Ẹlẹ́dàá Lè Mú Kí Ayé Rẹ Nítumọ̀
“Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà; nítorí pé òun fúnra rẹ̀ ni ó pàṣẹ, a sì dá wọn.”—SÁÀMÙ 148:5.
1, 2. (a) Ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò? (b) Báwo ni ìbéèrè Aísáyà ṣe kan ìṣẹ̀dá?
“ṢÉ O kò tíì mọ̀ ni?” Létí èèyàn, ìbéèrè yẹn lè dà bí pé ẹni tí ń béèrè ọ̀rọ̀ náà ṣì ní nǹkan kan lọ́kàn tó fẹ́ sọ, ó wá lè mú kí ọ̀pọ̀ fèsì pé, ‘Mọ kí ni?’ Ṣùgbọ́n, ìbéèrè pàtàkì lèyí. Báa sì ṣe lè lóye ìbéèrè náà dáadáa ni báa bá mọ bí ó ṣe jẹ yọ—orí ogójì ìwé Aísáyà nínú Bíbélì ló wà. Aísáyà, Hébérù ìgbàanì kan ló kọ ọ́, nítorí náà, ọjọ́ ti pẹ́ táa ti béèrè ìbéèrè yìí. Síbẹ̀, ìbéèrè náà ṣì bóde mu, torí ó ní í ṣe pẹ̀lú bí ìgbésí ayé rẹ yóò ṣe nítumọ̀.
2 Nítorí bí ìbéèrè tó wà nínú Aísáyà 40:28 yìí ti ṣe pàtàkì tó, ó yẹ ká gbé e yẹ̀ wò gidigidi: “Ṣé o kò tíì mọ̀ ni tàbí ṣé o kò tíì gbọ́ ni? Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, jẹ́ Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Nítorí náà ‘mímọ̀’ náà ní í ṣe pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá ayé, àyíká ọ̀rọ̀ náà sì tún fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ayé nìkan là ń sọ. Nínú ẹsẹ méjì tó ṣáájú, Aísáyà kọ̀wé nípa àwọn ìràwọ̀, ó wí pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye . . . Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”
3. Kódà bóo bá tilẹ̀ mọ ohun púpọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá, èé ṣe tó fi yẹ kí o fẹ́ láti mọ̀ sí i?
3 Láìsí àní-àní, ìbéèrè náà pé, “Ṣé o kò tíì mọ̀ ni?” jẹ́ ìbéèrè tó ní í ṣe pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá àgbáálá ayé wa. Ní tìrẹ, ó ṣeé ṣe kóo ti gbà pẹ̀lú ìdánilójú pé Jèhófà Ọlọ́run ni “Ẹlẹ́dàá àwọn ìkangun ilẹ̀ ayé.” Ó sì lè jẹ́ pé ó ti mọ púpọ̀ nípa àwọn ìwà rẹ̀ àti ọ̀nà rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ká lóo bá ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan pàdé ńkọ́, tó jẹ́ pé ó ń kọminú bóyá Ẹlẹ́dàá ń bẹ tàbí tí kò tiẹ̀ mọ irú ẹni tí Ẹlẹ́dàá jẹ́ gan-an? Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, máà jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu, torí pé àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, tí kò mọ nǹkan kan nípa Ẹlẹ́dàá tàbí tí kò gbà á gbọ́ pọ̀ lọ súà.—Sáàmù 14:1; 53:1.
4. (a) Èé ṣe tó fi yẹ láti ronú nípa Ẹlẹ́dàá náà ní àkókò yìí? (b) Àwọn ìdáhùn wo ni ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè mú wá?
4 Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn oníyèméjì ló ń gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́, àwọn tí wọ́n rò pé sáyẹ́ǹsì lè dáhùn (tàbí rí ìdáhùn sí) àwọn ìbéèrè nípa báa ṣe pilẹ̀ àgbáálá ayé àti bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀. Nínú ìwé náà, The Origin of Life (tí àkọlé rẹ̀ gan-an lédè Faransé jẹ́: Aux Origines de la Vie) àwọn òǹṣèwé náà, Hagene àti Lenay sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí pàápàá àwọn èèyàn ṣì ń jiyàn lórí bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀. Ìṣòro tó jẹ́ pé kò lè rọrùn rárá láti yanjú yìí, ń béèrè pé ká ṣèwádìí rẹ̀ ní gbogbo ẹ̀ka ẹ̀kọ́, bẹ̀rẹ̀ látorí gbalasa òfuurufú tó lọ salalu tó fi dórí ohun tó kéré jù lọ nínú ohun táa lè fojú rí.” Síbẹ̀, orí tó kẹ́yìn nínú ìwé náà tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “A Kò Tíì Rí Ìdáhùn Sí Ìbéèrè Náà Síbẹ̀,” sọ pé: “A ti ṣàyẹ̀wò àwọn ìdáhùn kan táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní sí ìbéèrè náà pé, Báwo ni ìwàláàyè ṣe dórí ilẹ̀ ayé? Ṣùgbọ́n èé ṣe tí ìwàláàyè fi wà? Ǹjẹ́ ìwàláàyè tiẹ̀ ni ète tó fi wà rárá? Sáyẹ́ǹsì kò lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Ìbéèrè ‘báwo’ làwọn nǹkan ṣe dé ló ń wá kiri. ‘Báwo’ àti ‘èé ṣe’ sì rèé, ìbéèrè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbáà ni wọ́n. . . . Ní ti ìbéèrè nípa ‘èé ṣe’ tí a ń sọ yìí, gbogbo wa pátá la gbọ́dọ̀ wá ìdáhùn sí i, àtọlọ́gbọ́n èrò orí, àtonísìn, kò yọ ẹnì kankan sílẹ̀.”
Rírí Ìdáhùn àti Ìtumọ̀ Rẹ̀
5. Irú àwọn èèyàn wo ni yóò jàǹfààní nínú títúbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá náà?
5 Òótọ́ ni, a fẹ́ mọ ìdí tí ìwàláàyè fi wà—pàápàá jù lọ ìdí táa fi wà níhìn-ín. Ní àfikún sí i, ó yẹ ká lẹ́mìí àtiṣèrànwọ́ fáwọn tí kò tí ì gbà pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ, tó sì jẹ́ pé ohun tí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀ kò tó nǹkan. Àbí kí la fẹ́ sọ nípa àwọn tí ọ̀nà táa gbà tọ́ wọn dàgbà tí jẹ́ kí wọ́n ní èrò tó yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì wí nípa Ọlọ́run. Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn ló jẹ́ pé Ìlà Oòrùn Ayé ni wọ́n dàgbà sí tàbí tí a tọ́ wọn dàgbà ní ibòmíràn tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ibẹ̀ kò tiẹ̀ gbà pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, àní tí wọn ò gbà pé ó jẹ́ ẹnì kan tó ní àwọn ìwà tó fani mọ́ra. Lójú tiwọn, ọ̀rọ̀ náà, “ọlọ́run,” lè túmọ̀ sí agbára kan tó rúni lójú tàbí tó ṣòro láti lóye. Àwọn wọ̀nyí kò tíì ‘mọ Ẹlẹ́dàá náà’ tàbí àwọn ọ̀nà rẹ̀. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn wọ̀nyí, tàbí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn tí wọ́n ní ojú ìwòye bíi tiwọn, bá lè gbà pẹ̀lú ìdánilójú pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ, àǹfààní tí wọn yóò rí gbà á mà pọ̀ ó, ọ̀kan lára rẹ̀ sì ni ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun! Wọ́n tún lè ní ohun kan tó ṣọ̀wọ́n gidigidi—ìgbésí ayé tó nítumọ̀ tòótọ́, tó ní ète gidi àti èyí tó kún fún ìbàlẹ̀-ọkàn.
6. Báwo ni ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lónìí ṣe fara jọ ìrírí Paul Gauguin àti ọ̀kan lára àwòrán tó yà?
6 Àpèjúwe kan rèé: Lọ́dún 1891, oníṣẹ́ ọnà tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, Paul Gauguin wá ìgbésí ayé tí ń tẹ́ni lọ́rùn lọ sí ilẹ̀ French Polynesia, ibi tí a sọ pé ó dà bí párádísè. Àmọ́ kò pẹ́ tí ìgbésí ayé oníwà ìbàjẹ́ tó ti gbé tẹ́lẹ̀ rí fi sọ òun àti àwọn ẹlòmíràn di olókùnrùn. Nígbà tó rí i pé ikú ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ló bá ya àwòrán ńlá sára aṣọ kan, àwòrán náà jẹ́ ká rí i pé, ó jọ pé ‘ó gbà lọ́kàn ara rẹ̀ pé àwámáàrídìí ni ìwàláàyè jẹ́.’ Ǹjẹ́ o mọ orúkọ tí Gauguin fún àwòrán tó yà yẹn? Ó pè é ní, “Ibo La ti wá? Kí Ni Wá? Níbo Là Ń Lọ?” O ti lè gbọ́ tí àwọn mìíràn ń béèrè irú ìbéèrè wọ̀nyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nígbà tí wọn kò bá rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn—tí ìgbésí ayé wọn kò sì nítumọ̀ gidi—ibo ní wọ́n wá fẹ́ lọ? Wọ́n wá lè parí èrò sí pé díẹ̀ bíńtín báyìí ni ìgbésí ayé àwọn fi yàtọ̀ sí tàwọn ẹranko.—2 Pétérù 2:12.a
7, 8. Èé ṣe tí ìwádìí sáyẹ́ǹsì alára kò fi kúnjú òṣùwọ̀n?
7 Nípa báyìí, o lè wá mọ ìdí tí ẹnì kan bí ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ físíìsì Freeman Dyson fi lè kọ̀wé pé: “Kò ṣàjèjì bémi náà bá béèrè irú ìbéèrè tí Jóòbù béèrè nígbàanì, ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń béèrè bẹ́ẹ̀. Èé ṣe táa fi ń jìyà? Èé ṣe tí ayé fi kún fún àìṣòdodo? Kí ni ìrora àti ọ̀ràn ìbànújẹ́ wà fún?” (Jóòbù 3:20, 21; 10:2, 18; 21:7) Gẹ́gẹ́ báa ti sọ lẹ́ẹ̀kan, kàkà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ì bá fi tọ Ọlọ́run lọ, sáyẹ́ńsì ni wọ́n yíjú sí láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí. Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè, onímọ̀ nípa ẹ̀dá inú òkun, àti àwọn mìn-ín-ìn bẹ́ẹ̀ ń fi kún ìmọ̀ wa nípa àgbáyé àti ẹ̀dá tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ọ̀nà mí-ìn làwọn mìíràn tilẹ̀ tún darí ìwádìí tiwọn sí, àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà àti onímọ̀ nípa ohun àdánidá túbọ̀ ń kọ́ nípa oòrùn wa àti àwọn ọ̀wọ́ rẹ̀, kódà wọ́n tún ń kọ́ nípa àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó jìnnà réré. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 11:6.) Ìparí èrò tó bọ́gbọ́n mu wo ni irú àwọn ìwádìí bẹ́ẹ̀ yóò jálẹ̀ sí?
8 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé “èrò inú” Ọlọ́run tàbí “ọwọ́” rẹ̀ hàn lára àgbáálá ayé wa. Ṣùgbọ́n ṣé kì í ṣe pé àwọn yẹn ti ṣìnà? Ìwé ìròyìn Science ṣàkíyèsí pé: “Bí àwọn olùṣèwádìí bá ń sọ pé ìmọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ń bẹ nínú àgbáálá ayé fi ‘èrò inú’ Ọlọ́run hàn tàbí pé ‘ọwọ́’ Ọlọ́run hàn lára wọn, ohun tó ṣeé ṣe kó kéré jù lọ nínú àgbáálá ayé ni wọ́n ń sọ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—ìyẹn ni àwọn ohun táa lè fojú rí.” Àní, agbẹ̀bùn ẹ̀yẹ Nobel náà, tó tún jẹ́ ògbógi nínú ìmọ̀ físíìsì, Steven Weinberg, kọ̀wé pé: “Bó ṣe ń jọ pé a túbọ̀ ń lóye àgbáyé wa sí i, bẹ́ẹ̀ náà ló ń jọ pé kò ní ète kan táa fi dá a.”
9. Ẹ̀rí wo ló lè ran àwa àti àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá?
9 Síbẹ̀, o lè jẹ́ ọ̀kan lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ti fi taratara kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀ràn yìí, tí wọ́n sì ti lóye pé lájorí ìgbésí ayé ni pé ká mọ Ẹlẹ́dàá. Rántí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ pé: “Àwọn ènìyàn kò lè sọ pé àwọn kò mọ Ọlọ́run. Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn lè mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ohun tí Ó dá. Èyí fi agbára Rẹ̀ tí ó ń wà títí ayé hàn. Ó fi hàn pé Òun ni Ọlọ́run.” (Róòmù 1:20, Holy Bible, New Life Version) Òótọ́ ni, àwọn ohun kan wà nípa ayé wa àti nípa àwa fúnra wa tó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Ẹlẹ́dàá, kí wọ́n sì mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ lọ́dọ̀ rẹ̀. Jẹ́ ká gbé mẹ́ta nínú ohun wọ̀nyí yẹ̀ wò: àgbáyé wa, bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀, àti agbára ọpọlọ àwa fúnra wa.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Gbọ́
10. Èé ṣe tó fi yẹ ká ronú nípa “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀”? (Jẹ́nẹ́sísì 1:1; Sáàmù 111:10)
10 Báwo tiẹ̀ ni àgbáálá ayé wa ṣe déhìn-ín? Ó ṣeé ṣe kí àwọn ìròyìn nípa àwọn awò awọ̀nàjíjìn àti àwọn ẹ̀rọ tí ń tàtaré ìsọfúnni láti ojúde òfuurufú ti jẹ́ kóo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà pé ìgbà kan wà tí kò sí nǹkan tí ń jẹ́ àgbáálá ayé wa yìí rárá. Ó ní bó ṣe bẹ̀rẹ̀, ó sì ń gbòòrò sí i ni. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Gbọ́ ohun tí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, Ọlọ́lá Bernard Lovell sọ: “Bó bá jẹ́ pé nígbà kan láyé ọjọ́un, Àgbáálá Ayé wa yìí ṣù mọ́ra lọ́nà tó kéré jọjọ, táa fẹ́ẹ̀ lè fi wé ṣóńṣó orí abẹ́rẹ́, ó yẹ ká béèrè ìbéèrè nípa ohun tí ń bẹ níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ kó tó dìgbà yẹn. . . . Ọ̀ràn nípa ohun tó wà níbẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ni ohun táa gbọ́dọ̀ wá ìdáhùn sí.”
11. (a) Báwo ni àgbáálá ayé wa yìí ṣe tóbi tó? (b) Kí ni ìṣètò fínnífínní nínú àgbáálá ayé wa fi hàn?
11 Àwọn ohun tó para pọ̀ sínú àgbáálá ayé wa, tó fi mọ́ ilẹ̀ ayé wa fúnra rẹ̀, fi àgbàyanu ìṣètò fínnífínní hàn. Fún àpẹẹrẹ, ohun méjì tó yani lẹ́nu nípa oòrùn àti àwọn ìràwọ̀ yòókù tó wà lágbàáyé wa ni pé agbára ìmọ́lẹ̀ wọn kì í dín kù, kì í sì í rẹ̀ wọ́n. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìì, iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ táa fojú bù pé ó wà nínú àgbáálá ayé wa táa lè fojú rí jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta bílíọ̀nù [50,000,000,000] sí bílíọ̀nù márùnlélọ́gọ́fà [125,000,000,000]. Kẹ́ẹ sì wá wò ó o, ìràwọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ ló wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà táwa wà nínú rẹ̀ yìí o. Ẹ jẹ́ á gbàyí yẹ̀ wò ná: A mọ̀ pé ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ kan nílò iye epo àti atẹ́gùn kan pàtó kó tó lè ṣiṣẹ́. Ká ní o dá ọkọ̀ tìrẹ ní, ó lè gba mẹkáníìkì kan láti bá ọ tún ẹ́ńjìnnì rẹ̀ ṣe, kí ọkọ̀ náà baà lè rìn láìsí ìdádúró, kí iṣẹ́ rẹ̀ sì lè pé. Bí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ lásán bá ń béèrè pé kí a ṣètò nǹkan fínnífínní bẹ́ẹ̀, oòrùn wa “tó ń jó,” tí agbára ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kì í sì í dín kù ńkọ́? Kò sí àní-àní nígbà náà pé, àwọn ohun pàtàkì-pàtàkì tó jẹ mọ ìwàláàyè ni a ti ṣètò fínnífínní kí ìwàláàyè bàa lè ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Ṣé ìyẹn kàn ṣàdédé ṣẹlẹ̀ ni? A béèrè lọ́wọ́ Jóòbù láyé ọjọ́un pé: “Ṣé ìwọ lo gbé àwọn ìlànà tí ń darí àwọn ọ̀run, tàbí èyí tí ń pinnu òfin ìṣẹ̀dá lórí ilẹ̀ ayé kalẹ̀?” (Jóòbù 38:33, The New English Bible) Kò sí ẹ̀dá ènìyàn kankan tó tó bẹ́ẹ̀. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ibo ni ìṣètò fínnífínní náà ti wá?—Sáàmù 19:1.
12. Èé ṣe tí kò fi jẹ́ èrò òmùgọ̀ láti ronú pé Onílàákàyè tó gadabú kan ló dá àwọn nǹkan?
12 Ó ha lè jẹ́ láti ọ̀dọ̀ nǹkan tàbí láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí ojú ẹ̀dá ènìyàn kò lè rí? Fi ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà ló ti wá gbà báyìí pé àwọn arabaríbí ìṣẹ̀dá ń bẹ lọ́run—àwọn ihò ọ̀run tó ṣókùnkùn birimù-birimù. A kò lè fojú ìyójú rí àwọn ihò ọ̀run tó ṣókùnkùn birimù-birimù wọ̀nyí, síbẹ̀ àwọn ògbóǹkangí gbà pé wọ́n wà. Bákan náà, Bíbélì pàápàá ròyìn pé àwọn ẹ̀dá alágbára ńlá tí a kò lè fojú rí wà ní àwọn àgbègbè mìíràn—ìyẹn làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Bí irú àwọn ẹ̀dá alágbára ńlá, tí a kò lè fojú rí bẹ́ẹ̀ bá wà, kò ha jẹ́ ohun tó ṣeé gbà gbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Onílàákàyè tó gadabú kan ni ìṣètò fínnífínní tó fara hàn jákèjádò àgbáálá ayé wa ti wá bí?—Nehemáyà 9:6.
13, 14. (a) Kí ni ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gbé kalẹ̀ ní ti gidi nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀? (b) Kí ni ìwàláàyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé ń tọ́ka sí?
13 Ẹ̀rí kejì tó lè ranni lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá kan ń bẹ ni bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀. Láti ìgbà tí Louis Pasteur ti parí ìwádìí tirẹ̀ ni a ti gbà pé ìwàláàyè kò ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ lójijì. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀? Ní àwọn ọdún 1950, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbìyànjú láti fẹ̀rí tì í lẹ́yìn pé ìwàláàyè ti lè bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ nínú àwọn òkun ìgbàanì kan, nígbà tí mànàmáná máa ń fìgbà gbogbo kọ mànà lórí afẹ́fẹ́ tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹ̀rí tó jẹ yọ láìpẹ́ yìí fi hàn pé, irú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kò lè jóòótọ́, torí pé irú afẹ́fẹ́ bẹ́ẹ̀ kò fìgbà kan sí. Nítorí èyí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ń wá àlàyé mìíràn tí irọ́ rẹ̀ kò ní tètè ṣeé já. Ṣùgbọ́n ṣé kì í ṣe pé àwọn náà ti ṣìnà?
