ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/8 ojú ìwé 15
  • Ibojì Kristi ní Japan Kẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibojì Kristi ní Japan Kẹ̀?
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • “Wákàtí Rẹ̀ Kò Tíì Dé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 4/8 ojú ìwé 15

Ibojì Kristi ní Japan Kẹ̀?

NÍ 1935, Koma Takeuchi, àlùfáà ìsìn Ṣintó kan, kéde pé òun ti ṣàwárí ibojì Jésù Kristi lórí òkè kan ní abúlé Shingo, ní ìhà àríwá Japan. Ó sọ pé àwọn àkọsílẹ̀ tí wọ́n rí níbi ìkẹ́rùsí ìdílé kan fi hàn pé Jésù ti fi àkókò kan gbé Shingo, ibẹ̀ ló sì kú sí. Níbi tí ó ti ń wá ibojì Jésù kiri, o rí òkìtì kan, ó sì parí èrò sí pé, ibojì náà nìyẹn.

Lẹ́yìn náà, àkọsílẹ̀ èdè Hébérù kan tí wọ́n sọ pé wọ́n rí ní ojúbọ ìdílé Takeuchi sọ pé Jésù ti ṣèbẹ̀wò sí Japan lẹ́ẹ̀mejì, ó sì tilẹ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ ìfòyemọlọ́run lọ́dọ̀ àwọn àlùfáà ará Japan. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé lẹ́yìn tí wọ́n ti da Jésù ní Jùdíà, ó sá lọ sí ijù Siberia, ó wá rìnrìn àjò lọ sí Japan, níbi tí ó ti gbé ọmọbìnrin ìbílẹ̀ kan tí ń jẹ́ Miyuko níyàwó, tí ó bí àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta, tí ó sì kú ní ọmọ ọdún 106. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ṣe sọ, ọkùnrin tí wọ́n pa ní Jerúsálẹ́mù kì í ṣe Jésù, àbúrò rẹ̀ tí ń jẹ́ Isukiri ni.

Kí ló lè ṣokùnfà irú ìtàn bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Mainichi Shimbun ṣe wí, ìsopọ̀ láàárín Jésù àti Shingo “dábàá àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ nítorí ọrọ̀ ajé, tí kò sì ṣókùnkùn sí àwọn aláṣẹ àdúgbò.” Nítorí náà, a fún lílọṣàfojúrí níṣìírí. A kò fún ṣíṣọ̀fíntótó níṣìírí. Alákìíyèsí kan sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká ní wọ́n gbẹ́ ibojì náà, wọn kò sì rí nǹkan kan níbẹ̀ yàtọ̀ sí ògbólógbòó egungun màlúù. Ẹ wo bí olúkúlùkù yóò ṣe ní ìjákulẹ̀ tó.”

Nítorí náà, lọ́dọọdún ni àwọn olùṣèbẹ̀wò ń kóra jọ níwájú ohun tí a sọ pé ó jẹ́ ibojì Jésù náà láìyẹhùn láti ṣàjọyọ̀ “Àjọ̀dún Kristi” ní May 3. Àlùfáà ìsìn Ṣintó kan ní ń darí ètò náà, ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jìnnà kí ijó tó bẹ̀rẹ̀.

Ǹjẹ́ ìtàn yìí ní òtítọ́ kankan nínú? Ó tì o. Bíbélì sọ fún wa pé nígbà tí Jésù di ọmọ 30 ọdún, a kò mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí arìnkáyé kan, ṣùgbọ́n a mọ̀ ọ́n bí ọmọkùnrin káfíńtà tó ti dàgbà ní Násárétì. Àwọn Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní àwọn àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àfojúrí nípa bí Kristi ṣe wàásù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì láàárín ìgbà tó wà ní ọmọ 30 ọdún sí ọmọ ọdún 33. Wọ́n dárúkọ àwọn ibi tí ó fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ni wọ́n pa ní Jerúsálẹ́mù, àti àwọn déètì pẹ̀lú. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ìròyìn alásọrégèé tí ń gbìyànjú láti dabarú òtítọ́ Bíbélì nítorí ète ìmọtara-ẹni-nìkan kò ṣi àwọn ojúlówó Kristẹni lọ́nà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́