Ẹ̀KỌ́ 51
Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan
Ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan wà nílẹ̀ Síríà, ibẹ̀ sì jìnnà gan-an sílùú ẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Síríà ni wọ́n mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ìránṣẹ́ ìyàwó ọ̀gágun kan tó ń jẹ́ Náámánì. Jèhófà ni ọmọbìnrin yìí ń jọ́sìn bó tiẹ̀ jẹ́ pé abọ̀rìṣà làwọn tó yí i kà.
Náámánì ní àìsàn burúkú kan tó máa ń jẹ́ kí ara ro ó. Ó sì wu ọmọbìnrin yìí pé kóun ran Náámánì lọ́wọ́. Ó wá sọ fún ìyàwó Náámánì pé: ‘Mo mọ ẹnì kan tó lè ran ọkọ yín lọ́wọ́. Ilẹ̀ Ísírẹ́lì lẹni náà wà, wòlíì Jèhófà ni, Èlíṣà sì lorúkọ ẹ̀. Ó lè wo ọkọ yín sàn.’
Nígbà tí ìyàwó Náámánì sọ̀rọ̀ ọmọbìnrin yìí fún Náámánì, ó gbà pé òun á lọ bá Èlíṣà ní Ísírẹ́lì. Náámánì rò pé tóun bá dé Ísírẹ́lì, ńṣe ni Èlíṣà máa ṣe òun bí èèyàn pàtàkì. Àmọ́ Èlíṣà ò tiẹ̀ yọjú sí Náámánì rárá, ìránṣẹ́ ẹ̀ ló rán sí i. Ó ní kó lọ pàdé Náámánì, kó sì sọ fún un pé: ‘Lọ wẹ̀ nínú Odò Jọ́dánì nígbà méje, àìsàn ẹ sì máa lọ.’
Ọ̀rọ̀ yìí bí Náámánì nínú gan-an. Ló bá ní: ‘Mo rò pé ńṣe ni wòlíì yìí á gbàdúrà fún mi táá gbọ́wọ́ lé mi lórí, tára mi á sì yá. Ó wá ń sọ pé kí n lọ wẹ̀ lódò kan ní Ísírẹ́lì. Ṣèbí a ní odò tó dáa jùyẹn lọ ní Síríà, kí ló dé tí ò lè sọ pé kí n lọ wẹ̀ níbẹ̀?’ Inú bí Náámánì gan-an débi pé ńṣe ló fìbínú kúrò nílé Èlíṣà.
Ni àwọn ìránṣẹ́ Náámánì bá sọ ohun tó mú kó tún ọ̀rọ̀ náà rò. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ohun tí wòlíì yẹn sọ ló máa mú yín lára dá, ṣé kò ní dáa kẹ́ ẹ ṣe é? Ohun tí wòlíì yìí sì ní kẹ́ ẹ ṣe ò le rárá, á dáa kẹ́ ẹ ṣe é.’ Náámánì fetí sí wọn. Ó lọ sí Odò Jọ́dánì, ó sì wẹ̀ níbẹ̀ nígbà méje. Nígbà tí Náámánì fi máa jáde nínú odò nígbà keje, àìsàn tó ń ṣe é ti lọ. Inú ẹ̀ dùn gan-an, ó sì pa dà lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ Èlíṣà. Náámánì sọ pé: ‘Mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Báwo ló ṣe máa rí lára ọmọbìnrin Ísírẹ́lì yẹn nígbà tó rí i pé ara Náámánì ti yá?
“Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ jòjòló lo ti mú kí ìyìn jáde.”—Mátíù 21:16