Àwọn Àpilẹ̀kọ Tuntun Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
1. Àwọn àpilẹ̀kọ wo ló máa bẹ̀rẹ̀ sí í jáde nínú Ilé Ìṣọ́ tí à ń fi sóde, báwo la sì ṣe ṣètò àwọn àpilẹ̀kọ náà?
1 Bẹ̀rẹ̀ látorí Ilé Ìṣọ́ January 1, 2011, a ó máa tẹ ọwọ́ àwọn àpilẹ̀kọ táá lè máa fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde. Àkòrí rẹ̀ ni “Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa máa gbádùn kíka àwọn àpilẹ̀kọ náà, àmọ́ ọ̀nà tá a gbà ṣètò rẹ̀ ní pé ká jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ẹni tá à ń wàásù fún.
2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà?
2 Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Àpilẹ̀kọ Náà: Àwọn àkòrí àtàwọn ìsọ̀rí tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà jẹ́ ìbéèrè tá a lè béèrè lọ́wọ́ ẹni tá à ń jíròrò pẹ̀lú rẹ̀. Ńṣe la kàn tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì tó wà níbẹ̀, a kò fa ọ̀rọ̀ wọn yọ, èyí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹni tá à ń ba sọ̀rọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ tààràtà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Àwọn ìpínrọ̀ tó wà níbẹ̀ kò gùn, kó bàa lè ṣeé ṣe láti jíròrò rẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpilẹ̀kọ náà ló ń tọ́ka sí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, èyí á mú kó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé yìí nígbà tó bá yẹ.
3. Bá a bá ń wàásù láti ilé-dé-ilé, báwo la ṣe lè fi àwọn àpilẹ̀kọ náà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà?
3 Bí A Ó Ṣe Máa Lò Ó: Bá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn, bi onílé ní ìbéèrè kan nípa ohun tó máa nífẹ̀ẹ́ sí, nípa ohun tí àpilẹ̀kọ náà dá lé. Bí àpẹẹrẹ, Ilé Ìṣọ́ January 1 jíròrò bí Bíbélì ṣe wúlò tó. O lè béèrè pé: “Ṣé o gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì àbí o rò pé ó kàn jẹ́ ìwé kan tó dára ni? [Jẹ́ kó fèsì.] Mo ní ìwé kan níbí lórí kókó yìí tó o máa nífẹ̀ẹ́ sí.” Fi ìbéèrè àkọ́kọ́ hàn án, ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́, kó o wá ka ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Ka ìbéèrè yẹn jáde lẹ́ẹ̀kan sí i, kó o wá ní kí onítọ̀hún dáhùn. Tó o bá ṣeé ṣe ẹ lè jíròrò gbogbo àpilẹ̀kọ náà tàbí kẹ́ ẹ máa jíròrò rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, kẹ́ ẹ máa lo àwọn ìbéèrè àti àlàyé tó wà níbẹ̀. Kó o tó parí ìjíròrò náà, pe àfiyèsí rẹ̀ sí ìbéèrè tó kàn, kó o sì ṣe àdéhùn pàtó nípa ìgbà tó o máa pa dà wá jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Rí i pé o pa dà lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti máa jíròrò àwọn àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú rẹ̀, títí dìgbà tó o máa mú ìtẹ̀jáde tó kàn wá fún un. Ohun míì tó o tún lè ṣe ni pé kó o fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ onílé náà ní tààràtà. Kó o wá lo àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ yẹn láti fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ hàn án.
4. Báwo la ṣe lè lo àpilẹ̀kọ yìí nígbà ìpadàbẹ̀wò?
4 O tún lè lo àwọn àpilẹ̀kọ yìí lọ́nà tó kẹ́sẹ járí fún àwọn tó o máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé àtàwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ. O kàn lè sọ pé: “A ti ní àwọn àpilẹ̀kọ tuntun kan nínú Ilé Ìṣọ́ báyìí. Jẹ́ kí n fi béèyàn ṣe lè lò ó hàn ẹ́.” Àdúrà wa ni pé kí àwọn àpilẹ̀kọ tuntun yìí ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tím. 2:4.