Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 27, 2010. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ November 1 sí December 27, 2010, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
1. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ akọrin ṣe fi ìyìn fún Ọlọ́run nínú 1 Kíróníkà 16:34? [w02 1/15 ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 6 sí 7]
2. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí Dáfídì fi hàn? (1 Kíró. 22:5, 9) [w05 10/1 ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 7]
3. Báwo ni Dáfídì Ọba ṣe fẹ́ kí Sólómọ́nì ọmọ òun mọ Ọlọ́run tó? (1 Kíró. 28:9) [w08 10/15 ojú ìwé 7, ìpínrọ̀ 18]
4. Kí nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú bí wọ́n ṣe fi àwọn ère akọ màlúù ṣe ibi tí wọ́n gbé òkun dídà náà lé? (2 Kíró. 4:2-4) [w05 12/1 ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 3; w98 6/15 ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 17]
5. Ṣé wàláà òkúta méjì nìkan ló wà nínú àpótí májẹ̀mú, àbí àwọn nǹkan míì tún wà níbẹ̀? (2 Kíró. 5:10) [w06 1/15 ojú ìwé 31]
6. Ìjọra wo ni tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ní pẹ̀lú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa lóde òní? (2 Kíró. 6:18-21) [w05 12/1 ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 8]
7. Ǹjẹ́ Ásà Ọba mú gbogbo “àwọn ibi gíga” kúrò? (2 Kíró. 14:2-5; 15:17) [w05 12/1 ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 3]
8. Báwo la ṣe lè lo ìlànà tó wà nínú 2 Kíróníkà 17:9, 10 lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? [w09 6/15 ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 7]
9. Báwo ni àwa èèyàn Ọlọ́run lóde òní ṣe lè fi ohun tó wà nínú 2 Kíróníkà 20:17 sílò? [w03 6/1ojú ìwé 21 sí 22 ìpínrọ̀ 14 sí 17]
10. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìtàn Ùsáyà Ọba tó jẹ́ agbéraga? (2 Kíró. 26:15-21) [w99 12/1 ojú ìwé 26, ìpínrọ̀ 1 sí 2]