Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 31, 2012. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
1. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Jóẹ́lì 2:1-10, 28 nípa àwọn kòkòrò tó ya bolẹ̀ ṣe nímùúṣẹ? [Nov. 5, w07 10/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 1]
2. Ta ni ọ̀rọ̀ tí Ámósì 8:11 sọ ṣẹ sí lára, ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa bá a ti ń gbé lákòókò tí oúnjẹ tẹ̀mí túbọ̀ ń pọ̀ sí i yìí? [Nov. 12, jd ojú ìwé 61 ìpínrọ̀ 9]
3. Kí ló ṣeé ṣe kó dá kún ìkùgbù ọkàn-àyà àwọn ará Édómù, òótọ́ wo la kò sì gbọ́dọ̀ gbàgbé láé? (Ọbad. 3, 4) [Nov. 19, w07 11/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 1]
4. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà pèrò dà lórí ìyọnu tó ti sọ pé òun máa mú wá sórí àwọn ará Nínéfè? (Jónà 3:8, 10) [Nov. 19, w07 11/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1]
5. Báwo ni rírìn ní orúkọ Ọlọ́run ṣe lè mú kí okùn ọ̀rẹ́ wa pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ yi? (Míkà 4:5) [Nov. 26, jd ojú ìwé 88 ìpínrọ̀ 12]
6. Ìdánilójú wo ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Náhúmù 2:6-10 fún wa? [Dec. 3, w07 11/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 2; w88 2/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 7]
7. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Hágáì 1:6, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo nìyẹn sì kọ́ wa? [Dec. 10, w06 4/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 12 sí 15]
8. Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tó wà nínú ìwé Sekaráyà 7:10 sílò tó sọ pé ká má ṣe “pète-pèrò nǹkan búburú sí ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì” nínú ọkàn-àyà wa? [Dec. 17, jd ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 6; w07 12/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3]
9. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Sekaráyà 4:6, 7 fi jẹ́ ìtùnú fáwọn olùjọ́sìn Jèhófà lóde òní? [Dec. 17, w07 12/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 1]
10. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé Málákì 3:16 sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sára, kí ohunkóhun má bàa mú ká yẹ ìpinnu tá a ti ṣe pé a ó máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìyẹsẹ̀? [Dec. 31, w07 12/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3]