Àpilẹ̀kọ Tuntun Tí Yóò Máa Jáde Nínú Ilé Ìṣọ́
Láwọn ọjọ́ Sátidé àkọ́kọ́ lóṣooṣù, a máa ń lo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan tó máa ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́ láti fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àkòrí àwọn àpilẹ̀kọ náà ni “Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Àmọ́ bẹ̀rẹ̀ láti oṣù January 2013, ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ” la máa fi rọ́pò àwọn àpilẹ̀kọ yẹn. Àpilẹ̀kọ tuntun yìí yóò sì máa wà lẹ́yìn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá à ń fi sóde. A lè lo àwọn àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ” lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bá a ṣe máa ń lo “Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (km 12/10 ojú ìwé 2) Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ yóò máa wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa bó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀.