Ìwà Bàsèjẹ́ Lè Dópin
“OJÚ táa sábà fi ń wo ìwà bàsèjẹ́ àwọn ọ̀dọ́langba ni pé ó jẹ́ ọ̀nà àtifi ìwà àìlọ́wọ̀ àti ẹ̀hónú wọn hàn sí àwọn àgbàlagbà àti ọ̀pá ìdiwọ̀n wọn,” èyí ni àlàyé àwọn òǹṣèwé náà, Jane Norman àti Myron W. Harris. Àwọn òǹṣèwé náà ròyìn pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló gbà pé ọ̀ràn náà kò látùn-únṣe, “ẹyọ kan nínú mẹ́ta gbà pé a lè ṣẹ́pá ìwà bàsèjẹ́ àwọn ọ̀dọ́langba bí àwọn òbí bá túbọ̀ ń bójú tó àwọn ọmọ wọn, tí ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́langba kò bá sì dilẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mímú kí ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ dí, kí àwọn òbí sì túbọ̀ máa ṣàkóso wọn, lè dín ìwà bàsèjẹ́ kù, ṣé ìyẹn nìkan ni ojútùú ìṣòro náà?
Nígbà táwọn ọ̀dọ́ bá dá wà, ọ̀pọ̀ nínú wọn kì í fàjọ̀ngbọ̀n, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá wà láàárín àwọn ẹlẹgbẹ́ tàbí ojúgbà wọn, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun táwọn èèyàn yóò fi mọ̀ pé àwọn wà nítòsí, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí hùwà tí kò ní láárí, ìwà òṣì. Bọ́ràn Nelson ṣe rí rèé, nígbà tó bá ti lo àwọn oògùn olóró tán, tàbí tó ti mutí yó, á wá bẹ̀rẹ̀ sí fìbínú hàn nípa bíba nǹkan jẹ́. Nígbà tí ìwàásù nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nípa àtúnṣe sí òfin dídi onílẹ̀ àti ẹ̀tọ́ àwọn òṣìṣẹ́ bá kó sí José lórí tán, á wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ó yẹ kóun kópa nínú ìyanṣẹ́lódì, kóun sì ṣètò báwọn èèyàn yóò ṣe ba nǹkan jẹ́ lọ́nà tó bùáyà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àtifi ẹ̀hónú hàn. Ṣùgbọ́n, Nelson àti José rí ohun kan tó dáa gan-an ju ìwọ́de àti ìwà bàsèjẹ́.
Àwọn Olórí Ohun Tí Ń Fa Ìwà Bàsèjẹ́
Ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìdí táwọn ọ̀dọ́ kan fi ń lọ́wọ́ sí ìwà bàsèjẹ́. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni ọkàn wọn ti dà rú, wọ́n sì “sọ pé ayé jẹ́ ibi rúdurùdu, ibi rádaràda, tó kún fún àwọn èèyàn rádaràda.” Síbẹ̀síbẹ̀, yàtọ̀ pátápátá sóhun táwọn kan gbà gbọ́, ìròyìn kan sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́langba ń ṣàníyàn nípa ibi tí ìgbésí ayé wọn dorí kọ. Ominú ń kọ wọ́n ju bí àwọn àgbà ti rò lọ.” Wọ́n mọ̀ o, wọn ò mọ̀ o, ọ̀dọ́ tó bá ń lọ́wọ́ nínú ìwà bàsèjẹ́ lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìjákulẹ̀ ńláǹlà, àwọn ìṣòro tí wọn kò rójútùú sí, tàbí nítorí àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n ní tí wọn kò ní. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ ti wí, “kò sí ìkankan lára àwọn táa bá sọ̀rọ̀ tó sọ pé ìwà bàsèjẹ́ dáa, kódà àwọn tó tilẹ̀ [ti] hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò sọ pé ó dáa.”
Ó lè jẹ́ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ọ̀dọ́ kan ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìmọrírì àti ìṣírí. Níwọ̀n bí ẹ̀kọ́ ti túbọ̀ ń ṣe kókó, tí iṣẹ́ púpọ̀ sí i ń béèrè fún ìmọ̀ ìwé gíga tàbí òye iṣẹ́ tó jáfáfá, ẹ̀rù lè máa bà á. Síwájú sí i, àwọn òbí, olùkọ́, tàbí àwọn ojúgbà lè má fi í lọ́rùn sílẹ̀, kí wọ́n máa béèrè ju ohun tí agbára rẹ̀ lè gbé, kí wọ́n máa tẹnu mọ́ àṣeyọrí ọ̀dọ́ náà, dípò ẹni tí òun jẹ́ gan-an. Ọ̀pọ̀ ló ń di ọlọ̀tẹ̀ tàbí bàsèjẹ́ kìkì nítorí pé wọ́n nímọ̀lára pé wọn ò ṣe tó bó ṣe yẹ. Ǹjẹ́ ìfẹ́ àti àfiyèsí àwọn òbí kò ní dín irú ìdààmú bẹ́ẹ̀ kù gan-an?
O lè ti ṣàkíyèsí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ kan ti jọ̀gọ̀nù nípa gbígbìyànjú láti ṣàkóso kíkọ ìkọkúkọ àti àwọn ìwà ìpátá mìíràn, àwọn èèyàn tọ́ràn náà ń dùn ṣì ń retí pé káwọn olùkọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ iléèwé ṣàkóso ìwà bàsèjẹ́. Nípa òfin, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, sọ pé: “Èèyàn lè sanwó ìtanràn tàbí kó lọ sẹ́wọ̀n nítorí ìwà bàsèjẹ́. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan ní àwọn òfin tó là á sílẹ̀ pé báwọn ọmọ bá hùwà bàsèjẹ́, àwọn òbí wọn ni yóò forí fá a. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ ìwà bàsèjẹ́ ni kì í la ìyà lọ. Òfin kì í sábà ṣiṣẹ́ nínú irú ọ̀ràn wọ̀nyẹn, ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ irú ìwà bẹ́ẹ̀ ń náni kò sì tó ohun téèyàn lè tìtorí ẹ̀ pẹjọ́.” Ìròyìn kan fi hàn pé kìkì ìdá mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó rú irú òfin bẹ́ẹ̀ la máa ń mú.
Ìwọ náà kúkú gbà pé títọ́mọ ní àtọ́yanjú ló fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà rẹ́yìn ìwà ìpátá. Àmọ́ nígbà tí ìdílé bá dojú rú, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ló máa ń forí fá a. Ọ̀jọ̀gbọ́n Ana Luisa Vieira de Mattos, ti Yunifásítì São Paulo, nílẹ̀ Brazil, ṣàlàyé pé díẹ̀ lára ìdí táwọn ọ̀dọ́ fi níṣòro ni “àìráyè tọ́mọ, àìsí ìlànà, àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, pípa ọmọ tì, ìwà àgunlá tàbí àìbìkítà.”
Ní àkókò wa, ó dájú pé a ti rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mátíù 24:12) Ta ló wá lè sọ pé ọ̀rọ̀ inú 2 Tímótì 3:1-4 kò tíì ṣẹ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” Òkodoro ọ̀rọ̀ náà ni pé, wíwulẹ̀ gbé láàárín àwọn tó ní irú ìwà bẹ́ẹ̀ ń dá kún ìwà ìpátá. Ṣùgbọ́n kò wá yẹ ká jọ̀gọ̀nù. Ní gbogbo gbòò, ó ti ṣòro fún ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà láti mú ìwà bàsèjẹ́ kúrò, àmọ́ a lè rí àwọn èèyàn tó ti yí ìgbésí ayé wọn padà, wọn kì í ṣe oníwà játijàti tàbí oníjàgídíjàgan mọ́. Nínú ọ̀ràn tiwọn, ìwà bàsèjẹ́ ti dẹ́kun.
