Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 3, 2011
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 15 ìpínrọ̀ 17 sí 20, àti àpótí tó wà lójú ìwé 160
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 29-32
No. 1: 2 Kíróníkà 30:13-22
No. 2: Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso Nígbà Táwọn Ọ̀tá Kristi Ṣì Wà Láàyè (td 21B)
No. 3: Bí Ìbẹ̀rù Ikú Ṣe Ń Sọ Àwọn Èèyàn Di Ẹrú (Héb. 2:15)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: A Yà Wá Sọ́tọ̀ Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà. Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 168, ìpínrọ̀ 2 sí ìparí orí náà.
10 min: Sọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ Nígbà Tó O Bá Ń Wàásù. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 128, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 129 ìpínrọ̀ 1. Ní ṣókí fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́ni àkéde kan tó ní ìrírí, tó jẹ́ ẹni tó ti borí ìtìjú. Kí ló ti ràn án lọ́wọ́ tí kò jẹ́ kó máa bẹ̀rù púpọ̀ mọ́ lóde ẹ̀rí?