Ẹ Máa Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọni ní Sátidé Àkọ́kọ́
Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù May ọdún 2011, à ń gba gbogbo akéde níyànjú láti máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn ní gbogbo Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù. A ti ṣe ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tó ń jáde déédéé nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí à ń fi sóde lọ́nà tá a fi lè máa lò ó láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn àwọn àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ.” Torí náà, nínú ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tá a bá ṣe ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù, ó yẹ ká máa sọ bá a ṣe lè lo àwọn àpilẹ̀kọ náà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì máa ṣe àṣefihàn rẹ̀.
Àwọn alàgbà lè ṣètò pé kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan pàdé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní Sátidé àkọ́kọ́, wọ́n sì lè ṣètò pé kí wọ́n pàdé pọ̀ níbì kan náà, bóyá ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́, bí ìjọ púpọ̀ bá ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, kí ìjọ kankan má ṣe sún ọjọ́ tí wọ́n á máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni sí ọjọ́ míì torí kí gbogbo àwùjọ wọn lè ráyè pàdé pọ̀ láti ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá.