ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 6/15 ojú ìwé 10-13
  • Ó Ha Yẹ Kí Òye Rẹ Kún Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí Òye Rẹ Kún Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọ Kúlẹ̀kúlẹ̀ Ọ̀ràn
  • Èrò Rẹ Nípa Àwọn Ẹlòmíràn
  • Nínú Fífúnni Ní Nǹkan
  • Nígbà Tóo Bá Ń Gbani Nímọ̀ràn
  • Sapá Kí O Lè Ní Òye Kíkún
  • Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń wo Àwọn Èèyàn Lo Fi Ń Wò Wọ́n?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Nípìn-ín Nínú Ayọ̀ Tó Wà Nínú Fífúnni!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Àṣìṣe Àwọn Míì Mú Ẹ Kọsẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Nǹkan Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 6/15 ojú ìwé 10-13

Ó Ha Yẹ Kí Òye Rẹ Kún Bí?

ÌSẸ̀LẸ̀ runlérùnnà kan kọ lu ìlú Kobe níwọ̀ oòrùn Japan, lójú ẹsẹ̀, àwọn èèyàn yọ̀ǹda ara wọn tọkàntọkàn wá ṣèrànwọ́ fún àwọn olùgbé ibẹ̀ tí àjálù náà dé bá. Àmọ́ ṣá o, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ Ẹ̀ka Ètò Ìlera kọ̀, kò fún àwùjọ dókítà tó wà ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ ní ohun èlò ìtọ́jú ìṣègùn tí wọ́n nílò. Ọ̀gá yìí, tó tún jẹ́ ọ̀gá àgbà fún ilé ìwòsàn ńlá kan tó jẹ́ ti ìjọba, fẹ́ kí àwọn tó ń fẹ́ ìtọ́jú lọ sí ọsibítù tó wà ní Kobe dípò tí àwọn dókítà yóò fi máa fún wọn lábẹ́rẹ́ tó gbówó lórí, tí wọn yóò sì máa fami sí wọn lára ní àwọn ibùdó ìpèsè ìrànwọ́. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a fọwọ́ sí ohun tí àwọn dókítà náà fẹ́, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tinúmi-ni-màá-ṣe àti ìwà ọ̀dájú tí ọ̀gá náà ti kọ́kọ́ hù ti jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa níbi gbogbo.

Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó jẹ́ aláṣẹ ti hu irú ìwà yìí sí ọ rí. Ìwọ pàápàá sì ti lè hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ séèyàn. Ǹjẹ́ o lè jàǹfààní láti inú gbígbìyànjú láti lóye nǹkan ní kíkún bí?

Mọ Kúlẹ̀kúlẹ̀ Ọ̀ràn

Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀, apá kan nínú rẹ̀ làwọn èèyàn máa ń ronú lé lórí, tí wọn kò sì ní lóye ọ̀ràn náà délẹ̀délẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń fa èyí ni ẹ̀kọ́ ìwé, ìrírí téèyàn ti ní láyé, àti ipò àtilẹ̀wá. Ó ṣeé ṣe láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání bí ẹni kan bá sapá láti lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn náà. Fún àpẹẹrẹ, bóo bá fẹ́ sọdá ní ìkóríta tí ọkọ̀ ti ń kọjá firifiri, tí kò sì síná tí ń darí ètò ìrìnnà níbẹ̀, ǹjẹ́ yóò bọ́gbọ́n mu kóo kàn máa wo ọ̀kánkán gbọnrangandan? Ó dájú pé o kò ni ṣe bẹ́ẹ̀! Bákan náà, fífẹ́ lóye kíkún nípa ọ̀ràn kan lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu àti láti hùwà lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ó tilẹ̀ lè gbẹ̀mí ẹni là.

Àfàìmọ̀ ni kò fi ni jẹ́ pé gbogbo wa pátá ni a ní láti ṣàtúnṣe nínú ọ̀ràn yìí. Nítorí náà, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ibi tí mo ti lè jàǹfààní nípa mímú kí òye mi kún sí i?’

