Ẹ̀bi Ta Ni?
ỌKÙNRIN àkọ́kọ́, Adamu, ni ó kọ́kọ́ ní ìtẹ̀sí náà. Lẹ́yìn tí ó dẹ́ṣẹ̀, ó sọ fún Ọlọrun pé: “Obìnrin tí ìwọ fi pẹ̀lú mi, òun ni ó fún mi nínú èso igi náà, èmi sì jẹ.” Níti gidi, ohun tí ó ń sọ ni pé: “Kì í ṣe ẹ̀bi èmi náà!” Obìnrin àkọ́kọ́, Efa, ṣe ohun kan náà nígbà tí ó sọ pé: “Ejò ni ó tàn mí, mo sì jẹ.”—Genesisi 3:12, 13.
Nípa báyìí a fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ nínú ọgbà Edeni fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn láti kọ̀ láti dáhùn fún ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá gbé. Ìwọ ha ti fìgbà kankan jẹ̀bi èyí rí bí? Nígbà tí ìṣòro bá dìde, ìwọ ha ń tètè dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́bi bí? Tàbí o ha máa ń gbé ipò ọ̀ràn náà yẹ̀wò láti lè mọ ẹni tí ó jẹ̀bi nítòótọ́ bí? Nínú ìgbésí-ayé ojoojúmọ́, ó rọrùn púpọ̀ láti ṣubú sínú ọ̀fìn dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́bi nítorí àwọn àṣìṣe wa kí a sì sọ pé, “Kì í ṣe ẹ̀bi èmi náà!” Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ipò ọ̀ràn tí ó wọ́pọ̀ yẹ̀wò kí a sì rí ohun tí àwọn ènìyàn kan máa ń ní ìtẹ̀sí láti ṣe. Èyí tí ó tún ṣe pàtàkì jùlọ ni pé, kí o ronú lórí ohun tí ìwọ yóò ṣe lábẹ́ irú àyíká ipò kan náà.
Ipò Ìṣòro Ìṣúnná Owó
Nígbà tí àwọn kan bá rí ara wọn nínú wàhálà ìṣúnná owó tí ó gadabú, wọ́n lè sọ pé, “Kì í ṣe ẹ̀bi èmi náà—ọrọ̀-ajé, àwọn oníbàràǹdà, ìnáwó ìgbọ́bùkátà tí ó túbọ̀ ń ga síi ni ó fà á.” Ṣùgbọ́n ṣe àwọn kòkó abájọ wọ̀nyí ni ó yẹ láti dá lẹ́bi nítòótọ́? Ó lè jẹ́ pé àwọn ipò tí kò dá wọn lójú ni ó sún wọn débi tí wọ́n fi dágbálé òwò tí ó lè gbé ìbéèrè dìde tàbí tí kò dá wọn lójú. Nígbà mìíràn ìwọra máa ń ṣíji bo góńgó tí a ní mọ́lẹ̀, àwọn ènìyàn a sì máa rí pé àwọn ń lúwẹ̀ẹ́ nínú odò tí kò ti ojú wọn kún, wọ́n sì ti di ẹran ìjẹ tí ó rọrùn fún àwọn alágbèédá. Wọ́n gbàgbé òwe náà pé, “Gbogbo ohun tí ń dán kọ́ ni wúrà.” Wọ́n a máa wá àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n fẹ́ láti gbọ́ kiri, ṣùgbọ́n nígbà tí ipò ìṣòro ọrọ̀-ajé bá lọ́ kọ́í, wọ́n a máa wá ẹlòmíràn tí wọ́n yóò dálẹ́bi kiri. Ó baninínújẹ́ pé, èyí máa ń wáyé nígbà mìíràn nínú ìjọ Kristian pàápàá.
Àwọn mìíràn ni àwọn ètò ìdókòwò tí kò bọ́gbọ́nmu tàbí tí a pète láti fi luni ní jìbìtì ti dẹkùn mú, irú bíi ríra diamondi tí kò sí, ṣíṣe onígbọ̀wọ́ àwọn ètò tí kò pẹ́ tí ó fi ṣá tí gbogbo ayé ń fẹ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, tàbí ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún ètò mímú dúkìá pọ̀ síi tí ó wọkogbèsè. Ìfẹ́-ọkàn tí ó rékọjá ààlà fún ọrọ̀ ti lè ra wọ́n níyè nípa ìmọ̀ràn Bibeli pé: “Awọn wọnnì tí wọ́n pilẹ̀pinnu lati di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò ati ìdẹkùn . . . wọn sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Timoteu 6:9, 10, NW.
Ìná àpà pẹ̀lú lè yọrí sí ìṣúnná owó tí ó dojúdé. Àwọn kan lérò pé ó yẹ kí àwọn rí bíi ti àwọn ènìyàn tí wọ́n ń rí nínú àwọn ìwé ìròyìn tí ń gbé àṣà ìgbàlódé lárugẹ, kí wọ́n lọ lo àkókò ìsinmi tí ń náni lówó gọbọi, kí wọ́n lọ jẹun ní ilé-àrójẹ tí ó tayọ jùlọ, kí wọ́n sì ra “ohun ìṣeré” àwọn àgbàlagbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde—àwọn ọkọ̀ ìgbafẹ́, ọkọ̀ ojú-omi, kámẹ́rà, ẹ̀rọ ìkọrin jìn-jin-jìn. Àmọ́ ṣáá o, láìpẹ́ láìjìnnà ó lè ṣeé ṣe fún àwọn kan láti ní àwọn nǹkan wọ̀nyí nípa ìwéwèé àti ìfowópamọ́ tí ó mọ́gbọ́ndání. Síbẹ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ń kánjú láti ní wọn lè dá gbèsè gọbọi. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ̀bi ta ni? Ó hàn gbangba pé wọ́n ti ṣá ìmọ̀ràn tí ó yèkooro tí Owe 13:18 fifúnni tì pé: “Òṣì àti ìtìjú ni fún ẹni tí ó kọ ẹ̀kọ́.”
Ìjákulẹ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Ọmọ
Àwọn òbí kan lè sọ pé, “Àwọn alàgbà ni wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọ mi kúrò nínú òtítọ́. Wọn kò fún àwọn ọmọ mi ní àfiyèsí tí ó tó.”
Ẹrù-iṣẹ́ àwọn alàgbà ni ó jẹ́ láti ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo kí wọ́n sì bójútó o, ṣùgbọ́n àwọn òbí fúnra wọn ńkọ́? Wọ́n ha jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ níti fífi àwọn èso ẹ̀mí Ọlọrun hàn nínú gbogbo ìbálò wọn bí? Wọ́n ha ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé nínú Bibeli déédéé bí? Àwọn òbí náà ha ń fi ìtara hàn nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa tí wọ́n sì ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún un bí? Wọ́n ha wà lójúfò nípa àwọn tí àwọn ọmọ wọn ń bá kẹ́gbẹ́pọ̀ bí?
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó rọrùn fún òbí kan láti sọ nípa iṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ pé: “Olùkọ́ ni kò jẹ́ kí ọmọkùnrin mi ṣe dáradára ní ilé-ẹ̀kọ́. Wọn kò fẹ́ràn ọmọkùnrin mi. Àti pé ọ̀pá ìdiwọ̀n ilé-ẹ̀kọ́ yẹn níti ẹ̀kọ́-ìwé tilẹ̀ ti lọ sílẹ̀ jù.” Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ àwọn òbí ń lọ wádìí bí àwọn ọmọ wọn ti ń ṣe ní ilé-ẹ̀kọ́ bí? Òbí náà ha ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ètò-ẹ̀kọ́ àti ohun ti ọmọ rẹ̀ ń kọ́ bí? Wọ́n ha ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ fùn isẹ́ àṣetiléwá rẹ̀, kí wọ́n sì ṣe ìtìlẹ́yìn tí ó bá nílò fún un bí? Ìṣòro tí ó wà nídìí ọ̀ràn náà ha lè jẹ́ ti ìṣarasíhùwà tàbí ìwà ọ̀lẹ ọmọ náà tàbí tí àwọn òbí rẹ̀ bí?
Kàkà tí àwọn òbí yóò fi máa dẹ́bi fún ètò ilé-ẹ̀kọ́, yóò so èso rere lọ́pọ̀lọpọ̀ bí wọ́n bá rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ní ìṣarasíhùwà tí ó tọ́ kí wọ́n sì lo àwọn àǹfààní àtikẹ́kọ̀ọ́ tí ó ṣí sílẹ̀ fún wọn ní ilé-ẹ̀kọ́.
Ìkùnà Láti Dàgbà Nípa Tẹ̀mí
A máa ń gbọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí àwọn kan máa ń sọ pé: “Èmi ì bá ti jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n kì í ṣe ẹ̀bi mi pé n kò jẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn alàgbà ni kò fún mi ní àfiyèsí tí ó tó. Èmi kò ní ọ̀rẹ́ kankan. Kò sí ẹ̀mí Jehofa lórí ìjọ yìí.” Ní àkókò kan náà, àwọn mìíràn nínú ìjọ ní àwọn ọ̀rẹ́, wọ́n ń láyọ̀, wọ́n sì ń ní ìtẹ̀síwájú rere nípa tẹ̀mí; a sì fi ìdàgbàsókè àti aásìkí tẹ̀mí bùkún ìjọ náà. Nítorí náà, èéṣe tí àwọn kan fi ń ní ìṣòro?