Ìtọ́sọ́nà Yíyèkooro fún Àwọn Ọ̀dọ́
Kí ló ti ran àwọn bàsèjẹ́ àti àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti yí ìwà wọn padà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ya àwọn olùkọ́ni àti àwọn òbí kan lẹ́nu, Bíbélì ló ń pèsè ìtọ́sọ́nà tó jíire, tó sì bóde mu. Nípa títẹ̀lé e, àwọn bàsèjẹ́ tẹ́lẹ̀ rí ti wá ń ṣègbọràn sí òfin tí Ọlọ́run là sílẹ̀ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.” (Ẹ́kísódù 23:2) Ọ̀pọ̀ ló ti fìfẹ́ hàn sí òtítọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa àwọn ẹ̀kọ́ àti ìgbàgbọ́ tí wọn kò lóye tẹ́lẹ̀, ohun tí wọ́n sì ti kọ́ ti tún ayé wọn ṣe. Ẹ jẹ́ ká gbé ìrírí José yẹ̀ wò, ọ̀dọ́ ni nílùú São Paulo. Inú ilé tí wọ́n ti ń lo àwọn ère nínú ìjọsìn ló dàgbà sí. Nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run, àti pé Òun kò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn ère, José yí padà kí ó lè máa ṣe ohun tó dáa lójú Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 20:4, 5; Sáàmù 83:18; 1 Jòhánù 5:21; Ìṣípayá 4:11.
Ní ti Nelson, kàkà tí ì bá fi máa ti orí ìrírí burúkú kan bọ́ sórí òmíràn nínú ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta àti nítorí lílọ́wọ́ nínú ìyanṣẹ́lódì, ó rí ìrètí tòótọ́ fún ọjọ́ iwájú, ìyẹn sì ti fọkàn rẹ̀ balẹ̀. Ó sọ pé: “Kàkà tí ìdílé mi ì bá fi ta mí nù nítorí ẹgbẹ́ búburú àti ìgbésí ayé ìjoògùnyó, nísinsìnyí èmi ni wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún jù lọ nínú ilé. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá mi máa ń sọ pé kí n gba àwọn ẹ̀gbọ́n mi nímọ̀ràn. Látìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ayọ̀ mi ti kún torí pé mo ti wá mọ ète ìgbésí ayé.” Àti ní ti Marco tí ń gbé nínú ìlú ńlá—tí gbígbé ní àyíká oníwà ipá ti mọ́ lára—mímọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run yóò sọ ilẹ̀ ayé di párádísè ti mú un lọ́kàn yọ̀ gan-an.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Tún gbé ọ̀ràn ọmọ kan yẹ̀ wò, tó wà lẹ́gbẹ́ jàǹdùkú, tó ń lọ́wọ́ sí dídàgbororú, tó sì jẹ́ bàsèjẹ́ tẹ́lẹ̀ rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ ọmọ òrukàn tí ìgbà ọmọdé rẹ̀ kún fún ìbànújẹ́, síbẹ̀ inú Valter dùn gan-an pé láàárín ètò oníwà ìbàjẹ́, oníwà burúkú yìí, Ọlọ́run ní àwọn èèyàn. Wọ́n ń fi tọkàntọkàn sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn, wọ́n ní ìyọ́nú, ìgbatẹnirò, àti inú rere. Valter ṣàlàyé pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣèlérí, nísinsìnyí mo ní ìdílé ńlá, ‘àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti ìyá àti bàbá.’ Ní ti ọjọ́ iwájú, mo ń wọ̀nà fún ìgbà táwọn èèyàn yóò máa gbé láyọ̀ àti ní ìrẹ́pọ̀ lábẹ́ àkóso òdodo Ọlọ́run.”—Máàkù 10:29, 30; Sáàmù 37:10, 11, 29.