Èrò Rẹ Nípa Àwọn Ẹlòmíràn

Nígbà tóo bá ń wo àwọn ẹlòmíràn, kí lò ń rí? O ha máa ń gbà pé gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn ló dára tàbí gbogbo ẹ̀ pátá ló burú, bí ẹni pé wọn kò kù síbì kankan tàbí wọn kò níwà rere èyíkéyìí? Ṣé ọ̀rọ̀ ìwúrí ni lágbájá sọ àbọ́rọ̀ àbùkù? Ṣé bí tàmẹ̀dò ṣe hùwà dáa délẹ̀délẹ̀ àbí kò tilẹ̀ dáa pín-ìnpín-ìn? Bó bá jẹ́ pé irú èrò yẹn la ní, kò sóhun táa fi yàtọ̀ sí onífọ́tò kan tí kò ka onírúurú àwọ̀ mèremère tó wà nínú pápá ìgbà ìwọ́wé tó fẹ́ yà ní fọ́tò sí, tó gbà pé gbogbo àwọ̀ tó wà níbẹ̀ kò ju dúdú àti funfun lọ. Àbí ìwà tí o kórìíra lára ẹnì kan ló máa ń ronú nípa rẹ̀ ṣáá, bíi ti arìnrìn-àjò kan tó jẹ́ kí ìdọ̀tí tí àwọn àlejò kan tí kò ka nǹkan sí dà sílẹ̀ bá ayọ̀ àwọn ohun rírẹwà tí òun ń rí jẹ́.—Fi wé Oníwàásù 7:16.

Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ báa bá gbé ojú tí Jèhófà fi ń wo àṣìṣe ẹ̀dá yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé a ní ọ̀pọ̀ ìkùdíẹ̀-káàtó, tí a sì ń ṣàṣìṣe, kì í gbé ìyẹn sọ́kàn rárá. Onísáàmù náà tó moore sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, . . . Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3.) Jèhófà ṣe tán láti mú àṣìṣe jìnnà sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ti ronú pìwà dà, àní ó ṣe tán láti pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà rẹ́ pátápátá, kí wọ́n má bàa kó àbààwọ́n bá ìbátan tó wà láàárín òun àti àwọn èèyàn. (Sáàmù 51:1; 103:12) Jèhófà lè sọ nípa Dáfídì Ọba, ẹni tó jẹ́ pé nígbà kan ó dẹ́ṣẹ̀ ńlá pẹ̀lú Bátí-ṣébà, pé, ó jẹ́ ọkùnrin “tí ó . . . fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ tọ̀ mí lẹ́yìn nípa ṣíṣe kìkì ohun tí ó tọ́ ní ojú mi.” (1 Àwọn Ọba 14:8) Èé ṣe tí Ọlọ́run fi lè sọ èyí nípa Dáfídì? Nítorí pé ó ronú lórí àwọn ànímọ́ rere tí Dáfídì tó ti ronú pìwà dà ní. Ó ronú lórí gbogbo àwọn kókó pàtàkì, ó sì yàn láti fi àánú hàn sí ìránṣẹ́ rẹ̀.

Lọ́nà pípé, irú ojú yìí ní Kristi Jésù fi ń wo àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn. (Jòhánù 5:19) Nígbà tó rí àléébù àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Jésù fi àánú àti ìgbatẹnirò hàn. Ó mọ̀ pé ní ti ọ̀ràn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, nígbà tí ‘ẹ̀mí bá ń háragàgà, ẹran ara lè ṣe aláìlera.’ (Mátíù 26:41) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, Jésù fi sùúrù àti òye bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò nítorí ìkùdíẹ̀-káàtó àti àṣìṣe wọn. Kò darí gbogbo ìrònú rẹ̀ sórí ìkùdíẹ̀-káàtó wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, ó ronú lórí ànímọ́ rere tí wọ́n ní.

