Iwe Titun Mú Araadọta-Ọkẹ Layọ
APAKAN Awọn Apejọpọ “Awọn Olùfẹ́ Ominira” tí o bẹrẹ ni oṣu June ti o kọja ní ọrọ asọye naa “Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí.” Apa pataki rẹ̀ ni imujade iwe naa ti o ni ẹṣin ọrọ kan naa. Iye awọn eniyan ti wọn ju million mẹfa lọ kari ayé ti lọ si ọ̀wọ́ awọn apejọpọ yii ṣaaju akoko yii wọn sì ti gbọ́ ọrọ asọye naa, eyi ti o farahan pẹlu awọn iyipada kekere ninu ọrọ-ẹkọ meji ti o ṣaaju eyi ninu iwe irohin yii.
Iye ti o ju million 12 ẹ̀dà iwe naa Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí ni a ti tẹ̀ ni nǹkan bii 60 èdè. Ó tilẹ wà larọọwọto ni awọn èdè Ila-oorun Europe ti Albania, Croatia, Hungary, Macedonia, Poland, Russia, Serbia, ati Slovenia. Ni pataki ni awọn ti wọn ju 74,000 ti wọn pesẹ si awọn apejọpọ meje ni Soviet Union layọ lati gbà á ni èdè Russia.
Orisun Iwe Naa
Awọn àlàyé inu iwe naa ti farahan ni ipilẹṣẹ ni ọ̀kan tẹle ekeji ninu 149 itẹjade tẹleratẹlera ti Ilé-Ìṣọ́nà, bẹrẹ pẹlu itẹjade April 1, 1985. Ọpọlọpọ awọn onkawe sọ pe ó ba awọn ninu jẹ nigba ti ọ̀wọ́ naa wá si opin pẹlu itẹjade June 1, 1991. Melissa, ọmọ ọdun 12 kan ni Italy, da omi loju nigba ti ó ka akọsilẹ ti o kẹhin ninu Ilé-Ìṣọ́nà. Ó sọ pe, “Ni alẹ́ ṣaaju apejọpọ wa, mo gbadura si Jehofa ni bibeere fun iwe kan lori igbesi-aye Jesu. Nigba ti a fi iwe naa lọ̀, mo pa atẹwọ titi ti emi kò fi lè ṣe bẹẹ mọ.”
Ọrọ ẹkọ ti a tò lọwọọwọ ninu Ilé-Ìṣọ́nà ni a tẹ̀ ti a sì mu wọnu iwe titun ti a yaworan si meremere, oloju-ewe 448 ti ó ni ori-iwe 133 naa. Isapa ni a ṣe lati gbe gbogbo ọrọ ti Jesu sọ ati gbogbo iṣẹlẹ ti a ṣakọsilẹ ninu igbesi-aye ori ilẹ-aye Jesu kalẹ, papọ pẹlu gbogbo awọn apejuwe ati iṣẹ iyanu rẹ̀. Dé iwọn ti o ṣeeṣe, gbogbo rẹ̀ ni a sọ tẹlera ni ọna ti wọn gbà ṣẹlẹ. Ni opin ori-iwe kọọkan itolẹsẹẹsẹ awọn ẹsẹ Bibeli ti a gbé ori-iwe naa kà wà.
Ẹnikan lè maa ronu pe, ‘Ó dara, mo ti ka iwe naa ṣaaju akoko yii nitori pe mo ka awọn ọ̀wọ́ inu Ilé-Ìṣọ́nà.’ Ṣugbọn awọn onkawe Ilé-Ìṣọ́nà gba akọsilẹ igbesi-aye Jesu ni awọn ẹyọ keekeeke ninu awọn ọrọ-ẹkọ ti ń farahan ni gbogbo ọsẹ mejimeji la sáà akoko awọn ọdun ti o ju mẹfa lọ já. Ani bi o tilẹ jẹ pe awọn ọrọ-ẹkọ naa kún fun isọfunni ni ọ̀kan tẹle ekeji, ronu ayọ ti kíka gbogbo akọsilẹ naa ni akoko kukuru ati dídi aworan kikun ti ọkunrin titobilọla julọ naa ti o tii gbé ayé rí mú!
