Ìwà Bàsèjẹ́—Kí Ló Ń Fà Á?
“MI Ò lọ́rọ̀ọ́ sọ.” A kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní lẹ́tà gàdàgbà-gadagba sára ògiri táa ṣẹ̀ṣẹ̀ kùn lọ́dà ládùúgbò kan tó gbayì nílùú São Paulo. Ìwà bàsèjẹ́ gbáà mà lèyí o, bóyá ìyẹn lèrò tó wá sí ẹ lọ́kàn. Kíkọ ìkọkúkọ sì jẹ́ ọ̀kan lára ìwà bàsèjẹ́.
Ká sọ pé àwọn bàsèjẹ́, àwọn èèyànkéèyàn kan ba ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tóo ṣẹ̀ṣẹ̀ rà jẹ́. Tàbí bóyá o ṣàkíyèsí pé wọn ti ba ohun ìní gbogbo ìlú—tó wúlò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀—jẹ́. Kí ló fà á? Àní, kí ni èrèdí sẹ́? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ti ronú rí nípa ìdí tí ìwà yìí fi wọ́pọ̀? Ní ibi púpọ̀, ó jọ pé inú àwọn èèyàn wọ̀nyí máa ń dùn láti ba àwọn ilé kótópó táa kọ́ fún tẹlifóònù jẹ́. Wọ́n sì tún máa ń dójú sọ àwọn ohun ìrìnnà tí ìjọba pèsè fún aráàlú, bíi rélùwéè tàbí àwọn bọ́ọ̀sì. Ó jọ pé àwọn kọ̀lọ̀rànsí wọ̀nyí kò bìkítà rárá nípa nǹkan kan. Ṣùgbọ́n kí ni okùnfà ọ̀pọ̀ ìwà bàsèjẹ́ táa ń rí, tàbí tó kàn wá?
Ìjákulẹ̀ dé bá Marco,a tí í ṣe ọ̀dọ́ kan láti ìlú Rio de Janeiro, nígbà tí wọ́n na ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀—ìjákulẹ̀ ọ̀hún pọ̀ débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀kò lu bọ́ọ̀sì àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó nà wọ́n. Tàbí, gbé ọ̀ràn Claus yẹ̀ wò. Nígbà tí kò ṣe dáadáa níléèwé, inú bí i débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀kò, ó sì fọ́ àwọn gíláàsì ojú fèrèsé. Àmọ́ o, kì í ṣe ọ̀ràn “eré” mọ́ nígbà tí wọ́n ní kí bàbá rẹ̀ sanwó ohun tọ́mọ rẹ̀ bà jẹ́. Ọ̀dọ́ mìíràn, tórúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Erwin, ń kàwé, ó sì ń ṣiṣẹ́. Ọmọlúwàbí làwọn èèyàn ń pe òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n tọ́wọ́ wọn bá ti dilẹ̀, wọn kò mọ̀ ju kí wọ́n máa ba nǹkan jẹ́ kiri àdúgbò. Àwọn òbí Erwin ò sì mọ̀ rárá pé itú tọ́mọ àwọn ń pa kiri nìyẹn. Valter jẹ́ ọmọ òrukàn, tó jẹ́ pé nítorí àìríbigbé, ó di ọmọ asùnta nílùú São Paulo. Àwọn bàsèjẹ́ ọmọọ̀ta làwọn tó ń bá rìn, ó tún ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń jà. Àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn pé àwọn èèyàn kì í dédé ya bàsèjẹ́, àti pé ọ̀kan-kò-jọ̀kan ni ohun tí ń fa irú ìwà yẹn, tàbí irú àwọn èrò tí ń gbin ìwà bàsèjẹ́ síni lọ́kàn.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, sọ pé: “Àwọn èèyàn lè máa hu ìwà bàsèjẹ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ ránró tàbí nítorí pé wọ́n fẹ́ fi ẹ̀hónú wọn hàn sáwọn olóṣèlú. Àtọmọdé àtàgbà ló ń hu ìwà ọ̀daràn yìí nígbà mìíràn, wọn á sì sọ pé àwọn kàn fi ‘ń ṣeré’ ni.” Ṣùgbọ́n, kàkà tí à bá fi pe ìwà ọ̀bàyéjẹ́ yìí ní erémọdé lásán, ó lè runlérùnnà, àní ó tilẹ̀ ń yọrí sí ikú. Àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kan fẹ́ “ṣeré,” fún ìdí yìí, nígbà tí wọ́n rí ọkùnrin kan tó sùn, wọ́n da nǹkan tó lè gbiná sí i lára, wọ́n sì ṣáná sí i. Ọkùnrin náà, tí í ṣe ọmọ Íńdíà, kú sí ọsibítù kan lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ti wí, “wọ́n ní àwọn ọ̀dọ́mọdé náà sọ pé àwọn kò rò pé ẹnikẹ́ni máa ka èyí sí nǹkan bàbàrà, ó ṣe tán, àìmọye àwọn oníbárà làwọn èèyàn ti dáná sun lójú pópó, tí kò sì sí nǹkan kan tó tìdí ẹ̀ yọ.” Ì báà jẹ́ pé ìwà yìí pa ẹnikẹ́ni lára tàbí kò pa ẹnikẹ́ni lára, ohun tó ń náni, ní ti owó àti ní ti ọ̀ràn èrò ìmọ̀lára, kò ṣeé kó. Nítorí náà, kí ló lè káwọ́ ìwà bàsèjẹ́, tàbí kó mú un wá sópin?
Ta Ló Lè Dá Ìwà Bàsèjẹ́ Dúró?
Àwọn ọlọ́pàá àti iléèwé ha lè dá ìwà bàsèjẹ́ dúró bí? Ìṣòro kan ni pé àwọn aláṣẹ lè máà rójú àwọn ìwà ìrúfin “tí kò pa ẹnikẹ́ni lára” níbi tí wọ́n ti ń sá sókè sódò nítorí àwọn ìwà ọ̀daràn tó lékenkà, bíi ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn egbòogi olóró tàbí ìpànìyàn. Ohun tí ọ̀gá ọlọ́pàá kan sọ ni pé, nígbà táwọn èwe bá wọ wàhálà, ṣe ni àwọn òbí máa “ń di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwọn ọmọ ọlọ́mọ tí wọ́n jọ́ ń kẹ́gbẹ́ kiri, tàbí iléèwé, tàbí àwọn ọlọ́pàá tó mú wọn.” Ẹ̀kọ́ àti mímú òfin ṣẹ lè dín ìwà bàsèjẹ́ kù; ṣùgbọ́n, bí ìrònú àwọn òbí kò bá yí padà ńkọ́? Ọ̀gá kan tó máa ń ṣèwádìí okùnfà ìwà àwọn jàǹdùkú ọmọ, sọ pé: “Ọwọ́ tó dilẹ̀ àti rírìn sákòókò rẹ̀ ló máa ń fà á. [Àwọn ọmọ wọ̀nyí máa] ń rìnru, wọn ò sì rí nǹkan kan ṣe. Ó sì jọ pé kò sẹ́ni tó ń mójú tó wọn—bó bá ṣe pé wọ́n lẹ́ni tó ń mójú tó wọn ni, wọn ò ní sí nígboro.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro ńlá ni ìwà bàsèjẹ́ lọ́pọ̀ ibi, ṣàkíyèsí ìyípadà tó lè wáyé. Àwọn ọmọ tó ya bàsèjẹ́ táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀, yí padà; nísinsìnyí, wọ́n ti yàgò pátápátá fún ìwà búburú láwùjọ. Kí ló mú káwọn jàǹdùkú tẹ́lẹ̀ rí wọ̀nyí yí ìgbésí ayé wọn padà? Pẹ̀lúpẹ̀lù, yóò ha yà ẹ́ lẹ́nu pé kì í ṣe kìkì pé ìwà bàsèjẹ́ yóò lọọ́lẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n pé yóò tilẹ̀ dópin pátápátá? Dákun, ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ padà.