ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/15 ojú ìwé 8-9
  • Ọmọbìnrin Kékeré Kan Tí Ó Fìgboyà Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọmọbìnrin Kékeré Kan Tí Ó Fìgboyà Sọ̀rọ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgboyà Láti Sọ̀rọ̀ Jáde
  • Wíwo Naamani Sàn
  • Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
  • Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkọ Ọ̀gá Rẹ̀ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ó Kọ́kọ́ Ṣàìgbọràn àmọ́ Nígbà Tó Yá Ó Ṣègbọràn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkùnrin Alágbára Kan Lọ́wọ́
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/15 ojú ìwé 8-9

Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jehofa

Ọmọbìnrin Kékeré Kan Tí Ó Fìgboyà Sọ̀rọ̀

NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹwàá ṣááju Sànmánì Tiwa, àjọṣepọ̀ láàárín Israeli àti Siria kò dán mọ́rán. Ìjà ń bẹ́ sílẹ̀ nígbà gbogbo débi pé nígbà tí ọdún mẹ́ta bá kọjá láìsí ìwà ipá, ìtàn tí ó gbàfiyèsí ni ó máa ń dà.—1 Awọn Ọba 22:1.

Ohun tí ń dáyà foni ní pàtàkì ní àwọn àkókò wọ̀nyẹn ni àwọn agbo onísùnmọ̀mí ti Siria, díẹ̀ nínú wọn tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọmọ ogun. Àwọn jagunjagun wọ̀nyí máa ń kọlu àwọn ọmọ Israeli, wọ́n sì máa ń jà wọ́n lólè, ní jíjí ọ̀pọ̀ gbé, àti ní kíkó ọ̀pọ̀ lẹ́rú—àní àwọn ọmọdé pàápàá.

Nígbà ìkọlù kan, “ọmọbìnrin kékeré kan” ní a fi àìláàánú gbé lọ kúrò lọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀ tí ó ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. (2 Awọn Ọba 5:2) Lẹ́yìn tí a mú un dé Siria, a mú un lápàpàǹdodo láti gbé láàárín àwọn tí wọ́n ti lè máa bà á lẹ́rù, tí wọ́n sì ṣàjèjì—àwọn ènìyàn tí ń jọ́sìn oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀, igi, ewéko, àti òkúta pàápàá. Ẹ wo bí wọ́n ti yàtọ̀ tó sí ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń jọ́sìn Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo náà, Jehofa! Ṣùgbọ́n, ní àyíká tí ó ṣàjèjì yìí pàápàá, ọmọbìnrin yìí fi ìgboyà títayọ lọ́lá hàn nípa ìjọsìn Jehofa. Ní ìyọrísí rẹ̀, ó yí ìgbésí ayé gbajúgbajà ìjòyè òṣìṣẹ́ kan tí ń ṣiṣẹ́ sìn lábẹ́ ọba Siria padà. Jẹ́ kí a wo bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀.

Ìgboyà Láti Sọ̀rọ̀ Jáde

Ìròyìn Bibeli kò dárúkọ ọmọbìnrin kékeré náà. Ó di ọmọ ọ̀dọ̀ fún ìyàwó Naamani, akíkanjú olórí ogun lábẹ́ Ọba Benhadadi Kejì. (2 Awọn Ọba 5:1) Bí a tilẹ̀ kà á sí púpọ̀, Naamani ní àrùn ẹ̀tẹ̀ akóninírìíra.

Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé bí ọmọdébìnrin náà ṣe ń hùwà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni ó mú kí ìyàwó Naamani finú hàn án. Obìnrin náà ti lè béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin náà pé, ‘Kí ni a máa ń ṣe fún àwọn adẹ́tẹ̀ ní Israeli?’ Omidan ọmọ Israeli yìí kò tijú láti sọ tìgboyàtìgboyà pé: “Oluwa mi ì bá wà níwájú wòlíì tí ń bẹ ní Samaria! Ní tòótọ́ òun ì bá wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”—2 Awọn Ọba 5:3.

A kò kó ọ̀rọ̀ ọmọdébìnrin yìí dà nù gẹ́gẹ́ bí èrò ọmọdé. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ròyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Ọba Benhadadi, ẹni tí ó rán Naamani àti àwọn mìíràn lọ ìrìn àjò oníkìlómítà 150 sí Samaria láti wá wòlíì yìí rí.—2 Awọn Ọba 5:4, 5.

Wíwo Naamani Sàn

Naamani àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọba Jehoramu ti Israeli, pẹ̀lú lẹ́tà ìfinimọni láti ọwọ́ Benhadadi àti ẹ̀bùn owó jíjọjú. Kò yani lẹ́nu pé, Ọba Jehoramu olùsin ère kò fi ìgbàgbọ́ tí ìránṣẹ́bìnrin náà fi hàn nínú wòlíì Ọlọrun hàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ronú pé Naamani wá fínràn ni. Nígbà tí Eliṣa, wòlíì Ọlọrun, gbọ́ nípa àìbalẹ̀ ọkàn Jehoramu, lójú ẹsẹ̀, ó ránṣẹ́ pé kí ọba jẹ́ kí Naamani wá sí ilé òun.—2 Awọn Ọba 5:6-8.

Nígbà tí Naamani dé ilé Eliṣa, wòlíì náà rán ońṣẹ́ kan sí i tí ó sọ fún un pé: “Wẹ̀ ní Jordani nígbà méje, ẹran ara rẹ yóò sì tún bọ̀ sípò fún ọ, ìwọ óò sì mọ́.” (2 Awọn Ọba 5:9, 10) Inú bí Naamani. Ní fífojú sọ́nà fún ìwòsàn oníṣẹ́ ìyanu àti aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀, ó béèrè pé: “Abana àti Farpari, àwọn odò Damasku kò ha dára ju gbogbo àwọn omi Israeli lọ? èmi kì í wẹ̀ nínú wọn kí èmí sì mọ́?” Naamani jáde kúrò ní ilé Eliṣa pẹ̀lú ìrunú. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Naamani ronú pẹ̀lú rẹ̀, ó gbà níkẹyìn. Lẹ́yìn wíwẹ̀ nínú Odò Jordani ní ìgbà méje, “ẹran ara rẹ̀ . . . tún padà bọ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹran ara ọmọ kékeré, òún sì mọ́.”—2 Awọn Ọba 5:11-14.

Nígbà tí ó padà sọ́dọ̀ Eliṣa, Naamani sọ pé: “Wò ó, nísinsìnyí ni mo tó mọ̀ pé, Kò sí Ọlọrun ní gbogbo ayé, bí kò ṣe ní Israeli.” Naamani jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun kì yóò tún “rúbọ sí àwọn ọlọrun mìíràn, bí kò ṣe sí Oluwa.”—2 Awọn Ọba 5:15-17.

Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́

Naamani kì bá tí lọ sọ́dọ̀ wòlíì Eliṣa ká sọ pé ìránṣẹ́bìnrin kékeré kan kò fi ìgboyà sọ̀rọ̀ jáde. Lónìí, ọ̀pọ̀ èwe ń hùwà lọ́nà jíjọra. Ní ilé ẹ̀kọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọrun lè yí wọn ká. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ jáde nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Díẹ̀ nínú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ orí tí ó kéré jọjọ.

Gbé ọ̀ràn Alexandra, ọmọdébìnrin ọlọ́dún márùn-ún kan ní Australia yẹ̀ wò. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́, ìyá rẹ̀ ṣètò láti lọ ṣàlàyé èrò ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún olùkọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu ń bọ̀ fún ìyá Alexandra. Olùkọ́ náà sọ pé: “Mo ti mọ púpọ̀ nínú èrò ìgbàgbọ́ yín tẹ́lẹ̀, títí kan ohun tí Alexandra yóò ṣe àti èyí tí kì yóò ṣe ní ilé ẹ̀kọ́.” Ẹnú ya ìyá Alexandra, níwọ̀n bí kò ti sí àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí mìíràn ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Olùkọ́ náà ṣàlàyé pé: “Alexandra ni ó sọ fún wa.” Bẹ́ẹ̀ ni, ọmọbìnrin kékeré yìí ti ní ìjíròrò tí a fọgbọ́n gbé kalẹ̀ pẹ̀lú olùkọ́ rẹ̀.

Irú àwọn èwe bẹ́ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ jáde tìgboyàtìgboyà. Wọ́n ń tipa báyìí hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Orin Dafidi 148:12, 13 sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn wúndíá, àwọn arúgbó ènìyàn àti àwọn ọmọdé. Kí wọn kí ó máa yin orúkọ Oluwa; nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá; ògo rẹ̀ borí ayé òun ọ̀run.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́