“Kíka Ìwé Ìròyìn Yín Ti Mọ́ Mi Lára”
Ìwé kan tí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Watch Tower Society ní Jámánì rí gbà kà lápá kan pé:
“Mo ti wá rí i báyìí pé kíka ìwé ìròyìn yín ti mọ́ mi lára. Ohun kan náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí mi lọ́dọọdún. Nígbà tí mo ń múra láti lọ fún ìsinmi, mo pinnu pé màá mú ìtẹ̀jáde méjì tó dé kẹ́yìn nìkan dání kí n lè máa rí nǹkan kà létí òkun. Kì í sọ̀rọ̀ àwàdà o!
“Ṣùgbọ́n bí mo ṣe kó wọn sọ́wọ́ báyìí nìṣòro bá tún dé. Mo kàn ní kí n wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àkọlé inú rẹ̀ ni o. Ó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀, ìtàn ìgbésí ayé ni mo bá pàdé! Jẹ́ kí n sáré ka òun nìkan, kí n kàn fi tọ́ o wò, òun nìkan ni màá kà o. Àdánwò ńlá, àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e tún fakíki lárà ọ̀tọ̀. Ó tó gẹ́ẹ́ wàyí! Mo ṣáà fẹ́ kó àwọn ìwé ìròyìn náà dání kí n lè rí nǹkan kà nígbà ìsinmi ni. Ó dára, jẹ́ kí n kàn ka àpilẹ̀kọ kan péré sí i. Abala “Wíwo Ayé” a sì máa ní gbankọ-gbì ìsọfúnni nínú! Ó ṣeé ṣe kẹ́ẹ ti máa ro ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀, kí n tó dé etíkun, mo ti ka gbogbo àpilẹ̀kọ inú rẹ̀ tán pátá.”
Iye ẹ̀dà Jí! ti a ń tẹ̀ jáde, èyí tí ó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ ó lé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [20,300,000] nínú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan ní èdè méjìlélọ́gọ́rin ló tún jẹ́ ẹ̀rí bí ìwé ìròyìn náà ṣe ń fani mọ́ra tó. Àwọn tó ń kà á máa ń gbádùn ojú ìwòye títọ̀nà tó ní. Àlàyé náà, “Ìdí Tí A Fi Ń Tẹ Jí! Jáde,” tó wà nínú ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan jẹ́ kí ó yé wa pé “ìwé ìròyìn yìí ń gbé ìgbẹ́kẹ̀lé ró nínú ìlérí tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe nípa ayé tuntun.”
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ń béèrè pé, ‘Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà fún àkókò pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀?’ A dáhùn ìbéèrè yẹn nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? O lè rí ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ yìí gbà tí o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.