Ó Ń Fun Igbagbọ Lokun
“Mo pari kíka itẹjade naa ni ọsẹ meji,” ni obinrin kan lati Washington, D.C., U.S.A. rohin. “Nigba ti mo ń kà á, omije ń dà ni oju mi. Emi yoo dawọ iwe kíkà duro emi yoo sì gbadura emi yoo sì sọkun. Ó mu mi nimọlara bii ẹni pe mo wà nibẹ gan-an pẹlu Jesu, ti mo ń jiya papọ pẹlu rẹ̀. Ani ni ọsẹ kan lẹhin kíka iwe naa, omije ṣì ń dà ni oju mi nigba ti mo bá ronu nipa ohun ti mo ti kà. Mo nimọlara sisunmọ Jehofa pẹkipẹki sii paapaa fun Ọmọkunrin rẹ̀ ti o ti fifunni.”
“Mo pari iwe naa nipa Jesu lonii,” ni obinrin kan lati Pittsburgh, Pennsylvania, U.S.A., kọwe. “Agbayanu ni. Omije dà ni oju mi bi mo ti ń ka iwọnba awọn ori-iwe ti o kẹhin. Kíka gbogbo iwe naa tan lẹẹkan naa dara gan-an ni. Emi kò lè ṣapejuwe imọlara mi nipa rẹ̀ niti gidi—kìkì pe mo fẹran rẹ̀ pupọpupọ gan-an!”
Awọn apejuwe ẹlẹwa inu iwe naa fikún ipa ti o ni niti imọlara, gẹgẹ bi onkawe onimọriri kan ti ṣakiyesi: “Ó mú mi nimọlara bi ẹni pe mo fẹrẹẹ lè gbọ wọn ti wọn ń sunkun lori oku ọmọ naa (ori-iwe 47) tabi pe a mọ ohun ti Jesu ń rò nigba ti obinrin naa ti o ni ìsun ẹ̀jẹ̀ fọwọkan an ti a sì mu un larada (ori-iwe 46). Irisi oju wọn fihan niti gidi gan-an pé ó ń dùn wọn. . . . Dipo ki iwe kíkà jẹ́ iṣẹ ti kò yánilára kan, iwe yii mu ki o dabi ìdárayá tabi igbadun kẹlẹlẹ kan lẹhin igbokegbodo òòjọ́. Ọna amuni nimọlara ti a gbà kọ iwe naa kò sọ nipa ohun ti Jesu ṣe nikan ṣugbọn ó funni ni fìrí ohun ti ó rò ti ó sì nimọlara.”
Oniruuru Ọ̀nà Ti A Gbà Ń Lò ó
Ọpọlọpọ ti bẹrẹ sii lo iwe naa ninu ikẹkọọ Bibeli idile wọn. “A ni awọn ọdọmọde mẹta,” ni awọn obi kan lati Silverton, Oregon, U.S.A., kọwe, “iwe yii sì jẹ́ eyi ti o dara julọ fun ‘ikẹkọọ idile ni alaalẹ́.’ Loootọ, ó ti bojumu tó pe ki a farabalẹ kẹkọọ ipilẹ Ọba wa onifẹẹ, Jesu Kristi.”
Ọdọlangba kan lati Japan ṣalaye pe: “Baba mi ti ń ka iwe naa fun wa nigba ti a bá ń sinmi lẹhin ounjẹ alẹ́. Gẹgẹ bi idile kan, a ń kà iwe naa lati ibẹrẹ, ṣugbọn mo pinnu lati ka ori-iwe kan lati ẹhin iwe naa ni alẹ́ kan ṣaaju ki n tó lọ sun. Bi o ti wu ki o ri, iwe naa gbafiyesi gan-an debi pe niye igba ó maa ń tó aago kan oru ki n tó kiyesi akoko.”
