ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 2/15 ojú ìwé 21-25
  • Awọn Erekuṣu Agbami-Okun India Gbọ Ihinrere Naa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Erekuṣu Agbami-Okun India Gbọ Ihinrere Naa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Ibi Ìdúró Akọkọ—Rodrigues
  • Seychelles Jijinna Réré
  • Pada si Réunion
  • Mayotte—Erekuṣu Olóòórùn Didun
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 2/15 ojú ìwé 21-25

Awọn Erekuṣu Agbami-Okun India Gbọ Ihinrere Naa

EYI ti ó tò tẹlera ní irisi apakan ayika ti o jọra pẹlu ti Madagascar ti o sì gbilẹ kọja 1.5 million ibusọ níbùú-lóòró ní iha iwọ-oorun Agbami-Okun India ni awọn erekuṣu Rodrigues, Mauritius, Réunion, Seychelles, Mayotte, ati Comoros. Bi o tilẹ jẹ pe ó kari iru ìgbòòrò-àyè ti ó tẹju tobẹẹ, awọn erekuṣu wọnyi papọ jẹ́ kiki 2,800 ibusọ níbùú-lóòró ni àyè ilẹ. Pẹlu iye awọn eniyan olùgbé 2.3 million, wọn wà lara awọn erekuṣu ti awọn olùgbé pọ̀ kítikìti sí julọ ni ayé.

Awọn olùgbé yii ní nǹkan bii 2,900 Ẹlẹ́rìí Jehofa ninu, ti wọn ṣiṣẹ taapọntaapọn lati waasu ihinrere Ijọba Ọlọrun fun awọn ara erekuṣu naa. Bi wọn ti wà ni àdádó, Awọn Ẹlẹ́rìí wọnyi ni pataki mọriri ibẹwo awọn alaboojuto arinrin-ajo ati awọn apejọ ọdọọdun tí ẹka ọfiisi Watch Tower Society ni Vacoas, Mauritius, ṣeto. Iwọnyi jẹ́ akoko nigba ti wọn lè yọ̀ ninu itumọ awọn ọrọ Aisaya 42:10 pe: “Ẹ kọ orin titun si Oluwa [“Jehofa,” NW], iyin rẹ̀ lati opin ayé, ẹyin ti ń sọkalẹ lọ si okun, ati ohun gbogbo ti ń bẹ ninu rẹ̀, erekuṣu, ati awọn ti ń gbé inu wọn.”

Lẹnu aipẹ yii, awọn ayanṣaṣoju lati ẹka ọfiisi rinrin-ajo lọ si awọn erekuṣu naa lati bẹ awọn ijọ wò ati lati ṣe ọ̀wọ́ awọn apejọ akanṣe ọlọjọ kan lọdọọdun, eyi ti o gbe ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Di Mímọ́ Ninu Gbogbo Iwa Yin,” ti a gbekari 1 Peteru 1:15 yọ. Lati kari ìgbòòrò-àyè fífẹ̀ ti òkun naa, irin-ajo ni ìwọ̀n ti o pọ jẹ́ nipasẹ ofuurufu—nigba miiran ninu ọkọ bàlúù ayara bi aṣa jumbo ti igbalode ṣugbọn niye igba ninu awọn ọkọ ofuurufu ti ó ni ẹ́ńjìnnì kekere. Ọkọ oju-omi ti a ń pe ni schooner ati awọn ọkọ oju-omi olópòó meji ni a tun lò. Bá wa kálọ, ki o sì ri bi awọn erekuṣu ni Agbami-Okun India jijinna réré ṣe ń gbọ ihinrere!

Ibi Ìdúró Akọkọ—Rodrigues

Lẹhin irin-ajo ọkọ ofuurufu lati Mauritius fun wakati kan ati aabọ, a ri okiti iyun (coral reef) kan. O sami si apa-ita adagun omi ńlá kan ti o yi ilẹ gátagàta keekeeke laaarin Agbami-Okun India ká. Eyi ni ibi iduro wa akọkọ, erekuṣu Rodrigues.