Nígbà kan, lẹ́yìn tí Jésù ti tọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ́nà nítorí pé wọ́n jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn, ó fi kún un pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan, kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” (Lúùkù 22:24-30) Bẹ́ẹ̀ ni, láìka ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn àpọ́sítélì sí, Jésù rántí ìṣòtítọ́ wọn àti ìfẹ́ tó ní sí wọn. (Òwe 17:17) Jésù ní ìgbọ́kànlé nínú ohun tí wọ́n lè ṣe àti ohun tí wọn yóò ṣe, nítorí náà ó bá wọn dá májẹ̀mú kan nípa Ìjọba. Bẹ́ẹ̀ ni, ‘Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé òpin.’—Jòhánù 13:1.

Nítorí náà bí ìwà ẹnì kan àti àṣìṣe rẹ̀ bá ń bí ọ nínú, fara wé Jèhófà àti Jésù. Gbìyànjú láti mọ ẹni náà délẹ̀délẹ̀, kí o sì gbé gbogbo àwọn kókó tó rọ̀ mọ́ ọn yẹ̀ wò. Nípa fífi àwọn nǹkan sí ipò to yẹ, yóò túbọ̀ rọrùn fún ọ láti lè fi ìfẹ́ hàn, kí o sì mọyì àwọn arákùnrin rẹ.

Nínú Fífúnni Ní Nǹkan

Àǹfààní fífúnni ní nǹkan tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí ń fúnni láyọ̀ tí a nawọ́ rẹ̀ sí àwọn Kristẹni. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó yẹ ká fi fífún tí a óò máa fúnni ní nǹkan mọ sórí ìgbòkègbodò kan ṣoṣo, fún àpẹẹrẹ ká fi mọ sórí lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá? (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Àbí o lè fi ohun tí àwọn kan nílò nípa ti ara àti ire wọn kún ohun tí o ti ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀? Àmọ́ ṣá o, gbogbo Kristẹni ló mọ̀ pé fífúnni ní nǹkan nípa tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù lọ. (Jòhánù 6:26, 27; Ìṣe 1:8) Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe pàtàkì láti máa fúnni ní nǹkan nípa tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣe pàtàkì láti máa fúnni ní nǹkan nípa tara.—Jákọ́bù 2:15, 16.

Báa bá ń ronú lórí àwọn ohun tí àwọn ará wa nípa tẹ̀mí nínú ìjọ wa àti jákèjádò ayé nílò ní kánjúkánjú, a óò lè rí ohun tí a lè túbọ̀ ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí àwọn tí wọ́n bá láǹfààní láti fi ìwà ọ̀làwọ́ ṣàjọpín ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn bá ṣe bẹ́ẹ̀, nǹkan kò ní fì síbì kan ju ibì kan lọ. Lọ́nà yìí a óò lè bójú tó àìní gbogbo àwọn arákùnrin wa. Kristẹni alàgbà kan sọ ọ́ lọ́nà yìí: “Bí àwọn ará ní apá kan nínú ayé bá ṣaláìní, àwọn ará ní apá ibòmíràn nínú ayé yóò wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àwọn yẹn kò bá sì lágbára àtiṣe é, àwọn ará níbòmíràn yóò ṣe é. Nípa báyìí a ń bójú tó ohun tí àwọn ará ṣaláìní káàkiri àgbáyé. Ká sòótọ́, àgbàyanu ẹgbẹ́ ni ẹgbẹ́ ará kárí ayé jẹ́.”—2 Kọ́ríńtì 8:13-15; 1 Pétérù 2:17.

Kristẹni arábìnrin kan tó lẹ́mìí àtilọ sí ọ̀kan lára àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé táa ṣe ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó gbọ́ pé àwọn ará tí wọ́n wà níbẹ̀ kò ní Bíbélì, ló bá fi owó ran ẹnì kan tó ń lọ sí àpéjọpọ̀ náà, pé kí ó bá òun fi ṣètọrẹ fún àwọn ara, kí wọ́n fi ra Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ní ayọ̀ fífúnni ní nǹkan, ìyẹn ni ti ṣíṣàjọpín ohun tó ní pẹ̀lú àwọn ará rẹ̀ tó wà nílẹ̀ òkèèrè.—Ìṣe 20:35.

Bóo bá ní òye kíkún, wàá lè túbọ̀ nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń gbòòrò sí i kárí ayé, wàá sì lè mú ara rẹ àti àwọn ẹlòmíràn láyọ̀.—Diutarónómì 15:7; Òwe 11:24; Fílípì 4:14-19.

Nígbà Tóo Bá Ń Gbani Nímọ̀ràn

Táa bá pè wá láti gbani nímọ̀ràn tàbí láti tọ́ni sọ́nà, ìrònú tí ń gba tẹni rò àti èyí tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jèrè ọ̀wọ̀ àwọn arákùnrin wa, kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́ gan-an. Ó rọrùn gidigidi láti ronú nípa kókó díẹ̀, kí a sì fi ìwàǹwára ṣe ìpinnu tó pọ̀n sápá kan. Báa bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí yóò jẹ́ káwọn èèyàn kà wá sí aláìgbatẹnirò, tàbí kí wọ́n kà wá sí ìkà èèyàn, bíi tàwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ Jésù, àwọn tí wọ́n di ẹrù òfin tí kò lóǹkà ru àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 23:2-4) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, báa bá yẹra fún àṣejù, tí a sì pèsè ìmọ̀ràn rere tí a gbé ka ìlànà Ìwé Mímọ́, tí ó fi ọ̀nà ìrònú Jèhófà tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó sì jẹ́ ti aláàánú hàn, yóò túbọ̀ rọrùn fún àwọn ẹlòmíràn láti gba ìmọ̀ràn wa, kí wọ́n sì fi wọ́n sílò.

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn àwọn ọ̀dọ́ arákùnrin láti inú ìjọ mélòó kan kóra jọ láti máa ṣeré ìdárayá. Ó dunni pé, ẹ̀mí ìbánidíje dìde láàárín wọn, ó sì yọrí sí pé kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ burúkú síra wọn. Báwo làwọn alàgbà ìjọ àdúgbò ṣe yanjú rẹ̀? Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ nílò eré ìnàjú, wọ́n ò sọ pé kí wọ́n má ṣeré ìdárayá mọ́. (Éfésù 5:17; 1 Tímótì 4:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n fún wọn ní ìkìlọ̀ tó rinlẹ̀, tó mọ́gbọ́n dání nípa ohun tí ẹ̀mí ìbánidíje lè yọrí sí. Wọ́n tilẹ̀ tún pèsè ìmọ̀ràn tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, irú bíi níní àwọn tó dàgbà díẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán láàárín wọn. Àwọn èwe náà mọrírì ọgbọ́n àti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì tó wà nínú ìmọ̀ràn náà, wọ́n sì ṣègbọràn. Ní àfikún sí i, ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ tí wọ́n ní fún àwọn alàgbà wá pọ̀ sí i.

Sapá Kí O Lè Ní Òye Kíkún

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè máà ní ẹ̀tanú lọ́kàn, o ní láti sapá gidigidi láti lè mú kí òye rẹ̀ kún. Bí o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, máa ṣàṣàrò lé e lórí, kí o lè lóye ọ̀nà ìrònú Jèhófà, kí o sì mọrírì rẹ̀. (Sáàmù 139:17) Gbìyànjú láti lóye ìdí táa fi lo gbólóhùn kan nínú Bíbélì àti ìlànà tó wé mọ́ ọn, kí o sì sapá láti fara balẹ̀ yẹ àwọn ọ̀ràn wò, bí Jèhófà ti máa ń ṣe. Èyí yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Dáfídì pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi.”—Sáàmù 25:4, 5.

Bí o ti ń mú òye kíkún dàgbà, a óò bù kún ọ. Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tó wà nínú mímú òye kíkún dàgbà ni pé, àwọn èèyàn yóò máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ pé o jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti olóye. Wàá lè fọgbọ́n àti òye hùwà nígbà tí o bá ń ṣèrànlọ́wọ́ nínú ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹ̀wẹ̀, èyí yóò fi kún ìṣọ̀kan àgbàyanu àti ìrẹ́pọ̀ tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará Kristẹni.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Fífi ìwà ọ̀làwọ́ fúnni ní nǹkan ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, ó ń mú ayọ̀ wá fẹ́ni tí ń fúnni, ó sì dùn mọ́ Baba wa ọ̀run nínú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́