Orin 131
Jèhófà Ń Ṣe Ọ̀nà Àsálà
1. Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run alààyè;
Iṣẹ́ rẹ̀ pọ̀ láyé,
ní òkun òun sánmà.
Kò sọ́lọ́run tó lè bá ọ dọ́gba, kò
sí rárá.
Àwọn ọ̀tá wa gbé.
(ÈGBÈ)
Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́.
Èèyàn rẹ̀ yóò rí bágbára rẹ̀ ti pọ̀ tó.
Pẹ̀lú ìgboyà àtìgbàgbọ́,
a ńkókìkí,
A sì ńyin Jèhófà,
Olùṣọ̀nà àsálà.
2. Ìjárá ikú lè yí mi ká, nó pè ọ́,
“Jèhófà jọ̀ọ́, fún mi
lókun àtìgboyà.”
Gbọ́ ohùn mi láti orí ìtẹ́ rẹ,
“Gbà mí là;
Ọlọ́run, kó mi yọ.”
(ÈGBÈ)
Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́.
Èèyàn rẹ̀ yóò rí bágbára rẹ̀ ti pọ̀ tó.
Pẹ̀lú ìgboyà àtìgbàgbọ́,
a ńkókìkí,
A sì ńyin Jèhófà,
Olùṣọ̀nà àsálà.
3. Ohùn rẹ yóò dún bí
ààrá látọ̀run wá.
Ọ̀tá rẹ yóò páyà;
ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀.
Alèwílèṣe ni ọ́ Baba;
Àwa yóò sì rí
Bí wàá ṣe gbà wá là.
(ÈGBÈ)
Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́.
Èèyàn rẹ̀ yóò rí bágbára rẹ̀ ti pọ̀ tó.
Pẹ̀lú ìgboyà àtìgbàgbọ́,
a ńkókìkí,
A sì ńyin Jèhófà,
Olùṣọ̀nà àsálà.
(Tún wo Sm. 18:1, 2; 144:1, 2.)