Ìjọsìn Ìdílé ni Kàlẹ́ńdà Ọdún 2011 Dá Lé
Ìjọsìn Ìdílé ni Kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2011 dá lé látòkè délẹ̀. Kàlẹ́ńdà náà ṣàfihàn àwòrán àwọn ìdílé lóde òní àti ti àwọn ìdílé lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Ó tún ṣàfihàn àwọn tọkọtaya àtàwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí kò tíì lọ́kọ tàbí tí kò tíì láyà tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Inú àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn máa ń dùn sí òfin Jèhófà, èyí sì ṣe pàtàkì gan-an torí pé ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó kojú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. (Sm 1:2, 3) Bá a ṣe ń wo àwòrán kọ̀ọ̀kan lórí kàlẹ́ńdà náà, ó máa jẹ́ ká rántí bí Ìjọsìn Ìdílé ti ṣe pàtàkì tó, ì báà jẹ́ inú ìdílé tó tóbi tàbí èyí tó kéré la wà, àti pé yálà gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ló ń jọ́sìn Jèhófà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. A fi àwọn àlàfo kan sínú kàlẹ́ńdà náà tẹ́ ẹ máa kọ ọjọ́ tí ìdílé yín ti yà sọ́tọ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé yín sí. Ṣé ẹ ti kọ ọjọ́ tẹ́ ẹ ó máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín síbẹ̀?