Ọgbọ́n Ìhùmọ̀ Ẹ̀bùn Ọlọ́làwọ́ Láti Ọwọ́ Ọlọrun
JEHOFA ń yọ̀ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. (Orin Dafidi 104:31) Ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀ tí ó ń rí nínú fífi ọgbọ́n hùmọ̀ nǹkan ni a sọ jáde nínú Genesisi 1:31 pé: “Ọlọrun sì rí ohun gbogbo tí ó dá, sì kíyèsí i, dáradára ni.”
Jehofa kò fi ìdùnnú-ayọ̀ yìí mọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nìkan. Ó fún Jesu ní àǹfààní jíjẹ́ aṣojú, tàbí irin-iṣẹ́ kan, tí a tipasẹ̀ rẹ̀ dá gbogbo àwọn nǹkan mìíràn. (Johannu 1:3; Kolosse 1:16, 17) Gẹ́gẹ́ bí “ọ̀gá oníṣẹ́,” Jesu tún “yọ̀ nígbà gbogbo níwájú [Jehofa].”—Owe 8:30, 31, NW.
Ṣùgbọ́n agbára-ìṣe láti hùmọ̀ nǹkan kò mọ sí ọ̀run nìkan. Eugene Raudsepp nínú ìwé rẹ̀ How Creative Are You? kọ̀wé pé: “A dá a mọ́ ìran ẹ̀dá ènìyàn.” Èyí kì í ṣe èèṣì, nítorí pé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọrun. (Genesisi 1:26) Jehofa ti tipa báyìí fi agbára-ìṣe láti hùmọ̀ jíǹkí ìran ènìyàn.—Jakọbu 1:17.
Kò yanilẹ́nu, nígbà náà pé Bibeli sọ̀rọ̀ lọ́nà rere nípa orin kíkọ, ijó jíjó, aṣọ híhun, oúnjẹ sísè, ọgbọ́n iṣẹ́-ọnà, àti àwọn ọgbọ́n ìhùmọ̀ mìíràn. (Eksodu 35:25, 26; 1 Samueli 8:13; 18:6, 7; 2 Kronika 2:13, 14) Besaleli, oníṣẹ́-ọnà, lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti ṣe “onírúurú iṣẹ́-ọnà” láti ṣe ìtìlẹ́yìn fún kíkọ́ àgọ́-àjọ. (Eksodu 31:3, 4) Olùṣọ́ àgùtàn náà Jabali ti lè jẹ́ ẹni tí ó hùmọ̀ àgọ́, ohun rírọrùn kan tí a dọ́gbọ́n hùmọ̀ fún gbígbé ìgbésí-ayé ṣíṣí káàkiri. (Genesisi 4:20) Dafidi kì í ṣe olórin àti akórinjọ nìkan, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ẹni tí ń ṣe àwọn ohun-èlò orin titun. (2 Kronika 7:6; Orin Dafidi 7:17; Amosi 6:5) Ó ṣeé ṣe kí Miriamu ti ṣètò ijó onídùnnú tí ó sàmì sí ìdáǹdè àwọn ọmọ Israeli la Òkun Pupa já lọ́nà ìyanu.—Eksodu 15:20.
Dúkìá kan ní ọgbọ́n ìhùmọ̀ sábà máa ń jẹ́ nínú gbígbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Jesu fi ọgbọ́n ìhùmọ̀ lo àwọn àkàwé àti ẹ̀kọ́ àwòkọ́ṣe láti gbé ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ kalẹ̀. Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni a rọ̀ lọ́nà kan náà láti “ṣiṣẹ́ kára ninu ọ̀rọ̀ sísọ ati kíkọ́ni.” (1 Timoteu 5:17, NW) Bẹ́ẹ̀ni, iṣẹ́ ìwàásù wọn kì í ṣe ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ lásán. Ó jẹ́ òye-iṣẹ́ kan tí ń béèrè ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ó gbe ìhùmọ̀ yọ. (Kolosse 4:6) Èyí ṣe kókó ní pàtàkì nígbà tí ẹnì kan bá ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀.—Deuteronomi 6:6, 7; Efesu 6:4.
Nípa báyìí, Jehofa ń ṣàjọpín ìdùnnú-ayọ̀ tí ṣíṣẹ̀dá àwọn nǹkan ń fún un pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ẹ wo irú ẹbun ọlọ́làwọ́ tí èyí jẹ́!