwádìí kan nípa apilẹ̀ àbùdá tẹnu mọ́ ọn pé “ó ṣeé ṣe kí àìṣòótọ́ wà nínú apilẹ̀ àbùdá wa. . . . Ó fara hàn pé a dá àwọn ọkàn tí ń rẹ́ni jẹ láti rí bẹ́ẹ̀ ni.” Wulẹ̀ finú wòye irú ìbàjẹ́ tí ìṣarasíhùwà yìí lè mú wá sórí àwọn ìgbéyàwó àti ìdílé nípa ṣíṣe ọ̀nà àsálà fún ẹnikẹ́ni tí ń fẹ́ láti béèrè fún ẹ̀bi tí kò to nǹkan fún ọ̀nà ìgbésí ayé ìṣekúṣe!

Nípa ti ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, ìwé ìròyìn Newsweek gbé àkọlé náà “Àbímọ́ Tàbí Àmúdàgbà?” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀ àrùn ọpọlọ ń jà fitafita láti lóye ìwádìí tuntun tí ó dámọ̀ràn pé ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ lè ní í ṣe pẹ̀lú apilẹ̀ àbùdá, kì í ṣe ọ̀nà ìtọ́dàgbà. . . . Ní àwùjọ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ fúnra rẹ̀, ọ̀pọ̀ ló tẹ́wọ́ gba ìtọ́kasí náà pé jíjẹ́ abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ bẹ̀rẹ̀ láti inú àwọn apilẹ̀ ẹ̀yà àjogúnbá.”

Àpilẹ̀kọ náà wá fa ọ̀rọ̀ Ọ̀mọ̀wé Richard Pillard yọ, tí ó sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé apilẹ̀ àbùdá ló ń pinnu ìtẹ̀sí ọkàn ẹni sí ìbálòpọ̀, ó túmọ̀ sí pé, ‘Èyí kì í ṣe àbùkù, kì í sì ṣe ẹ̀bi rẹ.’” Nígbà tí Frederick Whitam, olùṣèwádìí nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, ń kín ọ̀ràn “kì í ṣe ẹ̀bi” yìí lẹ́yìn, ó ṣàlàyé pé “àwọn ènìyán ní ìtẹ̀sí ìfọkànbalẹ̀ nígbà tí a bá wí fún wọn pé ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ jẹ́ àbímọ́ni. Ó máa ń fún àwọn ìdílé àti àwọn abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ ní ìtura kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi. Ó tún túmọ̀ sí pé àwọn aráàlù kò ní láti dààmú nípa àwọn nǹkan bí àwọn tí ń kọ́ni ní ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀.”

Nígbà míràn, àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde máa ń gbé ohun tí a pè ní ẹ̀rí lórí pé àwọn apilẹ̀ àbùdá ní ń pinnu àwọn ìtẹ̀sí ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òkodoro òtítọ́, tí kò ṣeé já ní koro dípò gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò dájú, tí a kò sì yanjú rẹ̀.

Ìwé ìròyìn New Statesman & Society bu ẹnu àtẹ́ lu díẹ̀ lára ọgbọ́n ìkọ̀wé tí wọ́n lò láti ròyìn àwárí náà pé: “Òǹkàwé tí nǹkan jọ lójú lè ti gbójú fo àìṣekedere òkodoro ẹ̀rí gidi tí ó ṣeé fojú rí—tàbí, ní ti gidi, àìsí ìpìlẹ̀ jíjẹ́ pátápátá kankan fún [ìgbèjà] aburú híhàn gbangba ní ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ náà pé ìṣekúṣe ‘wà nínú apilẹ̀ àbùdá ọkùnrin, tí a sì gbé sínú ìṣètò pátákó ìgbèsọfúnnikiri inú ọpọlọ ọkùnrin.’” David Suzuki àti Joseph Levine kọ àníyan wọn nípa ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ lóri apilẹ̀ àbùdá sínú ìwé wọn, Cracking the Code, pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe láti jiyàn pé apilẹ̀ àbùdá ń ṣàkóso ìhùwà ní ti gbogbogbòò, ọ̀ràn míràn pátápátá ni láti fi hàn pé apilẹ̀ àbùdá kan pàtó—tàbí awẹ́ méjì apilẹ̀ àbùdá, tàbí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ apilẹ̀ àbùdá pàápàá—ní ti gidi ń ṣàkóso àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ pàtó kan nípa bí ẹranko kan ṣe ń hùwà padà sí àyíká rẹ̀. Níbi tí a dé yìí, ó tọ́ láti béèrè bóyá ẹnì kan ti rí fọ́nrán ásíìdì DNA kankan tí ó ní ipa lórí àwọn ìhùwà pàtó lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ ní èrò ìtumọ̀ dan-indan-in ti ṣíṣàwárí àti ṣíṣèyípadà ní ti molecule.”

