Ọjọ́ Tá A Yà Sọ́tọ̀ Láti Máa Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ Àwọn Èèyàn
1 Láti January ọdún 2009, ìjọ kọ̀ọ̀kàn á máa ya òpin ọ̀sẹ̀ kan sọ́tọ̀ lóṣooṣù láti máa fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó bá ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ nínú oṣù. Ó lè jẹ́ ọjọ́ Saturday tàbí ọjọ́ Sunday lẹ máa yà sọ́tọ̀, bó bá ṣe bá ìpínlẹ̀ yín mu. Lọ́jọ́ náà, bí onílé kan kò bá gbà pé ká máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, akéde ṣì lè fún un ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Gbogbo àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló gbọ́dọ̀ máa kópa kíkún nínú ìgbòkègbodò yìí, kí wọ́n lè ran àwọn akéde lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
2 Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ló máa pinnu ọjọ́ kan ní òpin ọ̀sẹ̀ tí wọ́n máa yà sọ́tọ̀ fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí wọ́n máa rán àwọn ará létí látìgbàdégbà pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀, kí wọ́n sì máa sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ilé-dé-ilé àti nígbà tí wọ́n bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò.
3 Bó O Ṣe Máa Múra Sílẹ̀: A lè rí àwọn àbá lórí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March ọdún 2006 àti lójú ìwé 5 nínú ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. Àwọn kan lè yàn láti lo ìwé àṣàrò kúkúrú, irú bí Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? (Wo ojú ìwé 6.) Bákan náà, àbá lórí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá a bá pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó gbà ìwé ìròyìn wà lójú ìwé kẹta nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa toṣù August ọdún 2007. Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ á máa darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí kò ní ju ìṣẹ́jú 10 sí 15 lọ, wọ́n á sì jíròrò àwọn àbá tó gbéṣẹ́ lórí bí ẹnì kan ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí kí wọ́n ṣàṣefihàn rẹ̀.
4 Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa gbà pé ká kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kì í sì í ṣe gbogbo èèyàn ni wọ́n á máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn lọ fúngbà pípẹ́. Àmọ́ kò yẹ kéyìí mú ká fà sẹ́yìn, torí pé Jèhófà ló ń fa àwọn ẹni bí àgùntàn wá sínú ètò rẹ̀. (Jòh. 6:44) Ojúṣe wa kì í ṣe fífúnrúgbìn òtítọ́ nìkan, àmọ́ a tún ní láti máa bójú tó o, ká sì máa bomi rin ín, èyí sì kan kíkọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 3:9.