Ọpọlọpọ ni ẹnu yà sí pupọ awọn kulẹkulẹ ti akọsilẹ naa ní ninu. “Mo kẹkọọ ohun pupọ ti emi kò wulẹ mọ,” ni Ẹlẹ́rìí kan kọwe. Lẹta kan lati California, U.S.A., sọ pe: “Aya mi ati emi ti wà ninu otitọ fun ohun ti o ju ọdun 35 lọ, a sì lè fi ailabosi sọ pe a kò tíì ni itẹjade kan ni ọwọ wa ti o ti muni layọ gẹgẹ bi eyi rí.”
Iwe naa gbọdọ wó irọ naa pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò gbagbọ ninu Jesu palẹ̀. Onkawe kan ti ó kun fun imoore sọrọ ni ọ̀nà yii pe: “Emi kò lè gbé e silẹ, nitori pe o jẹ́ ìjáníkoro titobi julọ si àìmọ̀kan awọn wọnni ti wọn sọ pe awọn eniyan Jehofa kò gbagbọ ninu tabi bọla fun Jesu Kristi. Gbogbo ohun ti a nilati ṣe nisinsinyi ni ki a fi idahun yii ti o wà fun àìmọ̀kan wọn lé wọn lọwọ.”
Dajudaju iwe yii yoo ni àyè pataki kan ninu iṣẹ-ojiṣẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. “Mo fun obinrin kan ti mo ń bá kẹkọọ Bibeli ni ẹ̀dà kan,” ni Ẹlẹ́rìí kan kọwe, “ipa ti ó sì ni lori rẹ̀ dabi iṣẹ iyanu kan. Ó ti ń kẹkọọ fun ọdun kan, mo sì ti ni iṣoro ni mímú ki o wá si awọn ipade.” Lẹhin ti akẹkọọ naa ka ori-iwe 45 ninu iwe titun naa, Ẹlẹ́rìí naa ṣalaye pe, “ó sọ fun mi pe oun yoo wá si ipade ni ọjọ Sunday nitori pe akoko tó fun oun lati mu iduro oun.”
Awọn Apa Ti Wọn Ṣeyebiye
Niti tootọ, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí pese àlàyé lori Awọn Ihinrere. Àlàyé ọpọlọpọ ohun ti Jesu sọ ti ó sì kọni ni a pese, nitori naa iwe naa ni a lè lò gẹgẹ bi ohun èèlò iwadii ti o ṣeyebiye, nitori ti o dirọ timọtimọ mọ awọn akọsilẹ Bibeli.
Apa didara pataki kan ni pe ni ipilẹ gbogbo rẹ̀ ni a sọ ni itotẹlera kíka ọdun. Wiwulẹ ṣi awọn oju-iwe pẹlu eyi lọkan lè jasi aranṣe gidi kan ninu mímọ akoko wo, laaarin akoko iṣẹ-ojiṣẹ Jesu, ni awọn iṣẹlẹ kan ṣẹlẹ. Awọn onkawe Awọn Ihinrere niye igba dojukọ ohun ti o jọ awọn itakora. Iwe titun naa, lai fa afiyesi si iwọnyi lọna ti o pọndandan, mu wọn ṣọkan ninu igbekalẹ rẹ̀.
Gẹgẹ bii Kristẹni, ó daju pé awa kò gbọdọ fẹ́ lati ṣainaani ikẹkọọ igbesi-aye Awofiṣapẹẹrẹ oluṣotitọ wa, Jesu Kristi, tiṣọratiṣọra. Nitori naa, ẹ jẹ ki a gbe awọn akọsilẹ Ihinrere yẹwo kínníkínní pẹlu iranlọwọ iwe titun naa Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí.