Mọ Irú Ẹni Tí Ẹlẹ́dàá Rẹ Jẹ́
“Èmi fúnra mi yóò mú kí gbogbo oore mi kọjá níwájú rẹ, èmi yóò sì polongo orúkọ Jèhófà níwájú rẹ.”—Ẹ́KÍSÓDÙ 33:19.
1. Èé ṣe tó fi yẹ ká bọlá fún Ẹlẹ́dàá?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Jòhánù, ẹni tó kọ ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, kọ ìkéde tó kún fún ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ nípa Ẹlẹ́dàá, ó lọ báyìí pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:11) Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní túbọ̀ ń fi kún ìdí tí a fi gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó dá gbogbo nǹkan.
2, 3. (a) Kí ló yẹ káwọn èèyàn kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá? (b) Èé ṣe tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti fẹ́ rí Ẹlẹ́dàá lójúkoojú?
2 Bó ṣe ṣe pàtàkì láti gbà pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló tún ṣe pàtàkì pé kí a mọ irú ẹni tó jẹ́—ká mọ̀ pé ẹni gidi ni, ẹni tó láwọn ìwà àti ọ̀nà tó jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ sún mọ́ ọn. Láìka bí o ṣe mọ̀ ọ́n tó sí, ǹjẹ́ kò ní ṣe ọ́ láǹfààní bóo bá túbọ̀ mọ̀ ọ́n dunjú? Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a óò lọ bá a, ká lè jọ fojú kojú, bí ìgbà tí a bá tọ ẹnì kan lọ torí pé a fẹ́ mọ̀ ọ́n.
3 Jèhófà ni Orísun àwọn ìràwọ̀ pàápàá, oòrùn tiwa yìí sì rèé, ìràwọ̀ alábọ́ọ́dé ló jẹ́ láwùjọ ìràwọ̀. Ǹjẹ́ wàá fẹ́ sún mọ́ oòrùn dáadáa, kóo lè wò ó láwòfín, kóo lè mọ bó ṣe rí gan-an? Àgbẹdọ̀! Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tiẹ̀ máa ń bẹ̀rù àtiwò ó fírí lásán, àwọn mìn-ín-ìn ń fòyà àtiwà nínú ẹ̀ fúngbà pípẹ́ nítorí agbára ìtànṣán rẹ̀ tó pọ̀ jọjọ. Inú rẹ̀ lọ́hùn-ún máa ń gbóná tó nǹkan bí ìwọ̀n mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000,000] lórí ìwọ̀n Celsius (27,000,000°F.). Ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́rin tọ́ọ̀nù àwọn ìṣùjọ ni ààrò tó gbóná girigiri yìí ń sọ di ooru gbígbóná janjan. Ìwọ̀nba táṣẹ́rẹ́ nínú ooru gbígbóná janjan yìí ló ń dé orí ilẹ̀ ayé níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí ooru àti ìmọ́lẹ̀, síbẹ̀, ìwọ̀nba yẹn náà lo so ìwàláàyè ró níhìn-ín. Àwọn kókó pàtàkì wọ̀nyí yẹ kó yé wa yéké pé, agbára Ẹlẹ́dàá tóó bẹ̀rù. Abájọ tí Aísáyà fi kọ̀wé nípa “ọ̀pọ̀ yanturu okun [Ẹlẹ́dàá] alágbára gíga, àti . . . pé òun ní okun inú nínú agbára.”—Aísáyà 40:26.
4. Kí ni Mósè béèrè fún, báwo sì ni Jèhófà ṣe dáhùn?
4 Síbẹ̀, ǹjẹ́ o mọ̀ pé lẹ́yìn oṣù díẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi Íjíbítì sílẹ̀ lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, Mósè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá náà pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n rí ògo rẹ.” (Ẹ́kísódù 33:18) Tóo bá rántí pé Ọlọ́run ni Orísun oòrùn alára, ó yẹ kóo mọ ìdí tó fi fún Mósè lésì pé: “Ìwọ kò lè rí ojú mi, nítorí pé kò sí ènìyàn tí ó lè rí mi kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.” Ẹlẹ́dàá gbà kí Mósè fara pa mọ́ síbì kan ní Òkè Sínáì nígbà tí Òun bá ń “kọjá.” Nípa bẹ́ẹ̀, kí a sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe, Mósè rí “ẹ̀yìn” Ọlọ́run, nǹkan táa lè fi wé ìkọmànà ògo Ẹlẹ́dàá, tàbí ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dàá wà níbẹ̀.—Ẹ́kísódù 33:20-23; Jòhánù 1:18.
5. Ọ̀nà wo ni Ẹlẹ́dàá náà gbà dáhùn ohun tí Mósè bẹ̀bẹ̀ fún, ẹ̀rí wo sì ni ìyẹn jẹ́?
5 A kò paná ìfẹ́ tí Mósè ní fún mímọ Ẹlẹ́dàá náà dunjú. Ọlọ́run kọjá níwájú Mósè, ó sì hàn gbangba pé nípasẹ̀ áńgẹ́lì kan ló fi bá Móse sọ̀rọ̀, nígbà tó polongo pé: “Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, ṣùgbọ́n lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Èyí fi hàn pé mímọ Ẹlẹ́dàá wa dunjú kì í ṣe ọ̀ràn rírí i sójú, ká mọ bó ṣe rí gan-an, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí níní òye kíkún nípa irú ẹni tó jẹ́, ká mọ àwọn ìwà àti ànímọ́ tó ní.
6. Ọ̀nà wo ni agbára ìdènà àrùn ara wa gbà jẹ́ àgbàyanu?
6 Ọ̀nà kan táa lè gbà ṣe èyí ni nípa fífòyemọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run láti inú àwọn ohun tó dá. Ronú nípa agbára ìdènà àrùn ara rẹ. Nígbà tí ìwé ìròyìn náà, Scientific American, ń sọ̀rọ̀ lórí agbára ìdènà àrùn ara, ó wí pé: “Láti ìgbà táa bá ti bí ẹnì kan títí di ìgbà tí onítọ̀hùn yóò fi kú, agbára ìdènà àrùn ara rẹ̀ kò jẹ́ dáwọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dúró. Ọ̀kẹ́ àìmọye onírúurú èròjà ohun tín-íntìn-ìntín àti sẹ́ẹ̀lì . . . ló ń gbà wá lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àrùn. Ká ní kò lọ sírú àwọn ohun tí ń dáàbò boni bẹ́ẹ̀ ni, èèyàn kò ní lè wà láàyè.” Ibo ni ètò yìí ti wá? Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn yẹn wí pé: “Ọ̀kẹ́ àìmọye àgbàyanu sẹ́ẹ̀lì tí ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lọ́nà jíjáfáfá, tí ń dáàbò bo ara lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àrùn aṣejàǹbá, wá láti inú àwọn sẹ́ẹ̀lì díẹ̀ tó ń kọ́kọ́ jáde sínú ara, àwọn tí ń kọ́kọ́ fara hàn ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́sàn-án lẹ́yìn ìlóyún.” Bí obìnrin kan bá ti lóyún, yóò tàtaré agbára ìdènà àrùn sára ọlẹ̀ tí ń dàgbà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, nígbà tó bá ń fọ́mọ rẹ̀ lọ́mú, ó tún ń pèsè àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ń dènà àrùn àti àwọn èròjà tó ń ṣara lóore fún ọmọ jòjòló náà.
7. Kí la lè ronú lé lórí nípa agbára ìdènà àrùn ara wa, ìparí èrò wo ló sì lè mú kí a dé?
7 A kò lè bá ọ jiyàn rẹ̀ rárá tóo bá parí èrò sí pé agbára ìdènà àrùn ara rẹ̀ kò ṣeé fi wé ohunkóhun tí ìmọ̀ ìṣègùn òde òní lè pèsè. Nítorí náà, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni èyí ń sọ fún wa nípa Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti Olùpèsè rẹ̀?’ Ká sòótọ́, ìṣètò yìí, tó jẹ́ pé ‘nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́sàn-án lẹ́yìn ìlóyún ló kọ́kọ́ fara hàn,’ tó sì ti lè dáàbò bo ọmọ táa ṣẹ̀ṣẹ̀ bí fi ọgbọ́n àti òye hàn. Ṣùgbọ́n, ohun mìíràn ha wà tí a tún lè lóye nípa Ẹlẹ́dàá náà láti inú ìṣètò yìí bí? Kí ni púpọ̀ nínú wa ń sọ nípa Albert Schweitzer àti àwọn mìíràn tí wọ́n lo ìgbésí ayé wọn fún pípèsè ìtọ́jú ìṣègùn fún àwọn òtòṣì? A sábà máa ń sọ pé irú àwọn afẹ́dàáfẹ́re bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹniire. Bákan náà, kí la lè sọ nípa Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tó pèsè agbára ìdènà àrùn ara fún àtolówó àti tálákà? Ó hàn gbangba pé, onífẹ̀ẹ́ ni, ẹni tí kì í ṣojúsàájú ni, oníyọ̀ọ́nú ni, aláìṣègbè sì ni. Ǹjẹ́ èyí ò bá ọ̀nà tí Mósè gbọ́ táa gbà ṣàpèjúwe Ẹlẹ́dàá náà mu?
Ó Jẹ́ Ká Mọ Irú Ẹni Tí Òun Jẹ́
8. Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ wo ni Jèhófà gbà fi ara rẹ̀ hàn fún wa?
8 Àmọ́ ṣá o, ọ̀nà mìíràn tún wa táa lè fi mọ Ẹlẹ́dàá wa dunjú—ìyẹn ni nípasẹ̀ Bíbélì. Èyí ṣe pàtàkì gan-an o, torí pé àwọn nǹkan kan wà nípa rẹ̀ tí sáyẹ́ǹsì àti àgbáálá ayé wa kò lè fi hàn rárá, ọ̀pọ̀ ohun mìíràn ló sì wà tí Bíbélì túbọ̀ mú ṣe kedere. Ọ̀kan lára ohun tí Bíbélì mú ṣe kedere ni orúkọ Ẹlẹ́dàá. Bíbélì nìkan ló jẹ́ ká mọ orúkọ Ẹlẹ́dàá àti bó ti ṣe pàtàkì tó. Nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó jẹ́ ti Bíbélì lédè Hébérù, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] ìgbà ni orúkọ rẹ̀ fara hàn gẹ́gẹ́ bíi kọ́ńsónáńtì mẹ́rin tí a lè yí padà sí YHWH tàbí JHVH, èyí tí a sábà máa ń pè ní Jèhófà lédè Yorùbá.—Ẹ́kísódù 3:15; 6:3.
9. Kí ni orúkọ Ẹlẹ́dàá náà gan-an túmọ̀ sí, ìparí èrò wo sì ni a lè dé nípa èyí?
9 Báa bá fẹ́ mọ Ẹlẹ́dàá náà dunjú, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé òun kì í kàn ṣe “Ọba Tó Dá Wà”, tí orùkọ rẹ̀ ṣòro láti lóye, kì í sì í ṣe “Èmi Ni” tí ìtumọ̀ rẹ̀ rúni lójú. Orúkọ rẹ̀ gan-an fi hàn bẹ́ẹ̀. Orúkọ náà jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù kan tó túmọ̀ sí “di” tàbí “mú kí ó di.”a (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 27:29; Oníwàásù 11:3) Orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di,” ó fi hàn ní pàtàkì pé ó ń pète, ó sì ń gbégbèésẹ̀. Nípa mímọ orúkọ rẹ̀ àti lílò ó, a lè túbọ̀ wá mọ̀ pé bó ti ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, bẹ́ẹ̀ ló ń mú ète rẹ̀ ṣẹ.
10. Kí ni ìjìnlẹ̀ òye pàtàkì tí a lè jèrè láti inú àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì?
10 Bíbélì ni orísun táa ti lè mọ àwọn ète Ọlọ́run àti ìwà rẹ̀. Àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì fi hàn pé, nígbà kan rí, aráyé wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n sì ní ìrètí pípẹ́ láyé, kí wọ́n sì ní ìgbésí ayé tó nítumọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:7-9) Ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò fòpin sí ìjiyà àti hílàhílo tí ènìyàn ti kó sí tipẹ́tipẹ́ yìí. A kà nípa mímú ète rẹ̀ ṣẹ pé: “A tẹ ayé tí a lè fojú rí lórí ba fún ìjákulẹ̀, kì í ṣe nípa ìfẹ́-ọkàn òun alára, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìfẹ́ Ẹlẹ́dàá, ẹni tí ó jẹ́ pé nípa mímú kí ó rí bẹ́ẹ̀, ó fún un ní ìrètí pé ní ọjọ́ kan òun lè jẹ́ . . . kí ó nípìn-ín nínú òmìnira àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:20, 21, The New Testament Letters, láti ọwọ́ J. W. C. Wand.
11. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa ronú lórí àwọn ìtàn Bíbélì, kí sì ni kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀kan nínú irú ìtàn bẹ́ẹ̀?
11 Bíbélì tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Ẹlẹ́dàá wa dunjú ní ti pé ó jẹ́ ká mọ àwọn ìgbésẹ̀ àti ìṣarasíhùwà rẹ̀ nígbà tó ń bá Ísírẹ́lì ìgbàanì lò. Ronú nípa àpẹẹrẹ kan tó wáyé láàárín Èlíṣà àti Náámánì olórí àwọn ọmọ ogun Síríà tó mú gbogbo ayé lọ́tàá. Bóo ti ń ka ìtàn yìí nínú 2 Àwọn Ọba orí karùn-ún, wàá rí i pé ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan tí a kó nígbèkùn ló jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé nípasẹ̀ ìrànwọ́ Èlíṣà tó ń gbé ní Ísírẹ́lì, ẹ̀tẹ̀ Náámánì lè sàn. Ni Náámánì bá gbéra ó dibẹ̀, ó ń retí pé kí Èlíṣà bẹ̀rẹ̀ sí juwọ́ sófuururú bí ìgbà téèyàn bá fẹ́ pidán. Kàkà bẹ́ẹ̀, Èlíṣà sọ fún ará Síríà náà pé kó lọ wẹ̀ nínú Odò Jọ́dánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló rọ̀ ọ́ kó tó gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà tó ṣe ohun táa ní kó ṣe, a mú un lára dá. Ni Náámánì bá lọ kó àwọn ẹ̀bùn olówó iyebíye fún Èlíṣà, àmọ́ kò gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ìránṣẹ́ Èlíṣà yọ́lẹ̀ lọ bá Náámánì, ó sì firọ́ gba àwọn ohun olówó iyebíye lọ́wọ́ rẹ̀. Ìwà màkàrúúrù tó hù yìí ló jẹ́ kí a fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú. Ìtàn kan tó ṣeni láàánú lèyí, ọ̀kan tó lè ṣẹlẹ̀ sẹ́nikẹ́ni tí kò bá kíyè sára—ìtàn kan tí ẹ̀kọ́ pọ̀ nínú ẹ̀ táa lè kọ́.
12. Ìparí èrò wo nípa Ẹlẹ́dàá ni a lè dé táa bá ronú lórí ìtàn Èlíṣà àti Náámánì?
12 Ìtàn náà, lọ́nà tó fani lọ́kàn mọ́ra, fi hàn pé Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá àgbáyé kò gbé ara rẹ̀ ga débi tí kò fi lè fojúure wo ọmọdébìnrin pín-níṣín kan, èyí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó wọ́pọ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí. Ó tún fi hàn pé Ẹlẹ́dàá náà kò gbà pé ẹ̀yà kan tàbí orílẹ̀-èdè kan lọ́lá ju èkejì lọ. (Ìṣe 10:34, 35) Ohun mìíràn tó tún dùn mọ́ni ni pé, dípò ríretí kí àwọn èèyàn lo awúrúju—èyí tó wọ́pọ̀ lọ́dọ̀ “àwọn oníwòsàn” kan láyé àtijọ́ àti lóde ìwòyí—Ẹlẹ́dàá fi àgbàyanu ọgbọ́n hàn. Ó mọ bó ṣe lè wo àrùn ẹ̀tẹ̀ sàn. Ó tún fi ìjìnlẹ̀ òye àti ìdájọ́ òdodo hàn nípa pé kò gba kí ìwà màkàrúúrù kẹ́sẹ járí. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ǹjẹ́ ìyẹn kò bá ìwà Jèhófà tí Mósè gbọ́ nípa rẹ̀ mu? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn Bíbélì yẹn ṣe ṣókí, ẹ wo bí ẹ̀kọ́ táa lè rí kọ́ nínú rẹ̀ nípa irú ẹni tí Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ ti pọ̀ tó!—Sáàmù 33:5; 37:28.
13. Ṣàkàwé bí a ṣe lè rí ẹ̀kọ́ àkàkọ́gbọ́n láti inú àwọn ìtàn Bíbélì?
13 Àwọn ìtàn mìíràn nípa ìwà àìmoore tí Ísírẹ́lì hù àti ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wọn fi hàn pé lóòótọ́, Jèhófà bìkítà nípa ẹ̀dá. Bíbélì sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dán an wò léraléra, wọ́n mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ó dùn ún. (Sáàmù 78:40, 41) Èyí fi hàn pé, Ẹlẹ́dàá náà ní ìmọ̀lára, ó sì bìkítà nípa ohun tí àwọn èèyàn ń ṣe. Ẹ̀kọ́ pọ̀ jàra táa lè rí kọ́ pẹ̀lú, láti inú ìtàn àwọn kan táa mọ̀ bí ẹní mowó. Nígbà tí a yan Dáfídì láti di ọba Ísírẹ́lì, Ọlọ́run sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Bẹ́ẹ̀ ni, irú ẹni táa jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ni Ẹlẹ́dàá ń wò, kì í ṣe ìrísí wa lásán. Ìyẹn mà dùn mọ́ni gan-an o!
14. Bí a ti ń ka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kí la lè ṣe, tí yóò sì jẹ́ àǹfààní fún wa?
14 Mọ́kàndínlógójì nínú ìwé Bíbélì ni a ti kọ ṣáájú ká tó bí Jésù, ó sì ṣe pàtàkì pé kí a máa kà wọ́n. Èyí kò wulẹ̀ ní jẹ́ kíkà lásán láti mọ àwọn àkọsílẹ̀ tàbí ìtàn Bíbélì. Báa bá fẹ́ mọ irú ẹni tí Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ lóòótọ́, a óò ṣàṣàrò lórí àwọn ìtàn wọ̀nyí, a tilẹ̀ lè ronú lé wọn lórí pé, ‘Kí tiẹ̀ ni ìtàn yìí fẹ́ kí n mọ̀ nípa ìwà rẹ̀? Èwo nínú àwọn ànímọ́ rẹ̀ gan-an la gbé yọ níhìn-ín?’b Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ran àwọn oníyèméjì pàápàá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, èyí yóò sì jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ṣíṣeé ṣe fún wọn láti mọ Òǹṣèwé náà dunjú, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀dá.
Olùkọ́ Ńlá Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Mọ Ẹlẹ́dàá
15. Èé ṣe tí àwọn ìgbésẹ̀ àti ẹ̀kọ́ Jésù fi kún fún ìtọ́ni?
15 Òótọ́ náà pé àwọn tí ń ṣiyè méjì pé Ẹlẹ́dàá wà tàbí àwọn tí kò mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi kò mọ ohun púpọ̀ nípa Bíbélì kì í ṣe ohun táa lè máa jiyàn lé lórí. Ó ṣeé ṣe kí o ti pàdé àwọn kan tí wọn ò mọ̀ ẹni tó kọ́kọ́ gbáyé nínú Mósè àti Mátíù, tí wọn kò sì mọ ohunkóhun nípa ìṣe tàbí ẹ̀kọ́ Jésù. Ìyẹn mà báni nínú jẹ́ o, torí pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá náà lèèyàn lè rí kọ́ lára Olùkọ́ Ńlá náà, Jésù. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́, ó lè jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ẹlẹ́dàá wa jẹ́. (Jòhánù 1:18; 2 Kọ́ríńtì 4:6; Hébérù 1:3) Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Àní, ó tilẹ̀ sọ nígbà kan pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòhánù 14:9.
16. Kí ni ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó wáyé láàárín Jésù àti obìnrin ará Samáríà ṣàkàwé?
16 Gbé àpẹẹrẹ yìí yẹ̀ wò. Nígbà kan tí ó rẹ Jésù lẹ́nu ìrìn àjò, ó bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ lẹ́bàá Síkárì. Ó bá a sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ tó jinlẹ̀, èyí tó dá lórí ìjẹ́pàtàkì ‘jíjọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.’ Àwọn Júù ìgbà yẹn sì rèé, wọn kì í báwọn ará Samáríà da nǹkan pọ̀. Láìdàbí àwọn wọ̀nyí, Jésù fi hàn pé Jèhófà ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba tọkùnrin tobìnrin tó bá jẹ́ olóòótọ́ ọkàn láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lè wá sí, pàápàá gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn Èlíṣà àti Náámánì ti fi hàn. Èyí yẹ kó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà kò fọwọ́ sí ẹ̀mí ẹ̀tanú ẹ̀sìn, ẹ̀mí tí kò gba ti ẹlòmíràn rò, èyí tó gbayé kan lónìí. A tún lè kíyè sí kókó náà pé Jésù fẹ́ kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́, obìnrin táa sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí o, ọ̀dọ̀ ọkùnrin mìíràn tí kì í ṣe ọkọ rẹ̀ ló ń gbé. Kàkà tí Jésù yóò fi kà á sí èèyànkéèyàn, ó fi ọ̀wọ̀ tirẹ̀ wọ̀ ọ́, ó hùwà lọ́nà tí yóò fi lè ràn án lọ́wọ́. Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Samáríà mìíràn tẹ́tí sí Jésù, ohun tí wọ́n sì parí èrò wọn sí ni pé: “A . . . mọ̀ pé ọkùnrin yìí dájúdájú ni olùgbàlà ayé.”—Jòhánù 4:2-30, 39-42; 1 Ọba 8:41-43; Mátíù 9:10-13.
17. Ìparí èrò wo ni ìtàn àjíǹde Lásárù tọ́ka sí?
17 Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àkàwé mìíràn nípa báa ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá, nípa mímọ àwọn ìgbésẹ̀ àti ẹ̀kọ́ Jésù dáadáa. Jọ̀wọ́ ronú lórí àkókò tí Lásárù, ọ̀rẹ́ Jésù, ṣaláìsí. Ṣáájú àkókò yìí, Jésù ti fi agbára tí ó ní láti láti sọ òkú di alààyè hàn. (Lúùkù 7:11-17; 8:40-56) Ṣùgbọ́n, báwo ló ṣe ṣe nígbà tó rí Màríà, arábìnrin Lásárù, tó ń ṣọ̀fọ̀? Jésù “kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú.” Kò ṣe bí ẹni tọ́ràn náà ò kàn rárá, kó sọ pé òun fẹ́ ṣe bí ọkùnrin; ṣùgbọ́n ó “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” (Jòhánù 11:33-35) Èyí kì í ṣe ojú ayé lásán. A sún Jésù láti hùwà rere—ó jí Lásárù dìde. O lè ronú nípa bí èyí ṣe ran àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́ láti lóye ìmọ̀lára Ẹlẹ́dàá àti àwọn ìwà rẹ̀. Ó yẹ kí ó ràn àwa pẹ̀lú lọ́wọ́ àti àwọn ẹlòmíràn láti mọ ìwà àti àwọn ọ̀nà Ẹlẹ́dàá.
18. Ojú ìwòye wo ló yẹ káwọn èèyàn ní nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
18 Kò sídìí kankan tí a fi ní láti máa tijú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti kíkọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa. Bíbélì kì í ṣe ìwé tí kò bá ìgbà mu mọ́. Jòhánù jẹ́ ẹnì kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, tí ó sì di alábàáṣiṣẹ́ Jésù. Ó kọ̀wé lẹ́yìn ìgbà náà pé: “A mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ti wá, ó sì ti fún wa ní agbára ìmòye kí a lè jèrè ìmọ̀ nípa ẹni tòótọ́ náà. A sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹni tòótọ́ náà, nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi. Èyí ni Ọlọ́run tòótọ́ náà àti ìyè àìnípẹ̀kun.” (1 Jòhánù 5:20) Ṣàkíyèsí pé lílo “agbára ìmòye” láti jèrè ìmọ̀ nípa “ẹni tòótọ́ náà,” ìyẹn ni Ẹlẹ́dàá, lè yọrí sí “ìyè àìnípẹ̀kun.”
Báwo Lo Ṣe Lè Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Rẹ̀?
19. Ìgbésẹ̀ wo la ti gbé láti ran àwọn oníyèméjì lọ́wọ́?
19 Ó ń béèrè iṣẹ́ takuntakun kí àwọn kan tó lè gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá oníyọ̀ọ́nú kan ń bẹ, ẹni tó bìkítà nípa wa, ó sì tún ń béèrè irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó lè mọ irú ẹni tó jẹ́. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ṣì wà tí wọ́n ń ṣiyè méjì nípa Ẹlẹ́dàá tàbí tí ojú ìwòye wọn nípa rẹ̀ kò bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu. Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè àti ti àgbáyé tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lọ́dún 1998 sí 1999, a mú irin iṣẹ́ tuntun kan tó gbéṣẹ́ jáde ní ọ̀pọ̀ èdè—ìyẹn ni ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You?
20, 21. (a) Báwo ni a ṣe lè lo ìwé náà, Creator, lọ́nà tí yóò kẹ́sẹ járí? (b) Sọ ìrírí nípa bí ìwé Creator ti ṣe jẹ́ ìwé to gbéṣẹ́.
20 Ó jẹ́ ìwé kan tí yóò gbé ìgbàgbọ́ rẹ ró nínú Ẹlẹ́dàá wa, tí yóò sì jẹ́ kí o túbọ̀ mọ ìwà àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. Èé ṣe tí èyí fi dá wa lójú? Nítorí pé, ète bẹ́ẹ̀ la ní lọ́kàn táa fi ṣe ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You? jáde. Kókó kan tó jẹ yọ jálẹ̀ ìwé náà ni, “Kí ló lè túbọ̀ jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀?” A gbé àwọn kókó inú rẹ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó jẹ́ pé àwọn èèyàn tí wọ́n kàwé púpọ̀ pàápàá lè gbádùn ẹ̀. Síbẹ̀, ó sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí púpọ̀ nínú wa ń yán hànhàn láti mọ̀. Ọ̀rọ̀ tó lè fa àwọn tó ń kọminú nípa pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ mọ́ra wà nínú rẹ̀, wọ́n á gbádùn ẹ̀, ó sì lè yí èrò wọn padà. Ìwé náà kò wulẹ̀ gbà pé òǹkàwé náà ti gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ. Ọ̀nà táa gbà jíròrò àwọn àwárí àti èròǹgbà ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ́ọ́lọ́ọ́ yóò fa àwọn oníyèméjì lọ́kàn mọ́ra. Irú àwọn kókó bẹ́ẹ̀ pàápàá yóò fún ìgbàgbọ́ àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ pàápàá lókun.
21 Nígbà tóo bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé tuntun yìí, wàá rí i pé àwọn apá kan nínú rẹ̀ ṣàlàyé àkópọ̀ ìtàn Bíbélì lọ́nà tó gbé àwọn ìwà Ọlọ́run yọ, èyí tó lè ran àwọn òǹkàwé lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run dunjú. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti kà á ló ti sọ nípa bí kókó yẹn ṣe jóòótọ́ tó nínú ìgbésí ayé wọn. (Wo àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, ní ojú ìwé 25 sí 26.) Ǹjẹ́ kí ọ̀ràn tìrẹ náà rí bẹ́ẹ̀ bóo ti ń ka ìwé náà, tí o sì n lò ó láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ Ẹlẹ́dàá wọn lámọ̀dunjú.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, onísìn Jesuit nì, M. J. Gruenthaner, nígbà tó jẹ́ olóòtú àgbà fún ìwé ìròyìn náà, The Catholic Biblical Quarterly, sọ ohun kan náà tó ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ iṣe tó jẹ́ irú rẹ̀ pé “kò fìgbà kan túmọ̀ sí ẹni tí kò ṣeé lóye ṣùgbọ́n a sábà máa ń lò ó fún ẹni tó ṣeé lóye, ìyẹn ni ẹni tó fi ara rẹ̀ hàn kedere.”
b Báwọn òbí ti ń sọ ìtàn Bíbélì fáwọn ọmọ wọn, wọn lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa mímú irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn jáde. Àwọn èwe lè tipa báyìí mọ Ọlọ́run dunjú, kí wọ́n sì kọ́ báa ti í ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ǹjẹ́ O Kíyè Sí I?
◻ Báwo ni Mósè ṣe mọ Jèhófà dunjú lórí Òkè Sínáì?
◻ Èé ṣe tí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi jẹ́ àrànṣe fún mímọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́?
◻ Bí a ti ń ka Bíbélì, kí la lè ṣe láti lè sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa tímọ́tímọ́?
◻ Ọ̀nà wo lo wéwèé láti gbà lo ìwé Creator?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Kí ni agbára ìdènà àrùn ara wa ń sọ nípa Ẹlẹ́dàá wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Abala kan nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, tó fi Tetragrammaton (Orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù) hàn
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínuure Shrine of the Book, Israel Museum, Jerusalem
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nípa ìṣarasíhùwà Jèsú nígbà tó rí pé Màríà wà nínú ìbànújẹ́?