Pápá ọkọ ofuurufu naa ni a kọ́ sori ilẹ ti o nà jade lati ara okiti iyun, ti a ń pe ni Point Coraille. Ni agbegbe yii iyun naa nipọn tobẹẹ debi pe a lè fi ayùn rẹ́ ẹ si awọn ègé biriki ti a lè lò fun ile kíkọ́. Bọọsi kekere kan gbé wa gba oju-ọna tooro, ti o ṣe kọ́lọkọ̀lọ kan lati pápá ọkọ ofuurufu naa lọ si aarin ilu Port Mathurin. Ni akoko kan, sọda si odikeji erekuṣu naa a lè ríran rí awọn okiti iyun ti o wà lọ́kàn-án-kán, ọ̀sà aláwọ̀ búlúù, ati etikun alápàáta. Bi o ti jẹ pe igba ojo ṣẹṣẹ pari ni, awọn ẹ̀bá òkè naa kun fun awọn koriko ṣákiṣàki, ti ó dabi kàn-ìn-kàn-ìn tí awọn maluu, agutan, ati ewurẹ tí ń jẹko sì fọ́nká gátagàta sori rẹ̀.

Gbọngan Ijọba kekere, mímọ́ tónítóní kan laaarin Port Mathurin ni ibi ti a o ti ṣe apejọ akanṣe wa ọlọjọ kan. Iṣẹ naa ni Rodrigues kọkọ bẹrẹ ni 1964. Nisinsinyi, laaarin iye awọn eniyan 37,000 ti ń gbé ilu, 36 ni o jẹ́ akede ihinrere. Ayọ wo ni o jẹ́ lati rí 53 eniyan ti wọn wá ti ọdọmọkunrin ẹni ọdun 18 kan sì gba iribọmi. Iya rẹ̀, bi o tilẹ jẹ́ aláìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, tẹwọgba otitọ ni 1969, ó sì ti ń ba a lọ lati ṣiṣẹsin Jehofa laika atako idile si. Nisinsinyi meji ninu awọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ oluṣeyasimimọ si Jehofa.

Lẹhin apejọ naa, a lo ọsẹ kan ni wiwaasu ninu erekuṣu naa. A sọ èdè Creole ti Mauritius wa, gẹgẹ bi o ti jẹ́ èdè ti a ń sọ pẹlu nihin-in ni Rodrigues. Wíwọ bọọsi kan ati fifẹsẹ rin mu wa dé ipinlẹ wa—afonifoji titutuyọyọ kan ti o gbooro lati ori ilẹ lọ de inu okun. Iran mérìíyìírí wo ni ó jẹ́—ọ̀sà aláwọ̀ àdàlù búlúù ati awọ eweko, okiti iyun funfun, ati agbami okun aláwọ̀ aró ni ipilẹ! Bi a ti ru wá soke nipasẹ afẹfẹ olooorun didun ti a kò sọ deléèérí, a muratan lati lọ.

A gba oju ọna gbóóró ti o la awọn papa kọja sọda odo tééré ti o ni irà lati dé ọpọlọpọ awọn ile keekeeke ni afonifoji naa. A fi tọyayatọyaya ki wa kaabọ ni ile kọọkan a sì lè ba awọn onile sọrọ nipa awọn ibukun Ijọba ti yoo de laipẹ. Ki a tó fura a ti rin jinna lọ si isalẹ afonifoji naa, akoko sì ti tó lati lọ si ile. Eyi tumọsi pípọ́nkè pupọ sii ati ìrìn ọpọlọpọ wakati, ṣugbọn aajo alejo ṣiṣe ni adugbo naa ràn wá lọ́wọ́—a gbé wa sẹhin ọkọ jeep kan.

Lẹhin ìjádelọ atánnilókun yẹn, ó dun mọ wa ninu lati pada sinu Ile Bẹtẹli ẹlẹwa ni Vacoas. Ọjọ apejọ akanṣe meji ni a ṣeto ni Gbọngan Ilu. Ni ọjọ akọkọ, 760 eniyan ni o wá. Wọn wá lati inu ilaji ijọ 12 ti o wà lori erekuṣu naa. Ni ọjọ keji, a ṣajọpin itolẹsẹẹsẹ kan naa pẹlu 786 eniyan lati inu awọn ijọ mẹfa ti o kù. Ni opin ọsẹ yẹn, awọn ẹni titun mẹrin ni a bamtisi. Awọn aṣaaju-ọna akanṣe 30 ati aṣaaju-ọna deedee 50 ni ń bẹ ti wọn ńnípìn-ín ninu mímú ihinrere wá fun awọn ará erekuṣu naa.

Seychelles Jijinna Réré

Kò pẹ́ ti akoko tó fun wa lati tun wọ ọkọ ofuurufu, taarata lọ si ariwa la ẹgbẹrun kan ibusọ gbalasa òkun lọ si erekuṣu Mahé ni Seychelles, ti a ń pè ni Zil Elwannyen Sesel ni Creole, ti o tumọsi “Erekuṣu Seychelles Jijinna Réré.” Nitori jijinna, ẹka ọfiisi lè ṣeto fun kiki ibẹwo meji lọdun kan. Ọjọ apejọ akanṣe ati apejọ ayika ni a ṣe ni awọn ọjọ mẹta tẹleratẹlera ni igba iruwe. Apejọpọ agbegbe ni a ń ṣe lẹhin naa ninu ọdun. Nisinsinyi laaarin oṣu October, a wà nihin-in fun apejọpọ agbegbe, eyi ti ọsẹ ibẹwo si ijọ yoo tẹle. Nihin-in pẹlu a lè lo èdè Creole ti Mauritius wa.

Awọn ará lati erekuṣu Praslin ati La Digue ti o wà nitosi ti dé ṣaaju akoko. Ó ti runisoke tó lati ni awọn orilẹ èdè 12 ti a ṣoju fun! Ibi apejọ naa ni Gbọngan Ijọba adugbo, àyè ìgbọ́kọ̀sí ńlá kan ti a kò lò fun ète yẹn mọ ti ń bẹ lẹhin ile ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí naa. Niwọn bi o ti jẹ pe kiki arakunrin mẹfa, ti o ni awọn olubẹwo ti ń ṣebẹwo ninu, ni wọn tootun lati kopa ninu itolẹsẹẹsẹ, awọn kan ni anfaani sisọ awọn ọrọ-asọye melookan laaarin awọn ọjọ mẹrin naa. Awọn akede 81 naa ni ó dùn mọ lati ri 216 ti wọn wá ni ọjọ ti o kẹhin apejọpọ naa.

Lẹhin apejọpọ naa, a wọ ọkọ oju omi ti a ń pe ni schooner lọ si Praslin, ibusọ 25 si ariwa ila-oorun Mahé. Ọkọ oju-omi ti a fi igi tacamahac kàn tí gigun rẹ̀ jẹ́ 60 ẹsẹ bata. Ọkọ oju-omi ti o lẹwa naa lè kó 50 èrò ati nǹkan bii 40 tọ́ọ̀nù ẹrù. Bi a ti ń fi ebute ti o wà ni Mahé silẹ ti a sì dorí ọkọ oju-omi wa kọ ìhà òde Praslin ti o wà ni òréré ti o jinna kan, a lè nimọlara agbara ẹ́ńjìnnì ọkọ naa ti ń lo epo diesel tí aṣọ ìgbòkun funfun ti ń fẹ́lẹlẹ jade lati ara awọn òpó ọkọ̀ ń ràn lọ́wọ́.

Wakati meji ati aabọ lẹhin naa, a yí iyọri ilẹ alápàáta naa ká lati wọnu Ibi Iyawọlẹ Omi Okun St. Anne ẹlẹwa ti o tubọ dakẹrọrọ kan. Nigba ti a dasẹle ebute gigun naa, a rí awọn ará wa ti ń duro. Awọn akede 13 ni wọn wà ni erekuṣu kekere yii, awọn alejo 8 sì wá lati apa miiran. Nitori naa o jẹ pẹlu irusoke ńlá ni a fi ri gbọngan kekere naa ti awọn eniyan 39 kún fun ọrọ-asọye akanṣe naa. Iru agbara ṣiṣeeṣe fun ìdàgbàsókè wo ni eyi jẹ́!