Apilẹ̀ Àbùdá fún Ìmukúmu Ọtí àti Ìwà Ọ̀daràn

Ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá, ìwádìí lórí ìmukúmu ọtí ti fa ọkàn ìfẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèwádìí nípa apilẹ̀ àbùdá mọ́ra. Àwọn kan sọ pé àwọn ìwádìí ti fi hàn pé wíwà irú àwọn apilẹ̀ àbùdá kan tàbí àìsí wọn ló ń fa ìmúkúmu ọtí. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine ròyìn ní 1988 pé “ní ẹ̀wádún tó kọjá, àwọn ìwádìí mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti gbé ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro jáde pé ìmukúmu ọtí jẹ́ ìtẹ̀sí tí a jogún.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ní báyìí, àwọn ògbóǹtagì kan ní ẹ̀ka ìsọdibárakú ti ń pe èròǹgbà pé àwọn kókó àbínibí ní ń fa ìmukúmu ọtí níjà. Ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Boston Globe ti April 9, 1996, sọ pé: “A kò retí láti rí apilẹ̀ àbùdá ìmukúmu ọtí, àwọn olùṣèwádìí kan sì gbà pé èyí tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n rí jù lọ ni ìṣípayá apilẹ̀ àbùdá tí ń gba àwọn ènìyàn kan láyè láti mu àmujù láìpògìrá—ànímọ́ kan tí ó lè mú wọn ní ìtẹ̀sí láti ya onímukúmu ọtí.”

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn lórí àpérò kan ní Yunifásítì ti Maryland tí ó ní àkọlé náà “Ìtumọ̀ àti Ìjẹ́pàtàkì Ìwádìí Lórí Apilẹ̀ Àbùdá àti Ìwà Ọ̀daràn.” Èrò nípa apilẹ̀ àbùdá tí ń ṣokùnfà ìwà ọ̀daràn rọrùn lọ́nà tí ń rùmọ̀lára sókè. Ó jọ pé ọ̀pọ̀ àwọn olùsọ̀rọ̀ ń hára gàgà láti gbárùkù ti èrò náà. Òǹkọ̀wé nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kan sọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times Magazine pé ó ṣeé ṣe kí ìwà ibi “wà láàárín àwọn fọ́nrán lílọ́pọ̀ apilẹ̀ ẹ̀yà tí àwọn òbí wa ta látaré sí wa nígbà ìlóyún.” Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé ìjíròrò tí a kò jánu nínú rẹ̀ yìí nípa apilẹ̀ àbùdá ìwà ọ̀daràn ń fa èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn náà pé ìwà ọ̀daràn ní “ìpìlẹ̀ kan tí gbogbo ènìyán mọ̀—àìṣiṣẹ́déédéé ọpọlọ.”

Jerome Kagan, afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá ní Harvard, sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò ń bọ̀ tí àwọn àyẹ̀wò apilẹ̀ àbùdá yóò máa fi àwọn ọmọ tí wọ́n ní ìtẹ̀sí láti hùwà ipá hàn. Àwọn ènìyàn kan dámọ̀ràn pé ìrètí lè wà fún ṣíṣàkóso ìwà ọ̀daràn nípasẹ̀ ìṣàtúnṣe lọ́nà àbínibí dípò nípasẹ̀ ìmúbọ̀sípò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.

Ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò nínú àwọn ìròyìn nípa àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí nípa pé apilẹ̀ àbùdá ló ń fa ìhùwà, kì í sábà ṣe sàn-án, kì í sì í dájú. Ìwé Exploding the Gene Myth sọ nípa ìwádìí kan tí Lincoln Eaves, onímọ̀ apilẹ̀ àbùdá nípa ìhùwà, sọ pé òún rí ẹ̀rí okùnfà ìsoríkọ́ nínú apilẹ̀ àbùdá. Lẹ́yìn tí Eaves ṣèwádìí láàárín àwọn obìnrin tí ó ronú pé wọ́n lè ní ìtẹ̀sí láti sorí kọ́, ó “dàmọ̀ràn pé ìrísí ojú àti ìṣesí ìsoríkọ́ [àwọn obìnrin náà] lè ti túbọ̀ mú kí irú ọ̀kan-ò-jọ̀kan wàhálà bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀.” “Ọ̀kan-ò-jọ̀kan wàhálà” kẹ̀? Àwọn obìnrin tí a fi ṣèwádìí náà ni a ti “fipá bá lò pọ̀, fipá kọ lù, tàbí lé dànù lẹ́nu iṣẹ́.” Nítorí náà, ṣé ìsoríkọ́ ló fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ adanilórírú wọ̀nyí? Ìwé náà ń bá a lọ pé: “Irú èrò wo nìyẹ́n jẹ́? A ti fipá bá àwọn obìnrin náà lò pọ̀, fipá kọ lù wọ́n, tàbí lé wọn dànù lẹ́nu iṣẹ́ wọn, wọ́n sì sorí kọ́. Bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ wọ́n ṣe ń dani lórí rú tó ni ìsoríkọ́ náà ṣe ń burú tó. . . . Ì bá ti tóye yẹ láti wá apilẹ̀ àbùdá tí ó ṣokùnfà rẹ̀ ká ní ó [Eaves] rí i pé ìsoríkọ́ náà kò so pọ̀ mọ́ ìrírí kankan nínú ìgbésí ayé.”

