“Gbogbo Èèyàn Ló Yẹ Kó Kàwé Yìí O”
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ POLAND
Ní àwọn àpéjọ tó wáyé jákèjádò ayé, tó bẹ̀rẹ̀ lóṣù May ọdún 2003, la ti mú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà jáde ní onírúurú èdè. Bíi tàwọn ará wa níbi gbogbo làwọn ará Poland náà ṣe kún fún ayọ̀ pípabanbarì lẹ́yìn tí wọ́n gba ìwé tó ní àwòrán mèremère yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé la dìídì kọ ìwé náà fún, àwọn lẹ́tà tá a ti rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbàlagbà fi hàn pé tèwe tàgbà ló ń gbádùn ìwé náà. Díẹ̀ rèé lára àwọn lẹ́tà tá a rí gbà.
“Agata lorúkọ mi, ọmọ ọdún mẹ́jọ sì ni mí. Nígbà tí mo rí ìwé yìí gbà ni mo wá mọ bí Jèhófà ṣe fẹ́ràn mi tó. Orí keje tó sọ pé ‘Ìgbọràn Ń Dáàbò Bò Ọ́’ ni mo fẹ́ràn jù. Mo máa ń ṣàìgbọràn díẹ̀díẹ̀, àmọ́ mo ti wá mọ̀ báyìí pé ó yẹ kí ń yí padà nítorí pé Jèhófà fẹ́ràn àwọn ọmọ tó bá ń gbọ́ràn sí òbí wọn lẹ́nu.”
Marlena, ọmọ ọdún mẹ́tàlá, kọ̀wé tayọ̀tayọ̀ pé: “Mo mọ̀ pé torí àwọn ọmọdé lẹ ṣe kọ̀wé yìí o, àmọ́ mo gbà pé gbogbo èèyàn ló fẹ́ràn ẹ̀. Kíkà tí mò ń kà á ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà àti Jésù lágbára. Kódà, ìwé náà fi ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti yéni ṣàlàyé àwọn nǹkan tí ò lè tètè yéni. Bíi kí n máà gbé e sílẹ̀ mọ́ ni. Àwọn àwòrán inú ẹ̀ tún ti lọ wà jù! Àwọn ìbéèrè tí wọ́n kọ síbi àwòrán náà á máa fa ọkàn àwọn ọmọdé mọ́ra ṣáá ni! Ohun àgbàyanu ni ìwé náà jẹ́, nítorí ẹ̀ ni mo ṣe ń fara balẹ̀ kà á. Ẹ ṣeun gan-an ni.”
Justyna, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, sọ bí ìwé náà ṣe wọ òun lọ́kàn tó. Ó sọ pé: “Àwọn orí tí mo ti kà nínú ẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin débi pé mo fẹ́ láti dúpẹ́ tọkàntọkàn lọ́wọ́ yín fún ẹ̀bùn rírẹwà tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tó gbámúṣé náà. Ì bá
ti dáa tó ká ní gbogbo èèyàn, tó fi mọ́ àwọn arúgbó pàápàá, lè ka ìwé náà. Àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú ẹ̀ rọrùn, ó sì dà bí ẹni pé lójú tèmi, ọmọ ọdún kan pàápàá lè lóye wọn dáadáa. Àwọn àwòrán inú ẹ̀ ò wá àlàyé mọ́. Mi ò tiẹ̀ mọ bí ǹ bá ṣe ṣàlàyé bí ìwé náà ṣe máa ń rí lára mi nígbà tí mo bá ń kà á.”
Eunika pẹ̀lú dúpẹ́ ó tọ́pẹ́ dá nítorí ìwé yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni, ìháragàgà ló fi ka ìwé tuntun náà, ó sì sọ pé ìwé tó “wúlò fáwọn ọ̀dọ́” ni. Ó tún kọ̀wé pé: “Ìmọ̀ràn inú ẹ̀ wúlò gan-an fun gbogbo nǹkan téèyàn bá ń ṣe lójoojúmọ́, ì báà jẹ nínú ilé, níléèwé àti nínú ìjọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ẹ̀bùn yìí.”
Lẹ́yìn tí Maria, tó jẹ́ ìyá ọmọ ọlọ́dún kan tó ń jẹ́ Oliwia tí kíyè sí bí ọkàn ọmọ rẹ̀ ṣe ń fà sí àwọn àwòrán mèremère tó wà nínú ìwé náà, ó kọ̀wé pé: “Mo fi gbogbo ara dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìwé tí ò lẹ́gbẹ́ tá a lè máa fi kọ́ àwọn ọmọdé yìí. Oliwia, ọmọ wa kì í fẹ́ gbójú kúrò lára ìwé náà. Á jókòó sórí ẹsẹ̀ wa á sì fẹ́ ká máa sọ àwọn ohun tó wà nínú ìwé náà fóun. Àwòrán tó wà lójú ìwé kẹtàlélọ́gọ́rin ló fẹ́ràn jù. Àwòrán àwọn ọmọbìnrin méjì tí àwọ̀ ara wọn yàtọ̀ síra, tí wọ́n fọwọ́ kọ́ ara wọn lọ́rùn ló wà níbẹ̀. Àwọn àwòrán míì jọ èèyàn gidi débi pé á fọwọ́ kàn wọ́n, á wù ú kó dì mọ́ wọn, a wá gbé ìwé náà mọ́yà, á sì rẹ́rìn-ín múṣẹ́ sí wọn.”
Maria tún sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa bí ìwé náà ṣe dùn ún kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sí. Ó sọ pé: “Ó ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ nípa ẹ̀yà ìbímọ (ojú ìwé 58 sí 60) àti bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe (ojú ìwé 170 sí 171). Ó máa ṣèrànwọ́ fáwọn òbí tí wọ́n bá fẹ́ fọgbọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn nínú ayé búburú òde òní tó kún fún ewu.”
Àwọn tó ṣe ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà nírètí pé ìwé náà yóò ran ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti jàǹfààní tó pọ̀ látinú àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi, Olùkọ́ Ńlá náà kọ́ni ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Agata
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Marlena
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Eunika
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Maria àti Oliwia
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Justyna