Nigba ti a wà nihin-in ni Praslin, a gbọdọ bẹ Vallée de Mai ẹlẹwa wò. Ibi yii ni ile ọ̀pẹ Coco-de-mer, eyi ti ń so eso ti o tobi julọ ni agbaye, ti ọkọọkan wọ̀n 40 pound. Ni abẹ ojiji títutùyọ̀yọ̀ ti igbo ẹgàn, a ri awọn ọ̀pẹ wọnyi ni oniruuru ipele ìdàgbàsókè wọn. Iwe àlàyé ọna ti a pese fun awọn alejo ṣalaye pe eyi ti o ga julọ tó 102 ẹsẹ bata ni giga nigba ti a wọ̀n-ọ́n ni 1968. Diẹ lara awọn igi giga wọnyi ni a fojubu ọjọ ori wọn sí 800 ọdun. Ó ń tó ọdun 25 ki igi kan tó bẹrẹ sii so eso ati ọdun 7 ki awọn ẹ̀pà naa tó gbó. Abajọ ti iwe pẹlẹbẹ naa fi kilọ pe: “Fọto nikan ni ki o yà, ipasẹ̀ nikan ni ki o si fi silẹ sẹhin!”

Ni aago meje owurọ ọjọ keji, a wọ ọkọ òbèlè lọ si erekuṣu La Digue. Ọpọlọpọ awọn ọkọ òbèlè korajọpọ yika ebute naa. Awọn ni wọn jẹ́ ki ifarakanra laaarin awọn olugbe 2,000 ati ayé ẹhin-ode ṣeeṣe. Tọkọtaya agbalagba kan lati Switzerland ti wọn ti wà ninu awọn erekuṣu wọnyi lati 1975 pade wa. Dipo wíwọ “takisi” onikẹkẹ maluu, a rin lẹbaa etikun naa ti o ni okuta alawọ pupa bàrébàré ti okun ati ojo ti sọ di dídán. Lẹhin ounjẹ owurọ ti a gbafẹ́ jẹ, a gba ọ̀nà inu ẹgàn kekere kan lọ, nibi ti awọn ẹyẹ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ ṣíṣọ̀wọ́n dúdú ti ń pamọ, lọ si ile awọn olufifẹhan diẹ. Awọn eniyan mẹtala ni a kójọ lati gbọ ọrọ asọye ti a sọ ni èdè Creole. A pade tọkọtaya kan ti wọn ti ṣe gbogbo to lati mu igbeyawo wọn bá ofin mu ki wọn baà lè tẹsiwaju nipa tẹmi. Loootọ, Jehofa ń mú awọn ẹni ti o yẹ ninu awọn orilẹ-ede ani ninu awọn erekuṣu àdádó gan-an wọnyi wọle.

Pada si Réunion

Réunion ni erekuṣu ti o laju julọ ti a bẹwo lakooko irin-ajo yii. Bi a ti ń sunmọ ilẹ, a ri opopona gbalasa olópòó mẹrin, ti wọn kún fun awọn ọkọ irinna ti ń bọ̀ lati olu-ilu, Saint-Denis. Awọn ile gigagiga kún àyè ti o wà laaarin okun ati oke. Erekuṣu yii ni ile awọn eniyan ti wọn tó nǹkan bii 580,000 ó sì ti jasi pápá amesojade kan fun ijẹrii Ijọba. (Matiu 9:37, 38) Nǹkan bii 2,000 awọn onitara akede ihinrere ninu ijọ 21 ni wọn wà nibẹ nisinsinyi.

Ọjọ apejọ akanṣe ni a ṣe ninu pápá ere-idaraya ńlá kan ti a bò. A layọ lati ri 3,332 eniyan ti wọn wá sibẹ, idunnu wo ni o sì jẹ́ lati ri 67 ẹni titun ti wọn wá fun bamtisimu! Lẹhin gbigbadun ibakẹgbẹ pẹlu awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lori erekuṣu naa, a mu ọna wa pọ̀n lọ si ibi ti ó kàn ti a ń lọ.

