Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu
ỌRỌ ẹkọ naa “Jesu Pari Gbogbo Ohun Ti Ọlọrun Beere Fun,” ni oju-iwe ti o tẹle e, jẹ ipin naa ti o kẹhin ninu ọ̀wọ́ itotẹlera gigun ti “Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu.” Igbejade yii ti farahan ninu Ilé-ìṣọ́nà fun ohun ti o ju ọdun mẹfa, ninu itẹjade 149 ti o tẹlera, bẹrẹ pẹlu itẹjade ti April 1, 1985.
O jẹ ireti wa pe ọ̀wọ́ yii ninu Ilé-Ìṣọ́nà ti ran ọ lọwọ lati tẹle imọran apọsteli Pọọlu lati ‘wo Jesu’ ati lati kọbiara si aṣẹ Ọlọrun lati “gbọ tirẹ.” (Heberu 12:2, 3; Matiu 17:5) La awọn ọdun já, ọpọlọpọ ti kọwe lati sọ pe awọn ni a ti ran lọwọ lati ṣe eyi. “Ṣe ni ó dabi pe mo wa nibẹ ti mo nfetisilẹ sí i ti mo si nwo awọn ohun ti o nṣe,” ni onkawe kan kọwe. “Mo ti wá nifẹẹ rẹ̀ sii nitori awọn ọrọ ẹkọ wọnyi.”
Onkawe miiran kọwe pe: “Itẹjade kọọkan jọbi pe o ni koko kan ti mo ti padanu nigba ti mo nka akọsilẹ Bibeli naa ninu. Mo ti gbadun fifi awọn iṣẹlẹ ọtọọtọ ninu igbesi-aye Jesu ni itotẹlera akoko lọna ti o tubọ sanju sọkan nipa kika ọrọ ẹkọ kọọkan.” Ọpọlọpọ ti sọ imọriri ti o jọra pẹlu eyi jade fun mímọ ìgbà ati ibi ti Jesu ti kọni lẹkọọ ti o si ti ṣe awọn nǹkan lakooko iṣẹ-ojiṣẹ rẹ.
Obinrin kan ni Spain wipe: “Mo ti tọju gbogbo awọn ọrọ-ẹkọ naa lati ibẹrẹ. Wọn kun fun itọni gan an fun awọn agbalagba ati bakan naa pẹlu fun awọn ọmọde. Mo jẹ ẹni ọdun 44, a si ru mi lọkan soke nigba ti mo nka awọn akọsilẹ wọnyi. Ṣe ni o dabi ẹni pe mo wa nibẹ ni akoko ti itan kọọkan ṣẹlẹ.”
Iya kan ni United States kọwe pe: “Nitori iṣeṣoki awọn ọrọ ẹkọ naa ati awọn alaye wọn ti o rọrun, ọkọ mi ti dara pọ ninu ikẹkọọ idile wa. Ọmọkunrin mi ọlọdun mẹjọ rọ̀ mi pé kí nkọ̀wé lati dupẹ lọwọ yin pe baba oun ti nkẹkọọ Bibeli nisinsinyi. Ó beere pe ni ọjọ kan nigba ti awọn ọ̀wọ́ yii ba pari pe ki awọn ọrọ ẹkọ naa di eyi ti a tẹ̀ jade ninu iwe kan ki oun ba le ṣajọpin wọn pẹlu awọn ọmọ ile ẹkọ ẹlẹgbẹ oun.”
Boya iwọ ṣajọpin awọn imọlara onkawe naa ti o kedaro lẹnu aipẹ yii pe: “Mo nimọlara ibanujẹ diẹ lati ronu pe awọn ọ̀wọ́ naa yoo dopin laipẹ bi a ṣe ngbe awọn ọjọ ti o kẹhin ninu igbesi-aye Jesu yẹwo. Emi nitootọ yoo padanu àyè wọn ninu Ilé-Ìṣọ́nà.” Awa nireti pe iwọ yoo gbadun apá ti o kẹhin ninu ti ọ̀wọ́ ọrọ ẹkọ wa yii, “Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu.”