ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 6/15 ojú ìwé 25-26
  • ‘Iná Ẹ̀mí Ìtọpinpin Ń Jó Lọ́kàn Mi’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Iná Ẹ̀mí Ìtọpinpin Ń Jó Lọ́kàn Mi’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sáyẹ́ǹsì Tó Yéni Yéké
  • Mímọ Ẹlẹ́dàá Náà Dunjú
  • Iwe Titun Mú Araadọta-Ọkẹ Layọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Mọ Irú Ẹni Tí Ẹlẹ́dàá Rẹ Jẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹlẹ́dàá Lè Mú Kí Ayé Rẹ Nítumọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 6/15 ojú ìwé 25-26

‘Iná Ẹ̀mí Ìtọpinpin Ń Jó Lọ́kàn Mi’

“N kò lè sọ bínú mi ti dùn tó àti bí ara mi ti yá gágá tó nígbà tí mò ń ka ìwé yìí, Is There a Creator Who Cares About You? Ìwé yìí ò ṣeé gbé sílẹ̀ o, àfi kéèyàn ṣáà warí mọ́ ọn tó fi máa kà á tán. Ẹ mà ṣeun o, torí ẹ̀yin lẹ tanná ran ẹ̀mí ìtọpinpin lọ́kàn mi.”

BÍ Ọ̀KAN lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá láti Àríwá Carolina, ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe sọ nípa ìwé náà tí Watch Tower Society mú jáde ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” tó wáyé lọ́dún 1998 sí 1999 nìyẹn. Ká ní oò tilẹ̀ ní ẹ̀dà ìwé náà, gbọ́ nǹkan táwọn ẹlòmí-ìn sọ.

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ọkùnrin kan gba ẹ̀dà tirẹ̀ ní àpéjọpọ̀ tí wọ́n ṣe ní San Diego, California, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó kọ̀wé pé: “Ìwé yìí mà fún ìgbàgbọ́ lókun o. Ó mú kí ń kún fún ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà. Ojú ìwé kejìdínlọ́gọ́rùn-ún ni mo wà báyìí, ó sì ń ṣe mí bí ẹnì pé kó máà tán, kí n ṣáà máa kà á lọ ṣáá! Ayọ̀ ọ̀hún pọ̀ jọjọ.”

Obìnrin kan láti Ìlà Oòrùn Ayé kọ̀wé pé: “Olùbánisọ̀rọ̀ ní àpéjọpọ̀ náà lo gbólóhùn náà, ‘ìwé àrà ọ̀tọ̀,’ bẹ́ẹ̀ gan-an nìwé náà jẹ́. Ohun kan tó tún tayọ nínú ìwé náà ni pé kò fipá mú òǹkàwé láti gbà pé Ọlọ́run ń bẹ, síbẹ̀ ó sọ ojú abẹ níkòó.”

Àwọn ohun tó jẹ́ apà kan òkodoro ọ̀rọ̀ náà ni àwọn àwárí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó fani mọ́ra nípa àgbáálá ayé wa, ìwàláàyè àti àwa fúnra wa. Èyí wú ọ̀pọ̀lọpọ̀ lórí. Obìnrin kan láti California kọ̀wé pé: “N kò tiẹ̀ mọ ohun tí màá sọ nípa bí ìwé kékeré yìí ti nípa lórí mi tó. N kò lè gbé ìwé náà sílẹ̀ rárá torí pé ojú ìwé kọ̀ọ̀kan ló ń ṣàpèjúwe ọ̀pọ̀ nǹkan tí a ṣàwárí nípa àgbáálá ayé wa àti ìwàláàyè fúnra rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ki sínú ẹ̀! Ṣe ni n óò máa gbé ìwé kékeré yìí gẹ̀gẹ̀, tí n óò sì máa ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.”