Mayotte—Erekuṣu Olóòórùn Didun

Lẹhin irin-ajo ọkọ ofuurufu oniwakati meji, ọkọ ofuurufu ayara-bi-aṣa onijooko 40 wa bẹrẹ ìfòwálẹ̀ rẹ̀ si pápá ọkọ-ofuurufu Pamanzi, eyi ti o wà ni erekuṣu kekere kan ti a jápọ̀ nipasẹ opopona 1.2 ibusọ lọ si Dzaoudzi, olu-ilu Mayotte. Oju sanmọ aláwọ̀ búlúù, awọn kùrukùru funfun, awọn ẹgbẹ-oke onígbó kìjikìji, ati agbami-okun aláwọ̀ aró parapọ lati gbe aworan paradise ilẹ olooru alalaafia kan yọ. Lọna ti o ba a mu, Mayotte ni a pe ni orukọ inagijẹ naa Erekuṣu Olóòórùn Didun nitori itasansan didun ti igi ilang-ilang. Ohun ti a mujade lati inu ododo rẹ̀ ni a ń fi ranṣẹ si France gẹgẹ bi ipilẹ fun awọn oorun didun olokiki ayé.

Ó jẹ́ irin-ajo oniṣẹẹju 15 lori ọkọ oju-omi onidii pẹrẹsẹ lọ si ori erekuṣu gidi. Lẹhin awọn itura diẹ ni ile ojihin-iṣẹ-Ọlọrun, a késí wa si ikẹkọọ iwe ijọ kan ti ó fi ibusọ 12 jinna lodikeji erekuṣu naa. Oun ti o fopin si awọn ifojusọna ibẹwo igbafẹ wa niyẹn. A bọ sẹhin ọkọ jeep fun irin-ajo adáyàfoni kan lori awọn ọ̀nà tóóró. Ó dabi ẹni pe a fẹrẹẹ kọlu awọn eniyan, maluu, ati awọn ọkọ miiran. Ṣugbọn awakọ wa ti ó jẹ́ ara France mọ ọna naa. Laipẹ a dé si Chiconi, nibi ti a ti pade idile ti a ṣe ikẹkọọ naa ninu ilé wọn.

Baba, ti o jẹ́ Musulumi tẹlẹ, fi awọn ọmọ rẹ̀ mẹjẹẹjọ han. Ọmọkunrin rẹ̀ kekere julọ, ọmọ ọdun mẹrin, ṣe ohun ti a mọ lẹhin naa si ikini ibilẹ fun wa. Ó gbé ẹhin ọwọ kan sinu àtẹ́lẹwọ́ ekeji ó sì duro ni iwaju wa ni titẹ wọn kọrọdọ. A kọkọ gbiyanju lati bọ̀ ọ́ lọwọ, lẹhin naa aya mi gbiyanju lati gbé ọwọ rẹ̀ lé ori rẹ̀. Ọmọ kekere naa pẹlu ẹyinju rẹ̀ titobi fi suuru duro, laiṣe àníàní ó ń ṣe kayefi nipa ohun ti a ń ṣe. Nikẹhin ó yé wa—a gbé awọn ọwọ rẹ̀ lé ori rẹ̀. Ikẹkọọ naa bẹrẹ pẹlu awọn 14 ti wọn wá. Nigba ti a bá ikẹkọọ dé idaji, olufifẹhan kan wọle ó sì bọ gbogbo eniyan lọwọ. Iyẹn pẹlu jẹ́ aṣa wọn lọna ti o han gbangba.

Ni irin-ajo wa pada la aarin ilu ti o ti ṣokunkun nisinsinyi kọja, a ri awọn àdán ajèso ńlá ti wọn ń fò lọ sori igi kan fun ounjẹ alẹ́ wọn. A tun gbóòórùn eso gbẹrẹfúùtù ti o ti jasilẹ sori ọna kọ́lọkọ̀lọ ati oorun didun eso mangoro, ibẹpẹ, ati guafa. Ibi yii ni ile awọn lemur, awọn ẹranko kekere ti wọn dabi ọbọ ti wọn ni oju bii ti kọlọkọlọ ati ìrù gigun, wéréké, ti o ṣee lọ́ mọ́ nǹkan. Bi a ti yi ori oke naa ká, a gbadun araawa pẹlu iran àrímáleèlọ kan. Oṣupa aranmọju ti o pupa bi orombo ṣẹṣẹ yọ lori omi ti o ya lati inu okun ni, ni títan imọlẹ ti ń tàn rẹ́súrẹ́sú ninu omi ti o parọrọ naa. Awakọ wa paapaa tẹ sílóò lati gbadun wíwò rẹ̀. Fun eyi ti o kù ninu irin-ajo naa, a ń foju wá a ni gbogbo ibi ti a bá ti ṣẹkọna.