Àwọn ènìyàn díẹ̀ ni wọ́n fẹ́ láti jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n ń fi ẹ̀mí òdì àti aláròyé hàn. Ahọ́n mímú bérébéré àti ṣíṣàròyé nígbà gbogbo lè jẹ́ ohun tí ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni jùlọ. Nítorí tí wọn kò fẹ́ kí a kó àárẹ̀ bá wọn nípa tẹ̀mí, àwọn kan lè pààlà sí àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà wọn pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Bí ẹnì kan bá ka èyí sí ìtutù jọ̀bọ̀lọ̀ ìjọ náà, ó lè bẹ̀rẹ̀ síí ṣí kiri, kí ó kọ́kọ́ lọ sí ìjọ kan, lẹ́yìn náà kí ó kọjá sí òmíràn, àti òmíràn. Gẹ́gẹ́ bí àwọn agbo ẹran tí ń ṣí kiri ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Africa tí wọ́n ń wá koríko tútù yọ̀yọ̀ kiri, àwọn Kristian “tí ń ṣí kiri” wọ̀nyí máa ń wá ìjọ tí ó bá wọn mu ní gbogbo ìgbà. Ẹ wo bí wọn yóò ṣe jẹ́ aláyọ̀ tó bí wọ́n yóò bá kúkú wo àwọn ànímọ́ dídára tí àwọn ẹlòmíràn ní kí wọ́n sì làkàkà láti túbọ̀ fi àwọn èso ẹ̀mí ti Ọlọrun hàn ní kíkún síi nínú ìgbésí-ayé wọn!—Galatia 5:22, 23.
Àwọn kan ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe àkànṣe ìsapá láti bá ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ̀rọ̀ ní ìpàdé kọ̀ọ̀kan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kí wọ́n sì gbóríyìn fún wọn tọkàn-tọkàn lórí àwọn kókó dáradára. Ó lè jẹ́ nípa àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ní ìwà ọmọlúwàbí, wíwá sí àwọn ìpàdé Kristian déédéé, àwọn ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà tí a ti múra sílẹ̀ dáradára, ẹ̀mí àlejò ṣíṣe fún ṣíṣí tí ó ṣí ilé rẹ̀ sílẹ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti àwọn ìpàdé fún iṣẹ́-ìsìn pápá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nípa fífi ṣe olórí ète rẹ láti rí àwọn ànímọ́ tí ó wuyì tí àìpé lè mú kí a gbójúfòdá, ó dájú pé ìwọ yóò rí àwọn ànímọ́ tí ó wuyì lára àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀. Èyí yóò mú kí ó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wọn, ìwọ yóò sì rí i pé ìwọ kò lálàṣí àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin.
Àwáwí Gíga Jùlọ
“Ìfẹ́-inú Ọlọrun ni.” “Èṣù ni ó jẹ̀bi.” Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwáwí gíga jùlọ ni láti dá Ọlọrun tàbí Èṣù lẹ́bi fún àwọn ìkùnà tiwa fúnra wa. Òtítọ́ ni pé Ọlọrun tàbí Satani lè nípa ìdarí lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìgbésí-ayé wa. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kan gbàgbọ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo nǹkan, rere tàbí búburú, nínú ìgbésí-ayé wọn ni ó jẹ́ ìyọrísí ọwọ́ Ọlọrun tàbí Satani nínú ọ̀ràn náà. Ńṣe ni ó dàbí ẹni pé kò sí ohunkóhun tí wọ́n ṣe tí ó jẹ́ àbájáde ìgbésẹ̀ tiwọn fúnra wọn. “Bí Ọlọrun bá fẹ́ kí n ní ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ titun, òun yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún mi láti ní in.”
Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń gbé ìgbésí-ayé aláìbìkítà, ní gbígbé àwọn ìpinnu tí ó jẹmọ́ ti ìṣúnná owó àti àwọn nǹkan mìíràn ka orí èrò náà pé Ọlọrun yóò yọ wọ́n. Bí ìgbésẹ̀ aláìlọ́gbọ́n wọn bá yọrí sí àwọn ìjábá kan, ti ọrọ̀-ajé tàbí lọ́nà mìíràn, wọ́n yóò dá Èṣù lẹ́bi. Láti fi ìkùgbùù ṣe ohun kan láìkọ́kọ́ ‘gbéṣiròlé iye tí yóò ná ni’ kí a sì wá dá Satani lẹ́bi fún àìdójú ìwọ̀n náà, tàbí èyí tí ó tilẹ̀ tún burú jùlọ, kí a máa retí pé Jehofa yóò dá sí i, kí yóò jẹ́ kìkì ìwà ọ̀yájú, ṣùgbọ́n yóò tako Ìwé Mímọ́.—Luku 14:28, 29, NW.
Satani gbìdánwò láti mú kí Jesu ronú lọ́nà yẹn kí ó má sì gbà láti dáhùn fún àwọn ìgbésẹ̀ Rẹ̀. Nípa ti ìdánwò kejì, Matteu 4:5-7 ròyìn pé: “Èṣù mú un lọ sí ìlú-ńlá mímọ́, ó sì mú un dúró lórí odi orí òrùlé tẹmpili ó sì wí fún un pé: ‘Bí iwọ bá jẹ́ ọmọkùnrin Ọlọrun, fi ara rẹ sọ̀kò sílẹ̀; nitori a kọ̀wé rẹ̀ pé, “Oun yoo fún awọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní àṣẹ dandangbọ̀n nitori rẹ, ati pé wọn yoo gbé ọ ní ọwọ́ wọn, kí iwọ má baà fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta nígbà kankan.”’” Jesu mọ̀ pé òun kò lè retí pé kì Jehofa dá sí i bí òun yóò bá dágbálé ipa ọ̀nà òmùgọ̀ paraku, àní ti gbígbẹ̀mí-ara-ẹni. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fèsì pé: “A tún kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Iwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jehofa Ọlọrun rẹ wò.’”
Àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìtẹ̀sí láti máa dá Èṣù tàbí Ọlọrun lẹ́bi fún àwọn ìgbésẹ̀ wọn tí a lè gbé ìbéèrè dìde sí farajọ àwọn awòràwọ̀, tí wọ́n wulẹ̀ ń fi àwọn ìràwọ̀ rọ́pò Ọlọrun tàbí Èṣù. Ní mímọ̀ dájú pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ rékọjá agbára wọn, wọ́n gbójúfo ìlànà tí ó rọrùn tí a sọ ní Galatia 6:7 pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni oun yoo ká pẹlu.”
Dídojúkọ Òtítọ́ Gidi
Kò sì ẹnì kan tí ó lè jiyàn pé a ń gbé nínú ayé aláìpé. Àwọn ìṣòro tí a ti jíròrò níhìn-ín ń ṣẹlẹ̀ níti gidi. Àwọn ènìyàn yóò rẹ́ wa jẹ níti ìṣúnná owó. Àwọn agbanisíṣẹ́ kan kò ní ṣe ẹ̀tọ́. Àwọn ojúlùmọ̀ lè nípa lórí àwọn ọmọ wa lọ́nà búburú. Àwọn olùkọ́ àti ilé-ẹ̀kọ́ kan nílò ìmúsunwọ̀n síi. Àwọn alàgbà nígbà mìíràn lè túbọ̀ máa fi ìfẹ́ àti àníyàn hàn. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí a mọ ipa tí àìpé ń kó àti pé, gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti wí, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” Nítorí náà, kò yẹ kí a máa retí pé ipa-ọ̀nà wa jálẹ̀ ìgbésí-ayé yóò rọrùn ní gbogbo ìgbà.—1 Johannu 5:19, NW.
Ní àfikún síi, a gbọ́dọ̀ mọ̀ àìpé àti ààlà tiwa fúnra wa kí a sì mọ̀ pé lọ́pọ̀ ìgbà àwọn ìṣòro wa máa ń jẹ́ nítìtorí ìwà òmùgọ̀ tiwa fúnra wa. Paulu gba àwọn Kristian ní Romu níyànjú pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ lati máṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” (Romu 12:3, NW) Ìmọ̀ràn yẹn ṣeé fi sílò fún gbogbo wa lọ́nà kan náà lónìí. Nígbà tí nǹkan kò bá báradé nínú ìgbésí-ayé wa, a kò ní yára tẹ̀lé bàbáńlá àti ìyáńlá wa Adamu àti Efa kí a sì sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀bi èmi náà!” Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò bi ara wa léèrè pé, ‘Kí ni ó yẹ kí ń ti ṣe láti lè yẹra fún àbájáde bíbaninínújẹ́ yìí? Mo ha lo ojú-ìwòye tí ó dára lórí ọ̀ràn náà kí n sì wa àmọ̀ràn láti orísun tí ó lọ́gbọ́nnínú bí? Mo ha wo ẹgbẹ́ kejì tàbí àwọn ẹgbẹ́ kejì tí ọ̀ràn kàn bí ẹni pé wọn lè má mọwọ́mẹsẹ̀, ní bíbuyì fún wọn bí?’
Bí a bá ń tẹ̀lé àwọn ìlànà Kristian tí a sì ń lo ìrònú tí ó yèkooro, a óò ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ síi ìṣòro wa yóò sì dínkù. Púpọ̀ lára àwọn ìṣòro inú ìgbésí-ayé wa yóò yanjú. Àwa yóò rí ìdùnnú-ayọ̀ nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn a kì yóò sì kó ìdààmú bá wa pẹ̀lú ìbéèrè náà pé: “Ẹ̀bi ta ni?”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn òbí lè ṣe púpọ̀ láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí