ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 6/15 ojú ìwé 8-9
  • Ìfẹ́ Tí A ní Sí “Àwọn Tí Ó Bá Wa Tan Nínú Ìgbàgbọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́ Tí A ní Sí “Àwọn Tí Ó Bá Wa Tan Nínú Ìgbàgbọ́”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 6/15 ojú ìwé 8-9

Ìfẹ́ Tí A ní Sí “Àwọn Tí Ó Bá Wa Tan Nínú Ìgbàgbọ́”

ÀWỌN ojúlówó Kristẹni ní ohun kan tó dè wọ́n pa pọ̀ bí ìdílé kan. Ní tòótọ́, láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ni wọ́n ti ń pe ara wọn ní “arákùnrin” àti “arábìnrin.” (Máàkù 3:31-35; Fílémónì 1, 2) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń ṣàpèjúwe ojú táwọn olùjọsìn Ọlọ́run fi ń wo ara wọn lẹ́nì kìíní kejì. (Fi wé 1 Jòhánù 4:7, 8.) Jésù wí pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.

Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn kedere ní July 1997 nígbà tí ọ̀gbẹlẹ̀ ńlá kan ṣẹlẹ̀, tí àrọ̀ọ̀dá òjò àti omíyalé wá tẹ̀ lé e ní ilẹ̀ Chile. Lójijì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nílò oúnjẹ, aṣọ, àti àwọn nǹkan mìíràn. Nígbà àjálù, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Gálátíà, pé: “Ní ti gidi, nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”—Gálátíà 6:10.

Fún ìdí yìí, kíá ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò ara wọn láti wá nǹkan ṣe sí i. Wọ́n dá oúnjẹ, aṣọ, àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ jọ, wọ́n ṣà wọ́n, wọ́n dì wọ́n, wọ́n sì kó wọn lọ síbi tí jàǹbá náà ti ṣẹlẹ̀. Kódà àwọn ọmọdé kó ohun ìṣiré ránṣẹ́ láti fi ṣètọrẹ! Ìyàlẹ́nu bá arábìnrin kan nígbà tó rí i pé Gbọ̀ngàn Ìjọba kún fún ẹrù tí wọ́n fi ránṣẹ́. Ó sọ pé: “Ṣe ni mo kàn dúró, tí mo lanu, mi ò mọ̀ bóyá kí n máa rẹ́rìn-ín tàbí kí n máa ké. Àwọn nǹkan táa nílò gan-an rèé.”

Ṣùgbọ́n, lójijì, ni ìsẹ̀lẹ̀ bá sẹ̀ lápá kan àgbègbè kan náà tí omíyalé ṣẹ̀ṣẹ̀ gbá lọ. Ni ọ̀pọ̀ ilé bá tún wó palẹ̀. Ló bá tún di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò àwọn ìgbìmọ̀ mí-ìn láti bójú tó àwọn ìṣòro tó tún dìde. Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, tó jẹ́ pé kíkọ́ ilé ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n máa ń bójú tó, ló wá ń sá sókè sódò. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àwọn ilé mọ́ńbé—tí àwọn ará yàwòrán rẹ̀ tí wọ́n sì kọ́—ni wọ́n kọ́ lọ́fẹ̀ẹ́ fún àwọn tí ilé wọn ti wó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọ̀nyí kì í ṣe ilé ńlá, wọ́n ta yọ àwọn èyí táwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò fi ẹ̀yáwó kọ́, ilé tí wọn kò rẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí kò ní fèrèsé, tí wọn ò sì kùn.

Àwọn arákùnrin kan ti ọ̀nà jíjìn wá láti wá ṣèrànwọ́. Alága Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn kan fi ọjọ́ méjì gbáko ṣàbẹ̀wò síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà—bó tilẹ̀ jẹ́ pé àga onítáyà ló ń lò. Arákùnrin kan tó jẹ́ afọ́jú ṣiṣẹ́ kárakára, ó ń gbé àwọn ìtì igi lọ fún àwọn káfíńtà tó ń gé wọn. Arákùnrin kan tó jẹ́ adití á wá kó àwọn ìtì igi náà lọ síbi tí wọ́n á ti lò wọ́n.

Orí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kíyè sí ohun tó ń lọ wú nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ táwọn ará pèsè. Ní ìlú kan, ọkọ̀ ọlọ́pàá kan dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé arábìnrin kan tí a ń tún kọ́ lọ́wọ́. Àwọn ọlọ́pàá náà fẹ́ mọ ohun tí ń lọ. Ọ̀kan lára wọn bi arákùnrin kan léèrè pé: “Àwọn wo lòṣìṣẹ́ aláyọ̀ yìí, èló sì ni wọ́n ń gbà?” Arákùnrin náà ṣàlàyé pé wọ́n yọ̀ǹda ara wọn ni. Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà ṣàlàyé pé òṣooṣù lòun ń san ìdámẹ́wàá fún ṣọ́ọ̀ṣì òun, síbẹ̀ pásítọ̀ òun kò tíì dé ọ̀dọ̀ òun láti ìgbà ìsẹ̀lẹ̀ náà! Lọ́jọ́ kejì, ọ̀gá ọlọ́pàá kan fóònù arábìnrin náà. Òun náà ti wá wo àwọn òṣìṣẹ́ náà. Ó sọ pé ẹ̀mí ìtara àwọn òṣìṣẹ́ náà wọ òun lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi ṣe òun bí ẹni pé kóun máa bá wọn ṣiṣẹ́ náà!

Ká sòótọ́, iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ táa ṣe ní Chile jẹ́ ìrírí aláyọ̀ fún àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn, ó sì tún jẹ́ ẹ̀rí ńláǹlà fún àwọn tó ń kíyè sí ohun tó ń lọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́