Ni owurọ ọjọ keji a lọ fun wiwaasu pẹlu awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun. Lakọọkọ, a bẹ ọdọmọkunrin kan ti o jẹ́ olukọni ti ó ń sọ èdè French daradara wò. Ó jokoo lori ilẹ, awa sì jokoo lori bẹẹdi rẹ̀. Ikẹkọọ ti o tẹle e tun jẹ́ pẹlu ọdọmọkunrin kan, ó sì késí wa lati jokoo sori mátírẹ́ẹ̀sì rẹ̀ ti ó wà nilẹ ninu yara rẹ̀ kekere. Laipẹ a bẹrẹ sii rúnra, laika gbigbiyanju lati dagunla si pajápajá ti o mu wa lẹsẹ ati òógùn ti ń ṣàn lẹhin wa sí. Pẹlu redio ti ń ké tantan fun awo orin titun ti o ṣẹṣẹ jade ninu yara keji, kò rọrun lati pa afiyesi pọ sori ikẹkọọ naa, ti a dari lapakan ni èdè French ati apakan ni èdè Maori.

Ọdọmọkunrin kan ti ẹ̀yà Comoros ti o wà ni adugbo ni a késí gbẹhin. Ó tọrọ aforiji fun ṣiṣai sọ èdè French daradara tó, ó mu iwe pẹlẹbẹ rẹ̀ jade, ó sì ṣetan lati bẹrẹ. Nigba ti ojihin-iṣẹ-Ọlọrun naa ń ba a lọ lati ṣalaye ohun kan fun mi, ọdọmọkunrin naa jálù ú ó sì sọ pe oun fẹ́ ka ipinrọ. Ó fi iwarere sọ fun wa pe ki a dakẹ. Gbogbo awọn eniyan wọnyi jẹ́ Musulumi, ṣugbọn wọn mọriri ohun ti wọn ń kẹkọọ rẹ̀ lati inu Bibeli niti gidi.

Idi rẹ̀ ti ọpọlọpọ awọn ọdọmọkunrin tobẹẹ fi ń ṣe ikẹkọọ, sibẹ ti o jẹ́ pe iwọnba awọn obinrin tabi awọn ọdọmọbinrin ni ń ṣe bẹẹ yà wá lẹnu. A sọ fun wa pe, eyi jẹ́ nitori aṣa atọwọdọwọ ẹgbẹ-oun-ọgba ati idile. Niwọn bi wọn ti tẹwọgba aṣa ikobinrinjọ lọna ti isin ati ti ẹgbẹ-oun-ọgba ti aya kọọkan sì ń gbé ni ile tirẹ funraarẹ, ipa ti baba ń kó mọniwọn; iya ni o ń dari. A tun gbọ pe awọn ọdọmọbinrin a maa wà ni ile iya wọn lọna aṣa titi di igba ti wọn bá lọkọ. Awọn ọmọkunrin, ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, a maa fi ile silẹ ni igba ìbàlágà wọn a sì kọ́ banga, tabi ahere tiwọn funraawọn, tabi ki wọn gbe pẹlu awọn ọdọmọkunrin miiran ninu banga kan. Labẹ awọn ipo ayika wọnyi awọn ọdọmọkunrin lominira lati kẹkọọ bi wọn bá fẹ́, ṣugbọn awọn ọdọmọbinrin diẹ ni wọn ni iru ominira bẹẹ.

