Bí Ojú Ọjọ́ Yóò Ṣe Rí Lọ́jọ́ Iwájú
SÍSỌ afẹ́fẹ́ àyíká wa di eléèérí jẹ́ ọ̀kan péré lára àwọn ìṣòro àyíká tí ènìyàn ti dá sílẹ̀. Àwọn mìíràn ní ìpagbórun rẹpẹtẹ, pípa àwọn irú ọ̀wọ́ ẹranko run, àti sísọ àwọn odò, adágún omi, àti òkun di eléèérí nínú. A ti fìṣọ́ra ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìṣòro wọ̀nyí, a sì ti ṣe àwọn ìwéwèé láti ṣàtúnṣe wọn. Níwọ̀n bí àwọn ìṣòro náà ti wà káàkiri ayé, wọ́n nílò ojútùú kárí ayé. Ìfohùnṣọ̀kan ti wà káàkiri nípa àwọn ìṣòro náà àti ohun tí a lè ṣe láti yanjú wọn. Ọdọọdún ni a ń gbọ́ ìpè láti wá nǹkan ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ohun tí a ń ṣe nípa rẹ̀ lọ́dọọdún, kò tó nǹkan. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn tí ń gbé ìlànà kalẹ̀ ń kédàárò nípa àwọn ìṣòro náà, wọ́n sì gbà pé a gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan, àmọ́ wọ́n fi kún un pé, “kì í ṣe àwa ni a óò ṣe é, kì í sì ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́.”
Ní 1970, nígbà àkọ́kọ́ ayẹyẹ Àyájọ́ Ilẹ̀ Ayé, àwọn olùwọ́de ní Ìlú Ńlá New York gbé pákó ńlá kan. Pákó náà ṣàpèjúwe Ilẹ̀ Ayé tí ń kébòòsí “Ẹ Gbà Mí O!!” Ẹnikẹ́ni yóò ha dáhùn sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yẹn? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáhùn pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:3, 4) Onísáàmù náà wá tọ́ka sí Ẹlẹ́dàá nítorí Òun nìkan ló ní agbára, ọgbọ́n, àti ìfẹ́ láti yanjú gbogbo ìṣòro dídíjú tí ó wà níwájú aráyé. A kà pé: “Aláyọ̀ ni ẹni . . . tí ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, òkun, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn.”—Sáàmù 146:5, 6.
Ìlérí Onífẹ̀ẹ́ Tí Ẹlẹ́dàá Ṣe
Ilẹ̀ ayé jẹ́ ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó pilẹ̀ rẹ̀, ó sì dá a, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìṣiṣẹ́ àgbàyanu, tí ó díjú, tí ń mú kí ipò ojú ọjọ́ ilẹ̀ ayé gbádùn mọ́ni. (Sáàmù 115:15, 16) Bíbélì sọ pé: “[Ọlọ́run] ni Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ agbára rẹ̀, Ẹni náà tí ó fìdí ilẹ̀ eléso múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ ọgbọ́n rẹ̀, àti Ẹni náà tí ó na ọ̀run nípasẹ̀ òye rẹ̀. Nígbà tí ohùn rẹ̀ dún, òun a fúnni ní ìdàwìtìwìtì omi ní ojú ọ̀run, a sì mú kí oruku ròkè láti ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó tilẹ̀ ti ṣe ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ fún òjò, ó sì ń mú ẹ̀fúùfù jáde wá láti inú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ̀.”—Jeremáyà 10:12, 13.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ìfẹ́ tí Ẹlẹ́dàá ní sí ìran ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé fún àwọn ènìyàn Lísírà ìgbàanì. Ó wí pé: “[Ọlọ́run] kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Ìṣe 14:17.
Ọjọ́ iwájú pílánẹ́ẹ̀tì yìí kò sí lọ́wọ́ ìsapá àti àwọn àdéhùn tí àwọn ènìyàn ń ṣe. Ẹni tí ó ní agbára láti ṣàkóso ipò ojú ọjọ́ ṣèlérí fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ìgbàanì pé: “Dájúdájú, èmi yóò fún yín ní ọ̀wààrà òjò ní àkókò rẹ̀ tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu, ilẹ̀ yóò sì mú èso rẹ̀ wá ní ti gidi, igi pápá yóò sì fi èso rẹ̀ fúnni.” (Léfítíkù 26:4) Láìpẹ́ sí àkókò yìí, àwọn ènìyàn yóò gbádùn irú ipò yẹn jákèjádò ilẹ̀ ayé. Àwọn ènìyàn aláìpé kì yóò fòyà nípa ìjì tí ń ba nǹkan jẹ́, ìrugùdù omi, ìkún omi, ọ̀dá, tàbí ìjábá àdánidá èyíkéyìí mọ́.
Ìjì, ẹ̀fúùfù, àti ojú ọjọ́ lápapọ̀ yóò jẹ́ ohun gbígbádùnmọ́ni. Àwọn ènìyàn ṣì lè máa sọ̀rọ̀ nípa ojú ọjọ́, àmọ́ wọn kò ní ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Ní ọjọ́ iwájú tí Ọlọ́run yóò mú wá, ìgbésí ayé yóò mìnrìngìndìn gan-an tí kò fi ní sí ìdí fún wọn láti ṣàtúnṣe ojú ọjọ́.