ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 5/8 ojú ìwé 32
  • “Akérékorò Ni Ìwé Náà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Akérékorò Ni Ìwé Náà”
  • Jí!—2002
Jí!—2002
g02 5/8 ojú ìwé 32

“Akérékorò Ni Ìwé Náà”

Nígbà tí ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní báńkì kan ní Chicago, Illinois, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fiṣẹ́ sílẹ̀ láti lọ kà kún ìwé rẹ̀, ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ fún un ní ẹ̀dà kan ìwé Is There a Creator Who Cares About You?. Nígbà tó yá, obìnrin yìí gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ ọkùnrin náà. Ohun tó kọ rèé:

‘Akérékorò ni ìwé tó o fún mi yẹn o! Láti ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn ni mo ti ń kà á, àwọn ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ló sì wà nínú rẹ̀. Èyí tí mo fẹ́ràn jù lọ níbẹ̀ ni bó ṣe lo ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa sánmà àti ilẹ̀ láti ṣàlàyé pé ìṣẹ̀dá jẹ́ “ohun tí ọlọgbọ́n kan dìídì ṣe.” Bákan náà ni Ìwàásù Lórí Òkè tún wú mi lórí gan-an.’

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti túbọ̀ wá ń ronú jinlẹ̀ báyìí nípa ibi tí ìwàláàyè ti wá àti ìdí tá a fi wà láàyè lẹ́yìn tí wọ́n ka ìwé Is There a Creator Who Cares About You? Èyí tó ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé, ó ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti parí èrò wọn síbi tó ṣe sàn-án.

O lè béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé 192 yìí, tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì, nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tá a tò sí ojú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Òkè: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Anglo-Australian Observatory, David Malin ló ya fọ́tò; ẹ̀yìn ìwé: J. Hester àti P. Scowen (AZ State Univ.), NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́