Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Nǹkan Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?
“Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà.”—RÓÒMÙ 12:2.
1, 2. Bá a ṣe ń sún mọ́ Jèhófà, kí la máa bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀? Ṣàpèjúwe.
Ẹ FỌKÀN yàwòrán ọmọdé kan tí ẹnì kan fún lẹ́bùn, tí àwọn òbí rẹ̀ wá sọ fún un pé kó dúpẹ́. Lọmọ náà bá dúpẹ́ torí pé àwọn òbí rẹ̀ ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà sí i lá túbọ̀ máa lóye ìdí táwọn òbí rẹ̀ fi ní kó máa dúpẹ́ oore. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, òun fúnra ẹ̀ á máa dúpẹ́ oore láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni sọ fún un.
2 Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn, nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, a kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn òfin tó fún wa. Àmọ́ bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, a bẹ̀rẹ̀ sí í fòye mọ èrò rẹ̀, ìyẹn àwọn ohun tó fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́ tó fi mọ́ ojú tó fi ń wo nǹkan. Torí náà, táwa náà bá ń fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó, tá a sì ń jẹ́ kó hàn nínú ìwà wa àtàwọn ìpinnu tá à ń ṣe, ìyẹn á fi hàn pé à ń jẹ́ kí èrò Jèhófà darí wa.
3. Kí nìdí tí kò fi rọrùn láti máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó?
3 Òótọ́ ni pé inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tá a sì ń mọ èrò rẹ̀. Síbẹ̀, kò rọrùn láti máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó torí pé aláìpé ni wá. Bí àpẹẹrẹ, a mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìṣekúṣe, kíkó ohun ìní jọ, iṣẹ́ ìwàásù, gbígba ẹ̀jẹ̀ sára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀, a lè má lóye ìdí tí Jèhófà fi ń fi irú ojú yẹn wò wọ́n. Kí wá la lè ṣe ká lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó? Báwo sì nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?
BÓ O ṢE LÈ MÁA FOJÚ TÍ JÈHÓFÀ FI Ń WO NǸKAN WÒ Ó
4. Kí ló túmọ̀ sí láti ‘yí èrò inú wa pa dà’?
4 Ka Róòmù 12:2. Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ àwọn ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a rí i pé ká tó lè “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí,” a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba èrò ayé. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ó yẹ ká ‘yí èrò inú wa pa dà.’ Ìyẹn gba pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká lè mọ ohun tó fẹ́ ká ṣe, yàtọ̀ síyẹn ká ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́, ká sì jẹ́ kí èrò rẹ̀ máa darí wa.
5. Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú kéèyàn máa kàwé lóréfèé àti kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́?
5 Kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ kọjá kéèyàn kàn máa kàwé lóréfèé tàbí kó kàn máa fa ìlà sídìí àwọn ìdáhùn. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ ká ronú lórí ohun tí ibẹ̀ kọ́ wa nípa Jèhófà àti ojú tó fi ń wo nǹkan. Ó tún yẹ ká ronú jinlẹ̀ ká lè lóye ìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé ká ṣe àwọn nǹkan kan àti ìdí tó fi sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan míì. Kò tán síbẹ̀ o, ó yẹ ká ronú lórí ibi tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe nínú èrò wa àti nínú ìṣe wa. Òótọ́ ni pé, ó lè má rọrùn láti ronú lórí gbogbo nǹkan yìí ní gbogbo ìgbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ àá jàǹfààní gan-an tá a bá ń lo ìdajì nínú àkókò tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà.—Sm. 119:97; 1 Tím. 4:15.
6. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
6 Bá a ṣe túbọ̀ ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa “ṣàwárí fúnra” wa pé àwọn ìlànà Jèhófà ló dáa jù. Àá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ohun tó jẹ́ èrò Jèhófà lórí àwọn nǹkan, àwa náà á sì gbà pé èrò Jèhófà ló bọ́gbọ́n mu jù lọ. Ìyẹn máa jẹ́ ká ‘yí èrò inú wa pa dà,’ àá sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Díẹ̀díẹ̀, àá máa jẹ́ kí èrò Jèhófà darí wa.
OHUN TÁ A BÁ Ń RÒ LA MÁA Ń HÙ NÍWÀ
7, 8. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo nǹkan tara? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Tá a bá ń fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan tara wò ó, kí lohun tá a máa kà sí pàtàkì jù?