Ọjọ Sunday ni o yẹ ki o jẹ́ ọjọ apejọ akanṣe. Oju ọjọ bẹrẹ daradara, ṣugbọn nigba ti o di ọjọ́kanrí kùrukùru bẹrẹ sii gbarajọ, ati laipẹ ọ̀wàrà ojo aláfẹ̀ẹ́sí bẹrẹ sii rọ̀. Kò si ẹni ti o ṣe bi ẹni ti o bikita, niwọn bi o wulẹ ti mu awọn nǹkan rọlẹ ni. Nihin-in ni a tun ti ri awọn ọrọ̀ tẹmi yanturu gẹgẹ bi awọn akede 36 ati aṣaaju-ọna ti yọ lati ri iye eniyan 83 ti ó wa ti a sì bamtisi ẹni titun mẹta.

Imujade iwe pẹlẹbẹ naa Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! ni èdè wọn jẹ́ iṣẹlẹ pataki. Kii wulẹ ṣe itẹjade Watch Tower kanṣoṣo ti o wà ni èdè Maori niyẹn ṣugbọn o tun jẹ́ iru oriṣi itẹjade kanṣoṣo ti o tii wà rí ni èdè yẹn. Ó ni lẹta ikọwe Arabic ti a kọ si abẹ ọrọ-iwe onilẹta Roomu. Awọn eniyan kọ́ lẹta ikọwe Arabic ni ile-ẹkọ ṣugbọn kii ṣe èdè Arabic. Wọn lè tun adura kà ni èdè Arabic wọn sì lè ka Kuraani ni Arabic; sibẹ wọn kò loye ohun ti wọn ń pè. Bi wọn ti ń ka lẹta ikọwe Arabic ninu iwe pẹlẹbẹ naa, o ya wọn lẹnu pe awọn lè loye rẹ̀. Ohun ti wọn ń kà jẹ́ èdè Maori tiwọn funraawọn ti a kọ ni lẹta ikọwe Arabic niti gidi. Ó jẹ́ ayọ lati ri bi oju wọn ti túyáyá gẹgẹ bi wọn ti loye ohun ti wọn ń kà.

Awọn iwe pẹlẹbẹ ni ó rọrun lati fisode lọdọ awọn eniyan naa. Ninu ọ̀kan lara awọn abule ti ó jinna, ọkunrin kan wá sọdọ wa nigba ti a ń waasu fun obinrin kan. Ó bẹrẹ sii fi tagbaratagbara sọrọ si arakunrin wa ni èdè Maori. Ó farahan fun wa pe ó ń ṣatako gidigidi. Ọkunrin naa ṣe bẹẹ fun igba diẹ, ni fífaríya rẹ́kẹrẹ̀kẹ. Arakunrin naa ṣalaye lẹhin naa pe ọkunrin naa ń ṣaroye pe: “Bawo ni o ṣe lè reti pe ki a ranti awọn ohun ti o sọ fun wa nigba ti o ń bẹ̀ wá wo fun kiki ẹẹkan lọdun? Bawo ni iwọ ṣe lè ranti? Iwọ gbọdọ wá leralera lati ba wa sọrọ nipa awọn nǹkan wọnyi.”

Awọn ọrọ ti o kẹhin wọnyi fi awọn èrò tiwa naa han pẹlu. Dajudaju Jehofa ń kó awọn ohun didara gbogbo awọn orilẹ-ede jọ nipasẹ ihinrere Ijọba naa. Bi o tilẹ jẹ pe agbami-okun fífẹ̀ ńláǹlà yà wọn sọtọ, awọn ara erekuṣu naa ń fi ohùn wọn kún igbe iyin alagbara ti a ń fifun Ẹlẹdaa ati Baba wọn ọrun, Jehofa Ọlọrun.—Hagai 2:7.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 21]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an.)

SEYCHELLES

INDIAN OCEAN

COMOROS

MAYOTTE

MADAGASCAR

MAURITIUS

RÉUNION

RODRIGUES

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Iyọri ilẹ alápàáta ni Praslin, Bay St. Anne

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

“Takisi” onikẹkẹ maluu kan ni La Digue, Seychelles

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Wiwaasu pẹlu iwe pẹlẹbẹ titun naa ni Mayotte

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́