Ohun Kan Tó Sàn Ju Ìwọ́de
Ní àfikún sí gbígba tẹni rò àti nínífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì, àwọn bàsèjẹ́ tẹ́lẹ̀ rí wọ̀nyí ti kọ́ bí a ti í “kórìíra ohun búburú.” (Sáàmù 97:10; Mátíù 7:12) Ìwọ ńkọ́? Àní bí o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ń jìyà nítorí ìwà bàsèjẹ́ tó tàn kálẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò jẹ́ kí Jèhófà jẹ́ ẹni gidi sí ọ gẹ́gẹ́ bíi Baba ọ̀run onífẹ̀ẹ́ tó bìkítà nípa rẹ. (1 Pétérù 5:6, 7) Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí, láìka àwọn ibi tí nǹkan ti kù díẹ̀ káàtó tàbí ipò òṣì sí. Ìyẹn alára jẹ́ ìrírí àgbàyanu!
Lóòótọ́ ni Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, fẹ́ kí gbogbo onírúurú èèyàn ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣe ju pé kó kàn ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣíwọ́ jíjẹ́ bàsèjẹ́ nísinsìnyí. Ó lè sún wọn láti tún tẹ̀ síwájú nínú fífi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, wọ́n yóò di mẹ́ńbà ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé, tí a mọ̀ sí oníwà mímọ́ àti ọmọlúwàbí, ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé. Ní ìbámu pẹ̀lú Éfésù 4:24, àwọn Kristẹni olóòótọ́ inú wọ̀nyí ti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” Láìpẹ́ ayé yóò kún fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn wọ̀nyí nìkan ni yóò là á já, tí yóò sì wà láàyè títí láé.—Fi wé Lúùkù 23:43.
Ayé Tuntun Níbi Tí Kò Ní Sí Ìwà Bàsèjẹ́ Ṣeé Ṣe
Ǹjẹ́ o gbà pé ìwà bàsèjẹ́ lè dópin lóòótọ́? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, báwo ní irú ìyípadà gígadabú bẹ́ẹ̀ ṣe lè wáyé? Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ètò burúkú yìí kúrò láìpẹ́. Àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò jíhìn fún mímọ̀ọ́mọ̀ rú òfin òdodo Ọlọ́run. (Fi wé Aísáyà 24:5, 6.) Nígbà tí “ó dájú pé a ó pa àwọn olùrélànàkọjá rẹ́ ráúráú lápapọ̀,” a óò dá àwọn tó fẹ́ràn òdodo nídè. “Jèhófà yóò . . . ràn wọ́n lọ́wọ́, yóò sì pèsè àsálà fún wọn. Òun yóò pèsè àsálà fún wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn burúkú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí pé wọ́n sá di í.”—Sáàmù 37:38-40.
Ní tòótọ́, a ó fa ìwà bàsèjẹ́ tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò. Bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe sí gbogbo ìwà ọ̀daràn, ìninilára, ìjìyà, àti ìwà burúkú. Dípò nǹkan wọ̀nyí, àlàáfíà, òdodo tòótọ́, ìparọ́rọ́, àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ni yóò jọba nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn nínú ayé tuntun. Aísáyà 32:18 ṣàpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ gan-an lọ́nà yìí: “Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.” Bẹ́ẹ̀ ni, párádísè ẹlẹ́wà tó kárí ayé ni àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn tó sì ń gba tẹni rò yóò máa gbé.
Pa pọ̀ pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn, ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn bàsèjẹ́ tẹ́lẹ̀ rí ti ń gbádùn ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Wọn kì í lọ́wọ́ nínú ìwà bàsèjẹ́ mọ́. Ṣé ìwọ náà á jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ọ̀nà ìyè tó lọ sí ayé tuntun rẹ̀ hàn ẹ́? O ò ṣe fìwà jọ onísáàmù ìgbàanì, tó ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà polongo, pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—Sáàmù 32:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí àwọn òbí bá ń bójú tó àwọn ọ̀dọ́, tí wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn sí wọn, èyí yóò dáàbò àwọn ọ̀dọ́