Ojú ìwé 2
Ǹjẹ́ Lílo Oògùn Láìkọ́kọ́rí-Dókítà Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Tàbí Ó Lè Pa Ọ́ Lára? 3-9
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lílo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà ni oríṣi ìtọ́jú tó wà níbi púpọ̀ lágbàáyé. Ní àwọn ibòmíràn, àwọn oríṣi ìtọ́jú mélòó kan wà, tí a lè yan èyí tí a bá fẹ́ nínú wọn. Àmọ́ irú ìṣọ́ra wo ló yẹ kí a ní nígbà tí a bá ń yan oògùn tí a ó lò?
Kí Ló Burú Nínú Títage? 20
Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín híhùwà bí ọ̀rẹ́ àti jíjẹ́ ẹni tí ń tage? Èé ṣe tí títage fi léwu, tí ó sì jẹ́ ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan?
Wíwo Ẹyẹ—Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Tí Gbogbo Ènìyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí Ni Bí? 23
Bí a ti ní irú ọ̀wọ́ ẹyẹ tó lé ní 9,600 lágbàáyé, wíwo ẹyẹ lè jẹ́ ohun amóríyá tí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kan. Ṣe o lè ṣe é?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
© The Curtis Publishing Company