14 Lẹ́yìn tí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Ọlọ́lá Fred Hoyle ti fi ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún kẹ́kọ̀ọ́ nípa àgbáálá ayé àti ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀, ó sọ pé: “Dípò gbígbàgbọ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láti inú àwọn agbára ìṣẹ̀dá tó kéré jọjọ ni ìwàláàyè ti bẹ̀rẹ̀, ó kúkú sàn kí a gbà pé onílàákàyè kan ló mọ̀ọ́mọ̀ pilẹ̀ bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, báa bá ṣe túbọ̀ ń kọ́ nípa àwọn àgbàyanu ìwàláàyè tó, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò ṣe túbọ̀ máa rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ìwàláàyè wá láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ Onílàákàyè.—Jóòbù 33:4; Sáàmù 8:3, 4; 36:9; Ìṣe 17:28.
15. Èé ṣe táa fi lè sọ pé o yàtọ̀ pátápátá?
15 Nítorí náà ohun táa kọ́kọ́ ronú lé lórí ni àgbáyé wa, èkejì ni, bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Kíyè sí ẹ̀kẹta o—jíjẹ́ tí a jẹ́ ẹ̀dá ọ̀tọ̀. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni gbogbo ènìyàn fi jẹ́ ẹ̀dá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn túmọ̀ sí pé ẹ̀dá ọ̀tọ̀ nìwọ alára gan-an. Lọ́nà wo? Bóyá ìwọ náà ti gbọ́ táwọn kan ń fi ọpọlọ wé ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tí iṣẹ́ rẹ̀ ṣeni ní kàyéfì. Àmọ́ ṣá o, àwọn àwárí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìfiwéra yìí kù díẹ̀ káàtó. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀rọ ti Massachusetts wí pé: “A kò tilẹ̀ lè fi àwọn kọ̀ǹpútà òde òní wé ọmọ ọdún mẹ́rin ní ti agbára tí àwọn ọmọ wọ̀nyí ní láti ríran, láti sọ̀rọ̀, láti rìn, tàbí láti lo ọgbọ́n orí wọn. . . . A fojú bù ú pé gbogbo agbára tí kọ̀ǹpútà tí ọ̀nà ìṣiṣẹ́ rẹ̀ kàmàmà jù lọ ní, láti ṣiṣẹ́ lórí ìsọfúnni, kò ju ti ọpọlọ ìgbín—ìwọ̀n bíńtín nìyẹn jẹ́ táa bá fi wé àgbà kọ̀ǹpútà tí ń bẹ nínú agbárí [rẹ].”
16. Kí ni agbára tóo ní láti sọ èdè ń fi hàn?
16 Sísọ èdè tún jẹ́ agbára kan tí ọpọlọ rẹ fún ẹ. Àwọn kan ń sọ èdè méjì, mẹ́ta, àwọn mì-ín-ìn ń sọ jù bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ agbára àtisọ èdè kan ṣoṣo péré fi hàn pé ẹ̀dá ọ̀tọ̀ gbáà làwa èèyàn jẹ́. (Aísáyà 36:11; Ìṣe 21:37-40) Ọ̀jọ̀gbọ́n R. S. àti D. H. Fouts béèrè pé: “Ṣé èèyàn nìkan . . . ló lágbára àtisọ èdè ni? . . . Àwọn ẹranko yòókù tí wọ́n lọ́pọlọ pẹ̀lú ń bára wọn sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ . . . fífaraṣàpèjúwe, gbígbóòórùn, kíkígbe, híhan gooro àti kíkọrin, kódà àwọn oyin pàápàá ń bára wọn sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń fò lọ, fò bọ̀. Síbẹ̀, táa bá ti mú èèyàn kúrò, kò tún sí àwùjọ ẹ̀dá mìíràn tó ní èdè tí a ṣètò gírámà rẹ̀. Ohun mìíràn tó tún jọni lójú ni pé, àwọn ẹranko kò lè yàwòrán. Ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn lè ṣe kò ju pé kí wọ́n ya nǹkan gálagàla.” Ká sòótọ́, èèyàn nìkan ló lè lo ọpọlọ rẹ̀ láti sọ èdè, kó sì fi yàwòrán tó nítumọ̀.—Fi wé Aísáyà 8:1; 30:8; Lúùkù 1:3.
17. Ìyàtọ̀ pàtàkì wo ló wà láàárín ẹranko kan tó ń wo dígí àti èèyàn kan tó ń ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Ní àfikún sí i, o mọ irú ẹni tóo jẹ́; o mọ bóo ṣe rí. (Òwe 14:10) Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí ẹyẹ, ajà, tàbí ológbò, tó ń wo dígí, tó sì wá ń fẹnu ṣá a, tó tún ń kùn hùn-ùn mọ́ ọn, tàbí tó ń bá a jà? Ó rò pé ẹranko mìíràn lòún ń wò ni, kò mọ bóun ti rí. Àmọ́ wá wòyàtọ̀ o, nígbà tóo bá wo dígí, o mọ̀ pé ara rẹ lò ń rí. (Jákọ́bù 1:23, 24) O lè wo ìrísí rẹ tàbí kí o ṣe kàyéfì nípa bí wàá ṣe rí lọ́dún díẹ̀ sí i. Àwọn ẹranko kì í ṣèyẹn. Bẹ́ẹ̀ ni o, ọpọlọ rẹ mú kí o jẹ́ ẹ̀dá tó yàtọ̀ pátápátá. Ta ló wá yẹ ká fògo fún? Báwo ni ọpọlọ rẹ ṣe wáyé, bí kò bá jẹ́ láti ọwọ́ Ọlọ́run?
18. Àwọn agbára wo ni ọpọlọ rẹ ní tó mú ọ yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹranko?
18 Ọpọlọ rẹ tún ń jẹ́ kí o mọyì iṣẹ́ ọnà àti orin, ó sì ń jẹ́ kí o mọ ìwà tó tọ́. (Ẹ́kísódù 15:20; Àwọn Onídàájọ́ 11:34; 1 Àwọn Ọba 6:1, 29-35; Mátíù 11:16, 17) Èé ṣe tó fi jẹ́ pé ìwọ lo ní irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹranko kò ní? Ìdí ni pé kìkì ohun tí wọ́n nílò lójú ẹsẹ̀ ni wọ́n ń lo ọpọlọ tiwọn fún—ìyẹn ni wíwá ohun tí wọn yóò jẹ, wíwá akọ tàbí abo, tàbí kíkọ́ ìtẹ́. Èèyàn nìkan ló ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la. Àwọn kan tilẹ̀ ń ronú nípa bí ìgbésẹ̀ wọn yóò ṣe nípa lórí àyíká wọn tàbí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn lọ́jọ́ iwájú. Èé ṣe? Oníwàásù 3:11 sọ nípa ènìyàn pé: “Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni [Ẹlẹ́dàá] ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ gbáà lo ní láti lè ronú nípa ohun tí àkókò tí ó lọ kánrin tàbí ìyè àìlópin túmọ̀ sí.
Jẹ́ Kí Ẹlẹ́dàá Mú Kí Ayé Rẹ Nítumọ̀
19. Àwọn kókó mẹ́ta wo lo lè fi ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ronú nípa Ẹlẹ́dàá?
19 A ti jíròrò apá mẹ́ta péré: ìṣètò fínnífínní táa rí nínú àgbáálá ayé tó lọ salalu, bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àti òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro pé, ọpọlọ ènìyàn jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ pátápátá, táa bá ronú nípa onírúurú ohun táa lè fi ṣe. Kí ni àwọn ohun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn ń tọ́ka sí? Ọgbọ́n kan rèé tóo lè lò láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti dé orí ìparí èrò tó ṣe gúnmọ́. O lè kọ́kọ́ béèrè pé: Ǹjẹ́ àgbáálá ayé wa yìí ní ìbẹ̀rẹ̀? Ọ̀pọ̀ jù lọ ni yóò gbà pé ó ní. Wá béèrè pé: Ṣé ìbẹ̀rẹ̀ yẹn ṣàdédé ṣẹlẹ̀ ní, àbí a mú kó ṣẹlẹ̀? Ọ̀pọ̀ ni ìrònú wọn yóò sọ fún pé ṣe ni a mú kí ìbẹ̀rẹ̀ àgbáálá ayé wa ṣẹlẹ̀. Èyí ni yóò wá mú ìbéèrè tó kẹ́yìn wá pé: Ṣé nǹkan kan tó jẹ́ ayérayé ló ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àbí Ẹnì kan tó jẹ́ ẹni ayérayé? Pẹ̀lú báa ṣe gbé ọ̀ràn náà kalẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, tó sì bọ́gbọ́n mu, a lè mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ dórí ìparí èrò náà pé: Dájúdájú Ẹlẹ́dàá kan ń bẹ! Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kò ní ṣeé ṣe kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀?
