Ríran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Láti Bọ́ Lọ́wọ́ “Àṣà Ká Máa Pààyàn”
Kí ló ń fà á tí ọ̀ràn nípa ikú fi máa ń fa àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra báa ti ń rí i lónìí? Henry Hyde, tó ń ṣojú fún ìpínlẹ̀ Illinois, ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Ipò tẹ̀mí àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ṣófo, àṣà ká máa pààyàn àti ìwà ipá ló kún inú wọn.”
ẸNÌ kan tó ka ìwé ìròyìn Time kọ̀wé pé: “Àwọn òbí tó yọ̀lẹ, ohun àṣenajú tó kún fún ìwà ipá, àti àìfi ìwà rere àti ohun tẹ̀mí kọ́ wọn ló fa àṣà ká máa pààyàn tí àwọn ọ̀dọ́ gbọ́njú bá lónìí.”
Ìdáwà tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣòro pàtàkì tó ń pọ́n àwọn ọ̀dọ́ lójú. Àwọn kan ń gbé nínú ìdílé tí àwọn òbí méjèèjì ti máa ń lọ síbi iṣẹ́, èyí tí kì í jẹ́ kí wọ́n sí nílé látàárọ̀ ṣúlẹ̀; òbí kan ṣoṣo sì ni àwọn mìíràn ní. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan ti sọ, àwọn ọ̀dọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà máa ń dá wà fún nǹkan bí wákàtí mẹ́ta àtààbọ̀ lójoojúmọ́, àkókò tí wọ́n sì ń lò pẹ̀lú àwọn òbí wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fi wákàtí mọ́kànlá dín sí tàwọn ọ̀dọ́ láàárín ọdún 1960 sí 1969. Ká sọ tòótọ́, àwọn ọ̀dọ́ kan wà táwọn òbí wọn ò jókòó tì wọ́n rí, àwọn òbí wọn kì í sì í ṣèránwọ́ fún wọn láti bójútó ìmí ẹ̀dùn wọn.
Ohun Táwọn Òbí Lè Ṣe
Pẹ̀lú “ipò tẹ̀mí” tó “ṣófo” táwọn ọ̀dọ́ ń bá yí yìí, báwo ni ipa àwọn òbí ti ṣe pàtàkì tó? Àwọn òbí tó gbọ́n mọ̀ pé lọ́nà kan, àwọn ọmọ àwọn nílò ohun àṣenajú tó gbámúṣé àti pé lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn déédéé. Bí àwọn òbí bá ní ire àti ìfẹ́ wọn lọ́kàn, wọ́n lè bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn orin, ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, fídíò, ìwé, eré àṣedárayá orí fídíò, àti àwọn sinimá tí wọ́n yàn láàyò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ lè má sọ ọ́ jáde, púpọ̀ wọn ló ń fẹ́ pé káwọn òbí wọn fi ìfẹ́ hàn sáwọn, kí wọ́n sì fún wọn ní ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́. Wọ́n nílò àwọn ìdáhùn tó ṣe kedere nítorí inú ayé tó kún fún àìdánilójú ni wọ́n ń gbé. Ó yẹ káwọn àgbàlagbà mọ̀ pé ìṣòro táwọn ọmọ ń kojú rẹ̀ láyé ìsinsìnyí le gan-an ju èyí táwọn kojú rẹ̀ lọ nígbà tiwọn.
Àwọn òbí tí wọ́n fẹ́ láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn yóò máa jíròrò pẹ̀lú wọn déédéé, wọn yóò máa tẹ́tí sí wọn dáadáa, wọn yóò sì máa kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn ewu tó wà nínú àwọn àṣà tó wà lóde òní. Bí àwọn òbí bá ṣòfin tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí wọn ò gba gbẹ̀rẹ́, tí wọ́n fòye bá wọn lò, tí wọ́n sì fi hàn pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ àwọn, wọn yóò ṣàṣeyọrí.—Mátíù 5:37.
Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti bá àwọn ọmọ wọn jíròrò déédéé, ní lílo Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde àti fídíò tó dá lórí Bíbélì.a Wọn kì í lo irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ láti fi bá àwọn ọmọ wọn wí, ṣùgbọ́n láti fi jíròrò àwọn kókó tó ń gbéni ró nípa tẹ̀mí. Níbi ìpàdé ìdílé yìí, wọ́n máa ń tẹ́tí sí àwọn ìṣòro tàbí ìpèníjà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wọ́n bá ní, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀dọ́ náà bàa ní àǹfààní láti rí àfiyèsí gbà.
Àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò rí ìtọ́sọ́nà nípa tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn lè jèrè okun láti inú ohun tí Sáàmù 27:10 sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” Báwo ni Jèhófà, tí í ṣe Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ṣe ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́? Àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jẹ́ ibi ààbò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn mìíràn, wọ́n sì ti bá wọn wá nǹkan ṣe sí àwọn ohun tó ń bà wọ́n lẹ́rù. Josías, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ti rí ẹ̀rí pé òótọ́ lọ̀rọ̀ náà, sọ pé: “Ètò àjọ Jèhófà kó ipa pàtàkì kan. Mo ronú pé ìgbésí ayé ò já mọ́ nǹkan kan. Mo ń gbé ìgbésí ayé aláìléte, tí kò sírètí. Ìgbà tí mo wá mọ̀ pé mi ò dá wà ni ìgbésí ayé mi yí padà pátápátá. Láàárín àwọn ará nínú ìjọ ni mo ti rí ìdílé tí mo ti pàdánù. Àwọn alàgbà àti àwọn ìdílé nínú ìjọ dà bí ìdákọ̀ró fún mi nínú bíbójútó ọ̀ràn ìmí ẹ̀dùn mi.”
Ní gidi, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ àti àwọn àgbàlagbà ti mú èrò inú àti ipò tẹ̀mí wọn sunwọ̀n sí i nípa lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Patricia Fortuny, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, sọ̀rọ̀ lórí ipa rere yìí nínú àròkọ rẹ̀ náà, Los Testigos de Jehová: una alternativa religiosa para enfrentar el fin del milenio (Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà: Ìsìn Mìíràn Tó Yẹ Ní Yíyàn fún Kíkojú Òpin Ẹgbẹ̀rúndún), pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pèsè ètò kan tó ṣe kedere, tó ṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀ láti mú lò nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́, ó jẹ́ ọ̀nà ìhùwà tó ṣe déédéé gan-an tó ń ṣiṣẹ́ bí atọ́nà kan fún èrò àti ìṣe.” ‘Ètò tó ṣọ̀kan’ àti èyí tó “ṣe kedere” tí a ń sọ níhìn-ín la gbé karí Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kojú irú ìṣòro àti ìdààmú kan náà táwọn aládùúgbò wọn ń ní, ọgbọ́n àrà ọ̀tọ̀ tó tinú ìwé àtijọ́ yẹn wá ń fún wọn lókun. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn Ẹlẹ́rìí rí ààbò látinú ẹ̀kọ́ àti àwọn ìlànà tó ṣe kedere tí wọ́n ń rí nínú Bíbélì.
Nígbà Tí ‘Ikú Kì Yóò Sí Mọ́’
Ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ lemọ́lemọ́ nípa ìlérí Ọlọ́run nípa ayé tuntun tí yóò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́, níbi tí “òdodo yóò sì máa gbé” tí “kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì” níbẹ̀. (2 Pétérù 3:13; Míkà 4:4) Síwájú sí i, wòlíì Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ pé nígbà yẹn, Ọlọ́run “yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” Ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, ṣẹ̀ ni ikú tó ń kọ lu ìran ènìyàn jẹ́, ṣùgbọ́n ìlérí Ọlọ́run ni pé láìpẹ́, ‘ikú kì yóò sí mọ́.’—Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 21:3, 4; Róòmù 5:12.
Bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń wá ìrànlọ́wọ́, a ké sí ọ láti wádìí nínú Bíbélì nípa ìrètí àti ìdí táa fi wà láàyè. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè ní ìrètí pé àkókò tó dára jù lọ ṣì wà níwájú fún wa nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló ṣe fídíò náà, Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Ní báyìí, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi ṣe é, ó sì ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tó wúlò fún àwọn ọ̀dọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ó yẹ kí àwọn òbí tẹ́tí sí àwọn ọmọ wọn dáadáa kí wọ́n sì lóye àwọn ìṣòro wọn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pèsè ètò kan tó ṣe kedere, tó ṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀ láti mú lò nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́