ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 3-4
  • “Kì í Ṣe Ẹ̀bi Mi”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Kì í Ṣe Ẹ̀bi Mi”
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kì í Ṣe Ìtẹ̀sí Tuntun Ní Ti Gidi
  • Ẹ̀bi Ta Ni—Ṣé Ẹ̀bi Rẹ Ni Àbí Ti Apilẹ̀ Àbùdá Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Apilẹ̀ Àbùdá Ha Ní Ń Pinnu Àyànmọ́ Wa Bí?
    Jí!—1996
  • Ẹ̀bi Ta Ni?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Bíbélì Ha Fi Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ Kọ́ni Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 3-4

“Kì í Ṣe Ẹ̀bi Mi”

Ẹ̀Ẹ̀MELÒÓ ni o máa ń gbọ́ lóde òní tí ẹnì kan ń sọ pé, ‘Ẹ máà bínú. Ẹ̀bi mi ni. Èmi ni mo jẹ̀bi gbogbo rẹ̀!’? Irú ọ̀rọ̀ àìlábòsí ṣákálá bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀ mọ́. Ní tòótọ́, nínú ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, kódà bí a bá gbà pé a jẹ̀bi pàápàá, a máa ń sa gbogbo ipá láti ti ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà sórí ẹlòmíràn tàbí sórí ipò amọ́rànfúyẹ́ tí ẹni tí ó ṣàṣìṣe náà ń sọ pé òun kò lè ṣàkóso.

Àwọn kan tilẹ̀ ń di ẹ̀bi náà ru apilẹ̀ àbùdá wọn! Ṣùgbọ́n èyí ha bọ́gbọ́n mu bí? Ìwé Exploding the Gene Myth gbé ìbéèrè dìde sí àwọn ète àti bí àwọn apá kan nínú ìwádìí nípa apilẹ̀ àbùdá ṣe gbéṣẹ́ tó. Nínú àyẹ̀wò tí akọ̀ròyìn ará Australia, Bill Deane, ṣe lórí ìwé náà, ó dórí ìpinnu mímọ́gbọ́n dání yìí pé: “Ó jọ pé àwọn tí wọ́n ní ojú ìwòye pé a ti pinnu ìgbésẹ̀ ẹ̀dá látilẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé àwọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ rí gbogbo ẹ̀rí tí ó dájú ṣáká láti gbe ọgbọ́n èrò orí wọn lẹ́yìn pé a kò gbọdọ̀ dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi fún ohun tí wọ́n bá ṣe: ‘Olúwa mi, kò sí bí ọ̀daràn yìí ṣe lè ṣe é tí kò ní dúḿbú òjìyà ìpalára náà—apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ ló jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀.’”

Kì í Ṣe Ìtẹ̀sí Tuntun Ní Ti Gidi

Bí ìran yìí ti ń gbèrú díẹ̀díẹ̀ di ohun tí òǹkọ̀wé kan pè ní ìran “kì í ṣe ẹjọ́ mi,” ó lè jọ pé ìtẹ̀sí yìí ń di púpọ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, àkọsílẹ̀ ìtàn fi hàn pé títi ẹ̀bi sórí ẹlòmíràn, pẹ̀lú àwáwí pé “kì í ṣe ẹ̀bi mi ní ti gidi,” wà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn. Ìhùwàpadà Ádámù àti Éfà lẹ́yìn ẹ̀ṣẹ̀ wọn àkọ́kọ́, jíjẹ lára èso tí Ọlọ́run ti kà léèwọ̀, jẹ́ àpẹẹrẹ mánigbàgbé nípa títi ẹ̀bi sórí ẹlòmíràn. Àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa ìjíròrò tí ó ṣẹlẹ̀, Ọlọ́run ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ pé: “Ìwọ́ ha jẹ nínú igi nì, nínú èyí tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ? Ọkùnrin náà sì wí pé, Obìnrin tí ìwọ́ fi pẹ̀lú mi, òun ni ó fún mi nínú èso igi náà, èmí sì jẹ. OLÚWA Ọlọ́run sì bi obìnrin náà pé, Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Obìnrin náà sì wí pé, Ejò ni ó tàn mí, mo sì jẹ.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:11-13.

Láti ìgbà yẹn wá, ẹ̀dá ènìyán ti hùmọ̀ onírúurú èrò ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti wá oríṣiríṣi àwáwí àrà ọ̀tọ̀ tí yóò yọ wọ́n nínú jíjíhìn lọ́nàkọnà fún ohun tí wọ́n ṣe. Èyí tí ó gbajúmọ̀ lára ìwọ̀nyí ni èrò ìgbàgbọ ìgbàanì nínú kádàrá. Obìnrin onísìn Búdà kan tí ó gbà gbọ́ tọkàntọkàn nínú Karma sọ pè: “Mo lérò pé kò bọ́gbọ́n mu láti jìyà nítorí ohun kan tí wọ́n bí mọ́ mi ṣùgbọ́n tí n kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀. Mo ní láti gbà á bí àyànmọ́ tèmi ni.” Nítorí pé wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ àyànmọ́, gẹ́gẹ́ bí John Calvin ṣe fi kọ́ni, bọ́ wọn yó, ìgbàgbọ́ nínu kádàrá wọ́pọ̀ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù pẹ̀lú. Àwọn àlùfáà sábà máa ń wí fún àwọn ẹbí tí ń ṣọ̀fọ̀ pé irú ìjàm̀bá kan jẹ́ ìfẹ́ inú Ọlọ́run. Bákan náà, pẹ̀lú, àwọn Kristẹni kan tí wọ́n lọ́kàn rere máa ń dẹ́bi fún Sátánì fún gbogbo ohun tí kò bá ṣẹnuure nínú ìgbésí ayé wọn.

Nísinsìnyí, a ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìhùwà tí kò sí pé a ń jíhìn fún lábẹ́ òfin àti nínú ẹgbẹ́ àwùjọ. A ń gbé ní sànmánì tí ẹ̀tọ́ ẹni ń pọ̀ sí i, tí jíjìyà ẹ̀bi ẹni sì ń dín kù.

Ìwádìí nípa ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn ti gbé ẹ̀rí tí a pè ní ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, tí àwọn kan lérò pé ó lè fúnni láǹfààní híhùwà èyíkéyìí láti orí ìwà pálapàla dé ìṣìkàpànìyàn ní fàlàlà, jáde. Èyí jẹ́ ìgbéyọ ìháragàgà ẹgbẹ́ àwùjọ láti ti ẹ̀bi sórí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí ẹni náà fúnra rẹ̀.

A ń fẹ́ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: Kí ni ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ṣàwárí ní ti gidi? Apilẹ̀ àbùdá wa nìkan ló ha ń pinnu ìhùwà ẹ̀dá ènìyàn bí? Àbí ipá ti inú àti ti òde ara ló ń darí ìhùwa wa ni? Kí ni ẹ̀rí fi hàn ní ti gidi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́