7 Kò sí àní-àní pé ohun tá a bá ń rò ló máa pinnu ohun tá a máa ṣe. (Máàkù 7:21-23; Ják. 2:17) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan tó máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye kókó yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan tara. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yan Jósẹ́fù àti Màríà láti jẹ́ òbí Jésù bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lówó lọ́wọ́. (Léf. 12:8; Lúùkù 2:24) Nígbà tí wọ́n bí Jésù, Màríà “tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran kan, nítorí pé kò sí àyè fún wọn nínú yàrá ibùwọ̀.” (Lúùkù 2:7) Ká sọ pé Jèhófà fẹ́ ni, ó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu kí Màríà lè bí Jésù sí ibi tó dáa tó sì tura. Àmọ́ ìyẹn kọ́ ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà, ohun tó ṣe pàtàkì sí i ni pé kí Jésù dàgbà nínú ìdílé tí wọ́n ti fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run.
8 Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbí Jésù jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan tara. Àwọn òbí kan máa ń fi dandan lé e pé àfi káwọn ọmọ wọn rí towó ṣe tíyẹn bá tiẹ̀ máa kó bá àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà. Bó ti wù kó rí, ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà ni àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀. Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan tara lo fi ń wò ó? Ṣé ìwà àti ìṣe rẹ fi hàn bẹ́ẹ̀?—Ka Hébérù 13:5.
9, 10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo mímú àwọn míì kọsẹ̀ làwa náà fi ń wò ó?
9 Àpẹẹrẹ míì ni ojú tí Ọlọ́run fi ń wo mímú àwọn míì kọsẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí tí wọ́n gbà gbọ́ kọsẹ̀, yóò sàn fún un bí a bá gbé ọlọ irúfẹ́ èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí kọ́ ọrùn rẹ̀, kí a sì gbé e sọ sínú òkun ní ti gidi.” (Máàkù 9:42) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ọ̀ràn ńlá ni téèyàn bá mú àwọn míì kọsẹ̀. Níwọ̀n bí Jésù ti fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan, ó dájú pé Jèhófà náà kórìíra kẹ́nì kan fi àìbìkítà hùwà tó máa mú kí ẹlòmíì kọsẹ̀.—Jòh. 14:9.
10 Ṣé ojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo mímú àwọn míì kọsẹ̀ làwa náà fi ń wò ó? Ṣé ó hàn nínú ìwà wa pé a ò fẹ́ mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, a lè nífẹ̀ẹ́ àtimáa wọ àwọn aṣọ kan tàbí múra láwọn ọ̀nà kan tó ṣeé ṣe kó máa kọ àwọn míì lóminú nínú ìjọ, ó sì lè jẹ́ pé irú aṣọ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ káwọn míì ro èròkerò. Ǹjẹ́ ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará máa mú ká yẹra fún wíwọ àwọn aṣọ bẹ́ẹ̀?—1 Tím. 2:9, 10.
11, 12. Tá a bá kórìíra ohun tí Jèhófà kórìíra, tá a sì ń kó ara wa níjàánu, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká yẹra fún ìwà burúkú?
11 Àpẹẹrẹ kẹta ni pé, Jèhófà kórìíra àìṣòdodo. (Aísá. 61:8) Lóòótọ́, Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá, ìyẹn sì lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe ohun tó tọ́, síbẹ̀ ó gbà wá níyànjú pé káwa náà kórìíra àìṣòdodo. (Ka Sáàmù 97:10.) Tá a bá ń ronú lórí ìdí tí Jèhófà fi kórìíra ìwàkiwà, àwa náà á rí ìdí tí àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ fi burú. Ìyẹn á sì jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé a ò ní lọ́wọ́ sí ìwàkiwà èyíkéyìí.
12 Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwàkiwà làwa náà fi ń wò ó, ìyẹn máa jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìwà kan burú bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ọ́ ní tààràtà. Bí àpẹẹrẹ, ijó fìdígbòdí ti ń gbèèràn gan-an nínú ayé. Àwọn kan máa ń sọ pé kò sóhun tó burú nínú ijókíjó yìí torí pé àwọn méjèèjì ò kúkú ní ìbálòpọ̀.a Àmọ́ ṣé Jèhófà tó kórìíra gbogbo onírúurú ìwà burúkú máa ní irú èrò bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé, tá a bá ń kó ara wa níjàánu, tá a sì kórìíra gbogbo nǹkan tí Jèhófà kórìíra, ìyẹn á jẹ́ ká yẹra pátápátá fún gbogbo ìwà burúkú.—Róòmù 12:9.
MÚRA SÍLẸ̀ DE OHUN TÓ LÈ ṢẸLẸ̀
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká ti ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan?
13 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe láwọn ipò kan. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká ṣèpinnu lójú ẹsẹ̀. Àmọ́, tá a bá ti pinnu ṣáájú ohun tá a máa ṣe, kò ní bá wa lójijì. (Òwe 22:3) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì.
14. Kí la rí kọ́ nínú bí Jósẹ́fù ṣe kọ̀ láti bá ìyàwó Pọ́tífárì ṣèṣekúṣe?
14 Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì fi ìlọ̀kulọ̀ lọ Jósẹ́fù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jósẹ́fù kọ̀. Ìyẹn fi hàn pé ó ti ronú dáadáa nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo jíjẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya ẹni. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:8, 9.) Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún ìyàwó Pọ́tífárì pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” Èyí jẹ́ ká rí i pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìṣekúṣe lòun náà fi wò ó. Ìwọ náà ńkọ́? Kí lo máa ṣe tí ẹnì kan níbi iṣẹ́ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹ tage? Tí ẹnì kan bá fi ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tàbí àwòrán ìhòòhò ránṣẹ́ sí ẹ lórí fóònù, kí ni wàá ṣe?b Tó o bá ti ronú ṣáájú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tó o sì ti pinnu ohun tí wàá ṣe, á rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó tọ́.
15. Báwo la ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bíi tàwọn Hébérù mẹ́ta náà?
15 Ẹ tún wo àpẹẹrẹ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Bí wọ́n ṣe kọ̀ jálẹ̀ láti forí balẹ̀ fún ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀ àti èsì tí wọ́n fún ọba náà fi hàn pé wọ́n ti ronú nípa ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Ẹ́kís. 20:4, 5; Dán. 3:4-6, 12, 16-18) Ká sọ pé ẹni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ sọ pé kó o dáwó fún ayẹyẹ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èké, kí ni wàá ṣe? Dípò tí wàá fi dúró kí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ kó o tó ronú nípa ohun tí wàá ṣe, á dáa kó o ti ronú nísinsìnyí nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe nírú ipò bẹ́ẹ̀. Tí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ bá wá ṣẹlẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó tọ́ bíi tàwọn Hébérù mẹ́ta náà.
Ṣé o ti ṣèwádìí, ṣé o ti kọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù nípa irú ìtọ́jú tó o fẹ́, ṣé o sì ti bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀? (Wo ìpínrọ̀ 16)
16. Tá a bá lóye èrò Jèhófà, kí nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe kí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì tó ṣẹlẹ̀?
16 Tá a bá ti ronú ohun tá a máa ṣe kí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì nípa ìlera tó ṣẹlẹ̀, àá lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Lóòótọ́, a ti pinnu pé a ò ní gba ẹ̀jẹ̀ tàbí èyíkéyìí lára àwọn èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ìtọ́jú kan wà tó la ẹ̀jẹ̀ lọ tó máa gba pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe ìpinnu tó bá ìlànà Bíbélì mu. (Ìṣe 15:28, 29) Kò ní dáa kó jẹ́ pé ìgbà tá a bá wà nílé ìwòsàn, tá à ń jẹ̀rora, táwọn dókítà sì ń fúngun mọ́ wa láti ṣèpinnu làá ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú ohun tá a máa ṣe. Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká ti ṣèwádìí, ká kọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù nípa irú ìtọ́jú tá a fẹ́, ká sì bá dókítà wa sọ̀rọ̀.c
17-19. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan? Sọ àwọn nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ táá gba pé ká ti múra sílẹ̀.
17 Lákòótán, nígbà tí Pétérù gba Jésù nímọ̀ràn tí kò mọ́gbọ́n dání pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa,” ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jésù fún un lésì. Ó ṣe kedere pé Jésù ti ronú ṣáájú nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa ìgbésí ayé àti ikú rẹ̀. Èyí ló mú kó túbọ̀ pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kó sì fẹ̀mí ara ẹ̀ rúbọ fún gbogbo èèyàn.—Ka Mátíù 16:21-23.
18 Lónìí, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, ká sì ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. (Mát. 6:33; 28:19, 20; Ják. 4:8) Bíi ti Pétérù, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì ronú pé ire wa làwọn ń wá lè máa rọ̀ wá pé ká bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn nǹkan míì. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọ̀gá ẹ fẹ́ fún ẹ ní ìgbéga, á sì tún fi kún owó ẹ, àmọ́ ìgbéga náà ò ní jẹ́ kó o fi bẹ́ẹ̀ ráyè fáwọn nǹkan tẹ̀mí, kí ni wàá ṣe? Tó bá jẹ́ pé ọmọléèwé ni ẹ́, tí wọ́n fún ẹ láǹfààní láti lọ kàwé sí i, tíyẹn sì máa gba pé kó o kúrò nílé lọ síbi tó jìn, kí ni wàá ṣe? Ṣé ìgbà yẹn ló yẹ kó o ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣèwádìí tàbí fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí ẹ̀ àtàwọn alàgbà kó o tó ṣèpinnu? Á dáa kó o mọ èrò Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, kó o sì pinnu ohun tí wàá ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Tó bá wá ṣẹlẹ̀, kò ní bá ẹ lábo. Ó ṣe tán, o ti pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló máa gbawájú láyé rẹ.
19 Ìwọ náà lè ronú àwọn nǹkan míì tó lè ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ táá sì dán ìgbàgbọ́ rẹ wò. Òótọ́ ni pé, a ò lè múra sílẹ̀ fún gbogbo nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Àmọ́ tá a bá ń ronú lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan nígbà tá à ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó máa rọrùn láti rántí ohun tá a ti kọ́ nígbà táwọn nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀. Torí náà, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, ẹ jẹ́ ká máa sapá láti mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, káwa náà sì máa fojú yẹn wò ó. Paríparí ẹ̀, ká ronú nípa bí ohun tá a ti kọ́ ṣe máa jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.
ÌLÀNÀ JÈHÓFÀ LÀÁ MÁA TẸ̀ LÉ NÍNÚ AYÉ TUNTUN
20, 21. (a) Kí lá mú ká gbádùn òmìnira wa nínú ayé tuntun? (b) Tá a bá fẹ́ láyọ̀ lónìí, kí ló yẹ ká ṣe?
20 Gbogbo wa là ń fojú sọ́nà fún ayé tuntun. À ń retí ìgbà tá a máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo aráyé máa bọ́ lọ́wọ́ wàhálà àti ìdààmú tó kúnnú ayé yìí. Gbogbo wa la máa lómìnira láti pinnu ohun tá a fẹ́. Ẹnì kọ̀ọ̀kan á lè ṣèpinnu tó wù ú.
21 Àmọ́, òmìnira wa ṣì máa láàlà nínú ayé tuntun. Tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ìlànà Jèhófà làwọn olóòótọ́ máa tẹ̀ lé. Ó dájú pé èyí á jẹ́ kí wọ́n láyọ̀, kí wọ́n sì gbádùn àlàáfíà tí kò lópin. (Sm. 37:11) Ní báyìí ná, a lè gbádùn irú ayọ̀ yìí tá a bá ń fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó.
a Ìwé kan sọ pé ijó fìdígbòdí ni kí “obìnrin kan tó wọ aṣọ péńpé jókòó sórí ẹsẹ̀ ọkùnrin kan tó jẹ́ oníbàárà, kó sì máa jó sọ́tùn-ún sósì lórí ẹsẹ̀ onítọ̀hún.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn nǹkan yàtọ̀ síra, tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn alàgbà máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ náà burú débi tó fi máa gba pé kí wọ́n yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́ láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Tí Kristẹni kan bá ti lọ́wọ́ sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó lọ rí àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́.—Ják. 5:14, 15.
b Ó burú gan-an téèyàn bá ń fi ọ̀rọ̀, àwòrán tàbí fídíò tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn nǹkan yàtọ̀ síra, tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn alàgbà máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ náà burú débi tó fi máa gba pé kí wọ́n yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́ láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Kódà láwọn ibì kan, ìjọba máa ń ka àwọn ọmọdé tó bá ń fi ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù sí ọ̀daràn. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, lọ ka àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Fífi Ohun Tó Ń Mọ́kàn Fà sí Ìṣekúṣe Ránṣẹ́ Lórí Fóònù?” lórí ìkànnì jw.org/yo. (Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́.) O tún lè ka àpilẹ̀kọ náà “Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Fífi Ọ̀rọ̀ Ìṣekúṣe Ránṣẹ́ Lórí Fóònù” nínú Jí! January-February 2014, ojú ìwé 4 àti 5.
c Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, o lè wo ìwé How to Remain in God’s Love, ojú ìwé 246 sí 249 lédè Gẹ̀ẹ́sì.