Ìtẹ̀jáde yẹn kan náà sọ pé àwọn ìròyìn wọ̀nyí “jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìròyìn ẹnu àìpẹ́ yìí nípa apilẹ̀ àbùdá [ti ìhùwà], nínú ìṣètò ìròyìn àti nínú àwọn ìwé agbéròyìnjáde ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Wọ́n ní àdàlù àwọn òkodoro òtítọ́ tí ń fani lọ́kàn mọ́ra, àwọn èrò àbámodá tí kò látìlẹ́yìn, àti àwọn àsọdùn aláìfìdímúlẹ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì apilẹ̀ àbùdá nínú ìgbésí ayé wa. Ohun tí ń gbani láfiyèsí púpọ̀ lára àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ni àìṣekedere rẹ̀.” Ó ń bá a lọ pé: “Ìyàtọ̀ ńlá kan wà láàárín síso àwọn apilẹ̀ àbùdá pọ̀ mọ́ àwọn ipò tí ó tẹ̀ lé bátànì ìlànà Mendel ti ìjogúnbá àti lílo ìméfò ‘ìtẹ̀sí’ apilẹ̀ àbùdá láti ṣàlàyé àwọn ipò dídíjú bíi jẹjẹrẹ tàbí ẹ̀jẹ̀ ríru. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tún kánjú lọ sórí ìpinnú kan nígbà tí wọ́n dámọ̀ràn pé ìwádìí nípa apilẹ̀ àbùdá lè ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé àwọn ìhùwà ẹ̀dá.”

Síbẹ̀síbẹ̀, lójú gbogbo ohun tí a ti ń sọ bọ̀, ìbéèrè tí a ṣì sábà máa ń gbé dìde náà ni pé: Èé ṣe tí a fi ń rí bátànì ìhùwà yíyí padà nínú ìgbésí ayé wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Àkóso wo sì ni a ní lórí irú ipò bẹ́ẹ̀? Báwo ni a ṣe lè ṣàkóso ìgbésí ayé wa kí a sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e lè ṣàǹfààní ní pípèsè àwọn ìdáhùn kan sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Fífi Apilẹ̀ Àbùdá Ṣètọ́jú Ẹni—A Ha Ti Mú Àwọn Ìfojúsọ́nà Ṣẹ Bí?

Ọ̀ràn ti fífi apilẹ̀ àbùdá ṣètọ́jú ẹni—gígún abẹ́rẹ́ apilẹ̀ àbùdá aṣàtúnṣe fún àwọn agbàtọ́jú láti wò wọ́n sàn kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn tí ó jẹ mọ́ apilẹ̀ àbùdá ńkọ́? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní ìfojúsọ́nà gíga ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn. “Àkókò títọ́ ha nìyí láti bẹ̀rẹ̀ sí í fi apilẹ̀ àbùdá ṣètọ́jú ẹni bí?” ni ohun tí ìwé ìròyìn The Economist ti December 16, 1995 béèrè, ó sì wí pé: “Tí a bá gbé ọ̀ràn karí ọ̀rọ̀ tí àwọn tí ń lò ó sọ ní gbangba, àti ọ̀pọ̀ ohun tí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ti gbé, ìwọ́ lè rò bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ìgbìmọ̀ àwọn lóókọlóókọ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ America kan kò fohùn ṣọ̀kan. Harold Varmus, olùdarí Àjọ Ìlera Orílẹ̀-Èdè (NIH), ní kí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ jàǹkànjàǹkàn 14 kan ṣàtúnyẹ̀wò kókó ọ̀rọ̀ fífi apilẹ̀ àbùdá ṣètọ́jú ẹni. Lẹ́yìn lílo oṣù méje ní rírònú jinlẹ̀, wọ́n sọ nínú ìròyìn kan tí a tẹ̀ jáde ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fífi apilẹ̀ àbùdá ṣètọ́jú ẹni lè ṣàṣeyọrí, a ti sọ ‘àsọdùn’ nípa àwọn ohun tó ti ṣàṣeparí títí di báyìí.” A ti lo àwọn aláìsàn 597 tí àìnító adenosine deaminase (ADA) tàbí ọ̀kan lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àrùn tí a ronú pé ó yẹ fún ṣíṣètọ́jú nípa ṣíṣàfikún àwọn àjèjì apilẹ̀ àbùdá. Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ náà ṣe sọ, kò sí ọ̀kan lára àwọn aláìsàn náà tí ó tí ì jàǹfààní jálẹ̀jálẹ̀ láti inú kíkópa nínú irú ìṣàyẹ̀wò bẹ́ẹ̀.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Láìka ohun tí àwọn kan lè sọ nípa àyànmọ́ apilẹ̀ àbùdá sí, àwọn ènìyán lè yan bí wọ́n ṣe ń hùwà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́