Ṣé Gbogbo Àpilẹ̀kọ Tó Wà Nínú Rẹ̀ Lò Ń Lò?
1 “Ó ń ṣe mí bíi kí n ti máa lò ó lóde ẹ̀rí!” Ohun tí arábìnrin kan kọ sínú lẹ́tà tó fi ránṣẹ́ sí wa nìyẹn lẹ́yìn tó ka Ilé Ìṣọ́ January 1, 2008. Ṣó o ti ronú lórí àwọn kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tó máa ń jáde déédéé nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń fi sóde, ṣó o sì ti mọ bó o ṣe máa lò ó lóde ẹ̀rí?
2 “Ohun Tá A Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù”: Ó ṣeé ṣe kó o tí rí i pé àpilẹ̀kọ yìí mú kó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó ò bá tí ì lò ó, o lè gbìyànjú ẹ̀ wò nípa kíka àkòrí àpilẹ̀kọ náà fún onílé, kó o sì pàfiyèsí rẹ̀ sóhun tí Jésù sọ nípa kókó náà bó ṣe wà nínú ìpínrọ̀ kìíní. Bó o bá kíyè sí pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, sapá láti máa bá ìjíròrò náà lọ nípa lílo àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tá a fi ṣe ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ nínú àpilẹ̀kọ náà. Ní kó sọ èrò rẹ̀ lórí ìbéèrè náà. Ṣàlàyé ṣókí lórí àwọn àwòrán tó bá bá ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ mu, kó o sì máa bá ìjíròrò náà lọ nínú ìpínrọ̀ tó kàn. O lè bá onílé jíròrò ìlàjì lára àpilẹ̀kọ náà lọ́jọ́ àkọ́kọ́, kó o sì wá jíròrò apá tó ṣẹ́ kù nígbà tó o bá pa dà bẹ̀ ẹ́ wò. Gbára dì láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni nígbà tó o bá pa dà lọ.
3 “Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀”: Oṣù mẹ́ta mẹ́ta ni ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa ń jáde nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń lò lóde ẹ̀rí, ohun tó sì wà fún ni bí ọkọ, aya àtàwọn òbí ṣe lè fàwọn ìlànà Bíbélì yanjú àwọn ìṣòro tó fẹ́ bá ayọ̀ ìdílé wọn jẹ́. O tún lè lo àwọn àpilẹ̀kọ yìí láti mú kẹ́ni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí rí ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì.—2 Tím. 3:16, 17.
4 Àwọn Àpilẹ̀kọ Tó Wà Fáwọn Ọ̀dọ́: Ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Abala Àwọn Ọ̀dọ́” tá a kọ lọ́nà táá jẹ́ káwọn tó ń kà á lè ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ìtàn Bíbélì kan pàtó. O lè fàwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí ran àwọn ọ̀dọ́ tó o bá bá pàdé lóde ẹ̀rí lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìdí tó fí yẹ káwọn máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 119:9, 105) Tó o bá ń báwọn òbí sọ̀rọ̀, o lè fàwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó máa ń jáde lóṣù mẹ́ta mẹ́ta tá a pè ní “Kọ́ Ọmọ Rẹ” bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí lè mú káwọn ọmọ kéékèèké kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látara àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn. Ṣó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ?
5 Àwọn Àpilẹ̀kọ Míì: Oṣooṣù la máa ń fi àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé” dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kó máa jà gùdù lọ́kàn àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. O lè fi àpilẹ̀kọ yìí nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ nígbà tó o bá ń fi ìwé ìròyìn lọni láti ilé dé ilé. Ìròyìn amóríyá nípa ohun táwọn míṣọ́nnárì àtàwọn míì ń kojú lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ló máa ń wà nínú àpilẹ̀kọ tá a pè ní, “Lẹ́tà Kan Láti . . . ” Àpilẹ̀kọ yìí lè mú káwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wa rí i pé iṣẹ́ ìwàásù náà ti kárí ayé, ní ìmúṣẹ àmì wíwàníhìn-ín Kristi.—Mát. 24:3, 14.
6 Àpilẹ̀kọ náà “Sún Mọ́ Ọlọ́run” tó máa ń jáde lóṣooṣù, tá a gbé ka Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, lè mú káwọn olóòótọ́ ọkàn fẹ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà. Ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” tó máa ń jáde lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún la ṣe lọ́nà tẹ́ni tó ń kàwé á fi lè máa fojú inú wo àwọn ìtàn Bíbélì bíi pé wọ́n ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, bíi pé wọ́n ń fojú ara wọn rí àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn àti bí ìgbàgbọ́ wọn ṣe tó.
7 Ẹ ò rí i bínú wa ti máa ń dùn tó láti máa gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a dìídì ṣe fún iṣẹ́ ìwàásù yìí! Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti rí i dájú pé a mọ àwọn ohun tó máa ń wà nínú ẹ̀ dunjú, ká sì máa lò ó dáadáa lóde ẹ̀rí.