20, 21. Èé ṣe tí mímọ Ẹlẹ́dàá fi ṣe pàtàkì báa bá fẹ́ kí ayé wa nítumọ̀?
20 Gbogbo ọjọ́ ayé wa, títí kan òye wa nípa ìwà rere àti ìwà rere fúnra rẹ̀ gbọ́dọ̀ ti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wá. Dókítà Rollo May kọ̀wé nígbà kan pé: “Kìkì ìlànà ìwà rere tó bọ́gbọ́n mu ni èyí tí a gbé ka orísun ìgbésí ayé tó nítumọ̀.” Ibo ni a ti lè ríyẹn? Ó ń bá a nìṣó pé: “Orísun náà ni Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Àwọn ìlànà Ọlọ́run ló ti ń darí ìgbésí ayé láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá títí tí ìṣẹ̀dá fi parí.”
21 Nígbà náà, a wá lè lóye ìdí tí onísáàmù náà fi fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ọgbọ́n hàn nígbà tó ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá náà pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Sáàmù 25:4, 5) Nígbà tí onísáàmù náà wá mọ Ẹlẹ́dàá náà dáadáa, ayé rẹ̀ túbọ̀ nítumọ̀, ó ní ète, ó sì wá ní ohun tí ń tọ́ ọ sọ́nà. Bẹ́ẹ̀ náà lo ṣe lè rí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.—Ẹ́kísódù 33:13.
22. Kí ló wé mọ́ mímọ àwọn ọ̀nà Ẹlẹ́dàá?
22 Mímọ “àwọn ọ̀nà” Ẹlẹ́dàá náà wé mọ́ títúbọ̀ mọ irú ẹni tí ó jẹ́, àwọn ìwà rẹ̀ àti ọ̀nà rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tó jẹ́ pé a kò lè rí Ẹlẹ́dàá, tí agbára rẹ̀ sí kún fún ẹ̀rù, báwo la ṣe lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n? Èyí ni àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò gbé yẹ̀ wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí Dókítà Viktor E. Frankl ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Nazi, ó ní: “Wíwá ìtumọ̀ ìgbésí ayé ni ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé ẹ̀dá, èyí sì yàtọ̀ pátápátá sí àìka ìjẹ́pàtàkì ìgbésí ayé sí,” gẹ́gẹ́ bó ti rí nínú ọ̀ràn àwọn ẹranko. Ó tún fi kún un pé, ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìwádìí kan táa ṣe ní ilẹ̀ Faransé “fi hàn pé ìpín mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn táa fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà pé ‘ìdí pàtàkì’ kan ń bẹ tí èèyàn fi wà láàyè.”
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí kò fi yẹ ká fi òye wa mọ sórí kìkì ìsọfúnni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa àgbáálá ayé wa?
◻ Láti lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa Ẹlẹ́dàá, kí lo lè tọ́ka sí?
◻ Èé ṣe tí mímọ Ẹlẹ́dàá fi jẹ́ àṣírí sí gbígbé ìgbé ayé tó kún fún ìtẹ́lọ́rùn, tó sì nítumọ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Kí Lèrò Rẹ Báyìí?
Àgbáálá Ayé Wa
↓ ↓
Kò ní Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ́ ní Ìbẹ̀rẹ̀
↓ ↓
Ṣàdédé Wà Jẹ́ Èyí Táa
Mú Kí Ọ́ Wà
↓ ↓
Nípasẹ̀ Ohun Nípasẹ̀ Ẹni Aayérayé
Ayérayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Títóbi àgbáálá ayé wa àti ìṣètò fínnífínní tó wà nínú rẹ̀ ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa ronú nípa Ẹlẹ́dàá
[Credit Line]
Ojú ìwé 15 àti 18: Jeff Hester (Arizona State University) and NASA