Ohun kan tó tún mú inú ọ̀pọ̀ dùn ni bí ìwé náà ṣe ṣàkópọ̀ Bíbélì, tó sì ṣàgbéyọ àwọn ìwà Ẹlẹ́dàá náà. Ohun tí ẹnì kan sọ nípa ìwé náà rèé: “Kò tí ì síwèé tí mo kà tó ṣàkópọ̀ Bíbélì tó bí apá tó gbẹ̀yìn ìwé yìí ti ṣe.” Kété lẹ́yìn àpéjọpọ̀ kan tí a kọ́kọ́ ṣe ní New York, ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ẹlòmíràn kọ̀wé pé: “Ìwé tẹ́ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde yìí ló jẹ́ ìwé tó gbàfiyèsí ẹni jù lọ tí ẹ tí ì tẹ̀ jáde. Àwọn ẹ̀rí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. Àkópọ̀ rẹ́gí tó ṣe nípa Bíbélì ti tó lọ́tọ̀ láti ṣàlàyé àwọn kókó tó wà nínú rẹ̀ àti láti jẹ́ kí òǹkàwé náà fẹ́ mọ púpọ̀ sí i.”

Sáyẹ́ǹsì Tó Yéni Yéké

Ìsọfúnni lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ní àwọn òrí tó ṣáájú lè dà bí pé ó le díẹ̀, ṣùgbọ́n ohun táwọn kan sọ nípa rẹ̀ nìyí:

Ọkùnrin ará Kánádà kan kọ̀wé pé: “Èyí yàtọ̀ pátápátá sáwọn ìwé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mìíràn, tí àwọn tó kọ wọ́n máa ń fẹ́ fi ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà wọn fani mọ́ra. Ìmọ̀ tẹ́ẹ ní lórí àwọn ẹ̀kọ́ bíi físíìsì, kẹ́mísìrì, èròjà DNA, àwọn èròjà apilẹ̀ àbùdá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, kọyọyọ, yékéyéké làlàyé yìn yé wa. Ì bá ti lọ wà jù, ká lẹ́yìn lẹ kọ àwọn ìwé tí mo kà ní yunifásítì lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn!”

Ọ̀jọ̀gbọ́n yunifásítì kan nínú ìmọ̀ físíìsì kọ̀wé pé: “[Ìwé náà] gbé àwọn kókó ọ̀ràn náà kalẹ̀ láìkówọnú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó jẹ mọ́ ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Ìwé náà fèrò wérò pẹ̀lú òǹkàwé, ó sì fa ọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì yọ. Èyí jẹ́ ‘ìwé pàtàkì’ fún gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ nínú ìpilẹ̀ṣẹ̀ àgbáálá ayé àti ìwàláàyè, ì báà jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tàbí ọ̀gbẹ̀rì nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.”

Obìnrin kan tí ń kọ́ṣẹ́ nọ́ọ̀sì lọ́wọ́ sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo ṣí ìwé náà sí àkòrí kẹrin, tí mo sì ka àyọkà kan níbẹ̀, tí ó wá láti inú ìwé tí à ń lò gan-an ní kíláàsì! Mo fún ọ̀jọ̀gbọ́n wa ní ìwé náà, mo sì sọ fún un pé mo mọ̀ dájú pé ìsọfúnni inú ìwé náà yóò tù ú lára. Mo fi ojú ìwé kẹrìnléláàádọ́ta tó sọ nípa ọpọlọ hàn án. Ó kà á sínú, ó sì wí pé: ‘Èyí mà ga o! Màá kà á dáadáa.’”

Ẹni kan tó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Belgium kọ̀wé pé: “Ohun tó yà mí lẹ́nu, tó sì jẹ́ kó gba àfiyèsí mi pátápátá ni àwọn àlàyé lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó fi hàn pé dípò tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní fi máa tako ẹ̀kọ́ náà pé Ọlọ́run ń bẹ, èyí tí Bíbélì fi kọ́ni, ṣe ló fara mọ́ ẹ̀kọ́ náà. Ojú ìwòye tó múná dóko lèyí jẹ́.”

Mímọ Ẹlẹ́dàá Náà Dunjú

Ìwé náà ran àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run dunjú, kí wọ́n sì sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí. Òǹkàwé kan ní Fukuoka City, Japan, sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé fún ìgbà àkọ́kọ́ a darí àfiyèsí sí Jèhófà. Ìwé náà yíni lérò padà lọ́nà tó yani lẹ́nu. Ó jẹ́ kí n mọ Jèhófà lọ́nà tí ń kò ronú nípa rẹ̀ rí.” Ará El Salvador kan kọ̀wé pé: “Ẹ ṣàlàyé kúnnákúnná nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ aláàánú, olóore ọ̀fẹ́, ẹni tí ń lọ́ra láti bínú, tó sì pọ̀ ní ìṣeun ìfẹ́ tó. Lóòótọ́, ohun tí a nílò gan-an nìyí táa bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Èyí ni ìwé tó kọ́kọ́ ṣàlàyé ìmọ̀lára Jèhófà àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò tí Ọmọ rẹ̀, Jésù, ní.” Ẹnì kan tó ka ìwé náà ní Zambia sọ pé: “Èrò mi nípa Jèhófà yí padà pátápátá.”

Ó wá yéni kedere, ìdí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń fi tayọ̀tayọ̀ fi ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You? lọ àwọn ẹlómíràn. Ẹnì kan sọ pé: “Bí mo ti ń parí orí kẹwàá [“Bí Ẹlẹ́dàá Bá Bíkítà, Èé Ṣe Tí Ìyà Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?”], ohun tó jáde lẹ́nu mi ni pé, ‘Ìwé táa nílò ní Japan gan-an nìyí!’ Màá fẹ́ láti lè rántí ohun tí mo kà nínú àkòrí yìí, kí n bàa lè lò ó nínú iṣẹ́ ìsìn pápá léraléra.” Obìnrin kan ń bá ọmọdébìnrin kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, inú tẹ́ńpìlì àwọn ẹlẹ́sìn Búdà tí baba ọmọdébìnrin náà ti ń ṣiṣẹ́ àlùfáà ni a sì ti tọ́ ọmọ náà dàgbà. “Ó nira fún un láti tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye náà pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ. Kò sí ohun kan tó fipá múni nínú àlàyé ti ìwé yìí ṣe, ṣùgbọ́n àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀ ń bẹ níbẹ̀, nítorí náà mo gbà pé àwọn ẹlẹ́sìn Búdà pàápàá lè ka ìwé yìí láìkọminú rárá. Ó tún jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa.”

Àgbéyẹ̀wò yìí wá láti ìlú England: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ìwé Creator tán ni o, mo tún fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tún un kà. Ìwé nìwé yìí o jàre! Kò sí béèyàn ò ṣe ní nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó bá ń kà á. Mo ti fún aládùúgbò mi ní ẹ̀dà rẹ̀ kan, lẹ́yìn tó sì ka àkòrí méjì péré tán, ó wí pé, ‘Mi ò lè gbéwèé náà sílẹ̀, ó ti lọ wà jù.’ Ó dá mi lójú pé èyí yóò ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá dunjú.”

Ọkùnrin kan ní Maryland, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Ẹ wò ó, ọ̀rọ̀ ẹ̀ wọ̀ mí lákínyẹmí ará! Mo ti wéwèé pé gbogbo àwọn tí a jọ ń ṣòwò ni màá fún ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan. Nígbà mìíràn, ó máa ń ṣòro fún mi láti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tọ́wọ́ wọn máa ń dí, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀mọ̀wé. Àmọ́ báyìí o, ìwé yìí yóò ràn mí lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó fani mọ́ra, tó sì gbéṣẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi.”

Ó dájú pé, ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You?, yóò nípa tó dáa lórí àwọn èèyàn jákèjádò ayé.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwòràn tó wà lókè, Eagle Nebula: J. Hester and P. Scowen (AZ State Univ.), NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́