Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 27
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 25-28
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀. “Ìjọsìn Ìdílé ni Kàlẹ́ńdà Ọdún 2011 Dá Lé.” Àsọyé.
10 min: Bí Ìlapa Èrò Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 168 ìpínrọ̀ 2. Ṣe àṣefihàn bí akéde kan tó ń dá sọ̀rọ̀ ṣe ń ronú lórí ọ̀nà tó máa gbà gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kálẹ̀ lóde ẹ̀rí, kó lo ìwé tá a máa fi wàásù lóde ẹ̀rí lóṣù tó ń bọ̀.
10 min: Orí Ewú Jẹ́ Adé Ẹwà. (Òwe 16:31) Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ August 15, 2008, ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 13-16. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìrírí kọ̀ọ̀kan, ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Ni Oṣù January. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì jíròrò ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Kó o wá yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o sì ní kí àwùjọ sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà.