“Èmi Kò Tíì Rí Irú Èyí Rí!”
NÍ 1993 a késí ẹ̀ka Watch Tower Society ní Argentina láti fi ẹgbẹ̀rún kan àwọn àyànṣaṣojú ránṣẹ́ sí Santiago, Chile, fún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ọlọ́jọ́ mẹ́rin ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a késí àwọn Ẹlẹ́rìí ará Argentina láti rìnrìn-àjò gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ńlá kan lọ sí àpéjọpọ̀ ní ilẹ̀ àjèjì.a Báwo ní wọn ṣe dáhùnpadà? Ìwé ìbéèrè ṣé-kí-n-wá tí ó ju 8,500 lọ ni ó rọ́ wọlé wá, láti inú èyí tí a ti yan 1,039 àwọn àyànṣaṣojú.
Àròpọ̀ bọ́ọ̀sì 14 ni a háyà fún rírin ìrìn-àjò 1,400 kìlómítà yìí láti Buenos Aires sí Santiago. Àwọn ìran àrímálèlọ fífanimọ́ra fikún ìgbádùn ìrìn-àjò oníwákàtí 26 náà. Bí wọ́n ti sọdá Òkè-Ńlá Andes, àwọn àyànṣaṣojú náà gba ẹ̀gbẹ́ Aconcagua kọjá, ní ìwọ̀n 6,960 mítà, ṣóńṣó òkè tí ó ga jùlọ ní Apá Ìdajì Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀-Ayé. Èyí tí ó jẹ́ mánigbàgbé jùlọ ni ti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kọ́lọkọ̀lọ tí ó da fíríì wọnú Chile. Àwọn awakọ̀ náà ni a pàtẹ́wọ́ fún lákọlákọ, nítorí òye-iṣẹ́ wọn nínú rírí ọgbọ́n dá sí wíwakọ̀ ní àwọn agbègbè ilẹ̀ tí ń gbé ìpèníjà dìde náà!
Bí ó ti wù kí ó rí, ìran tí ó rẹwà jùlọ ní a lè rí ní àpéjọpọ̀ náà fúnra rẹ̀. Nínú ayé tí ó kún fún ìjà orílẹ̀-èdè àti pákáǹleke ẹ̀yà-ìran, ẹ wo bí ó ti tunilára tó láti rí ọ̀pọ̀ jaburata 80,000 ènìyàn láti orílẹ̀-èdè 24 tí ó pésẹ̀ tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan—ẹgbẹ́ àwọn ara kárí-ayé ni ó jẹ́ nítòótọ́! Níwọ̀n bí wọ́n ti rí ìṣọ̀kan tí ó wà láàárín àwọn olùpéjọpọ̀ náà ní tààràtà, àwọn kan lára àwọn tí ń wa bọ́ọ̀sì náà fi ìfẹ́-ọkàn láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa hàn. Ọ̀kan nínú wọn fi ìyàlẹ́nu sọ pé, “Èmi kò tíì rí irú èyí rí!”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìkálọ́wọ́kò tí ìjọba gbé karí Argentina láti 1949 sí 1982 ti mú kí irú ìdáwọ́lé bẹ́ẹ̀ má ṣeé ṣe.