ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 2/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 2/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àwọn wo ni àwọn Filistini tí a mẹ́nukàn nínú Bibeli?

Bibeli sábà máa ń tọ́ka sí àwọn ènìyàn tí a mọ̀ sí Filistini, tí wọ́n gbé ní Kenaani nígbà tí àwọn ènìyàn Ọlọrun ní ìjímìjí gba Ilẹ̀ Ìlérí. Fún àkókò gígùn, àwọn Filistini ará ìgbàanì yìí gbógunti àwọn ènìyàn Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí a ti tẹnumọ́ ọn nínú àkọsílẹ̀ nípa bí Dafidi ṣe wà á kò pẹ̀lú òmìrán akọgun Filistini náà tí a pè ní Goliati.—1 Samueli 17:1-3, 23-53.

Bibeli fihàn pé àwọn Filistini ìgbàanì ṣílọ sí bèbè etíkun gúúsù ìwọ̀-oòrùn Kenaani láti Kaftori. (Jeremiah 47:4) Níbo ni Kaftori wà? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia (1979) sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí náà kò fàyègba ojútùú ṣíṣe gúnmọ́, àkójọ ìmọ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ jẹ́rìí sí i pé erékùṣù Krete (tàbí bóyá Krete àti Erékùṣù Aegean, tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ jọ dà wọ́n pọ̀) ni ibi tí ó dájú pé ó ṣeé ṣe jùlọ kí ó jẹ́ ilẹ̀ náà.”—Ìdìpọ̀ 1, ojú-ìwé 610.

Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures kà ní Amosi 9:7 pé: “‘Ẹ̀yin kò ha dàbí awọn ọmọkùnrin Kuṣi fún mi bí, Óò ẹ̀yin ọmọkùnrin Israeli?’ ni àsọjáde-ọ̀rọ̀ Jehofa. ‘Èmi kò ha mú Israeli fúnra rẹ̀ jáde ti ilẹ̀ Egipti wá, ati awọn Filistini jáde ti ilẹ̀ Krete wá, ati Siria jáde ti ilẹ̀ Kiri wá?’”

A kò mọ ìgbà tí àwọn ènìyàn tí ń gbé lẹ́bàá omi yìí ṣí kúrò láti Krete lọ sí ẹ̀ka-ìpín ilẹ̀ Kenaani tí a wá ń pè ní Filistia, apá gúúsù ìwọ̀-oòrùn ìlà bèbè etíkun tí ń bẹ láàárín Jopa ati Gasa. Ó dàbí ẹni pé wọ́n ti wà ní ẹkùn pẹ̀tẹ́lẹ̀ bèbè etíkun rírẹlẹ̀ yìí ní àwọn ọjọ́ Abrahamu àti Isaaki.—Genesisi 20:1, 2; 21:32-34; 26:1-18.

Àwọn Filistini ń báa lọ láti jẹ́ agbára ìdarí lílágbára ní agbègbè náà fún àkókò pípẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israeli ti wọ ilẹ̀ tí Ọlọrun ti ṣèlérí fún wọn. (Eksodu 13:17; Joṣua 13:2; Awọn Onidajọ 1:18, 19; 3:3, 4; 15:9, 10; 1 Samueli 4:1-11; 7:7-14; 13:19-23; 1 Awọn Ọba 16:15) Tipẹ́ sẹ́yìn láti ìgbà ìṣàkóso ọba Judea náà Ussiah, ni àwọn Filistini ti dúró sínú àwọn ìlú-ńlá wọn ní Gati, Jabne, àti Aṣdodu. (2 Kronika 26:6) Òmíràn nínú àwọn ìlú-ńlá wọn tí ó rọrùn láti tètè rí nínú àkọsílẹ̀ Bibeli ni Ekroni, Aṣkeloni, àti Gasa.

Alexander Ńlá ṣẹ́gun àwọn Filistini ní ìlú-ńlá Gasa, ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò tó, ó farahàn kedere pé àwọn Filistini ṣíwọ́ láti máa jẹ́ ènìyàn ọ̀tọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Lawrence E. Stager kọ̀wé nínú Biblical Archaeology Review (May/June 1991) pé: “Àwọn Filistini pẹ̀lú ni a kó nígbèkùn lọ sí Babiloni. . . . Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí àkọsílẹ̀ kan nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Filistini tí a kó lọ sí ìgbèkùn náà. Ó dájú pé àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n wà ní Aṣkeloni lẹ́yìn ìjagunmólú Nebukadnessari ni a kò dámọ̀ yàtọ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ẹ̀yà kan pàtó. Wọ́n parẹ́ ráúráú kúrò nínú ìtàn.”

Orúkọ òde-òní Palestine ni a fàyọ láti inú ọ̀rọ̀ Latin àti Griki náà, èyí tí ó mú wa padà sórí ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “Filistia.” Àwọn ìtumọ̀ Bibeli kan ní èdè Arabia lo ọ̀rọ̀ kan fún “Filistini” tí a lè tètè ṣìmú fún ọ̀rọ̀ tí a lò fún àwọn ará Palestine òde-òní. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé Today’s Arabic Version lo ọ̀rọ̀ Arabia mìíràn tí ó yàtọ̀, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ìyàtọ̀ sí àárín àwọn Filistini ìgbàanì àti àwọn ará ilẹ̀ Palestine ti òde-òní.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwókù díẹ̀ ní Aṣkeloni

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́